Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òwewè 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ya ọkan rẹ ya ohun gbogbo ti ko tọ ti o n jẹ ki awọn ibaṣepọ rẹ kan, ti o si tun n di iriri didara rẹ lọwọ ninu aye rẹ. Amin.
Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti o ma n jẹ ki o ṣoro fun wa lati ni ibaṣepọ ti o larinrin pẹlu awọn ti o wa ninu aye wa ni imọtaraẹninikan. Ki ni imọtaraẹninikan? Imọtaraẹninikan ni ki a lọ fun nkan ti a fẹ lalai bikita nipa ọna ti yoo gba pa awọn miran lara. Eyi jasi pe, o ṣa fẹ nkan ti o fẹ ni, o ko si bikita boya eyi pa ẹnikẹni lara tabi pa wọn run.
Nitorina, imọtaraẹninikan ni ipilẹ fun gbogbo iwa ibi ti a n wu laye. Oun ni idi ti awọn eniyan ṣe n jale, ṣe iṣekuṣe, fi ipa bani lopọ, paniyan, ṣẹ oṣo owo ati bẹẹbẹẹ lọ. Wọn kan ṣa fẹ nkan ti wọn fẹ fun ara wọn ni. Wọn ko si bikita nipa nkan ti wọn nilo lati ṣe lati ni i ati bi ọna ti wọn gba lati ni nkan yi ṣe le pa awọn miran lara. Tara wọn nikan ni wọn mọ.
Imọtaraẹninikan, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, naa ni idi ti awọn eniyan ko ṣe le fi irẹpọ gbe ninu igbeyawo wọn, ni adugbo wọn, ni ibi iṣẹ wọn ati ninu ijọ Ọlọrun wọn pẹlu. Ohun kan ṣoṣo ti wọn ma n ro ko ju nkan ti wọn fẹ lọ ati bi wọn yoo ti ṣe ri i. Wọn ko ni ronu nipa bi oun ti wọn fẹ ati ọna ti wọn gba lati ri yoo ṣe pa awọn ti o wa pẹlu wọn tabi ni ayika wọn lara. Nitorina, o di dandan ki wọn ba atako pade, eyi ti o si le lewu tabi ki o na wọn ni nkan ti o pọ jọjọ.
Ni ọdun melokan ṣẹyin, oorun buruku kan ti ko ṣe farada rara ni o ki mi nigba ti mo pada de lati ibi iṣẹ. “Kini o ṣẹlẹ nibi?” mo bere lọwọ awọn ti a jọ n gbele. “Ki lo de ti oorun buruku yi ṣe gba ibi gbogbo kan?” Wọn si sọ fun mi pe awọn ara ile ti o wa lẹgbẹ wa ni o ko ṣalanga wọn, ti wọn si da omi rẹ si oju ọna wa.
Ki wa lo fa ti wọn ṣe ṣe eyi? Ṣe wọn ronu nipa bi nkan ti wọn ṣe yi ṣe le pa ilera wọn ati ti awọn aladugbo wọn lapapọ lara? Irọ o! Ṣe wọn tilẹ ro wipe oorun ti o n jade lati ipasẹ nkan ti wọn ṣe yi yoo le gbogbo awọn ti o wa ni adugbo kuro ni ile wọn? Irọ o! Awọn kan ṣa ri wipe iho ti o n gba omi ile igbọnsẹ wọn ti kun, o si nilo ki wọn ko o. Nitorina, wọn ko o, wọn si da a si oju ọna. Eyi si wa jẹ ki awọn aladugbo kan ke si awọn oṣiṣe eto ilera ti ijọba melokan lati wa bẹ wọn wo ati lati fun wọn ni ijiya ti o tọ.
Ki wa ni koko ọrọ mi? Oun naa ni pe imọtaraẹninikan yoo mu ki aye ṣoro fun iwọ ati awọn ti o wa ni ayika rẹ. Idi si ni yi ti ọrọ Ọlọrun ṣe sọ fun wa pe, “Ẹ ma ṣe ohunkohun ninu ilepa-ara tabi ogo asan, ṣugbọn ni irẹlẹ ọkan ki olukuluku ro awọn ẹlomiran si ẹni ti o san ju oun lọ. Ki olukuluku yin ma ṣe ro ohun ti ara rẹ nikan, ṣugbọn ti ẹlomiran pẹlu.” (Fílípì 2:3-4) Njẹ o ri bayẹn? Ti a ba fẹ alaafia ni ile wa, ni adugbo wa, ni ibi iṣẹ wa ati ninu ijọ wa, ẹnikọọkan wa ko gbọdọ ma lepa ohun ti o fẹ fun ara rẹ nikan ṣugbọn ohun ti awọn miran naa fẹ fun ara wọn pẹlu.
Se o ri, ti ko ba ki i ṣe ọrọ ti ara wa nikan ni a mọ, ti ọrọ ti awọn miran naa jẹ wa logun pẹlu, a o fi iṣọra ati oye ba wọn lopọ. Nitorina, a ko ni gbe igbesẹ ti yoo pa wọn run nigba ti a ba n gbiyanju lati tẹ ara wa lọrun tabi ki a ma fi ẹtanu ba wọn lo ti wọn ba nilo lati kọ lati fun wa ni awọn nkan kan ti a tọrọ lọwọ wọn. Ṣugbọn ti a ba n gbe igbesẹ ti o n pa aye tabi ayọ awọn miran run nitoripe a fẹ tẹ ara wa lọrun tabi ti a ba n sọ awọn miran di ọta wa nitoripe wọn ko fun wa ni awọn nkan kan ti a bẹbẹ fun (awọn nkan ti ko ki ṣe ẹtọ wa), nṣe ni a n rin ninu imọtaraẹninikan. Bi o ti wa wu ki a lọ soke to ni aye yi, ibanujẹ ati irora ko ni jina si aye wa.
Nitorina, ṣe ayewo aye rẹ fun oniruuru imọtaraẹninikan ti o le wa nibẹ, ki o si ri daju pe o mojuto pẹlu ọrọ Ọlọrun ati pẹlu agbara Ẹmi rẹ. Ki Ọlọrun si fun ọ ni okun lati ṣe eyi. Amin.
Ki o ni ọṣẹ ti o ga.
Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
