Má sọ ààyè rẹ nù

Bawo ni o ti ṣe n lọ pẹlu rẹ? | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Erele 27, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 43

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Olurapada wa ọwọn. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun yi. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ṣe ọkan rẹ yẹ pẹlu rẹ ninu ọsẹ naa ati titi Jesu Oluwa wa yoo fi pade de. Amin.

Ọkan lara awọn nkan ti ẹni ti o kọ iwe Heberu tẹnumọ ninu gbogbo oju-ewe iwe naa ni pataki ki ijọ Ọlọrun kọọkan ma fi oju ṣọ awọn ọmọ ijọ rẹ. Ki si ni idi? Idi ni pe ki wọn ma ba ṣina ṣako lọ kuro ninu ifẹ Ọlọrun fun aye wọn ati ki wọn ma ba ba ilera ijọ jẹ tabi pa a lara. Nitorina, ti ọmọ ijọ rẹ kankan ba ṣiju si ọrọ aye rẹ, ti o si tun n bere awọn ibere ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ati igbagbọ rẹ lọwọ rẹ, ma fi ṣe ibinu tabi ki o bẹrẹ si ni bu wọn. Nṣe ni wọn n mu ofin Kirisiti ṣe lori aye rẹ (Galatia 6:2).

Wayi o, mi o wa sọ pe gbogbo awọn ti o wa ninu ijọ rẹ naa ni wọn loye to lati mọ awọn nkankan nipa aye rẹ tabi lati ṣe amulo ti o peye nkan ti o ba sọ fun wọn nipa ara rẹ. Mi o si tun so pe gbogbo ẹni ti o ba pe ara rẹ ni Kirisitiẹni naa ni o le fi ọrọ aye rẹ han. Ẹnikẹni, gẹgẹ bi ọrọ iwe mimọ, ti igbe aye igbagbọ rẹ ko ba han kedere si ọ lati ri, ki o ba le sọ daju pe ko ni ṣe ọ ni ijamba, fi idibajẹ saye rẹ tabi yan ọ jẹ, jẹ ẹni ti o yẹ ki o ṣọra fun. Ti o ba si wa woye pe ko si ẹnikẹni ninu ijọ rẹ ti o loye to lati mọ ohun ti o n lọ laye rẹ tabi lati ma fi oju ṣọ ẹ, nṣe ni ki o kuro nibẹ ki o si gba ijọ miran lọ ti iwọ yoo ti le turuka. Aijẹbẹ, ko ni pẹ ti o o fi pa igbagbọ tabi aye rẹ lara. (Wo: 2Kọrinnti 7:2)

Nitorina, fun anfaani ara rẹ, duro sinu ijọ ti o ba ti mọ pe o le turuka nibẹ fun awọn ara rẹ lati mọ bi o ti ṣe n lọ ninu aye rẹ ati lati ma fi oju ṣọ ọ. Lafikun, fun ilera ijọ Ọlọrun, o ṣe pataki ki o fi bi o ti ṣe n lọ ninu aye rẹ han awọn ara rẹ, ki o si tun jẹ ki wọn darapa mọ ọrọ ayẹ rẹ lọna ti o peye, ki wọn ba le ma fi gbogbo igba ran ọ lọwọ lati gbajumọ ṣiṣe ifẹ Ọlọrun.

Ki lo fa ti a ṣe ni ọpọlọpọ Kirisitiẹni ti igbagbọ wọn ko mọkun ati ti ko gboriduro ni ọpọ ijọ wa loni? Ki si ni idi ti a ti fi ri ọpọ ijọ wa ninu eyi ti awọn ara ti n ṣe ẹtanu ara wọn tabi ti wọn n fi gbogbo igba ja lori nkankan tabi omiran? Idi kan pataki fun eyi ni pe ọpọ wa ko fẹ ki awọn ara wa mọ nkan ti o n lọ ninu aye wa tabi ki wọn tun aye wa to? Nkan ti a fẹ ni ki a ma gbe aye wa bi o ti ṣe wu wa, lalai si ilọwọsi tabi idasi ẹnikẹni. Eyi ko si dara rara fun wa tabi fun ilera ijọ Ọlọrun.

Fun apẹẹrẹ, ẹni ti o kọ iwe Herebu sọ eyi fun wa: “Ẹ ma kiyesara ki ẹnikẹni ki o ma ṣe kuna oore-ọfẹ Ọlọrun; ki gbongbo ikoro kan ki o ma baa hu ṣoke ki o si yọ yin lẹnu, ọpọlọpọ a si ti ipa rẹ di aimọ; Ki ẹnikẹni ma baa di alagbere tabi alaiwa-bi-Ọlọrun bi Isọ, ẹni ti o ti itori okele ounjẹ kan ta ogun ibi rẹ.” (Heberu 12:15-16) Bawo ni a ṣe le kiyesara lati ri pe ọkankan ninu wa ko kuna oore-ọfẹ Ọlọrun, ti a ko ba mọ bi o ti ṣe n lọ ninu aye gbogbo wa? Bawo ni a ṣe le ri pe ikoro tabi iyapa ko ṣẹlẹ laarin wa, ti a ko ba mọ nkan ti o n ṣẹlẹ laarin wa? Tabi bawo ni a ṣe le ma jẹ ki awọn ara wa bọ sinu panpẹ agbere tabi ẹṣẹ miran ti o le ba aye tabi igbeyawo wọn jẹ, ti a ko ba mọ ohun ti o n lọ ninu aye wọn? Ko le ṣeeṣe fun wa.

Wo o, igba ti a ba ni oye ti o peye nkan ti o lọ ninu aye wa ni a le ran ara wa lọwọ lati duro ṣinṣin ninu igbagbọ ni ọna ti o peye. Bẹẹ si ni, igba ti a ba ni imọ ti o ye kooro awọn nkan ti o n lọ laarin ijọ wa ni a to le mojuto ilera ijọ Ọlọrun lọna ti o peye. Fun apẹẹrẹ, nigba ti ijọ bẹrẹ si ni pọ si ni iye ni awọn ọjọ wọnni, awọn apa kan lara wọn bẹrẹ si ni woye pe awọn aṣoju wọn ninu pipin ounjẹ ko mojuto awọn opo wọn bi o ti ṣe tọ ati yẹ. Ki wa ni wọn ṣe lori eyi? Wọn sọ fun awọn apọsiteli nipa rẹ, a si ri pe wọn mojuto ọrọ naa ni kiakia, ijọ si duro ṣinṣin si. Ka wa sọ pe wọn dakẹ lori ọrọ yi nkọ? Ko ni pẹ rara ti ikoro, ibinu, ikorira ati owu jijẹ yoo fi gba gbogbo ijọ kan, ti yoo si ba a jẹ. (Wo: Iṣe Apọsiteli 6:1-7)

Nitorina, fun ilẹra rẹ ninu ẹmi ati fun ilera ijọ Ọlọrun, jẹ ki bi o ti ṣe n lọ ninu aye rẹ ati pẹlu awọn ibaṣepọ rẹ jẹ mimọ si awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ninu aye rẹ. Ma si ṣe rin pẹlu erokoro ‘Ọrọ aye mi ko ki ṣe ẹjọ ẹnikankan’ tabi pẹlu ironu pe ko si ẹni ti ọrọ rẹ le ye tabi ti o le ran ọ lọwọ ti o ba tilẹ jẹ ki wọn mọ bi o ti ṣe n lọ. Ẹjọ gbogbo wa ni ọrọ aye rẹ. Ẹjọ tirẹ si ni lati ri pe a mọ ati pe a tun ni oye bi o ti ṣe n lọ ninu aye rẹ. Adura mi si ni pe ki Ẹmi Ọlọrun ṣe ọ ye lati ni oye ati lati ma rin ninu imọlẹ ọrọ yi ni gbogbo igba, ki o ma ba bọ sinu pakute Eṣu nikẹyinkẹyin tabi ki o di irinṣẹ rẹ lati pọn ijọ Ọlọrun loju.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *