Ǹjẹ́ ọkàn rẹ ṣe déédé níwájú rẹ̀ bí? | Pst. J.O. Lawal | Èbìbí 15, 2022 | Vol. 11, No. 2

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọṣẹ miran ninu oṣu yi. Mo si tun gbadura pe ki Ọlọrun ṣe ọkan rẹ yẹ niwaju rẹ ni gbogbo igba, ki eré-ìje Kirisitiẹni rẹ ninu aye yi ma ba ja si asan. Amin.

Ninu iwe Iṣe awọn Apọsiteli, a ri akọsilẹ arakunriin kan ti a n pe ni Simoni Oṣó. Ọkunrin yi, bi akọsilẹ naa ti ṣe lọ, je olugbe ilu awọn ara Samaria kan ti Filipi ti kọkọ waasu ihinrere Jesu Kirisiti. Nigba ti o si ri awọn iṣẹ iyanu ati ara ti ajinhinrere yi ṣe, ẹnu yaa to bẹẹ gẹẹ ti oun naa fi ṣe iribọmi ni orukọ Oluwa bi awọn ara Samaria yoku ti o wa ninu ilu yi. (Ìṣe Àpọ̀sítélì 8:5-24) 

Ṣugbọn oṣo ni ọkunrin yi jẹ, oṣo ti o ti fi akoko kanrí jọ awọn eniyan wọnyi loju pẹlu agbara àlùpàyídà ati oṣo rẹ. Nitorina, nipa ṣiṣe iribọmi ni orukọ Jesu, o n fihan pe oun gba pe Filipi n ṣiṣẹ pẹlu agbara ti o ga, ti o si pọ ju ti oun lọ. Eyi si jẹ nkan ti gbogbo ọmọ Ọlọrun gbọdọ fi sọkan. A n ṣiṣẹ pẹlu agbara ati aṣẹ ti o ga julọ ni ibi yowu ti awọn ẹda Ọlọrun le wa. Nitori eyi, nṣe ni o yẹ ki a gbe gbogbo ibẹru iṣẹ awọn ajẹ, oṣo ati alafọsẹ ti a ni ju ṣọnu. Bẹẹni, nṣẹ ni o yẹ ki a gbe gbogbo ibẹru Eṣu ati awọn ẹmi aimọ rẹ ti a ni ju danu. Idi si ni pe a ni aṣẹ ati agbara lori wọn ninu Kirisiti Jesu – abẹ atẹlẹṣẹ wa ni gbogbo wọn wa. (Wo: Luuku 10:19; Roomu 16:20; 1Johanu 2:14; 1Johanu 4:4)

Ni kukuru, lẹyin igba ti o ti ṣe iribọmi ni orukọ Jesu, Simoni bẹrẹ si ni tẹle Filipi lọ si ibikibi ti o ba lọ, nitoripe awọn iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu ti o n ri jọ ọ loju pupọ. Eyi tunmọ si pe oun naa bẹrẹ si ni ṣe bi ọmọ Ọlọrun, bi Kirisitiẹni tootọ. Ṣugbọn nigba ti awọn Apọsiteli Peteru ati Johanu de si ilu kannaa yi, ti wọn si bẹrẹ si ni gbe ọwọ le awọn ti o gbagbọ lori lati gba Ẹmi mimọ, ete ibi inu ọkan Simoni farahan.

Ki gan an lo ṣe? O gbiyanju lati fun wọn ni owo lati rẹ ẹbun Ẹmi mimọ. Ki si ni idi? Idi ni pe oun naa fẹ maa ṣe ohun ti Filipi ati awọn apọsiteli yi n ṣe. O si ni itara lati ṣe to bẹẹ gẹẹ ti o fi ṣetan lati fi owo ra agbara lati ṣe bẹ ẹ. Nitorina, ko jẹ tuntun lati ri awọn eniyan ti wọn ṣetan lati gbe igbesẹ-ki-gbesẹ, pẹlupẹlu didara pọ mọ ẹgbẹ okunkun tabi lilo afọsẹ ati ẹmi oṣo, ti yoo jẹ ki wọn le ma jọ awọn eniyan loju, ki wọn si ma fi ara wọn han gẹgẹ bi eniyan pataki ninu ijọba Ọlọrun.

Bawo wa ni Peteru ṣe fesi si nkan ti Simoni ṣe? O da lohun nipa sisọ awọn ọrọ wọnyi:

“Ki owo rẹ ṣegbe pẹlu rẹ, nitori iwọ ro lati fi owo ra ẹbun Ọlọrun. Iwọ ko ni ipa tabi ipin ninu ọran yii: nitori ọkan rẹ ko ṣe deedee niwaju Ọlọrun. Nitori naa ronupiwada kuro ninu iwa buburu rẹ yii, ki o si gbadura sọdọ Ọlọrun, boya yoo dari ete ọkan rẹ ji ọ. Nitori ti mo woye pe, iwọ kun fun owu kikoro, ati wi pe ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni iwọ n ṣe.”

Njẹ o ri bayẹn? Ki ni iṣoro ti Simoni ni? Ohun naa ni pe ọkan rẹ ko ṣe deede pẹlu Ọlọrun. Ko fi igba kankan di atunbi ni tootọ. Ko fi igba kankan ni ipa ninu Kirisiti. Ẹ si wa wo o, o n ṣe wọle-wọde pẹlu Filipi ati awọn apọsiteli yi o. O sun mọ wọn pẹkipẹki, o si tun jẹ igbadun ibaṣepọ pẹlu wọn. O tilẹ ṣeeṣe ki o ti ba wọn jẹun papọ ni awọn igba kan tabi ki o ti ba wọn jẹ awọn iṣẹ kọọkan ri. Sibẹsibẹ, ọkan rẹ ko ṣe deede.

Nitorina, pe o n wa si ipade ijọ loorekoore tabi pe o n ṣe wọle-wọde pẹlu awọn oniwasu ati awọn onigbagbọ kan tabi omiran ko tunmọ si pe ọkan rẹ ṣe deede. Lotitọ, awọn eniyan le ma mọ nkan ti o n lọ ninu ọkan rẹ, ti a ko ba fi han wọn, bi a ti ṣe niti Simoni. Wọn le ma mọ pe o kun fun owu, ojukokoro, idibajẹ ati ẹtanu. Ṣugbọn Ọlọrun mọ. Iwọ naa si mọ pẹlu. Ti o ko ba si ronupiwada lakoko ti o tọ, ọjọ kan le de ti awọn iṣẹlẹ kan yoo tu aṣiri ete eke ati ika inu ọkan rẹ.

Yatọ si iyẹn, niwọn igba ti ọkan rẹ ko ba ti ṣe deede niwaju Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ atunbi ni tootọ, o di dandan ki o pa iriri didara Ọlọrun ti o yẹ ki o ni lara. Eyi si ni alaye fun bi igbega, iwosan, isesorere, ibalẹ-ọkan ati iṣoriire ti awọn onigbagbọ kan n wa ko ni lailai jẹ ti wọn. Ọkan wọn ko ṣe deede. Ti wọn ko ba si ronupiwada, ko si ni ki nkan ma bajẹ ju bayi lọ fun wọn. Nitori eyi, ṣọ kan rẹ pẹlu ìfarabalẹ̀ ti o ga, ki o si tun ti ilẹ̀kuǹ rẹ̀ mọ́ ojukokoro, ẹtanu, owu ati èrò ìkà gbogbo. Ki Ọlọrun oore-ọfẹ jẹ ki o le ma fi gbogbo igba ṣe eyi fun anfaani ara rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ǹjẹ́ ọkàn rẹ ṣe déédé níwájú rẹ̀ bí? | Pst. J.O. Lawal | Èbìbí 15, 2022 | Vol. 11, No. 2 Read More »