latori tabili paito

Má sọ ààyè rẹ nù

Má sọ ààyè rẹ nù | Pásítọ̀ J.O. Lawal | LTB | Ògún 28, 2022

Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 17

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ tayọtayọ si ọjọ Isinmi ti o kẹyin oṣu yi, oṣu Ògún 2022. Mo si gbadura pe a ko ni gbe ipo rẹ ninu ijọba Ọlọrun ati Baba wa fun ẹlomiran, ni orukọ Jesu. Amin.

Lẹyin igbasoke Jesu Oluwa wa, awọn ọmọ ẹyin rẹ korajọpọ si Jerusalẹmu, wọn si ṣe ipade lati yan ẹnikan lati rọpo Judasi Isikariọti. Luuku, ninu akọsilẹ rẹ lori eyi, sọ wipe Peteru sọ bayi, “Nitori a ṣaa ti kọ nipa rẹ ninu iwe Saamu pe, ki ibujoko rẹ di ahoro, ki ẹnikẹni ki o ma si ṣe gbe inu rẹ, ati ipo rẹ, ni ki ẹlomiran gba.” (Iṣe Apọsitei 1:20) Njẹ o ri bayẹn? Peteru, ni asiko ti a n wi yi, pe akiyesi awọn ọmọ ẹyin yoku si nkan ti Iwe Mimọ sọ lori Judasi ati lori bi elemoran ṣe gbọdọ gba ààyè rẹ ninu ijọba Ọlọrun. Ki wa ni idi ti ẹlomiran ṣe gbọdọ gba ààyè ti o tọ si arakunrin yi? Idi ni wipe o sọ ààyè naa nu. Ki lo ṣi jẹ ki o padanu ààyè rẹ? Ojukokoro ni o jẹ ki o padanu rẹ.

Nibakanna, ọmọ Ọlọrun kọọkan ni o ni ààyè ninu ijọba Ọlọrun, ààyè ti Baba wa funrarẹ pese ni pataki silẹ fun. Jesu Oluwa wa tilẹ sọ fun wa pe awọn eniyan yoo wa lati ibi gbogbo ni agbaye lati gba ààyè ti Baba wa ti pese silẹ fun ẹnikọọkan wọn ninu ijọba rẹ (Matiu 8:11). Amọ ọtọ ni ki eniyan gba ààyè rẹ ninu ijọba Ọlọrun nigba ti o wa ninu ayé yi; ọtọ tun si ni ki o di ààyè yi mu titi de opin ohun gbogbo.

Judasi, bi awọn ọmọlẹyin Jesu Oluwa yoku, naa fi igba kan wa lati gba ààyè rẹ ninu ijọba Ọlọrun. Ṣugbọn o padanu rẹ ni ikẹyinkẹyin. Ọlọrun nikan ni o si mọ iye awọn ti o ti padanu ààyè wọn ninu ijọba rẹ, ti awọn miran si ti gba mọ wọn lọwọ. Nitorina, ko to fun wa lati mọ pe a ni ààyè pẹlu Ọlọrun ati Jesu Oluwa wa ninu ijọba wọn. O tun ṣe pataki ki a ma padanu ààyè wa pẹlu wọn.

Peteru, ninu episiteli rẹ keji, sọ eleyi fun wa: “Nitori naa ẹyin olufẹ, bi ẹyin ti mọ nnkan wọnyi tẹlẹ, ẹ maa kiyesara, ki a ma ba fi iṣina awọn eniyan buburu fa yin lọ, ki ẹ si ṣubu kuro ni iduro ṣinṣin yin.” (2Peteru 3:17) Ṣe o ri bayẹn? Ti a ko ba kiyesara, a le ṣubu kuro ni aaye wa ti o daju ninu ijọba Ọlọrun. Ojukokoro mu ki Judasi ṣubu. O si le mu ki awọn naa pẹlu ṣubu. Ti eyi ko be tilẹ mu wa ṣubu, igberaga, ifẹkufẹ, iṣọtẹ, ówu tabi arankan nkọ? Njẹ ọkan lara awọn nkan wọnyi ko ni bi wa ṣubu bi?

Ti Judasi Isikariọti ba ti kiyesara fun ojukokoro ni, ko ba ma ti ṣubu bi o ti ṣe ṣubu. Si wa ranti pe Oluwa ti kọ wọn lati kiyesara fun oniruuru ojukokoro (Luuku 12:15). O wa ṣeni laanu pe ko kọbiara si nkan yi. Nitori eyi, o ṣubu, o si sọ ààyè rẹ ninu ijọba Ọlọrun nu. Ti awa naa ba si kọ lati fiyesi awọn nkan ti O n ba wa sọ lori awọn nka ti o yẹ ki a kiyesara fun, o ṣeeṣe ki awa na pari irinajo wa bi ti Judasi.

Bẹẹni, a le rin irin-ajo kaakiri agbaye ni orukọ Jesu Oluwa, ki a si tun ṣe oniruuru iṣẹ nipasẹ agbara rẹ, gẹgẹ bi o ti ṣe ri fun Judasi Isikariọti. Ṣugbọn gbogbo awọn nkan wọnyi ko ni jamọ nkankan lẹyin-ọ-rẹyin, ti a ba padanu ààyè wa ninu ijọba rẹ. Adura mi si ni pe ki a mu ọkan wa duro ṣinṣin ninu otitọ ni gbogbo igba, ki a ma ba fi aye gba ohunkohun ti yoo jẹ ki a padanu ààyè wa ninu ijọba ayeraye Baba wa. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má sọ ààyè rẹ nù | Pásítọ̀ J.O. Lawal | LTB | Ògún 28, 2022 Read More »

Ki O ba le kọ ọ bi a ti ṣe n jagun | Paito J.O. Lawal

Ọjọ: Ẹrẹna 13, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 45

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Olurapada wa. Kaabọ sinu ọsẹ tuntun miran ninu oṣu yi. Mo gbadura pe ki a ma fi gbogbo ṣe ọkan rẹ yẹ pẹlu igboya ti o peye lati ṣe amulo oore-ọfẹ Ọlọrun lati rin ninu iṣẹgun lori idojukọ yowu ti o le ba pade ni aye yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọpọ igba ni awọn eniyan ma n fẹ mọ idi ti Ọlọrun nigbamiran fi ma n fi aye silẹ fun awọn ọmọ rẹ lati ni awọn idojukọ kan tabi omiran ni aye yi. Ṣe nitoripe ko ni ifẹ wọn ni? Rara o! Ṣe nitoripe ọrọ wọn ko fi taratara mumu laya rẹ ni? Rara o! Abi ṣe nitoripe ọrọ aye wọn ko jẹ logun ni? Rara o! Ki wa gan lo fa ti O fi ma n fi aye gba Satani, olori-ọta awọn ọmọ rẹ, lati kọju ija si wọn pẹlu oniruuru idojukọ ati idanwo ti o ṣeeṣe ki o pa wọn run?

Ka ma ṣaroye pupọ, a ni idahun ti o dangajia si awọn ibere yi ninu bibeli. Fun apẹẹrẹ, a sọ eyi fun wa ninu rẹ: “Ko si idanwo kan ti o ti i ba yin, bi ko ṣe iru eyi ti o mọ niwọn fun eniyan: ṣugbọn olododo ni Ọlọrun, ẹni ti ki yoo jẹ ki a dan yi wo ju bi ẹyin ti le gba; ṣugbn ti yoo si ṣe ọna atiyọ pẹlu ninu idanwo naa, ki ẹyin ki o ba le gba a.” (1Kọrinnti 10:13) Pẹlu nkan ti a sọ fun wa nibi, a ri idi mẹta pataki ti Ọlọrun fi n jẹ ki a dojukọ iṣoro ati idanwo laye. Idi akọkọ lara wọn si nipe awọn eniyan bi ti wa ti dojukọ irufẹ iṣoro tabi idojukọ yowu ti a le ma dojukọ, gẹgẹ bi a ti ri awọn eniyan ti o n dojukọ irufẹ iṣoro yowu ti a le ma dojukọ lọwọlọwọ yi. Nitorina, a ko gbọdọ ri idojukọ tabi idanwo kankan ti o ba ba wa gẹgẹ bi kayefi, nitoripe ko ki i ṣe kayefi. Dipo eyi, o jẹ eyi ti o wọpọ laarin awọn eniyan.

Idi miran ti Ọlọrun fi n fi aye silẹ fun wa lati dojukọ awọn nkan wọnyi ni pe Oun ni alakoso aye ati gbogbo ẹda lapapọ. Nitorina, O ni agbara lati sọ irufẹ iṣoro ti yo wa sinu aye wa tabi ti ko ni wa. O si ti wa ṣe ileri pe Oun ko ni jẹ ki a dojukọ iṣoro kankan ti a ko ni le bori. Nitorina, ti o ba wa sọdọ rẹ, mọ wipe idi ni pe Ọlọrun mọ pe o le bori rẹ. Njẹ o wa le bori iṣoro tabi idojukọ yowu ti o ba wa si ọdọ rẹ lotitọ bi? Bẹẹni, o le bori rẹ. O le bori rẹ nitoripe Ọlọrun yoo ri daju pe ohun gbogbo ti o nilo lati bori rẹ ni o wa ni ikawọ rẹ. Eyi si ni idi kẹta ti O fi n fi aye gba isoro lati ya ọdọ wa. O n fi aye gba wọn nitoripe O mọ pe ipese rẹ fun wa lati bori wọn ti wa nilẹ fun wa.

O wa yẹ ki o ri bayi pe ko si ikankan lara wa ti o yẹ ki o ma bẹru lati dojukọ iṣoro tabi idojukọ. Amọ ọpọ igba ni ẹru ma n ba wa lati dojukọ wọn. Ki si ni idi? A fẹ wa ni ifọkanbalẹ ati lalai ni idamu kankan ni gbogbo igba. Ṣugbọn otitọ ti o wa nibẹ ni pe ti a ko ba ba idojukọ pade laye, awọn ipo wa ti a ko le de, awọn nkan wa ti a ko le gbese ati pe awọn irufẹ igbadun ati itura kan wa ti a ko le ni iriri wọn. Niwọn igba ti Ọlọrun si mọ eyi, ni oorekoore, O ma n fi aye gba awọn iṣoro tabi idanwo oniruuru lati wọ inu aye wa wa. Nipa eyi, a o le kọ lati ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ ti o to bẹẹ, ti o si tun ju bẹẹ lọ, fun wa lati rin ni iṣẹgun lori wọn ati lati gba aye ti o tọ si wa laye.

Iwọ naa wo nkan ti a sọ lori ọrọ yi nipa bi O ti ṣe ba awọn ọmọ Isiraẹli lo pọ:

“Iwọnyi ni awọn orilẹ-ede ti Oluwa fi silẹ, lati maa fi wọn dan Isiraẹli wo, ani iye awọn ti ko mọ gbogbo ogun Kenaani; Nitori idi yii pe, ki iran awọn ọmọ Isiraẹli le mọ, lati maa kọ wọn ni ogun, ani iru awọn ti ko ti mọ ọn ni iṣaaju ri. Awọn ni awọn Filistini marun-un, ni gbogbo awọn Kenaani, awọn ara Sidoni ati awọn Hifi ti n gbe oke Lebanoni, lati oke Baali-hamoni lọ de atiwọ Hamati. Iwọnyi ni a o si maa fi dan Isiraẹli wo, lati mọ bi wọn o feti si ofin Oluwa ti o fi fun awọn baba wọn lati ọwọ Mose wa.” (Awọn Onidajọ 3:1-4) Njẹ o ri bayi? Ọkan lara idi ti Ọlọrun fi fi awọn ọta awọn ọmọ Isiraẹli yi silẹ si ayika wọn ni lati kọ wọn ni bi a ti ṣe n jagun. Eyi tunmọ si pe O fi wọn silẹ lati kọ wọn lati ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ. Ọwọ wọn lo wa ku si lati ṣe amulo ọrọ oore-ọfẹ rẹ fun iṣẹgun wọn lori awọn ọta yi tabi lati kọ ọrọ rẹ silẹ, si ikuna, abamọ ati idojuti.

Ni bakanna, a gbọdọ kọ lati ri gbogbo awọn idojukọ wa gẹgẹ bi ọna fun Ọlọrun lati kọ wa ni ijagun ẹmi dipo ti a o fi ma bẹru wọn tabi ti a o fi sọreti nu nitori wọn. Bẹẹni, a gbọdọ ri wọn gẹgẹ bi ọna lati mu ọrọ Ọlọrun ni ọkunkundun ati lati ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ fun iṣẹgun wa. Niwọn igba ti a ba si n gbe aye wa lọna yi, a ko tun ni fi igba kankan bẹru idojukọ kankan mọ. Dipo eyi, a o ma fi gbogbo igba darapọ mọ Pọọlu lati ṣe amulo oore-ọfẹ Ọlọrun ati lati ma sọ pe, “Ninu gbogbo nkan wọnyi, awa ju ẹni ti o ṣegun lọ nipa ẹni ti o fẹ wa.”

Ki O ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ki O ba le kọ ọ bi a ti ṣe n jagun | Paito J.O. Lawal Read More »