Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun yi, eyi ti i ṣe ọsẹ ti o so oṣu Èbìbí ati Òkúdù pọ mọ ara wọn. Mo si gbadura pe ki ọkan rẹ ma fi igba gbogbo gba okun lati mu iṣẹ-iranṣẹ yowu ti Ọlọrun gbe le ọ lọwọ ninu ijọba rẹ ni ọkunkundun, ki o ma ba ja a kulẹ, ki o si tun padanu ere rẹ. Amin.
Jesu Oluwa wa ni igba kan ri sọ eyi fun awọn ọmọ ẹyin rẹ: “Ounjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹni ti o ran mi, ati lati pari iṣẹ rẹ.” (Jòhánù 4:34) Ni akoko miran ẹwẹ, O tun sọ eyi naa fun wọn: “Emi ko le ṣe alaiṣe iṣẹ ẹni ti o ran mi, nigba tii ṣe ọsan: oru n bọ wa nigba ti ẹnikan ki yoo le ṣe iṣẹ mọ.” (Jòhánù 9:4) Ki ni idi ti Jesu Oluwa wa fi sọrọ bi eyi? Lakọkọ, O sọ eyi nitoripe O mọ pe Ọlọrun gbe iṣẹ-iransẹ kan le Oun lọwọ lati gbe ṣe ninu aye yi. Ekeji, O ṣọ eyi nitoripe O mọ ojuṣe rẹ ni ojuṣe rẹ. Eyi lo si jẹ ki O mu iṣẹ iranṣẹ ti Ọlọrun fun ni ọkunkundun. Ẹkẹta, O sọ awọn nkan wọnyi nitoripe O mo wipe Oun ko ni gbogbo ayeraye lati ṣe iṣẹ ti Ọlọrun gbe fun un. Nitorina, ti ko ba gbajumọ iṣẹ naa, ki O si ṣe ni ‘ohun tí ó bá gbà ni a ó fún’, ko ni pari iṣẹ naa titi akoko rẹ ni aye yi yoo fi pari.
Ni bakanna, ẹnikọọkan wa naa ti gba iṣẹ iranṣẹ kan tabi omiran ni ọwọ Oluwa. Ẹnikọọkan wa ni o ni iṣẹ kan tabi omiran ti Ọlọrun ti yan fun un lati ṣe fun ati fun ijọba rẹ ni aye yi. Nkan ti bibeli ṣọ fun wa ni eyi. O wa ku si ọwọ wa lati mọ irufẹ iṣẹ-iranṣẹ ti a ti rigba lọwọ rẹ, ki a si bẹrẹ si ni ṣe pẹlu ifarabalẹ ati pẹlu imura lati pari rẹ ni akoko. Pọọlu, nigba ti o n ba awọn alagba ijọ Efesu sọrọ lori awọn nkan wọnyi, sọ eyi nipa ara rẹ: “Ṣugbọn emi ko ka ẹmi mi si nnkan bi ohun ti o ṣọwọn fun mi, ki emi ki o baa le fi ayọ pari ire-ije mi ati iṣẹ-iranṣẹ ti mo ti gba lọdọ Jesu Oluwa, lati maa royin iyinrere oore-ọfẹ Ọlọrun.” (Iṣe Apọsiteli 20:24)
Ṣe o ti wa ri pe afojusun ti Pọọlu ni fun aye rẹ ko yatọ rara si eyi ti Jesu Oluwa wa ni fun aye tirẹ naa? Afojusun Pọọlu naa ni fun lati ṣe ifẹ Ọlọrun pẹlu aye rẹ ati lati pari iṣẹ rẹ. Njẹ eyi yoo wa rọrun fun bi? Ko lero pe yoo rọrun fun oun. O tilẹ sọ wipe Ẹmi Mimọ ti kilọ fun oun tẹlẹ pe ki oun ma lero pe yoo rọrun fun oun (Ìṣẹ Àpọ́sítélì 20:22-23). Sibẹsibẹ, boya o rọrun fun o tabi ko rọrun fun, o pinnu lọkan rẹ lati ṣe ifẹ Ọlọrun pẹlu aye rẹ ni gbogbo ọna ati lati fi ifarabalẹ pari iṣẹ ti O gbe fun. Ki si ni idi? Idi ni pe o mọ wipe ẹni ti o pe oun, ti o si ya oun sọtọ fun ara rẹ yo ma fi igba gbogbo wa pẹlu oun ati pe yoo ri daju pe oun ṣe aṣeyọri.
Wayi o, ti awa naa ba mura lati rin pẹlu afiyesi ti Jesu Oluwa wa ati Pọọlu ni nipa gbigbe aye wa fun Ọlọrun ati ṣiṣe iṣẹ rẹ, ko si bi a o ṣe ja Ọlọrun kulẹ, bi o ti wu ki nkan le to tabi bi o ti wu ki nkan ma rọrun fun wa to. Amọ ṣe irufẹ ọkan ti a fi n gbe aye niyi bi? Njẹ a n gbe aye pẹlu afiyesi pe o yẹ ki a fi aye wa jin lati dun Ọlọrun ninu ati lati ṣe iṣẹ ti o gbe fun wa, iṣẹ yowu ti o le jẹ ati asiko yowu ti aye wa le wa?
Ti a ko ba ma rin pẹlu afiyesi yi, a kan n fi aye wa ṣofo ni. Lotitọ, o le ma dabi pe a n fi aye wa ṣofo, paapaa julọ ti awọn eniyan ba n yin wa fun awọn aṣeyọri ti a ti ṣe ni awọn abala aye wa kan. Ṣugbọn akoko n bọ, bi o ti ṣe de ba Jona, ti a o ri daju ṣaka pe inu ikun ẹja n la kan, ni inu okunkun birimu-birimu, nibi ti ko ti si èrè, nibi ti ko ti si oriyin, ni gbogbo ere ti a n sa lodi si ifẹ Ọlọrun yoo pari si. Igba yi gan ni a o to wa mọ pe asan lori asan ni gbogbo nkan ti a ti fi aye wa gbe ṣe. Adura mi wa ni pe ki ere-ije rẹ ati laalaa rẹ ninu aye yi ma ja si asan ni ikẹyinkẹyin, ni orukọ Jesu. Amọ iwọ naa gbọdọ tun afojusun rẹ ṣe, ti o ba mọ pe ko da lori bi iwọ yoo ṣe ṣe ifẹ Ọlọrun, ki o si pari iṣẹ ti O gbe fun ọ.
Ki o ni ọsẹ ti o ga.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
