Ma sọ imọ ohun ti ọ tọ nu | Paito J.O. Lawal
Ọjọ: Ẹrẹna 20, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ| Nọmba: Vol. 10, No. 46
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ẹrẹna 2022. Adura mi ni pe awọn ibi ọjọ ikẹyin yi ko ni ya ọ niwere ati pe ko ni jẹ ki iwọ naa pada da awọn nkan ti o ti fi gbogbo ọjọ aye rẹ lodi si, ni orukọ Jesu. Amin.
Bibeli sọrọ nipa asiko kan ni ilẹ Isiraẹli ti ẹnikọọkan n ṣe ohun ti o tọ loju ara rẹ (Onidajọ 17:6 & 21:25). Eyi jasi pe, fun apẹẹrẹ, ti ẹnikan ba ro pe nkan ti o tọ ni lati mu ọmọbinrin aladugbo rẹ kan ṣaya, lalai gba aṣẹ lọdọ baba onitọun, o le e ṣe bẹ ẹ, niwọn igba ti o ba ti ni ipa tabi agbara lati ṣe bẹ ẹ. Iwọ naa wa wo bi iwa ika yoo ti ṣe gbilẹ to ni ilẹ naa ni akoko yẹn. Awọn eniyan n wu oniruuru iwa aitọ, wọn si tun da ara wọn lare pe awọn n ṣe bẹ ẹ.
Ki lo wa ti wọn, gbogbo orilẹ-ede yi, sinu iru okunkun birimubirumu yi? Sisọ imọ nkan ti o tọ nu lo tiwọn sibẹ. Ma gbagbe pe a ko imọ ifihan Ọlọrun lori bi a ṣe n gbe ninu ododo le awọn eniyan wọnyi lọwọ. Nitorina, wọn wa ni ipo lati mọ ohun ti o tọ ati ohun ti ko tọ. Ti akoko kan ba wa de ninu igbesi aye wọn, ninu eyi ti o jẹ wipe imọ ohun ti o tọ tabi ti ko tọ wa di ọrọ oju ti ẹnikọọkan ba fi wo, a jẹ wipe wọn ti kọ ọrọ Ọlọrun silẹ niyẹn. Eyi si lo fa ti wọn fi bẹrẹ si ni fa ara wọn ya pẹrẹpẹrẹ, ti wọn si n ba ilẹ wọn jẹ pẹlu itajẹsilẹ ati oniruuru iwa eeri. Nitorina, wọn ko le ṣe rere gẹgẹ bi orilẹ-ede tabi gberi laarin awọn orilẹ-ede agbaye yoku ni igba naa. (Wo: Onidajọ 17-21)
Nibakanaa, igbakigba ti awa naa ba pa ọrọ Ọlọrun ati ifihan rẹ lori bi a ti ṣe n gbe aye ti ṣẹgbẹ kan, o di dandan ki a sọ imọ ohun ti o tọ ati eyi ti ko tọ nu. Nibi ti eleyi ba si ti ri bẹ ẹ, awọn nkan ti yoo pa aye wa ati awujọ wa lara ati awọn nkan ti yoo jẹ ki alaafia, ayọ ati iṣoriire jina si wa nikan naa ni a o ma ṣe. Wo ọpọ lara awa ti a pe ara wa ni Kirisitiẹni loni. Njẹ a n gbe aye wa lori gbedeke ọrọ Ọlọrun bi tabi lori oju ti a ba fi wo bi nkan ti ṣe ri? Ti a ba n gbe aye wa lori gbeke ifihan Ọlọrun, o di dandan ki a mọ, fun apẹẹrẹ, pe awọn nkan bi ibaraẹnilopọ laigbeyawo, riba gbigba, irọ pipa, ibanijẹ, odi yiyan, lilu owo ilu ni ponpo, iwe yiyi, ogun owo ṣiṣe, iṣẹ gbajuẹ ati awọn nkan buruku miran ti ọpọ wa n ṣe laibikita loni ko dara.
Ṣugbọn a ko ri nkan ti ko dara pẹlu awọn nkan wọnyi mọ. Idi si ni pe oju ara wa ni a fi n wo bi nkan ti ṣe ri, ti a si fi n ṣe idajọ nkan ti o tọ ati eyi ti ko tọ, ko ki i ṣe oju Ọlọrun mọ. Awa naa ti wa dabi awọn ti aye yi, ti wọn ti sọ imọ ohun ti o tọ ati eyi ti ko tọ nu, ti wọn si wa n fi tayọtayọ sọ pe ko si nkan ti o buru ninu ki ọkunrin ma ba ọkunrin ẹgbẹ rẹ lopọ ati awọn nkan radarada miran ti o fi ara pẹ — ohun gbogbo ni i ṣe pẹlu oju ti ẹnikọọkan ba fi n wo o. Bi mo ṣe wa sọ tẹlẹ, ibikibi ti ọrọ ba ti ri bi eyi, ko si ni ki a ma ba aye ara wa ati ti awọn miran pẹlu jẹ, nikẹyinkẹyin.
Wayi o, ọpọ igba lo wa jẹ pe a le ma ba aye ara wa jẹ ki a ma mọ lẹsẹkẹsẹ pe a n ṣe bẹ. Fun apẹẹrẹ, ko han kedere si Samusoni lẹsẹkẹsẹ pe ẹṣẹ agbere ti o tọwọ bọ n ba aye rẹ jẹ. Ṣugbọn ẹṣẹ yi n yọ kẹlẹkẹlẹ sọ di alailagbara ati alailokun ninu ọkan rẹ. Akoko kan si wa de ti ẹṣẹ naa bori rẹ patapata, ti o si ṣọ di ẹlẹmi kukuru. (Wo: Onidajọ 16)
Nitorina, bi ko ba tilẹ da bi ẹni pe awọn nkan aida ti o n kopa ninu rẹ n ba aye rẹ jọ lọwọlọwọ bayi, ọjọ kan n bọ ti iwọ naa yo ri kedere pe awọn nkan yi ti n ba aye rẹ jẹ lọna ti ko han si ọ tipẹtipẹ. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun da imọ ohun ti o tọ ati ti o yẹ pada sinu ọpọlọ rẹ, ki O si tun dari rẹ lati ronupiwada lọgan, ki ọjọ iparun ati idojuti ti o n bọ wa ma ba de saye rẹ nikẹyinkẹyin. Amin.
Ki o ni ọsẹ iyanu.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Ma sọ imọ ohun ti ọ tọ nu | Paito J.O. Lawal Read More »
