Fi ara rẹ si ipo irẹlẹ. | Pst. J.O. Lawal. | Òkúdù 12, 2022. | Vol. 11, No. 6
Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òkúdù 2022. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki ọkan rẹ wa ni itẹriba niwaju rẹ ni gbogbo igba, ki ainitẹsiwaju ma ba gba ijọba aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Gẹgẹ bi a ti sọ fun wa ninu bibeli, idi ti angẹli Ọlọrun ti a n pe ni Satani loni fi di ẹni ti a n pe ni Satani ni igberaga. Ni ibẹrẹ-pẹpẹ, Ọlọrun da ni pipe ninu ẹwa ati ninu ọgbọn, a si tun fi si ipo nla laarin awọn angẹli Ọlọrun yoku. Ṣugbọn nigba ti o jẹ ki ẹwa rẹ ko si lori, Ọlọrun re jabọ kuro ni ipo atata ati ipo agbara ti o wa. (Isikiẹli 28:11-19)
Ki wa ni idi ti a fi sọ eyi fun wa ninu bibeli? Oun naa ni ki a le mọ pe Ọlọrun korira igberaga. Ki lo si fa ti O fi korira igberaga? Idi ni pe igberega jẹ ami wipe a ko fẹ gbe oriyin ti o jẹ tirẹ fun lori awọn nkan daradara ti a ni tabi ti a n gbe ṣe. Bi a si ti ri ninu bibeli, gbogbo wa ko jẹ nkankan lalaisi Ọlọrun ati pe a ko le da ohunkohun ni lailisi rẹ. Oun ni ẹlẹda wa ati ẹlẹda ohun gbogbo ti o n bẹ. Nitorina, ko si nkan ti a le sogo le lori ninu aye yi tabi ninu aye eyi ti o n bọ. Òun ti wà ki ohun gbogbo to wa ati pe ohun gbogbo wa lati ọdọ rẹ, wọn si tun jẹ tirẹ. (Wo: Saamu 24:1; Kolose 1:16:17; Ifihan 4:11)
Ṣugbọn nigba ti a ba kọ lati gba ododo yi, ti a si bẹrẹ si ni ṣe bi pe a ja mọ nkan, boya si Ọlọrun tabi si awọn eniyan, nṣe ni a n gbe ara wa gori ẹṣin aáyán, ti a si n fi ara wa si ipo ti Ọlọrun yoo fi re wa jabọ, gẹgẹ bi O ti ṣe re Satani jabọ. Bibeli sọ wipe, “Ọlọrun n kọ oju ija si awọn agberega; ṣugbọn O n fi oore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ.” Nitorina, iru ẹni yowu ti a jẹ tabi ipo yowu ti a wa ni aye yi, ni kete ti a ba ti fi aye gba igberaga ninu aye wa, ni kete ti a ba ti bẹrẹ si ni ronu tabi wiwu bi igba ti o jẹ pe Ọlọrun ni wa naa ni a o ti ri pe O ti n doju ija kọ wa. Ti a ba si wa kọ lati ronupiwada ni kiakia, ko ni pẹ rara ti a o fi ri pe a ti di ẹni itẹmọlẹ tabi pe a ti di ero ọrun apadi. (Wo: Jemisi 4:6; 1Peteru 5:5)
Nitorina, ma ṣe fi aye silẹ fun irufẹ igberaga kankan ninu aye rẹ, bi o ti wu ki aye ma lọ ni mẹlọmẹlọ fun ọ to tabi bi ipo atata ti o wa ti le ga to tabi bi o ti wu ki o wulo ni ọwọ Ọlọrun to. Ranti pe Satani naa ti fi igba kan ri jẹ ohun elo iyin ti o ga ni ọwọ Ọlọrun. Ṣugbọn igberaga ba aye rẹ jẹ. O ṣi le ba aye awa naa jẹ pẹlu. O le fi idibajẹ sinu ẹwa, ọgbọn, imọ, ipo ati iwulo wa, ti awa naa ba fi aye gba. O le sọ wa di eranko buburu, ẹranko buburu ti Ọlọrun ko ni fẹ ba ni ohunkohun ṣe pẹlu.
Ṣe nkan ti o wa fẹ ni eyi? Ṣe o wa fẹ di ẹni ti Ọlọrun yoo ma lepa lati gbe ju sọnu tabi palẹ rẹ mọ? Mo mọ pe o ko fẹ ki nkan ri bẹ fun ọ. Ṣugbọn nkan le papa ri bẹ fun ọ, ti o ba fi aye gba irufẹ igberaga kan tabi omiran ninu aye rẹ, Nitori eyi, ṣọ ara rẹ. Kiyesi bi o ti ṣe n ba Ọlọrun ati awọn eniyan lopọ. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun ṣi oju rẹ si irufẹ igberaga yowu ti o le wa ninu rẹ, ki o ba le ṣe ohun ti o tọ nipa rẹ ki o to yọri si iṣubu rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Fi ara rẹ si ipo irẹlẹ. | Pst. J.O. Lawal. | Òkúdù 12, 2022. | Vol. 11, No. 6 Read More »

