Ànfààní fún un láti ṣiṣẹ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 03, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 18
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. O dun mọ mi ninu lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Òwewè 2023. Adura mi si pe ki Ọlọrun ṣe ara rẹ logo ni ọna ti o han kedere ni gbogbo abala aye rẹ ninu oṣu naa ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi. Àmín.
Bi a ti ṣe ri ninu Iwe mimọ, aye ti a n gbe inu rẹ yi jẹ eyi ti o wa labẹ agbara Satani (1Jòhánù 5:19). Idi si niyi ti ko fi si ibi kankan laye naa ninu eyi ti iṣẹ ika rẹ ko ti ma fi ara han. Amọ ṣa o, Ọlọrun, ninu aanu rẹ, ti ran ọmọ rẹ lati pa awọn iṣẹ ẹda buburu ati ika yi run (1Jòhánù 3:8). Ibikibi ti awọn eniyan ba si ti fi aaye gba a lati ṣiṣẹ, o di dandan ki iṣẹ Satani di piparun nibẹ, ki Ọlọrun ṣi jẹ ṣiṣe logo.
Fun apẹrẹ, Johanu fun wa ni akọsilẹ yi nipa ọkunrin kan ti Jesu Oluwa wa wosan:
“Bi o si ti n kọja lọ, o ri ọkunrin kan ti o fọju lati igba ibi rẹ wa. Awọn Ọmọ ẹyin rẹ si bi i leere, pe, “Olukọ, ta ni o dẹsẹ, ọkunrin yii tabi awọn obi rẹ, ti a fi bi i ni afọju?” Jesu dahun pe, “ki i ṣe nitori pe ọkunrin yii dẹṣẹ, tabi awọn obi rẹ: ṣugbọn ki a baa le fi iṣẹ Ọlọrun han lara rẹ. Awa ni lati ṣe iṣẹ ẹni ti o ran mi, niwọn igba ti o ba ti jẹ ọsan: oru n bọ wa nigba ti ẹnikan ki yoo le ṣe iṣẹ.”” (Jòhánù 9:1-4)
Njẹ o ri bayẹn? A bi ọkunrin yi ni afọju, ṣugbọn ko ki i ṣe nitori ẹṣẹ ẹnikẹni bikoṣe nitori pe Satani kọlu u. Nitorina, ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni ẹṣẹ ma n wa nidi ipọnju awọn eniyan. Awọn igba ma n wa ti o jẹ wipe awọn eniyan a ma jiya nitoripe Satani kan fẹ fiya jẹ wọn ni. Ti wọn ko ba si mọ bi a ti ṣe n kọju ija si, ki wọn si kọju ija si, yoo ṣe aṣeyọri lati fi iya jẹ wọn, ti Ọlọrun ko ba da a duro. Nkan ti o ṣẹlẹ si Jobu niyẹn. Nkan ti o si ṣẹlẹ bakanna si ọkunrin ti a n sọrọ rẹ yi niyẹn.
Satani kọlu ọkunrin yi nigba ti o si wa ninu iya rẹ lati sọ ọ di afọju. Ọna ti o wa gba ṣe eyi ni a ko mọ. Ṣugbọn kedere ni o han si wa pe awọn obi arakunrin yi ko kọju ija si. Ki ni idi? Ni kukuru, idi kan ti o le jẹ naa ni pe awọn naa, gẹgẹ bi awọn apọsiteli Oluwa, gbagbọ pe iya ẹṣẹ ara rẹ tabi ti wọn ni o n jẹ. Niwọn igba ti eyi si ri bẹ, wọn ko le ri Satani rara ninu ọran naa. Nkan kan ṣoṣo ti wọn le ri ni pe Ọlọrun n fi iya jẹ ẹ nitori ẹṣẹ wọn. Nitorina, ireti kan ti wọn le ni naa ko ju pe yoo boju aanu wo wọn lọjọ kan, yoo si mu ọwọ idajọ rẹ kuro lara ọmọkunrin naa.
Amọ ṣa o, nigba ti Jesu da si ọrọ naa, o yi gbogbo ero wọn pada. Akọkọ, O jẹ ki o ye awọn ọmọ ẹyin rẹ pe ọmọkunrin yi ko si ni ipo ti o wa yi nitori ẹṣẹ rẹ. Ekeji, O sọ fun wọn pe ohun ti o ṣẹlẹ si ko ki i ṣe iṣẹ Ọlọrun ṣugbọn ti eṣu. Ẹkẹta, O fi han wọn pe iṣẹ eṣu, bi ifọju arakunrin yi, ma n fun Ọlọrun ni anfaani lati ṣe iṣẹ igbala ati itusilẹ tirẹ. Ẹkẹrin, O fi han wọn pe idi ti Oun ṣe wa ninu aye ni lati ṣe iṣẹ Ọlọrun laarin awọn eniyan. Ṣe O wa ṣe iṣẹ Ọlọrun ninu aye ọkunrin yi tabi ko ṣe? O ma ṣe e. O ri daju pe o bẹrẹ si ni riran lati ọjọ naa lọ. Eyi si jẹ ki Ọlọrun jẹ ṣiṣe logo lati ọwọ ọkunrin yi, awọn obi rẹ ati awọn alabayọ miran. (Wo: Johanu 9:6-38)
Nibakanna, Ọlọrun n wọna bi yoo ṣe jẹ ṣiṣe logo ninu aye iwọ naa nipa pipa ohunkohun ti o ba jẹ iṣẹ ti Satani ti ṣe tabi ti o n ṣe ninu rẹ run. Ko si wa bikita boya ẹṣẹ ni o fa iṣẹ rẹ ninu aye rẹ tabi ẹṣẹ kọ. Kiki nkan ti O fẹ ni ki o mọ pe ohun yowu ti Satani ba n ṣe ninu aye rẹ jẹ anfaani fun lati ṣiṣẹ ninu aye rẹ ati lati jẹ ṣiṣe logo. Nitorina, fi aye gba a lati ṣiṣẹ ati lati yi nkan pada si rere fun ọ.
Bawo wa ni a ṣe le fi aye gba Ọlọrun lati ṣiṣẹ ninu wa ati lati pa iṣẹ eṣu run? Akọkọ, a le fi aye gba a nipa sisọ fun pe ko ṣe bẹ. Nitorina, gbadura si nipa iṣẹ yowu ti o ba kẹfin pe eṣu n ṣe ninu aye rẹ, ki o si sọ fun pe ki O pa a run. Yoo si ri bẹ. Siwaju si, a tun le fi aye gba a lati ṣiṣẹ nipa ṣiṣe ohunkohun ti O ba sọ fun wa pe ki a ṣe. Bi a ti ṣe ri ni ti ọrọ ọmọkunrin afọju yẹn, Oluwa sọ fun pe ki o lọ wẹ ninu adagun Omi Siloamu. Nigba ti o si lọ, o pada wa sile gẹgẹ bi ẹni ti o n riran. Ti awa naa ba si le mu ohunkohun ti O ba sọ fun wa nipa igbala, iṣoriire ati iwosan wa ni pataki, ki a si ṣiṣẹ le lori, iṣẹ rẹ yoo faharan ninu aye wa, awọn eniyan yoo si ṣe e logo lati ipasẹ wa.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ aláyọ̀.
Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)




