Má sọ ààyè rẹ nù

Idajọ ẹtan | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Ogun 15, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 15

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ pipọsi fun ọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ogun 2021. Adura mi si ni pe ki ọkan rẹ ma fi gbogbo igba gba okun lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun lati rin ninu ifẹ ati otitọ inu pẹlu awọn eniyan Ọlọrun ti o wa ninu aye rẹ, ki o ma ba ṣilẹkun aye rẹ silẹ fun idajọ Ọlọrun dipo ki o ma gbadun ẹkunrẹrẹ ayọ ibaṣepọ Kirisitiẹni si Kirisitiẹni. Amin.

Bibeli sọ wipe, “Ẹ ma si ṣe purọ fun ẹnikeji yin, ẹyin sa ti bọ ogbologbo ara ẹṣẹ ni silẹ ati iṣẹ buburu rẹ; Ẹ si ti gbe ara tuntun ni wọ, eyi ti a sọ di tuntun gẹgẹ bi aworan ẹni ti o da a, sinu imọ kikun.” (Koloso 3:9-10) Njẹ o ri bayi? Irọ pipa, eke ṣiṣe tabi ẹtan jẹ ọmọ iṣẹda iku ti Ọlọrun yọ danu kuro ni aye wa nigba ti a di atunbi. Nitorina, a ko gbọdọ gba a laye ninu aye wa tabi ninu ibaṣepọ wa pẹlu ara wa. Aijẹbẹ, a o ma ṣilẹkun aye wa silẹ fun idajọ Ọlọrun. Tani o si mọ ọna ti O le gba dawa lẹjọ? Ko si!

Fun apẹẹrẹ, ti Ananaya ati Safira iyawo rẹ ba lero pe Ọlọrun le fun wọn ni idajọ iku lori pe wọn fi ẹtan ba awọn awọn eniyan rẹ lo pọ ni, o ṣeeṣe ki wọn ma ṣe bi wọn ṣe ṣe nigba yẹn. Ṣugbọn nitori pe wọn ko ni lọkan rara pe O le e ṣe bẹ, wọn parọ nipa fi fifunni wọn, a si da seria fun wọn lẹsẹkẹsẹ. Awọn mejeeji si ni Ọlọrun da lẹjọ, ti O si tun pa ni ọjọ kannaa. (Wo: Iṣe Apọsiteli 5:1-11)

Wayi o, ẹnikan wa le sọ wipe, “Ṣebi ọpọ laarin awọn ọmọ Ọlọrun lo si ma n wuwa ẹlẹtan loorekoore. Sibẹsibẹ, ko ki i ṣe gbogbo igba ti wọn ba ṣe eleyi ni Ọlọrun n lu wọn pa. Ki lo wa fa ti ọrọ ti Ananaya ati ti iyawo rẹ ṣe yatọ niwaju rẹ?” Lakọkọ, a gbọdọ jẹ ki o ye wa pe wipe Ọlọrun ko ṣe idajọ iku fun awọn eniyan lẹsẹkẹsẹ nitori pe wọn wuwa ẹtan tabi ṣe nkan buburu miran ko tunmọ si pe ko ma ṣe idajọ fun wọn rara. O ni ọpọ ọna ti O fi n ṣe idajọ awọn eniyan. Ti wọn ko ba si ni ifura, wọn le ma fi akoko kankan mọ pe a n ṣe idajọ wọn.

Ekeji, a nilo lati jẹ ki o ye wa pe ko ki i ṣe pe Ọlọrun fi ojusaaju bọ ọrọ Ananaya ati iyawo rẹ. Nkan ti o ṣẹlẹ ni pe O kan pinnu lati fi wọn jofin ni, ki wọn ba le jẹ arikọgbọn fun awọn miran ti wọn le fẹ ma rin nipasẹ wọn. Adura mi si ni pe o ko ni gbe igbesẹ kankan ti yoo jẹ ki Ọlọrun fi ọ se arikọngbọn ọna ti O n gba ṣe idajọ ibi fun awọn eniyan. Amin. Ṣugbọn ki gan an lo fa ti Ọlọrun fi lo Ananaya ati Safira gẹgẹ bi arikọgbọn fun awọn miran? Idi ni wipe wọn gbiyanju lati fi ẹtan lọlẹ ninu ijọ rẹ. Awa naa si gbọdọ kiyesara lori irufẹ awọn nkan ti a n filọlẹ ninu ijọ Ọlọrun, nitori pe O n wo wa, yoo si pin wa lere gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wa ba ṣe ri.

Ni kukuru, bi akọsilẹ bibeli ṣe fi ye wa, nkan ti o ṣẹlẹ si Ananaya ati aya rẹ ṣẹlẹ ni akoko ti ifẹ Kirisiti n jọba lotitọ ninu aye awọn eniyan rẹ ati lori ọrọ aye wọn. Ifẹ yi si gbakoso aye wọn to bẹẹ gẹẹ ti awọn ti wọn ni awọn nkan ini to lowura bẹrẹ si ni ta wọn, ti wọn si n mu owo ti wọn pa nibẹ wa fun awọn apọsiteli lati pin fun awọn ti o ṣe alaini ni aarin wọn. Eyi gan an lo le iṣẹ jade kuro laarin wọn, nitoripe bibeli sọ wipe, “Ko si alaini kankan ni aarin wọn ni akoko yi.” (Wo: Iṣe Apọsiteli 4:32-35)

Nitorina, gbogbo awọn ara ni akoko yi, iye yowu ti wọn jẹ, ni wọn n ba ara wọn lo pẹlu otitọ ati ifẹ. Bi Ọlọrun si ṣe fẹ ki o ri ni eyi, nitoripe eyi ni yoo jẹ ki awọn ti aye yi mọ pe ọmọlẹyin Kirisiti Jesu Oluwa ni wọn nitootọ. O wa ṣe ni laanu pe, ni akoko kannaa yi, Satani ṣe aṣeyọri lati mu ki Ananaya ati iyawo rẹ bẹrẹ si ni ronu yatọ ati wuwa yatọ. Bi wọn ṣe pẹ to lori eleyi ni a ko mọ. Ṣugbọn a mọ pe, ni akoko kan, awọn naa, gẹgẹ bi awọn ara yoku, ṣeleri lati ta ilẹ wọn kan ati lati mu owo rẹ wa sinu ijọ. Wọn si ṣe bẹẹ gẹgẹ.

Amọ ṣa o, wọn ko ṣetan lati mu gbogbo owo ti wọn pa nidi ilẹ ti wọn ta naa wa siwaju Ọlọrun. Nitori naa, wọn fi diẹ lara rẹ pamọ fun ara wọn. Njẹ eyi jẹ nkan ti o buru bi? Rara o! Awọn ni o ni owo yi lakọkọ, bi Peteru ṣe sọ fun wọn lẹyinọrẹyin. Nitori naa, wọn ni aṣẹ lati sọ bi wọn ṣe fẹ ẹ lo o. Ṣugbọn lati wa gbiyanju lati tan awọn eniyan Ọlọrun yoku jẹ, awọn eniyan rẹ ti wọn nifẹ wọn, ti ọrọ aye wọn si jẹ wọn logun, ki wọn si jẹ ki o dabi ẹni pe owo ti wọn fi silẹ ju iye ti wọn fi silẹ lọ jẹ eyi ti ko ṣe itẹwọgba ni ọwọ Ọlọrun. Idi niyi ti O ṣe ṣe idajọ ẹtan wọn, ti O si lo eyi lati fun awọn miran bi tiwọn ni anfaani lati kẹkọ ati lati ronupiwada.

Ni bakanna, ti awa naa ko ba ni rin pẹlu ifẹ ati ọkan otitọ pẹlu awọn ara wa ninu oluwa, boya nipa awọn ọna ti a n gba lo nkan ini wa tabi ẹbun ẹmi wa ni tabi nipa awọn ọna ti a n gba ṣe awọn nkan miran, a le ma ṣi ilẹkun silẹ fun idajọ Ọlọrun, eyi ti o si le ja si iku ti ara. Nitorina, ẹ jẹ ki a fi aye gba ọrọ Ọlọrun lati fọ wa mọ kuro ninu aiṣododo ati agabagebe gbogbo, nigba ti eyi si ṣeeṣe. Ki Ẹmi Ọlọrun si ran iwọ ati emi lọwọ lati ṣe ohun ti o tọ lori ọrọ yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ adun o.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Idajọ ẹtan | Paitọ J.O. Lawal Read More »