Iranṣẹ gbogbo eniyan | Paito J.O. Lawal
Ọjọ: Owara 24, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 25
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Ọwara 2021. Adura mi si pe ki o lo eyi ti o ku ninu ọdun yi ninu ẹkunrẹrẹ ayọ Ẹmi, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ṣe n bẹrẹ ọsẹ yi, jẹ ki n ran ọ leti ọrọ Jesu Oluwa wa ti o sọ wi pe, “…Bi ẹnikẹni ba n fẹ ṣe ẹni iwaju, oun naa ni yoo ṣe ẹni ikẹyin gbogbo wọn, ati iranṣẹ gbogbo wọn.” (Maaku 9:35) Pẹlu nkan ti Oluwa sọ nibiyi, kedere ni a ri pe Ọlọrun ko lodi si ki awọn ọmọ rẹ di asiwaju tabi ẹni akọkọ ninu aye yi. Bi a tilẹ ṣe ri, lara awọn nkan ti o ṣeleri lati ṣe fun awọn ọmọ Isiraẹli, ti wọn ba pa aṣẹ rẹ mọ, ni lati sọ wọn di ori dipo iru ni aarin awọn orilẹ-ede aye gbogbo (Ditaronomi 28:13). Nitorina, ko lodi si erongba rẹ ki iwọ ati emi jẹ ori dipo iru nibikibi ti a ba ti ba ara wa ninu aye yi.
Amọ ọna wo wa ni a le gba jẹ irufẹ ori ti Ọlọrun fẹ ki a jẹ, ti ko si ni mọ ni aye yi nikan sugbọn ti yoo tun jẹ bẹẹ gẹgẹ ninu ijọba ayeraye rẹ pẹlu? Bawo ni a ṣe le di ipo pataki mu ninu eto rẹ fun ohun gbogbo? Oun naa ni Oluwa n ba wa sọrọ le lori ninu ẹsẹ bibeli yẹn. O si sọ wipe nipa jijẹ iranṣẹ gbogbo eniyan ni.
Ki wa ni o tunmọ si lati jẹ iranṣẹ fun gbogbo eniyan? Ṣe o wa ja si pe ki a di ọmọ ti gbogbo eniyan a ma pe ran niṣẹ ni bi? A bi ṣe o wa jasi pe ki a di akitan fun gbogbo eniyan, ki a di ẹni ti ẹnikẹni le ṣe baṣabaṣa bi o ba ṣe wu wọn? Rara o! Ki wa ni o tunmọ si?
Ni kukuru, a le mọ nkan ti o tunmọ si nipa wiwo bi Jesu Oluwa wa ṣe ṣe nigba ti o wa laye yi. Ranti pe O sọ wipe Oun ko wa sinu aye ki wọn ba le sin Oun ṣugbọn ki Oun ba le sin awọn eniyan, ki Oun si fi ẹmi Oun silẹ fun irapada ọpọ (Maaku 10:45). Bawo wa ni O si ṣe sin awọn eniyan? Ṣe nipa dida ọmọ ti gbogbo wọn n pe ran niṣẹ ni tabi dida ẹni ti wọn kan le ṣe bi o ba ṣe wu wọn si ni? Rara o! Dipo eyi, o sin wọn nipa lilọ lati ibikan si ibikan lati ṣe awọn nkan ti yoo mu ki ifẹ Ọlọrun wa si imuṣẹ ninu aye wọn.
Lotitọ, awọn akoko kan wa ti awọn eniyan bu u, ti wọn si tun gan an nitori awọn nkan ti O sọ nipa ibaṣepọ rẹ pẹlu Ọlọrun. Ki a tilẹ sọ otitọ, wọn papa wuwa aidara si, ti wọn si tun pa a nitori ti o pe ara rẹ ni Ọmọ Ọlọrun. Ṣugbọn ni gbogbo akoko ti O fi ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laarin awọn eniyan rẹ, gbogbo wọn pata ni o bọwọ fun ati awọn ọta rẹ gan paapaa.
Nitori naa, jijẹ iranṣẹ gbogbo eniyan ko tunmọ si pe ki a sọ ara wa di ẹni ti ko naani ara rẹ ati ti awọn eniyan le ṣe bi o ba ṣe wu wọn si. Dipo eyi, o tunmọ si pe ki a gbe aye wa ni ọna ti o jẹ wipe awọn nkan ti a ba ṣe tabi sọ yoo mu ete Ọlọrun wa si imuṣẹ ninu aye awọn ti o wa ni ayika wa ati awọn ti a n ba ṣepọ, lọna kan tabi omiran. Ti o ba si jẹ pe bi eyi ni a ṣe n ṣe, ko wa ni ja mọ nkankan ni oju wa lati ṣiṣẹ ẹru tabi ti ọmọ aperannisẹ, niwọn igba ti yoo ba yọri si imuṣẹ ete Ọlọrun ninu aye awọn ẹlomiran.
Igba kan wa, fun apẹẹrẹ, ti Jesu Oluwa wa fọ ẹsẹ awọn apọsiteli rẹ, nkan ti o jẹ iṣẹ fun awọn ẹru. O ṣe eyi lati fi han wọn pe oye tabi ipo lasan kọ ni o ma n sọ eniyan di giga bikoṣe igbaradi rẹ lati ṣe ohunkokun ti o ba tọ fun lati ṣe lati sin awọn ti o wa ni abẹ akoso rẹ, bi o tilẹ ni i ṣe pẹlu fifọ ẹsẹ wọn. Ṣe eyi wa jẹ ki awọn apọsiteli yi ri fin? Rara! Dipo bẹẹ, o jẹ ki wọn bọwọ fun gidigidi si ni. Yatọ si eyi, o tun jẹ apẹẹrẹ fun wọn lori nkan ti O ti n kọ wọn tẹlẹ pe ẹnikẹni ti o ba fẹ di ẹni akọkọ tabi ẹni giga ninu ijọba Baba rẹ gbọdọ ṣetan lati sin awọn miran ni ọnakọna ti yoo mu ki ifẹ Ọlọrun wa si imuṣẹ ninu aye wọn. (Wo: Johanu 13:1-17)
Ti awa naa, ẹwẹ, ba fẹ di ipo ti o ga ninu ijọba Ọlọrun Baba wa mu, a gbọdọ ṣetan lati sin awọn ara wa ati awọn ti o wa ninu aye yi pẹlu wa ni ọnakọna ti ifẹ Ọlọrun yoo fi wa si imuṣẹ ninu aye wọn. Ṣugbọn ṣe a o rẹ ara wa silẹ lati ṣe eyi bi abi nṣe ni a o tunbọ ma ro pe a to nkan ti a ko to? Adura mi ni pe ki a ṣe ọkan wa ni rirẹ silẹ lati sin gbogbo awọn ti Ọlọrun fẹ ki a si ni ọna ti yoo yọri si igbega wa ninu ijọba ayeraye rẹ. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Iranṣẹ gbogbo eniyan | Paito J.O. Lawal Read More »
