Akori: Iyi dipo itiju | Lati ọwọ: J.O. Lawal | Ọjọ: Igbe 24, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ Nọmba: Vol. 10, No. 51

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu yi. Adura mi si pe ki o ni iriri igbega iyanu ni gbogbo ibi ti a ti pa ọ ti, yan ọ jẹ, pọn ọ loju tabi ja o lole, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitori pe o wa ni ibamu pẹlu nkan ti Ọlọrun ti sọ siwaju lati ẹnu ọkan lara awọn wolii rẹ igbaani nipa awọn eniyan rẹ. Ki si ni o sọ? O sọ wipe, “Kiyesi i, nigba naa ni emi o jẹ awọn ti n pọn ọ loju niya: emi a gba atiro la, emi o si ṣa ẹni ti a le jade jọ; emi o si sọ wọn di ẹni iyin ati olokiki ni gbogbo ilẹ ti a ti gan wọn.” (Sẹfanaya 3:19)

Njẹ o ri bayi? Akọkọ, Ọlọrun ṣe ileri lati ba awọn ti o n pọn awọn eniyan rẹ loju wi. Nitorina, ti a ba ri awọn ti o n pọn iwọ naa loju lọwọlọwọ yi, mo fẹ ki o mọ pe opin ti de ba iṣẹ ọwọ wọn. Idi si ni pe dandan ni ki Ọlọrun na ọwọ gan wọn, ki O si da ṣeriya fun wọn gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wọn ti ri. Ko wa ki i ṣe iṣẹ tirẹ ni lati mọ nkan ti yoo ṣe fun wọn bi ko ṣe iṣẹ tirẹ. Ṣugbọn o le mọ daju pe nigbati ti o ba ṣetan pẹlu wọn, wọn ko tun ni lailai ronu lati pọn ẹlomiran loju mọ, niwọn igba ti wọn ba ṣi n mi. Ti o ba bere lọwọ rẹ, Ọba Abimeleki igba aye Aburahamu yoo sọ fun bi o ti ma n ri ti Ọlọrun ba n da ṣeriya fun awọn apọniloju, bi o tilẹ jẹ pe aimọkanmọkan ni o sun wọn de bẹ. (Wo: Jẹnẹsisi 20)

Siwajusi, Ọlọrun sọ pe Oun yoo bu okiki ati iyi kun awọn eniyan rẹ ni gbogbo ibi ti wọn ti ba itiju pade sẹyin. Eyi ni yoo si jẹ iriri ti iwọ naa, ti o ba gba ọrọ rẹ pẹlu igbagbọ. Yoo jẹ ki awọn eniyan yọ mọ ọ ni gbogbo ibi ti wọn ti gan ọ tabi doju ti ọ tẹlẹ.

Ranti pe O ṣe ohun ti o jọ eyi fun Josefu. Ni ibi kanna ti o ti sinru gẹgẹ bi ẹru ati ẹlẹwọn ni o tun ti pada wa ṣiṣẹ gẹgẹ bi adari ijọba. Wa wo bi awọn eniyan bi Pọtifa ati aya rẹ yoo ṣe ma ṣe si i lẹyin-ọ-rẹyin. Iyẹn jẹ ọkan lara apẹẹrẹ bi Ọlọrun ti ṣe le gbe eniyan soke, ki O si tun bu iyi kun wọn ni ibi ti a ti gan wọn tẹlẹ. (Wo: Jẹnẹsisi 39-41)

Nitorina, ma ṣe ba ọkan jẹ, ipo yowu ti o le wa laye lọwọlọwọ yi. Dipo bẹẹ, tẹwọgba ọrọ Ọlọrun si ọ lori igbega ati iyi rẹ. Bẹẹni, tẹwọgba ọrọ rẹ nipa sisọ nkankanna pẹlu rẹ, bi o ti wu ki nkan ri fun ọ ni akoko yi. Ti o ko ba si rẹwẹsi, o di dandan ki o ni iriri imuṣẹ ọrọ rere rẹ nipa rẹ ni akoko ti o tọ.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Akori: Iyi dipo itiju | Lati ọwọ: J.O. Lawal | Ọjọ: Igbe 24, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ Nọmba: Vol. 10, No. 51 Read More »