Fi ara rẹ si ipo iwulo | Pst. J.O. Lawal
Belu 07, 2021 | Nọmba: Vol. 10, No. 27
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Belu 2021. Mo si wa gbadura pe ki Ọlọrun ro ọ ni agbara lati pọ si ni iwulo ati ilere-lori ninu ijọba rẹ ninu ọsẹ naa ati ni gbogbo eyi ti o ku ni ọjọ aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitori pe iwulo awọn eniyan mu ọmu laya Ọlọrun gidigidi. Idi si ni yi ti O ṣe ti bukun ẹnikọọkan ti o wa laye lara wọn pẹlu amuyẹ kan tabi omiran lati jẹ ki wọn le wulo fun ara wọn ati fun awọn yoku ti o wa ni aye. Idi naa si tun ni yi ti O fi bukun ọmọ rẹ kọọkan pẹlu okereju ẹbun ẹmi kan lati jẹ ki wọn wulo, ki wọn si lere lori ninu ijọba rẹ. Nitorina, ti a ko ba wulo ninu ijọba rẹ, paapaa julọ laarin awọn ti a jọ wa ninu ijọ kaa naa, ko ni jẹ nitori pe a ko le wulo ni; dipo bẹẹ, yoo jẹ nitori pe a kọ lati wulo ni.
Bẹẹni, ko si ni ki idi ma wa ti a ko fi ni wulo fun Ọlọrun ati fun awọn eniyan rẹ. O le jẹ ẹru, ọrọ aye wa, anikanjọpọn tabi imẹlẹ. Ṣugbọn bi Oluwa ti ṣe tọka si fun wa, awọn ti o ba fi ara wọn si ipo iwulo pẹlu ẹbun ti Ọlọrun fun wọn nikan naa ni yoo jẹ ki wọn di pataki si ninu aye yi ati ninu ijọba rẹ. Ko si wa si nkan miran tii awọn ti o kọ lati wulo fun le reti ninu aye wọn ju adinku ninu pataki wọn, ilọsiwaju wọn ati awọn ohun rere miran laye yi. (Wo: Luuku 19:12-27)
Nitorina, ti o ko ba fẹ adinku pataki rẹ ninu ijọba Ọlọrun ati ninu awọn nkan ti aye miran, bẹrẹ si ni fi ara rẹ si ipo iwulo pẹlu awọn ẹbun ẹmi rẹ, ẹbun ti ara ti o ni, amuyẹ rẹ, imọ ijinlẹ rẹ ati nkan ini rẹ. O ṣi le bẹrẹ ni kiakia lati arin wa. Nkan akọkọ ti o si nilo lati ṣe eyi naa ni ki o kọkọ ronu nipa bi o ṣe le lo awọn ibukun Ọlọrun ninu aye rẹ lati ran igbagbọ ẹnikọọkan wa lọwọ, ki o si bẹrẹ si ni lo awọn Ibukun naa lati ṣe bẹẹ pẹlu ẹmi itẹriba.
Fun apẹẹrẹ, wo nkan ti a sọ nipa Apolo, lẹyin igba ti a ti fi ọna Oluwa han ni ọna ti o peye: “Nigba ti o si n fẹ kọja lọ si Akaya, awọn arakunrin gba a ni iyanju, wọn si kọwe si awọn ọmọ ẹyin ki wọn ki o gba a: nigba ti o si de, o ran awọn ti o gbagbọ nipa oore-ọfẹ lọwọ pupọ.” (Iṣe Apọsiteli 18:27) Njẹ o ri bayi? Ni kese ti Apolo de si aarin awọn ara Kọrinnti naa ni o ti bẹrẹ si ni ṣe awọn nkan ti o ran igbagbọ wọn lọwọ ni ọna ti o ga.
Iwọ wa n kọ o? Ki ni iwọ naa n ṣe lọwọlọwọ yi lati ran igbagbọ awọn miran ninu ijọ yi lọwọ? Ki ni o n ṣe lati ri pe wọn fi ara wọn jin fun Ọlọrun ati igbe aye ododo siwaju ati siwaju si? Ti ko ba si nkankan ti o n ṣe lati ran idagbasoke igbagbọ wa lọwọ, a jẹ pe o n kuna niyẹn. Ki a si sọ otitọ, o ko yatọ si ẹnikẹni ti o le ma ṣiṣẹ lati pa igbagbọ wa run. Bẹẹ ṣi ni a ri awọn eniyan kaakiri awọn ijọ Ọlọrun loni ti wọn n pa igbagbọ awọn ara wọn run tabi fi idibajẹ ba a dipo ki wọn ma ran an lọwọ. Iru awọn ẹni bẹẹ ko wa ni lọ lai jẹ iya ẹṣẹ wọn, bi a ti ṣe ri ninu iwe mimọ, gẹgẹ bi iwọ naa ti o ko ṣe nkankan lati ran igbagbọ awọn ara rẹ lọwọ ko ṣe ni lọ lai jẹ iya. (Wo: 1Timoti 1:18-20)
Nitori naa, ji kuro loju orun rẹ, ki o si bẹrẹ si ni fi ara rẹ si ipo iwulo fun Ọlọrun ati fun awọn eniyan rẹ. Ẹnu yoo si wa ya ọ lati ri bi aye rẹ yoo ṣe bẹrẹ si ni pọ si ni pataki laarin awọn ọmọ Ọlọrun ati laarin awọn ti aye yi.
Ki o ni ọṣẹ alarinrin.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Fi ara rẹ si ipo iwulo | Pst. J.O. Lawal Read More »
