Ma jẹ kan da ọ lẹbi | Paito J.O. Lawal
Ọjọ: Belu 21, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 29
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Belu 2021. Mo gbadura pe ki ọsẹ naa kun akunwọsilẹ pẹlu didara ati ojurere Ọlọrun fun ọ ati fun ile rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, jẹ ki n ran ọ leti ọrọ Pọọlu, ti o sọ wipe, “Nitori naa, ẹ ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni maa ṣe idajọ yin ni ti jijẹ, mimu, ọjọ ase, tabi oṣu tuntun, tabi ọjọ isinmi: Awọn ti i ṣe ojiji ohun ti o n bọ, ṣugbọn Kirisiti ni otitọ.” (Kolose 2:16-17) Ki ni koko ọrọ apọsiteli yi nibi yi? Oun naa ni pe a ko gbọdọ gba ki ẹnikẹni ṣe idajọ wa pẹlu ofin Mose.
Ki wa lo fa ti Pọọlu fi sọ eyi? Idi ni pe loorekoore ni a o ma pade awọn eniyan ti wọn yoo fẹ ṣe idajọ wa tabi da wa lẹbi pẹlu ofin yi. Bẹẹni, loorekoore ni a o ma ri awọn eniyan ti wọn yoo fẹ ma gbe odiwọn didangajia wa niwaju Ọlọrun lori bi a ṣe fi ara jin si ofin yi to, ti wọn o si sọ ominira wa ninu Kirisiti di radarada (Galatia 2:4-5). Mo ranti, fun apẹrẹ, bi ọkan lara awọn ọmọbirin kan ti o darapọ mọ awọn akọrin wa nigba ti a kọkọ bẹrẹ awọn ipade wa ṣe bẹrẹ si ni ṣaroye nitori awọn arabinrin wa kan ti wọn n wọ ṣokoto wa fun isin. Nigba ti mo si bere lati mọ idi ti o ṣe n ṣe eyi, o sọ wipe idi ni pe nkan ti wọn n ṣe ko wa ni ibamu pẹlu nkan ti bibeli sọ. Abala bibeli wo si ni o n tọka si? Daju saka, abala ti a ti ri ofin Mose ni.
O wa ṣe ni laanu pe arabinrin yi gan funrarẹ ma n wọ ṣokoto ti ko ba si ni awọn ipade ṣọọṣi. Nigba ti mo si bere lọwọ rẹ pe, “Ṣugbọn mo ti ri ọ ni igboro lọpọ igba pẹlu ṣokoto. Ki wa lo de ti ko fi buru ki iwọ wọ ṣokoto ti o ko ba si ni ipade ṣọọṣi, ti o wa ro pe o buru ki awọn miran wọ ọ wa si ipade ṣọọṣi?” Eyi ti yoosi fi fun mi ni idahun taara, nṣe ni o kan sọ pe, “Mo ṣa mọ pe ko tọ, gẹgẹ bi ọrọ bibeli, ki obirin ma wọ awọn nkan ti o jẹ ti ọkunrin.” Bi o si ṣe dẹkun lati ma wa si awọn ipade ṣọọṣi wa niyẹn patapata.
Wayi o, nkan ti o ṣe yi ko ni orukọ meji ju agabagebe lọ. Agabagebe ni ki eniyan gba pe nkankan ko dara, gẹgẹ bi ọrọ Ọlọrun ti wi, ki o si tun ma ṣe e, boya ni kọrọ tabi ni gbangba. Agabagebe si tun ni pẹlu ti eniyan ba n da awọn miran lẹbi fun ohun ti oun funrarẹ n ṣe. O tilẹ tun wa burujai ti eniyan ba tun wa n da alare ni ẹbi. Ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun loni ni o si n da awọn ọmọ rẹ miran lẹbi. Ki si ni idi? Idi naa ni pe wọn ko kọbiara si otitọ inu iwe mimọ.
Fun apẹẹrẹ, gẹgẹ bi Pọọlu ti fi han wa ninu ẹṣẹ bibeli ti o wa ni oke yẹn, ọkan lara awọn otitọ ti a ko ki i kọbiara si ni pe Kirisitiẹni ko gbọdọ gba ki a da oun lẹbi lori nkan ti ofin Mose sọ. Ki si ni idi? Idi ni pe Ọlọrun ko fi igba kankan fun ni ofin yi. Dipo eyi, awọn ọmọ Isiraẹli ni a fun gẹgẹ bi ofin orilẹ-ede wọn nigba ti a ko wọn jade kuro ni Ijibiti. Ọlọrun si tun wa pa a ti sẹgbẹ kan nigba ti Jesu ti mu ohun ti o wa ninu rẹ ṣe, ti O si ti la ọna tuntun ati ọna iye lati sin in silẹ fun wa. (Wo: Ẹkisodu 24:12; Iṣe Apọsiteli 15:1-29; Heberu 8-10)
Njẹ gbogbo eleyi wa tunmọ si pe Kirisitiẹni ko le kọ nkankan nipa Ọlọrun lati ara ofin Mose bi? Rara! O le kọ ọpọlọpọ nkan lati ara rẹ. O ṣi yẹ ko tiraka de oju gongo lati kọ ohunkohun ti o ba le kọ lati ara rẹ. Amọ ṣa o, bi Pọọlu ṣe tẹsiwaju lati fi han wa, ojiji nkan ti Ọlọrun fẹ ki awọn eniyan rẹ mọ nipa rẹ ati nipa aye lasan ni ofin yi jẹ. Inu Kirisiti Jesu gangan ni otitọ wa. Eyi jasi pe ti o ba fẹ mọ otitọ nipa Ọlọrun ati nipa aye nitootọ, Jesu Kiristi Oluwa wa ni o gbọdọ gbajumọ. Oun ni ọna, otitọ ati iye. Ko si si ẹnikẹni ti o le wa si ọdọ Ọlọrun tabi mọ Ọlọrun tabi aye bikoṣe nipasẹ rẹ. (Wo: Johanu 14:4) Nitori naa, kiki otitọ ti a ba fihan nipa rẹ ninu iwe mimọ ni o yẹ ki a kọbiara si, ki a si tun gbajumọ. Lafikun, kiki otitọ ti a ba fihan ninu iwe mimọ nipa rẹ ni a gbọdọ ma lo gẹgẹ bi ipilẹ fun mimọ itunmọ awọn nkan miran ti a ba sọ ninu rẹ. Idi si ni pe otitọ ti a sọ nipa rẹ nikan ni o le sọ wa di ominira lati gbe igbe aye ti Ọlọrun fẹ ki a gbe.
Pẹlu gbogbo nkan ti a n sọ yi, o wa jasi pe a ko gbọdọ gba ki ẹnikẹni lo ogboju tabi ẹtan lati ti wa lati bẹrẹ si ni gbe igbe aye kankan ti ko wa ni ibamu pẹlu awọn nkan ti a fi han wa nipa Jesu Oluwa wa ninu Iwe mimọ. A ko si tun gbọdọ barajẹ tabi ba ọkan jẹ nitoripe inu awọn kan ko dun si wa nitoripe a kọ lati ma gbe aye wa ni ibamu pẹlu ofin Mose tabi awọn aṣa awọn eniyan kan ti o lodi si otitọ Jesu. Ṣugbọn o wa di dandan ki a banujẹ tabi ki a tilẹ gba fun awọn ti wọn fẹ fi ogboju tan wa kuro ninu otitọ Jesu pẹlu ẹsin tabi ifarajin eke, ti a ko ba mọ otitọ ti a kọ nipa rẹ ninu Iwe mimọ, ki a si tun tẹsiwaju ninu rẹ. Nitorina, mu gẹgẹ bi iṣẹ rẹ lati ma fi gbogbo igba kọ nipa otitọ ti a fi han nipa rẹ ninu Iwe mimọ, ki O si tun ma ṣe amulo rẹ. O ko si ni lugbadi asiṣe tabi aṣeju ẹnikẹni.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Ma jẹ kan da ọ lẹbi | Paito J.O. Lawal Read More »
