Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Belu 2023. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma fi igba gbogbo kun ọkan rẹ pẹlu ọgbọn ati igboya ti o peye lati lo aṣẹ ti O fifun ọ ninu Kirisiti Jesu lati pa iṣẹ eṣu run ninu aye rẹ ati ni ayika rẹ. Amin.
Njẹ o tilẹ mọ wipe Ọlọrun ti fun gbogbo awa ti a jẹ ọmọ rẹ ni aṣẹ lori eṣu ati gbogbo iṣẹ rẹ? Bẹẹni, O ti ṣe bẹẹ nipasẹ ọmọ rẹ, Jesu Kirisiti. Iwọ naa wo nkan ti Jesu Oluwa wa funrarẹ rẹ sọ lori eyi: “Kiyesi i, emi fun yin ni aṣẹ lati tẹ ejo ati akeeke mọlẹ, ati lori gbogbo agbara ọta; ko si si ohun kan bi o ti wu ki o ṣe, ti yoo pa yin lara.” (Lúùkù 10:19) Njẹ o ri bayẹn? Satani ni agbara nitootọ. Idi si niyi ti o fi le da oniruuru wahala silẹ ninu aye yi ati pẹlupẹlu ninu aye wa.
Amọ ṣa o, Oluwa sọ fun wa pe Oun ti fun wa ni aṣẹ lati bori agbara rẹ ati lati pa iṣẹ rẹ run. Iwọ naa ro wo. Ko ki i ṣe pe O fẹ fun wa ni aṣẹ lori eṣu ati iṣẹ rẹ — O ti kanlẹ fun wa ni aṣẹ yi ni. O wa ku si ọwọ wa lati jẹwọ ohun ti a ti rigba lọwọ rẹ. Bẹẹni, o ku si ọwọ wa lati ma fi ojoojumọ gbe igbe aye awọn ti Ọlọrun ti fun ni aṣẹ lati pa iṣẹ eṣu run.
Ranti wipe a sọ nipa Jesu Oluwa wa pe O wa lati pa iṣẹ eṣu run (1Jòhánù 3:8). A tun sọ nipa rẹ pe O n kiri ṣoore, O si tun n wo gbogbo awọn ti eṣu n pọn loju san (Ìṣe Àpọ́sítélì 10:38). Bi o tilẹ wa jẹ wipe Oun ko si ninu aye yi mọ nipa ti ara, O ti fun awa ti a gbagbọ ninu rẹ ni aṣẹ lati tẹsiwaju pẹlu iṣẹ ti O n ṣe nigba ti O wa nibi. O ti fun wa ni aṣẹ lati doju ija kọ eṣu ninu aye wa ati ni ayika wa, ki o si sa.
Àmọ́, a wá gbọdọ fi han pe a ti ri aṣẹ yi gba nitootọ lati ọdọ Oluwa. Lọna wo? Akọkọ, a le fi han nipa didupẹ lọwọ rẹ fun un. A kọ sinu bibeli pe gbogbo igba ni awọn eniyan ma n yin Ọlọrun logo fun bi O ti ṣe fun ọmọniyan ni aṣẹ lati pa iṣẹ eṣu run nigbakugba ti Jesu ba tu ẹnikan silẹ (Mátíù 9:8 & 15:31).
Ona keji lati fi han pe a ti gba aṣẹ lọwọ Ọlọrun lati bori gbogbo agbara eṣu ni nipa lilo aṣẹ yi. Aṣẹ ti a ko ba lo lati mu ete ti a fi fun wa ṣẹ ko ja mọ nkankan. Nitorina, niwọn igba ti a ko ba bẹrẹ si ni lo aṣẹ ti Ọlọrun fun wa lori eṣu lati fooro rẹ ati awọn angẹli rẹ pẹlu ọpọlọ pipe, aṣẹ naa ko le ja mọ nkankan ni ọwọ wa.
Wo o, lilo aṣẹ ti Ọlọrun fun wa lori eṣu nikan ni o le jẹ ki alaafia, ayọ, iṣoriire ati iwosan jọba ninu aye wa ati ni ilẹ wa. Lilo aṣẹ yi ni yoo mu igbala tọ aye ọpọ wa. Fun apẹrẹ, Luuku, nigba ti o n sọrọ nipa iṣẹ iranṣẹ Pọọlu ni Filipi, sọ fun wa nipa arabrin kan ti o ni ẹmi afọsẹ ti wọn ṣe alabapade. Gẹgẹ bi o ti ṣe sọ, arabinrin yii n yọ wọn lẹnu fun ọpọlọpọ ọjọ nipasẹ ẹmi afọsẹ rẹ. Idi si ni pe nṣe ni o n tẹle wọn kaakiri lati ma sọ fun awọn eniyan pe iransẹ Ọlọrun ni wọn ati lati ma jẹ ki wọn lero pe ẹmi kanna ni o jọ n lo wọn papọ. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 16:16-18)
Si iyalẹnu eniyan, Ọlọrun ko ma ṣe nkankan si arabinrin yi. Ọlọrun ko le danu tabi ki O dawọ bi o ti ṣe n yọ awọn apọsiteli yi lẹnu duro. Ki ni idi? Idi ni pe O ti fun wọn ni aṣẹ lati ba ẹmi inu rẹ wi. Ti wọn ba wa yan lati ma ba wi, iṣoro ti wọn ni eyi, ko ki i ṣe iṣoro tirẹ. Ṣugbọn nipa ti Pọọlu ba ẹmi inu rẹ yi wi ni orukọ Jesu, o fi silẹ, a si tu u silẹ. Nitorina, o dẹkun lati ma yọ wọn lẹnu ati lati ma tan awọn eniyan jẹ.
Nibakanna, awọn igba ma n wa ti o jẹ wipe ti a ba kọ lati lo aṣẹ ti Ọlọrun fun wa lati ba eṣu wi, Ọlọrun le ma ṣe ohunkohun nipa iṣẹ rẹ ninu aye wa tabi ni ayika wa. Lotitọ, a le wa ninu irora, ki inu wa si ma dun nitori iṣẹ ibi Satani. Sibẹsibẹ, ti a ba kọ lati lo aṣẹ ti a ni ninu orukọ Jesu lati ba a wi, o ṣeeṣe ki Ọlọrun kan ma wo wa niran. Boya eyi si ni o fa ti o fi n ni iriri inira ati ibanujẹ ni awọn abala aye rẹ kan lọwọlọwọ yi. Iwọ n duro de Ọlọrun lati ṣe nkankan nipa inira ti o ni; Oun naa si n duro de ọ lati lo aṣẹ rẹ lati sọ ara rẹ di ominira. Adura mi wa nipe ki a fun ọkan rẹ ni okun lati dide lati bẹrẹ si ni lo aṣẹ ti o jẹ tirẹ ninu Kirisiti Jesu lati fi opin si gbogbo iṣẹ eṣu ninu aye rẹ ati ni ayika rẹ, ki o ba le ni iriri alaafia ti o peye. Amin.
Kí oṣú Belu 2023 rẹ jẹ́ alárinrin.
Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
