IDAJỌ LAARIN AGBO IJỌ | Pst. J.O. Lawal
ỌJỌRU 21, AGẸMỌ 2021 | AYỌKA: ISIKIẸLI 34:17-22
AKỌSORI: AKỌSORI: “Njẹ o yẹ ki awa ti jẹ alailagbara ninu igbagbọ lee ma ru ẹru ailera ti awọn alailera, ki a ma si ṣe ohun ti o wu ara wa.” (Roomu 15:1)
ỌRỌ AKỌSỌ
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, loorekoore ni Ọlọrun ma n gbẹsan awọn eniyan rẹ lara awọn ika eniyan ti o n pọn wọn ni oju tabi ṣe wọn ni ibi. Eyi si yatọ si idajọ si ipo egbe ayeraye ti yoo ṣe fun gbogbo awọn ti ko mọ ọ tabi kọbiara si nigba ti wọn wa laye. (Wo: Iṣe Apositeli 12; Filipi 1:28; 2Tẹsalonika 1:6-10) Amọ ṣa o, ko ki i ṣe idajọ laarin awọn ika eniyan ati awọn ọmọ rẹ nikan ti Ọlọrun ma n ṣe. O tun ma n ṣe idajọ laarin awọn ọmọ rẹ ati ara wọn pẹlu. Idi si ni pe olotitọ ati olododo ni, ko si fẹ eke, aiṣododo, iyanjẹ tabi ipọniloju, yala laarin awọn ọmọ rẹ si ara wọn ni tabi laarin awọn ọmọ rẹ ati awọn ti aye yi. Ti a ko ba wa fi eyi sọkan, ki a si kiyesara nipa bi a ṣe n ba awọn ọmọ Ọlọrun miran lo pọ, paapaa julọ ninu ijọ ti a wa, ko si ni ki a ma ba idajọ Ọlọrun pade laye yi ni akoko kan tabi omiran.
IDAJỌ LAARIN AGBO IJỌ
Njẹ a wa ri arigbamu ninu bibeli pe Ọlọrun ma n ṣe idajọ laarin awọn eniyan rẹ bi? Bẹẹni. Fun apẹẹrẹ, ninu iwe Isikiẹli, ori ikẹrin-le-lọgbọn, Oluwa sọ eyi fun awọn eniyan rẹ:
“Bi o ṣe ti yin, ẹyin ọwọ ẹran mi, bayii ni Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o ṣe idajọ larin ẹran ati ẹran, laarin agbo ati abukọ. Ohun kekere ni ni oju yin ti ẹ ti jẹ oko daradara, ṣugbọn ẹyin si fi ẹsẹ tẹ oko yooku mọlẹ, ẹ si ti mu ninu omi jinjin, ṣugbọn ẹ si fi ẹsẹ ba eyi ti o ku jẹ? Bi o ṣe ti ọwọ ẹran mi ni, wọn jẹ eyi ti ẹ ti fi ẹsẹ yin tẹ mọlẹ; wọn si mu eyi ti ẹ ti fi ẹsẹ yin bajẹ. Nitori naa, bayii ni Oluwa Ọlọrun wi fun wọn, Kiyesi i, emi ani emi o ṣe idajọ laarin ọwọ ẹran ti o sanra, ati eyi ti o ru. Nitori ti ẹyin ti fi ẹgbẹ ati ejika gbun, gbogbo awọn ti o ṣe ailera ti ẹ si ti fi iwo yin kan wọn titi ẹ fi tu wọn kaakiri. Nitori naa ni emi o se gba ọwọ ẹran mi la, wọn ki yoo si jẹ ijẹ mọ, emi o si ṣe idajọ laarin ẹran ati ẹran.” (Isikiẹli 34:17-22)
Ki ni koko nkan ti Ọlọrun n ba awọn eniyan rẹ sọ ninu awọn ẹsẹ bibeli yi? Oun na ni pe O ṣetan lati ṣe idajọ wọn. Irufẹ idajọ wo ni O si fẹ ṣe laarin wọn? Idajọ iṣesi ati ibalopọ wọn si ara wọn! Eyi n fi ye wa wipe Ọlọrun ti o jẹ Baba gbogbo wa n wo iṣesi wa si ara wa ninu gbogbo awọn ijọ wa. O n wo bi a ṣe n ba ara wa lo pọ lati ri boya a n ṣe ni ọna ti o tọ ati ti o yẹ tabi bẹẹkọ. Ki wa ni awọn ẹsun ti Ọlọrun fi kan awọn eniyan rẹ ninu awọn ẹsẹ bibeli yi, ti O fi fẹ ṣe idajọ wọn ni dandan? Awọn naa niwọn yi:
– Anikanjọpọn: gẹgẹ bi Ọlọrun ti fi idi rẹ mulẹ, awọn kan wa laarin awọn eniyan rẹ ti o jẹ pe ti ara wọn nikan ni wọn mọ. Idagbasoke, iserere ati ilọsiwaju ti ara wọn nipa ti ẹmi ati nipa ti ara nikan ni wọn mọ. Nitorina, igbesẹ bi yoo ṣe dara ati rọgbọ fun wọn nikan ni wọn n gbe. Ko si nkan ti o kan wọn pẹlu ti awọn ara wọn yoku. Eyi tunmọ si pe awọn wọnyi ko ki i fi igba kankan lepa lati ran awọn eniyan Ọlọrun yoku lọwọ pẹlu oye, imọ, nkan ini, adura ati gbajumọ wọn, ki awọn naa ba a le dagba soke nipa ti ẹmi ati nipa ti ara. Wọn ko ni ṣe afẹri tabi awari tabi amojuto awọn ara wọn lati ri pe wọn n gbe awọn igbesẹ ti o yẹ ki wọn gbe, ki aye wọn ba le ni itunmọ, ki igbagbọ wọn si fi ẹṣẹ mulẹ. Dipo eyi, nkan ti o wu wọn ni wọn a ma a ṣe. Awọn kanna yi si tun ni ẹnu ma n saba ya lati bu ẹnu atẹ lu awọn ti igbagbọ wọn ko fi ẹṣẹ mulẹ, ti irin wọn ko ṣe deede pẹlu Ọlọrun tabi ti aye wọn ko ni ilọsiwaju bi o ṣe yẹ ki o ni. Alanikanjọpọn ni wọn. O si di dan ki Ọlọrun ṣe idajọ wọn nigba ti osuwọn anikanjọpọn wọn ba kun, ti wọn si kọ lati ronupiwada. (Wo: Roomu 15:1; Filipi 2:3-4 &19-24; Kolose 4:12-13)
– Aikanisi: ki ni o ma n fa anikanjọpọn? Ọkan lara rẹ ni aikanisi. Niwọn igba ti a ko ba ka awọn miran ti o wa ni ayika wa, adugbo wa, ile-iṣẹ wa, ile-iwe wa, orilẹ-ede wa tabi ijọ wa si, ko si ni ki anikanjọpọn ma jọba ninu aye wa. Gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣe fi ẹsun kan awọn eniyan rẹ, a ri lara wọn awọn ti ko ni akasi ọmonikeji wọn. Wọn ko bikita boya aye wọn dara tabi ko dara. Wo ko bikita boya igbagbọ wọn duro deede tabi ko duro deede. Wọn ko si bikita boya wọn ko sinu panpẹ Esu, ki wọn si farapa, ṣubu, sọnu tabi padanu ẹmi wọn tabi ko ri i bẹẹ. Eyi si tunmọ si pe ọkan awọn ara wọn ko ṣe iyebiye si wọn bi ọkan ti wọn ṣe ṣe iyebiye si Ọlọrun to bẹẹ gẹẹ ti O fi fi ọmọ bibi rẹ Jesu Kirisiti Oluwa wa silẹ fun igbala ati irapada wọn (Johanu 3:16). O si ṣe ni laanu pe bi o ṣe ri gẹlẹ ni yi ni ọpọ ijọ wa loni. Ọkan awọn ara wa ninu Oluwa ko ṣe iyebiye si wa bi o ṣe ṣe iyebiye si Jesu Olugbala gbogbo wa. Nitorina a a ki i naani wọn ni ọpọlọpọ ọna, ayafi ti a ba n ri nkan gba lọwọ wọn. Ti a ba si n ri nkan gba lọwọ wọn naa, igbala ọkan wọn kọ ni o ṣe pataki si wa, bi ko ṣe nkan ti a n ri gba lọwọ wọn. Idi si ni yi ti a fi ri ọpọ ti aye wọn ko nitunmọ, ti ile wọn ko ṣe e ri tabi ti iṣẹ ọwọ wọn lodi si ifẹ Ọlọrun ninu ijọ loni, ti ko si si ẹni ti o n ba wọn ọn wi tabi yẹ wọn lọwọ wo. Irufẹ iṣesi yi, gẹgẹ bi Ọlọrun ti wi, di dandan ki o fa idajọ rẹ wa sori wa, ti a ba kọ lati ṣe atunṣe ni akoko.
– Irẹnijẹ: Yatọ si awọn ẹṣun meji akọkọ ti a ti gbe yẹwo, Ẹṣun miran ti Ọlọrun tun fi kan awọn eniyan rẹ ni irẹnijẹ. Eyi jasi pe wọn n fi ọwọ ọla gba ara wọn loju, wọn n ṣe ara wọn leṣe, wọn n wuwa ibajẹ si ara wọn ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ko si yẹ ki o ya wa lẹnu pe iru nkan bayi ma n ṣẹlẹ laarin awọn eniyan Ọlọrun. Idi ni pe niwọn igba ti a ko ba ti naani ara wa tabi ka ara wa si ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, ko si ni ki a ma rẹ ara wa jẹ. A le ja ara wa lole, pọn ara wa loju, ba ara jẹ ninu iṣekuṣe, sọ ọrọ alufanṣa si ara wa, parọ tan ara wa jẹ tabi ṣeku pa ara wa (1Korinnti 5-6; Jemisi 4:1&5:1-6). Igba miran ẹwẹ, nipa aibikita fun ọkan, igbagbọ ati iduroṣinṣin awọn ara wa ninu Kirisiti, a le fi imọ ominira wa tabi ailoye wa ṣe ara wa ni ijamba (Roomu 14; 1Korinnti 8). Irufẹ awọn iṣeṣi yi ni o n le ọpọ ọmọ Ọlọrun kuro ninu ijọ loni, ti ko si tun jẹ ki ọpọ ti ko i ti kuro ninu ijọ duro deede lati sin Ọlọrun tọkantọkan. Yatọ si eyi, irufẹ awọn iwuwasi yi ni ko jẹ ki ọpọ ti ko gba Jesu gbọ fẹ ni nkankan ṣe pẹlu ijọ Ọlọrun.
Ṣe awọn nkan wọnyi le wa ma lọ ni aarin wa, ki Ọlọrun si fi ọwọ lẹran bi? Ko ṣeeṣe. Nitori pe Ọlọrun ni ifẹ gbogbo wa gẹgẹ bi ọmọ rẹ, o didan ti O ba ri wipe a ko tọju ara wa bi o ṣe yẹ tabi mojuto ara bi o ṣe tọ, ki O gbe igbesẹ idajọ lori wa ati laarin wa. Eyi ko tunmọ si pe ko fẹran wa. Dipo bẹ, o tunmọ si pe Oun, gẹgẹ bi Onidajọ ododo, ni lati ṣe ohun ti o tọ ati ti o yẹ lati ri pe ilera wa ninu ijọ awọn ọmọ rẹ ati wipe a ko fi aye silẹ fun awọn ti aye yi lati gan orukọ rẹ nipasẹ wa. Nigba ti O ba si wa n ṣe eyi, o ṣeeṣe ki idajọ rẹ mu ipalara wa fun wa ni oriṣiriṣi ọna.
Ti a ko ba gbagbe, nigba ti Kaini pa aburo rẹ Abẹẹli, Ọlọrun ko fi akoko ṣofo rara lati ṣe idajọ laarin awọn mejeeji. Ọlọrun tilẹ sọ fun pe nṣe ni ẹjẹ arakunrin rẹ n kigbe tantan fun idajọ ati igbẹsan ododo. Nitorina, Ọlọrun fi si abẹ eegun aṣedanu nidi iṣẹ ọgbin. O si tun sọ di alarinkirin, ẹni ti ọkan rẹ ko ni fi igba kankan balẹ. Bẹẹ gẹgẹ ni a si ri awọn ọmọ Ọlọrun ti igbe oro awọn ara wọn ti wọn ti han lemọ, yanjẹ, pọn loju tabi ba aye wọn jẹ n fi gbogbo igba wa si eti Ọlọrun. Bawo wa ni Ọlọrun ko ṣe ni ṣe idajọ awọn naa, bi O ṣe ṣe ti Kaini? Ko si ni, ayafi ti wọn ba tete ronupiwada. (Wo: Jẹnẹsis 4:1-16; Jemisi 5:1-6; 1Peteru 3:7).
Siwaju si, ninu ọkan lara lẹta rẹ si awọn ijọ Kọrinnti, Pọọlu jẹ ki o ye wọn pe ọkan gboogi lara idi ti ọpọ laarin wọn ṣe n ṣaisan tabi wa ni ailera, ti ọpọ miran ẹwẹ si ti ṣe jade laye laitọjọ ni pe Ọlọrun n ṣe idajọ laarin wọn. Ki lo si fa ti Ọlọrun fi n ṣe eyi? Idi ni pe wọn ko fi imọ ati oye ba ara wọn lo gẹgẹ bi ẹya ara Kirisiti. Bi a ṣe ri ninu bibeli, gbogbo awa ti a gbagbọ ninu Jesu Kirisiti ni Ẹmi mimọ ti tẹwa bọ inu ara rẹ gẹgẹ bi ọkan. Nitorina, bi o ti wu ki a pọ to tabi ki ẹya wa yatọ to, ara kan naa ni gbogbo wa jẹ ninu Kirisiti Oluwa wa. A wa gbọdọ mọ eyi daju, ki a si ma ba ara wa lo pẹlu oye rẹ. Aijẹbẹ, ni awọn akoko kan, Ọlọrun ko ni ṣe meni tabi ṣe meji ju ki O bẹ wa wo pẹlu idajọ lọ. Irufẹ idajọ bẹ si le yọri si aisan, ailera, adanu, aṣedanu, iku ati bẹẹbẹẹ lọ, gẹgẹ bi o ti ri fun awọn ara Kọrinnti igbanni. (Iṣe Apositeli 5:1-11; Roomu 12:4-5; 1Korinnti 11:17-34 & 12:12-27)
A tilẹ tun ri ninu iwe Ifihan ti a fun Johanu pe Jesu Oluwa kọ lẹta si ijọ Tiatira wipe Oun yoo ṣe idajọ laarin wọn nitoripe wọn fi aye gba awọn kan lara wọn lati ma ṣi awọn ọmọ rẹ lọna lati ṣe agbere ati lati bọriṣa. Irufẹ idajọ wo si ni Oluwa fẹ mu wa si ori wọn nitori aironupiwada wọn? Idajọ aisan! Idajọ ipọnju nla! Idajọ iku. Nitorina, ti a ba dede ri pe ikoro bẹrẹ si ni farahan ninu ijọ kan, a nilo lati fura ni kiakia, ki a si bẹrẹ si ni wadi lati ṣe idajọ ara wa pẹlu ọrọ Ọlọrun. Nitori pe o le jẹ wipe ẹṣẹ si ara wa ati si ara Kirisiti ni o fa. (Wo: Ifihan 2:20-23)
ỌRỌ IPARI
Iha ti a kọ si ibaṣepọ pẹlu awọn ara wa ninu Oluwa, paapaa julọ awọn ọmọ ijọ wa, ṣe pataki pupọ. Idi si ni pe Ọlọrun Baba wa n wo gbogbo wa lati san wa ni ẹṣan gẹgẹ bi iṣesi wa si ara wa ba ṣe ri. Ti a ko ba wa fẹ ki O jẹ wa niya nitori aiṣedede wa si ara wa, a gbọdọ kiyesi lati ma ka ara wa si, ki a ma ba ara wa lo pẹlu ifẹ ti o peye, ki a si tun ma ṣe idajọ awọn iwa ti ko ba tọ ni aarin wa pẹlu ọrọ Ọlọrun ati ninu ododo.
IBEERE
– Ṣe ẹkọ yi ṣe pataki fun awọn ọmọ Ọlọrun tabi ko ṣe pataki?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
IDAJỌ LAARIN AGBO IJỌ | Pst. J.O. Lawal Read More »
