Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́ láìsi mọ nkànkan | Pst. J.O. Lawal | Ọ̀wàrà 09, 2022 | Vol. 11, No. 23
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Ọwara 2022. Mo gbadura pe ki Ẹmi Ọlọrun lo ọrọ rẹ ti o n tọ ọ wa ninu ijọ yi lati fọ wọn danu kuro ninu aye rẹ ohun gbogbo ti o n di isesorere rẹ lọwọ, ni orukọ Jesu. Amin.
Pọọlu, ninu lẹta rẹ keji si Timoti, sọ eyi nipa awọn kan ninu ijọ ti ko gbọdọ ni nkankan ba ṣe pọ: “Nitori ninu iru eyi ni awọn ti n rako wọ inu ile, ti wọn si n di awọn obinrin alailọgbọn ti a di ẹṣẹ ru ni igbekun, ti a si n fi oniruuru ifẹkufẹẹ fa kiri. Wọn n fi igba gbogbo kẹkọọ, wọn ko si le de oju imọ otitọ.” (2Timoti 3:6-7) Pẹlu nkan ti apọsiteli yi sọ nibiyi, a ri wipe ọkan lara awọn idi ti o fi sọ fun Timoti lati ma ni nkankan ba awọn ara wọnyi ṣe pọ ni pe ọga ni wọn ninu ki a ma jẹ awọn eniyan mọlẹ, paapaa julọ awọn obinrin, ati ki a ma tan wọn jẹ.
Ki wa ni o jẹ ki o ma fi ọpọ igba rọrun fun wọn lati tan awọn eniyan jẹ ati lati tun gba akoso aye wọn? Idi ni pe awọn ti o n fi igba gbogbo kẹkọọ ṣugbọn ti imọ otitọ ko wọle si lori ni wọn ma n ṣaba lọ fun. Eyi tunmọ si pe wọn ki fojusun gbogbo eniyan. Dipo eyi, awọn ti wọn lọra lati ni oye otitọ nkan ti ẹmi ati lati mu wọn lo ni wọn ma n fojusun.
Mo gbọ ni igbakan pe wolii kan ni aṣa ki o ma ba awọn abilekọ ti o ba wa sọdọ rẹ fun adura nipa iṣoro aye wọn sun. Ki lo fa ti ọkunrin yi fi n ṣe aṣeyọri ni ṣiṣe eyi? Idi naa ni pe awọn ti o n lugbadi rẹ gba igbakugba. Ki lo si fa ti wọn fi gba igbakugba? Idi naa ni pe wọn kọ lati tẹwọgba otitọ Ọlọrun ti wọn n kọ.
Ṣe wọn ko mọ ifẹ Ọlọrun lori agbere ni? A bi ṣe ko si ẹnikẹni ti o fi igba kankan kọ wọn pe nini ibaṣepọ pẹlu ẹni ti eniyan ko fẹ kọ tọna ni? A ti gbọdọ kọ wọn ni awọn nkan wọnyi lera-lera, paapaa julọ ti wọn ba jẹ Kirisitiẹni. Ṣugbọn ọtọ ni ki awọn eniyan ma kọ otitọ lati ọdọ Ọlọrun; ọtọ si tun ni ki otitọ ti wọn n kọ ye wọn, ki wọn si mọ ibi ti o ti ba aye ti wọn n gbe lojoojumọ mu.
Ti awọn eniyan ba kọ lati ni oye iwulo otitọ ti wọn n kọ ninu ijọ, o ṣeeṣe ki wọn ma ṣe amulo rẹ. Irufẹ awọn wọnyi si ni wọn ma n di eran ijẹ fun awọn eke olukọ ati eke wolii. Iru awọn eniyan yi ni wọn ma n tete ṣubu sinu ẹtan Eṣu, ti wọn a si fi idibajẹ ṣinu aye wọn, rẹ wọn jẹ tabi ṣe wọn ni ijamba.
Iwọ naa wa bere lọwọ ara rẹ, “Njẹ mo n kọ nkankan bi lati ara awọn nkan ti a n kọ mi ninu awọn ipade ijọ wa?” O n wa lọsọọsẹ fun ipade ijọ lati gbadura, lati sin Ọlọrun ati lati kọ ọrọ rẹ. Ṣugbọn ṣe o n kọ nkankan bi? Ṣe o n ni imọ-kun-imọ ninu otitọ Jesu nipasẹ awọn nkan ti o n kọ? Ṣe o si n ri bi o ti yẹ ki o ṣe amulo awọn otitọ ti o n kọ yi ninu aye re?
Ti idahun rẹ si awọn ibere yi ko ba ki i ṣe ‘Bẹẹni’, a jẹ wipe ọkan lara awọn ti o ma n fi gbogbo igba kẹkọọ ṣugbọn ti imọ otitọ ko ki wọ ọkan wọn ni o jẹ niyẹn. Nitorina, a ko le ni igbekele ninu rẹ lati ṣiṣẹ lori ọrọ Ọlọrun ti o n kọ. Bẹẹ si ni adura wa le ma le daabo bo ọ kuro lọwọ awọn ti o n lepa lati yan ọ jẹ ati lati pa aye rẹ run. Adura mi fun ọ wa ni pe ki Ọlọrun ma kun ọkan rẹ pẹlu oye ọrọ rẹ ti o peye ni igbakigba ti o ba ti gbọ ọrọ naa, ki O si tun fun ọ ni okun lati ṣiṣẹ tọ ọrọ ti o ba gbọ, ki o ma ba tun ṣe fi igba kankan jẹ ẹran ijẹ fun awọn opurọ tabi ẹlẹtan yowu ti Satani le ran lati ba aye rẹ jẹ mọ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ atata.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
