Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun yi, eyi ti ṣe ọsẹ akọkọ ninu oṣu Ògún ti ọdun 2022. Mo ṣi gbadura pe ki Ọlọrun, ẹni ti O ti n tọju wa latẹyin wa, tẹsiwaju lati ma pa wa mọn ni awọn akoko ewu yi, ki O si tun tẹsiwaju lati jẹ ki a ma pọ si ni iwulo, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ni oniruuru asiko laye yi, Ọlọrun ma n mọnmọn gbin wa sinu aye oniruuru eniyan lati le jẹ oluranlọwọ tabi olutunu fun wọn. Eyi ko si ki i ṣe lati fi wa ṣe ẹru fun wọn rara, bi o tilẹ wa jẹ wipe a le ni lati ṣe awọn iṣẹ ti o jẹ mọ ti ẹru ni igba miran. Dipo eyi, O n ṣe eyi lati jẹ ki a le wa ni imurasilẹ fun awọn aye giga ti O fẹ gbe wa lọ tabi fun awọn iṣẹ nla ti O fẹ fun wa.Fun apẹrẹ, ki Josefu to di igbakeji fun Farao, o ti kọkọ jẹ iransẹ ati oluranlọwọ fun Pọtifa ati fun alakoso túbú ti a mu u lọ, iyẹn lẹyin igba ti iyawo Potifa ṣe akoba fun un. Awọn iriri ati ẹkọ ti o si ba pade nigba ti o n sin awọn eniyan yi si wa lara awọn nkan ti o ran an lọwọ nigba ti o bẹrẹ si ni dari orilẹ-ede Ijibiti.
Lafikun, ki Eliṣa to di olori awọn wolii yoku ti o wa ni orilẹ-ede Isiraẹli, o ti kọkọ sin Elija ni ọpọ ọna, ti o si tun ran an lọwọ. Akoko ti o si lo pẹlu eniyan Ọlọrun yi wa wa lara awọn nkan ti o ran lọwọ lati mọ bi a ti ṣe lo ọrọ Ọlọrun, paapaa julọ ni akoko ti nkan ko ba rọgbọ. (Wo: Jẹnẹsisi 39-41; 1Awọn Ọba 19 – 2Awọn Ọba 2)
Amọ ṣa o, o gbọdọ ye wa pe idi ti Josefu ati Eliṣa ṣe papa de ibi giga ti Ọlọrun fẹ ki wọn de, ti wọn si tun ṣe aṣeyọri ni ibẹ ni pe wọn fi ara wọn si ipo ẹni ti o wulo fun awọn ti o yẹ ki wọn sin ni akoko ti o yẹ ki wọn sin wọn. Fun apẹrẹ, ti o ba jẹ wipe Josefu ko wulo fun Pọtifa ni, ko ni fi gbogbo dukia rẹ si ikawọ rẹ. Tabi ka sọ wipe ko wulo fun alakoso tubu ti a mu lọ ni, o ṣeeṣe ki o ma ri anfaani ti o ri lati pade ọkunrin naa ti o pada yọ ọ jade.
Nitorina, nibikibi ti o ba wa, ripe o da awọn ti Ọlọrun fẹ ki O sin, ran lọwọ tabi tu lara mọ, ki o si fi ara rẹ si ipo ẹni ti o wulo jọjọ tabi ti iwulo rẹ ko ṣe fẹnu sọ fun wọn, dipo ti o o fi sọ ara rẹ di ajaga alainitunmọ fun wọn. Ma ṣe dabi awọn ọrẹ Joobu mẹta ti wọn wa lati tu u lara amọ ti wọn wa pada fi kun ipọnju rẹ. Iwọ naa wo ọrọ rẹ nipa wọn: “Ẹyin n fi eke pe otitọ, oniṣegun ti ko le wo ni san ni yin. O ṣe! Ẹ ba kuku pa ẹnu yin mọ patapata! Eyi ni iba ṣi ṣe ọgbọn yin.
“Yato si eyi, ma ṣe da bi Johanu Maaku, ẹni na ti o jẹ wipe, ni igba ti o ṣi jẹ ewe ninu iṣẹ iranṣẹ, o pa Pọọlu ati Banaba ti nigba ti wọn rin irin-ajo iṣẹ itankalẹ ihinrere akọkọ wọn. Gẹgẹ bi Luuku ti ṣe fi ye wa, ọkunrin yi tẹle awọn apọsiteli yi lati ran wọn lọwọ ni ọna yowu ti wọn ba ti nilo rẹ ni. Eyi tunmọ si pe o ṣeeṣe ki wọn nilo rẹ lati ba wọn mojuto ile wọn, ṣe eto fun iriin-ajo wọn, ba wọn kọ lẹta tabi pin lẹta, ba wọn mojuto sisan owo ori wọn ati bẹẹbẹẹ lọ. Ṣugbọn lalai si idi kan gbogi, o fi wọn silẹ nigba ti iṣẹ gan ṣẹṣẹ n bẹrẹ. Nitorina, iranṣẹ ti ko wulo rara ni o jẹ fun wọn ni akoko yi, bi o tilẹ jẹ wipe ẹbi Banaba ni o jẹ. Abalajọ ti Pọọlu ko ṣe fẹ ki wọn mu lọwọ nigba ti wọn fẹ rin irin-ajo iṣẹ ijinhinrere wọn lẹkeji. (Wo: Iṣe Apọsiteli 13:5&13; Iṣe Apọsiteli 15:36-41)A wa dupẹ lọwọ Ọlọrun pe Maaku taji kuro loju orun rẹ lẹyin-ọrẹyin, o si bẹrẹ si ni fi ara rẹ sipo ẹni ti o mọ ojuṣe rẹ ni sinsin awọn adari ijọ ti Ọlọrun fẹ ki o sin. Nitorina, nigba ti o ṣe diẹ si, Pọọlu sọ fun Timoti lati mu lọwọ wa si ọdọ oun nitori ti o ti di ẹni ti o wulo fun ninu iṣẹ iranṣẹ rẹ (2Timoti 4:11).
Bi Ọlọrun si ṣe fẹ ki nkan ri fun gbogbo wa ni eyi. O fẹ ki a dagba soke si lati di ẹni ti o wulo gidigidi fun awọn ti o wa ninu aye wa, paapaa julọ awọn adari wa, boya ni ile ni o, tabi ninu ijọ tabi ni ibi iṣẹ.Ṣe o ri, awọn olori, pẹlupẹlu awọn obi wa, ko ki fẹ ki awọn eniyan ti o wa ni ṣakani wọn jẹ ajaga si wọn lọrun bikoṣe oluranlọwọ. Iṣẹ ti o wa ni ọwọ wọn pọ to fun wọn lati ṣe, wọn ko si fẹ awọn ọmọlẹyin tabi oṣiṣẹ ti yoo jẹ ki iṣẹ wọn le si afi awọn ti yoo jẹ ki iṣẹ naa rọrun si fun wọn. Nitorina, ti o ko ba ma mu ki iṣẹ awọn adari rẹ rọrun si fun wọn, ibi yowu ti o le wa, o ko wulo fun wọn. Niwọn igba ti iwọ ko ba si wulo fun wọn, awọn adari rẹ ko ni ri idi lati gbe o ga. Ọlọrun paapa ko ni ṣi ilẹkun fun ọ lati pọ si ni iwulo, ti o ko ba wulo fun awọn eniyan ti o fẹ ki o sin tabi ran lọwọ. Nitorina, ji kuro loju orun rẹ, gẹgẹ bi Maaku naa ti ṣe ji, ki o si bẹrẹ si ni fi ara rẹ si ipo ẹni ti o wulo fun awọn ti Ọlọrun fẹ ki o sin. Ki o si to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ, ọpọlọpọ ilẹkun anfaani lati de ibi giga yoo bẹrẹ si ni ṣi fun ọ kaakiri-kaakiri.Ki o ni ọsẹ alarinrin.Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)