Má sọ ààyè rẹ nù

Ẹbun ololufẹ | Paito J.O. Lawal

Ọjọ: Ẹrẹna 06, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 44

Olufẹ: ki oorẹ-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun miran ninu oṣu Ẹrẹna 2022. Adura mi si ni pe ki a kọ ọkan rẹ lati mọ ifẹ Ọlọrun siwaju ati siwaju si, ki o ba le ma fi gbogbo igba fi ara rẹ ati awọn nkan ini rẹ jin fun lalai fa sẹyin rara. Amin.

Ki ni idi ti Maria, arabinrin Mata, ṣe gbe keregbe ikunra oloorun didun ti o niye lori pupọ, ti o si tu gbogbo ikunra inu rẹ si ẹsẹ Jesu? Idi ni pe o fẹran rẹ gidigidi. Ki si ni idi ti o ṣe fẹran rẹ gidigidi? Idi ni pe Jesu naa ti fi ifẹ ailodiwọn han si arabinrin yi ati idile rẹ. Ranti pe ọrẹ ni Jesu jẹ si idile arabinrin yi, ti O si ma n fi gbogbo igba bẹ wọn wo lati mọ bi o ti ṣe n lọ pẹlu wọn, ti O si tun n yi aye wọn pada pẹlu awọn ẹkọ ti O n kọ wọn. Si ranti pẹlu pe Oun kan yi naa ni o ji arakunrin ọmọbinrin yi dide kuro ninu oku, lẹyin igba ti a ti gbe sinu iboji fun ọjọ mẹrin gbako. Ni ọjọ ti o si wa tu ikunra oniyebiye yi si ẹsẹ Jesu, nṣe ni a n ṣe ase lati mọ riri rẹ fun awọn nkan ti O ti ṣe fun idile naa.

Nitorina, nitoripe Maria ti mọ ifẹ Oluwa, ti o si tun ti jẹ igbadun rẹ ni o ṣe yẹẹ si pẹlu nkan ini rẹ bi o ti ṣe ṣe. Bi o tilẹ wa jẹ pe nkan ti o fi fun un yi jẹ nkan ti o niye lori pupọ, ti o niye lori debi pe O to san owo oṣu ẹnikan fun odidi ọdun kan, ko wo o pe o ti pọju lati lo lati yẹẹ si. Nitorina, Oluwa sọ wipe gbogbo ibi ti a ba ti waasu ihinrere ni agbaye ni a o ti ma sọ nkan ti arabinrin yi ṣe ni iranti rẹ. Idi naa si ni yi ti a ṣe n ka, ti a si tun ṣe n sọrọ nipa rẹ loni. (Wo: Matiu 26:6-13; Maaku 14:1-9; Johanu 12:1-8)

Nibakan naa, ti awa naa ba ti mọ ifẹ Oluwa, ti a si tun ti n gbadun rẹ, ti a ba ti gba aye wa la nitootọ, ti a si tun ti yi wọn pada nipasẹ ifẹ rẹ, o di dandan ki awa naa fẹ fi ifẹ han si pada. Ti o ba si ri bẹ, ko ki i ṣe aye wa nikan ni a o fẹ ki o jẹ tirẹ, a o tun fẹ ki ohun gbogbo ti a ni jẹ tirẹ pẹlu. Ki a ma tilẹ fa ọrọ gun, ko si nkan ti a ni ti a ro pe o pọju lati fifun un.

Wo bi a ti ṣe n mojuto awọn ibaṣepọ wa nipa ti ara, fun apẹẹrẹ. A ko ki i ṣaba bikita bi awọn nkan ti a ba fẹ fun ẹni ti a fẹran gidigidi ti ṣe wọn si. Dipo eyi, nkan ti a o ma bere lọwọ ara wa ni, “Njẹ owo ti o wa lọwọ mi to ra nkan yi?” Ti a ba si ti ri mọ pe a ni owo ti o to lati ra ohun yowu ti a ba fẹ fun ẹni naa ti a fẹran, nṣe ni a ra a ni kiakia lalai ṣeju pẹrẹ.

Ki ni koko nkan ti mo n ṣọ? Oun naa ni pe ti o ko ba ki fifun Oluwa ati ọrọ rẹ ni ọna ti o ga, o ṣeeṣe pe ifẹ rẹ si ni ko to nkan.Ti ifẹ rẹ si ba pọ gidigidi, wa a fun ni ohukohun lati yẹẹ si, lalai wo bi nkan naa ti ṣe wọn to tabi nkan ti awọn eniyan yoo sọ le lori. Awọn eniyan ṣaroye lori ẹbun Maria si Jesu. Wọn sọ pe o kan fi ṣofo ni. Wọn sọ pe ko mọ owo naa rara. Ṣugbọn ṣe o bikita? Rara! Ṣe Oluwa wa naa gan tilẹ bikita? Rara o. Dipo eyi, Oluwa sọ `pe, “Anfaani lati yẹ mi si ninu ifẹ bi eleyi ko ni fi gbogbo igba wa nibẹ fun yin. Amọ nisisiyi ti o wa nibẹ, arabinrin yi ti ṣe ohun ti o tọ nipa ṣiṣe amulo rẹ.”

Wo o, awọn olufẹ Ọlọrun tootọ nikan naa ni o ma ṣe idamọ awọn anfaani lati yẹ ẹ si pẹlu nkan ini wọn. Nitorina, ti iwọ ko ba i ti ma a ri anfaani lati yẹ Ọlọrun si pẹlu nkan ini rẹ, boya ni ọna ti o ga ni o tabi ni ọna ti o kere, o yẹ ki o yẹ itara ina ifẹ rẹ si i wo. Idi si ni pe ojoojumọ ni anfaani lati yẹ ẹ si ma n farahan. Amọ ṣa o, awọn ọkan ti o ba kun akunwọsilẹ pẹlu ifẹ si nikan naa ni yoo ri awọn anfaani yi, ti yoo si tun ṣe amulo wọn. Adura mi si ni pe ki a kun ọkan rẹ pẹlu ifẹ si i, ki iwọ naa ba le ma fi gbogbo igba da awọn anfaani lati yẹ ẹ si ni ọna ti awọn eniyan ko ni dẹkun lati ma sọrọ nipa mọ .

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *