Ṣiṣẹ́ kárakára si fun un. | Pst. J.O. Lawal. | Òkúdù 05, 2022. | Vol. 11, No. 5
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Òkúdù 2022. Mo si gbadura pe ki ọkan rẹ ma fi gbogbo igba gba okun ati iwuri lati ma pọ si ninu iṣẹ Oluwa dipo ki o ma rẹwẹsi ninu rẹ ni gbogbo oṣu yi ati titi Oluwa wa yoo fi de. Amin.
Pọọlu, ninu lẹta rẹ kan si awọn ara Kọrinnti, sọ wipe, “Ṣugbọn nipa oore-ọfẹ Ọlọrun, ni mo ṣe ri bi mo ti ri: oore-ọfẹ rẹ ti a fi fun mi ko si jẹ asan; ṣugbọn mo ṣiṣẹ lọpọlọpọ ju gbogbo wọn lọ: ṣugbọn ki i ṣe emi, bi ko ṣe oore-ọfẹ Ọlọrun ti o wa pẹlu mi.” (1Kọrinnti 15:10) Bawo ni o ṣe ṣeeṣe fun Pọọlu lati ṣiṣẹ karakara fun Oluwa ju awọn apọsiteli rẹ yoku lọ? Nipasẹ oore-ọfẹ Ọlọrun ni. Nitorina, ko ki i ṣe nitori pe o ja fafa ju wọn lọ, ni imọ ju wọn lọ tabi ṣe olododo ju wọn lọ ni o se ṣiṣẹ karakara ju wọn lọ; dipo eyi, nitori pe o ṣe amulo ti o peye gbogbo nkan ti Ọlọrun pese fun lati sin in ni o ṣe ṣiṣẹ karakara ju wọn lọ.
Ṣe Pọọlu lotitọ wa ṣiṣẹ karakara ju gbogbo awọn apọsiteli Oluwa yoku lọ? Ni lilo oṣuwọn ti ara rẹ, o gbagbọ pe oun ṣiṣẹ julọ wọn lọ. Boya o wa jana tabi ko jana lori ọrọ yi jẹ nkan ti a o ma mọ nigba ti Oluwa wa ba de lati pin ere fun gbogbo awọn eniyan mimọ rẹ. Ṣugbọn, eyi ko ki i ṣe nkan ti o yẹ ki a ma ṣe àríyànjiyàn le lori. Nkan ti o ṣe pataki si wa lati kọbiara si lori ọrọ yi ni pe ọkunrin yi ko jẹ ki oore-ọfẹ Ọlọrun ti a tu le lori lẹkunrẹrẹ ṣofo. Dipo ki o fi ṣofo, nṣe ni o lo lati sin in tọkantọkan, lati sin lọpọlọpọ si titi ti akoko rẹ ni aye yi fi wa si opin.
Amọ ṣe awa naa le sọ nkankanna nipa ara wa? Ṣe a le sọ pe awa naa n ṣe amulo oore-ọfẹ Ọlọrun lati pọ si ninu iṣẹ irẹ? Pọọlu, ninu lẹta kanna si awọn ara Kọrinnti, sọ fun wọn pe, “Nitori naa ẹyin ara mi olufẹ, ẹ maa duro ṣinṣin, laiyẹsẹ, ki ẹ si maa tẹsiwaju ninu ṣiṣe iṣẹ Oluwa nigba gbogbo, niwọn bi ẹyin ti mọ pe iṣẹ yin kii ṣe asan ninu Oluwa.” (1Kọrinnti 15:58) Ṣe o ri bayi? A gba awọn ara yi niyanju lati ma ya ọ̀lẹ nidi iṣẹ Ọlọrun ṣugbọn lati ma fi ara wọn jin fun ni gbogbo igba.
Ki si ni idi? Idi ni pe laalaa wọn ko ni lọ lasan. Eyi tunmọ si pe Ọlọrun yoo pin wọn ni ere fun ohunkohun ti wọn ba ṣe fun. Iwọ naa wa ro wo. Bi o tilẹ jẹ wipe Oluwa ni O n pese ohun gbogbo ti a nilo lati sin in, sibẹsibẹ O ṣe ileri lati pin wa ni ere fun ohunkohun ti a ba ṣe fun un. Bi o si tun tilẹ jẹ wipe gbogbo ogo aṣeyọri wa ni ṣiṣẹ sin jẹ tirẹ nikan, sibẹsibẹ O ṣe ileri lati pin wa ni ere fun laalaa yowu ti a ba ṣe fun.
Idi wa niyi ti a ṣe nilo lati jígìrì, ti o ba jẹ wipe a ti n ṣun, ki a si mura si iṣẹ rẹ. Bẹẹni, a nilo lati dẹkun lati ma fi ara pamọ tabi sa fun iṣẹ rẹ tabi lati ma wa awawi fun bi a ṣe n rẹwẹsi ni ṣiṣe iṣẹ rẹ dipo ki a ma pọ si ni ṣiṣe e. A si tun nilo lati dẹkun lati ma fi oju alaṣeju tabi alaṣehan wo awọn ti o ba mura si iṣẹ rẹ layika wa. Idi si ni pe ko tọ si wa lati ṣe idajọ bi iṣẹ ẹnikẹni fun Ọlọrun ṣe munadoko si. Iṣẹ Ọlọrun pọ́nbélé ni eyi jẹ.
Iṣẹ tiwa, ẹwẹ, ni ki a ṣe bi Pọọlu ti ṣe, ki a si ma woye bi a ṣe le ṣe amulo oore-ọfẹ Ọlọrun ni ojumọ kọọkan lati ṣiṣẹ karakara si fun ju ti atẹyin wa lọ ati ju awọn ti o wa ni ayika wa lọ? Ki si ni idi? Ṣe ki a ba le ma fọ́nu lori iṣẹ wa ni? Rara O! Dipo bẹẹ, idi ni pe eyi yoo jẹ ki a le ru awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni ayika wa soke lati ma fi ara wọn jin siwaju ati siwaju si lati fun ni iṣẹ-sin ti o tọ, ti o si munadoko. Adura mi si ni pe ki ọkan rẹ ma fi gbogbo igba gbinájẹ lati ṣe eyi, ni orukọ Jesu. Amin.
Kí o ní oṣù Òkúdù alárinrin
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Ṣiṣẹ́ kárakára si fun un. | Pst. J.O. Lawal. | Òkúdù 05, 2022. | Vol. 11, No. 5 Read More »

