Iwa bi olorun

Ọ̀NÀ LÁTI TỌ́ ARA RẸ SÍ ÌWÀ-BÍ-ỌLỌ́RUN (2) | Pst. J.O Lawal |TÍMÓTÌ 4:7-11 | ỌJỌ́RÚ 25, ÈBÌBÍ 2022

ÀKỌ́SÓRÍ: “Má ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ tàbí ìtàn asán; ṣùgbọ́n tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run.” (Tímótì 4:11)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ

Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin lori ọna lati tọ ara wa si iwa-bi-Ọlọrun, a mẹnuba awọn ipese Ọlọrun fun wa lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun ati pataki ki a ṣe amulo wọn. Ki si wa ni awọn ipese wọnyi? Awọn naa ni Ẹmi mimọ, ọrọ Ọlọrun, anfaani adura gbigba, anfaani ibaṣepọ pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun ati iṣẹ iranṣẹ awọn angẹli. Ninu ẹkọ eyi ẹwẹ, a tun fẹ wo igbesẹ miran ti a nilo lati ma a gbe lati le tọ ara wa si iwa-bi-Ọlọrun. Lalai si mọ igbesẹ yi, ki a si ma gbe e, yoo ṣoro fun wa lati ma fi gbogbo igba gbe igbe aye ẹni ti o wa bi Ọlọrun. 

YẸRA FUN IBASEPỌ AIDỌGBA PẸLU AWỌN ALAIGBAGBỌ

Igbesẹ miran wo lo wa yẹ ki a ma gbe lati tọ ara wa si iwa-bi-Ọlọrun yatọ si pe ki a ma ṣe amulo awọn ipese Ọlọrun fun wa lati ṣe bẹẹ? Oun naa ni o ni i ṣe pẹlu yiyẹra fun ibasepọ ti ko dọgba pẹlu awọn alaigbagbọ. Iwọ naa wo ọkan lara awọn nkan ti Pọọlu sọ lori ọrọ yi: “Ki a ma tan yin jẹ: ẹgbẹ buburu ba iwa rere jẹ.” (1Kọrinnti 15:33) Ki ni idi ti o fi nira fun ọpọ lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun loni? Oun naa la ri ninu ọrọ ti Pọọlu sọ silẹ yi. O ni ki a ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni tan wa jẹ: ẹgbẹ buburu ma n ba iwa rere jẹ. Eyi jasi pe niwọn igba ti a ba n kọwọ rin pẹlu awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, o didan ki awa na ma wuwa bi ti wọn lẹkọkan tabi ni ọpọ igba. Niwọn igba ti a ba si ti n wuwa bi wọn ti ṣe n wuwa, ko si ni ki o ma mu ipalara wa fun igbe aye iwa-bi-Ọlọrun wa.

Pọọlu tun sọ eyi lori ọrọ yi kannaa: “Ẹ ma ṣe fi aidọgba dapọ pẹlu awọn alaigbagbọ: nitori idapọ kin ni ododo ni pẹlu aiṣododo? Idapọ ki ni imọlẹ si ni pẹlu okunkun? Irẹpọ kin ni Kirisiti ni pẹlu Belili? Tabi ipin wo ni ẹni ti o gbagbọ ni pẹlu alaigbagbọ? Irẹpọ ki ni Tẹmpili Ọlọrun ni pẹlu oriṣa? Nitori ẹyin ni tẹmpili Ọlọrun alaaye; gẹgẹ bi Ọlọrun ti wi pe, Emi o maa gbe inu wọn, emi o si maa rin ninu wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, wọn o si jẹ eniyan mi.” (2Kọrinnti 6:14-16) 

Ṣe o tun ri bayi? A ki wa nilọ nibiyi pe ki a ma ṣe fi aidọgba dapọ pẹlu awọn alaigbagbọ. Eyi tunmọ si pe ibadapọ pẹlu awọn alaigbagbọ pin si ọna meji pataki. Akọkọ ni ibadọpọ ti o dọgba. Eyi ni i ṣe pẹlu ibaṣepọ wa pẹlu awọn alaigbagbọ ti o jẹ obi wa, ọmọ wa, aya wa, ọkọ wa, ara wa, ibatan wa, aladugbo wa, ọga wa nibi iṣẹ, akẹgbẹ wa nibi iṣẹ tabi ni ile-iwe ati bẹẹbẹẹ lọ. A ko le sọ wipe a ko ni ni nkankan ṣe pẹlu awọn eniyan yi nitoripe alaigbagbọ ni wọn. A gbọdọ ni nkan ṣe pẹlu wọn, ki a si ma ṣe ojuṣe wa lori wọn ni gbogbo igba. Ayafi ti a ba fẹ fi aye yi silẹ nikan ni a ko ṣe ni ni nkankan ba awọn ẹni wọnyi ṣe papọ. (Wo: 1Kọrinnti 5:10)

Irufẹ ibadapọ keji ti a le ni pẹlu awọn alaigbagbọ, eyi ti a si n kilọ fun wa ninu bibeli pe ki a ma ni, ni ibapadọ aidọgba. Ki ni idi ti a si ṣe n kiwa nilọ pe ki a ma ni irufẹ ibadapọ yi pẹlu wọn? Idi ni pe nigba ti a wa jẹ ododo, awọn je aiṣododo. Nigba ti awa si jẹ imọlẹ, awọn jẹ okunkun. Bẹẹ si ni, nigba ti awa jẹ Kirisiti, awọn jẹ Belili. Eyi lo wa tunmọ si pe, ni akọkọ, ibaṣepọ yowu ti a o ni pẹlu awọn alaigbagbọ ti yoo sọ wa di alaiṣododo si Ọlọrun tabi si eniyan jẹ eyi ti a gbọdọ yẹra fun. 

Nkan ti a n sọ ni pe niwọn igba ti ibaṣepọ wa pẹlu alaigbagbọ kan tabi omiran tabi awọn eto tabi irinṣẹ ti wọn gbe kalẹ ba ti jẹ eyi ti ko ni jẹ ki a jẹ olotitọ ni sisin Ọlọrun tabi si awọn eniyan, yala awọn ẹbi wa ni, ijọba ni, ijọ Ọlọrun ni, akẹgbẹ wa ni tabi aladugbo wa ni, ko tọna. A si gbọdọ fi opin si, ti o ba jẹ wipe o ti n waye. Aijẹbẹ, a ko ni le gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun. 

Nkan keji ti ọrọ yi tun fi ye wa ni pe ibadapọ yowu ti a le ni pẹlu awọn alaigbagbọ ti o si le sọ imọlẹ wa di okunkun jẹ eyi ti ko gbọdọ waye rara. Bẹẹni ibadapọ yowu ti a le ni pẹlu wọn ti yoo jẹ ki a bẹrẹ si ni ṣe nkan ikọkọ tabi ti ko ni jẹ ki a le ba wọn wi ninu aiwa-bi-Ọlọrun wọn jẹ eyi ti a ko gbọdọ jẹ ki o waye. Nitori irufẹ awọn ibaṣepọ yi ni o ma n sọ ọmọ Ọlọrun di ẹlẹṣẹ nikẹyinkẹyin.

Nkan ẹkẹta ti ọrọ Pọọlu tun n fi ye wa ni pe ibadapọ yowu ti a le ni pẹlu awọn alaigbagbọ ti ko ni jẹ ki a le ṣe iyatọ wa si wọn, ti ko ni jẹ ki awọn eniyan mọ pe ti Kirisiti ni a jẹ ati pe a ko ki i ṣe ti Eṣu jẹ eyi ti a ko gbọdọ faye gba. Ibadapọ aidọgba ni. O si wa ṣe ni laanu loni pe ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun ni a ko le ṣe iyatọ laarin wọn ati awọn alaigbagbọ ti wọn jọ n ko ara wọn kaakiri. Idi si ni pe aguntan wọn ti ba aja rin, o si ti jẹ ìgbẹ́, o ti ba ẹkùn rin, o ti wọ ẹ̀wù ẹ̀jẹ̀. 

Lotitọ, kíkọ̀ lati ni ibaṣepọ aidọgba pẹlu awọn alaigbagbọ le ma ba irọrun de. O tilẹ le fi aye silẹ fun inunibini lati ọdọ wọn. Ṣugbọn ti ibaṣepọ ayeraye ti a ni pẹlu Ọlọrun ba jẹ wa logun, a gbọdọ fi ara da ohun yowu ti o ba ti ẹyin kíkọ̀ lati fi aidọgba lo pọ pẹlu awọn alaigbagbọ le mu lọwọ. Aijẹbẹ, gbogbo awọn iwa palapala, iwa omugọ ati iwa eeri ti a ti kọ silẹ nitoripe a jẹ ti Jesu ko ni ṣalai tun ma ma fi ara han ninu aye wa.

ỌRỌ IPARI

Ti a ba fẹ ṣe aṣẹyọri ni gbigbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun, a gbọdọ yẹra fun fifi aidọgba ba awọn alaigbagbọ ti o wa ninu aye wa tabi ni ayika wa lopọ. Eyi ni yoo fi iyatọ han laarin awa ati awọn. Aijẹbẹ, ibaṣepọ wa pẹlu wọn ko ni ṣai pa igbe aye iwa-bi-Ọlọrun wa lara.

IBEERE

Irufẹ ibadapọ melo ni a le ni pẹlu awọn alaigbagbọ? Darukọ wọn.

Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022,  Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ọ̀NÀ LÁTI TỌ́ ARA RẸ SÍ ÌWÀ-BÍ-ỌLỌ́RUN (2) | Pst. J.O Lawal |TÍMÓTÌ 4:7-11 | ỌJỌ́RÚ 25, ÈBÌBÍ 2022 Read More »

Ọ̀NÀ LÁTI TỌ́ ARA RẸ SÍ ÌWÀ-BÍ-ỌLỌ́RUN AYỌKA: TÍMÓTÌ 4:7-11 ỌJỌ́RÚ 27, IGBE 2022

ÀKỌ́SÓRÍ: “Má ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ tàbí ìtàn asán; ṣùgbọ́n tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run.” (Tímótì 4:11)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ

Bi a ti ṣe kọ ninu ẹkọ ti a kọ sẹyin lori titọ ara wa si iwa-bi-Ọlọrun, iwa-bi-Ọlọrun ko ki ṣa dede jẹyọ ninu aye eniyan, bi o tilẹ ti ni amuyẹ lati ọdọ Ọlọrun fun un. A gbọdọ tọ ara wa lati wa bi Ọlọrun ki iwa-bi-Ọlọrun to le bẹrẹ si ni jẹyọ laye wa lọna ti o ni apẹẹrẹ. Aijẹbẹ, bi a tilẹ pe ara wa ni ọmọ rẹ, iwa ati iṣeṣi wa le ma fi taratara jọ tirẹ ni ọna pupọ. Eyi si ni o jẹ ki ọpọ Kirisitiẹni loni ri bi wọn ti ṣe ri, ti igbe aye wọn ko si wú awọn ti o wa ni ayika wọn lori debi pe wọn yoo fẹ ba Ọlọrun ni ajọṣepọ. Ti a ba wa fẹ ki awọn ti o wa ni ayika wa tabi ni awujọ wa gba iwuri lati ba Ọlọrun ṣepọ nipasẹ igbe aye ti a ngbe, a gbọdọ tọ ara wa lati wa bi i rẹ.

Ọ̀NÀ LÁTI TỌ́ ARA RẸ SÍ ÌWÀ-BÍ-ỌLỌ́RUN

Bawo wa ni a ṣe le tọ ara wa si iwa-bi-Ọlọrun? A le tọ ara wa si iwa bi Ọlọrun nipa ṣiṣe amulo awọn ipese rẹ fun wa lati gbe igbe aye ti o dabi tirẹ. Ranti wipe Peteru ṣọ eyi fun wa nipa iwa-bi-Ọlọrun: “Gẹ́gẹ́ bí agbára Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí í ṣe ti ìyè àti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa ògo áti ọlá ńlá rẹ̀. Nípa èyí tí o ti fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó si ṣe iyebíye fún wa: pé nìpa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin kí ó le di alábáápín nínú ìwà bí Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yin bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ ti n bẹ ninu aye nipa ifẹkufẹẹ.” (2Pétérù 1:3-4) Njẹ o ri bayẹn? Nipa mimọ Ọlọrun, a ti di ajogun awọn ipese rẹ fun wa lati gbe igbe aye ìwà-bí-Ọlọ́run.

Lafikun, Pọọlu naa sọ eyi fun wa: “Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ń mú ìgbàlà wà fùn gbogbo ènìyàn ti farahàn. Ó ń kọ wa pé, kí á ṣẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé, kí a si maa wà ní àìrékọjá, ní òdodo, àti ní ìwà-bí-Ọlọ́run ní ayé ìsinsìnyí.” (Títù 2:11-12) Ṣe o tun ri bayẹn? Ẹkọ wa fun gbogbo wa lati kọ lori bi a ti ṣe n gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun ninu aye ti a wa yi. A si le kọ ẹkọ yi nipasẹ oore-ọfẹ Ọlọrun, eyi ti a tun le pe ni ipese rẹ.

Ki wa ni awọn nkan ti Ọlọrun ti pese fun lati gbe igbe ayẹ bi tirẹ ninu aye yi, ti a si le ṣe amulọ wọn? Awọn naa ni iwọnyi:

–    Ẹ̀mí Ọlọ́run: Pataki ninu awọn ipese Ọlọrun fun gbogbo awọn ọmọ rẹ lati gbe igbe aye ìwà-bí-Ọlọ́run ni Ẹmi Mimọ rẹ ti O fun wa lati ma ba wa gbe titi lailai. Ki si ni idi ti Ọlọrun fi fun wọn ni Ẹmi rẹ lati ma ba wọn gbe titi lailai? Idi ni ki O ba le dari wọn sinu gbogbo ọtitọ ti wọn nilo lati mọ lati gbe irufẹ aye ti O fẹ ki wọn gbe ati lati fun wọn ni okun, igboya, oriya ati itunu ti wọn nilo lati gbe aye naa. Ọlọrun ti mọ pe ko si nkankan ti a le da se lailai jẹ wipe Ẹmi rẹ ṣe wa yẹ lati ṣe (Jòhánù 15:5). Idi naa niyi ti O fi fi Ẹmi rẹ jinki wa lọfẹ. Awa ni a wa gbọdọ kọ lati ma fi gbogbo igba rin pẹlu afiyesi pe a ko le gbe igba aye ìwà-bí-Ọlọ́run laifi ti Ẹmi mimọ ṣe. Niwọn igba ti a ba si ti da ara le Ẹmi yi fun okun, igboya, ifaraji ati ohun yowu ti a tun le nilo lati gbe igbe aye ti Ọlọrun fẹ ki a gbe, ko si ni ki a ma ṣe aṣeyọri ninu gbigbe igbe aye naa. (Wo: Ìsíkíẹ̀lì 36:27; Jòhánù 14:26; Jòhánù 16:12-15; 2Kọ́rínntì 3:4-6; Gàlátíà 5:16; Fílípì 3:3)

–    Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: Bi a ti ṣe sọ siwaju, a nilo lati ṣe amulo wiwa Ẹmi Ọlọrun ninu aye wa lati gbe igba aye iwa-bi-Ọlọrun. Amọ ti a ko ba mọ ọna lati ṣe eyi, wiwa rẹ ninu wa ko ni jamọ nkankan taarataara. Ọkan lara ọna ti a wa le gba ṣe amulo wiwa rẹ ninu wa ati pẹlu wa ni fifi ara wa jin fun ọrọ iwe mimọ. Nkan ti a n sọ nipe ọrọ Ọlọrun, ti a kọ silẹ fun wa ninu bibeli, jẹ ọkan lara nkan ti Ẹmi Ọlọrun ma n lo lati ṣe awọn Ọmọ Ọlọrun yẹ fun igbe aye iwa mimọ. Iwọ naa wo nkan ti Pọọlu sọ fun awọn alagba ijọ Efesu lori eyi: “Njẹ nisinsinyi, ara, mo fi yin le Ọlọrun lọwọ ati ọrọ oore-ọfẹ rẹ, ti o le gbe yin duro, ti o si le fun yin ni ini laarin gbogbo awọn ti Oluwa sọ di mimọ.” (Iṣe Apọsiteli 20:32) Nitorina, ẹnikẹni ti o ba fẹ mọ ifẹ Ọlọrun daju lori bi o ṣe yẹ ki o gbe aye rẹ lati wu u ninu ohun gbogbo, ki o si tun duro ṣinṣin ninu ifẹ rẹ naa ti o mọ gbọdọ fi ara rẹ jin fun ọrọ Ọlọrun. O gbọdọ maa ka a, ki o maa tẹti gbọ ọ, ki o si ma ṣe asaro ninu rẹ lojoojumọ ki o ba le yee, ki o si le ṣe amulo rẹ (Jọ́súà 1:8; Mátíù 13:1-23). Aijẹbẹ, ko si bi yoo ṣe le gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun.

–    Ànfààní àdúrà gbígbà: Ipese Ọlọrun miran fun awọn ọmọ rẹ lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun ni anfaani adura gbigba si i. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, gbogbo awa ti a jẹ ọmọ rẹ ninu Kirisiti Jesu ni a le tọ ọ wa pelu igboya ati laibẹru nigbakigba lati tẹwọgba awọn nkan ti O ti pese silẹ fun igbayegbadun wa ati igbayetẹlọrun wa (Éfésù 3:12; Hébérù 4:16). Nitorina, ẹnikẹni ninu wa ti o ba wa fẹ ri ifarahan iṣẹ Ẹmi Ọlọrun ninu rẹ ni ọna ti o peye, ti ko si fẹ ṣe alaini ohun ti o dara kankan lati gbe aye ti o wu Ọlọrun, gbọdọ fi ara rẹ jin fun adura gbigba, ni aisimi ati ni aiṣaarẹ. Bi Jesu Oluwa wa si ti fi ye wa, lalai ṣe pe a ba n fi gbogbo igba gbadura si Ọlọrun lati fun wa ni okun nipasẹ Ẹmi rẹ, ko si ni bi a ko ṣe ni ṣubu sinu idanwo Eṣu. Bẹẹni, o ṣeeṣe ki ọkan wa fẹ ṣe ohun ti o tọ, ti o si yẹ. Ṣugbọn niwọn igba ti ko ba ti si okun fun ailera ara wa, ko si bi iwa-bi-Ọlọrun yoo ṣe ṣeeṣe fun wa. Idi niyi ti a ko fi gbọdọ fi adura gbigba ṣere rara, boya adura gbigba fun ara wa ni o tabi adura gbigba pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun miran, paapaa julọ awọn ti ijọ wa wa. (Wo: Lúùkù 22:31-32&39)

–    Ànfààní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ọlọ́run míràn: Pataki lara awọn nkan ti ẹnikẹni ti o ba ṣẹṣẹ di atunbi ninu Jesu gbọdọ mọ ni pe nṣe ni a tun un bi sinu idile Ọlọrun, sinu agbo ile igbagbọ, sinu ara Kirisiti (1Kọ́rínntì 12:12-13; Gàlátíà 6:10; 1Tímótì 3:14-15). Nitorina, igbe aye ìwà-bí-Ọlọ́run ati ìgbáyégbádùn ko ki i ṣe adagbe ni fun un bikoṣe eyi ti yoo gbe pẹlu itọni, iranlọwọ ati ibawi awọn ọmọ Ọlọrun yoku. Idi si ni yi ti o fi gbọdọ pọn ni dandan fun ara rẹ lati darapọ mọ agbo awọn ọmọ Ọlọrun yowu ti o ba wa ni arọwọto rẹ, ti o si ri pe oye bi a ti ṣe n gbe aye tẹ Ọlọrun lọrun ye wọn. Awọn wọnyi ni Ọlọrun yoo ma lo lati kọ ọ, lati gba a niyanju, lati tu u ninu ati ran a lọwọ ni akoko ailera rẹ ati lati ṣe aṣọna fun ẹmi rẹ. Aijẹbẹ, ko si bi yoo ṣe le gbe igbe aye ìwà-bí-Ọlọ́run. Ọpọ ni aimọkan ti wa jẹ ki wọn ṣe aṣiṣe lori eyi, ti Eṣu si ti rapala wọle lati ṣi wọn lọna ati lati jẹ wọn niya, nitoripe wọn ko ṣe amulo ti o peye ibaṣepọ ti wọn ni anfaani rẹ pẹlu ijọ ọmọ Ọlọrun kankan. Wọn ro lọkan wọn pe awọn le da igbe aye Kirisitiẹni gbe ni. Amọ aṣiṣe yi gan an ni Eṣu lo lati ya wọn sọtọ lati rẹ wọn jẹ. Ti awa naa ko ba si fẹ ki Eṣu ni anfaani lati ya wa sọtọ kuro lọdọ awọn ọmọ Ọlọrun ti o le ran igbagbọ wa ati ìwà-bí-Ọlọ́run wa lọwọ, a gbọdọ mu ibaṣepọ pẹlu awọn ọmọ ijọ wa ni ọ́kúnkúndùn. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 20:28-31; Éfésù 4:11-16; Hébérù 3:12-13; Hébérù 10:24-25; Hébérú 12:15-17)

–    Iṣẹ iranṣẹ awọn angẹli Ọlọrun: Bibeli sọ eyi fun wa nipa awọn angẹli: “Ẹ̀mí tí ń jísẹ́ ha kọ́ ni gbogbo wọn í ṣe bí, tí a n rán lọ láti maa jọ́sìn nítorí àwọn tí yoo jogún ìgbàlà?” (Hébérù 1:14) Ki ni nkan ti eyi n jẹ ki o ye wa? O n jẹ ki o ye wa pe iṣẹ iranṣẹ gbogbo awọn angẹli ni lati ṣiṣẹ ran awọn ọmọ Ọlọrun lọwọ. Idi si ni yi ti a fi kọ wa lati ma ṣoore fun awọn eniyan, paapaa-julọ awọn alejo ati awọn ti a ko mọ ri. Nitoripe a ko le sọ igba ti a o ṣoore fun angẹli kan tabi omiran ti a ran lati yọ wa ninu ewu tabi ran wa lọwọ (Hébérù 13:2). A si ri oniruuru àpẹrẹ ninu bibeli awọn ti a ran angẹli si lati ran igbe aye iwa mimọ wọn lọwọ tabi laye yọ wọn kuro ninu ewu ti o sọrọ mọ gbigbe igbe aye yi. Lọọti, Daniẹli ati Jesu Kirisiti Oluwa wa si wa lara awọn wọnyi (Jẹnẹsisi 19; Daniẹli 6; Luke 22:39-44). Nitorina, gbogbo awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ni a nilo lati ma fi gbogbo igba fi sọkan pe awọn angẹli Ọlọrun rọgba yi wa ka lati ran igbe aye ìwà-bí-Ọlọ́run wa lọwọ. Niwọn ti a ba si n rin pẹlu afiyesi yi, ẹru ko ni fi igba kankan ba wa lati duro lori ẹsẹ wa lati ṣe ifẹ Ọlọrun, bi o ti wu ki inunibini awọn ti o wa ni ayika tabi awujọ wa to. Aiwa ni oye yi ni o jẹ ki ọpọ ọmọ Ọlọrun fi ibẹrubojo fi ara wọn jin fun oniruuru ẹṣẹ ati iwa aitọ lawujọ wọn.

Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ

Igbe aye ìwà-bí-Ọlọ́run jẹ eyi ti ọmọ rẹ kọọkan gbọdọ lepa lati gbe. Idi si ni pe Ọlọrun ti pese gbogbo nkan ti wọn nilo lati gbe igbe aye yi fun wọn. Awọn ti o ba wa lepa lati ṣe amulo awọn ipese yi nikan naa ni yoo ri igbe aye yi gbe pẹlu irọrun, nitoripe Ẹmi Ọlọrun yoo ṣe ni irọrun fun wọn. 

ÌBÉÈRÈ

–    Bawo ni o ṣe ṣe pataki si fun awọn ọmọ Ọlọrun lati ni oye ipese Ọlọrun fun wọn lati gbe igbe aye ti O fẹ ki wọn gbe?

–    Mẹnuba diẹ lara awọn nkan ti o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi.

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022,  Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ọ̀NÀ LÁTI TỌ́ ARA RẸ SÍ ÌWÀ-BÍ-ỌLỌ́RUN AYỌKA: TÍMÓTÌ 4:7-11 ỌJỌ́RÚ 27, IGBE 2022 Read More »