Ọlọrun n ṣiṣẹ ninu rẹ | Paito J.O. Lawal
Ọjọ: Owara 17, 2021 | Nọmba: Vol. 10, No. 24
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Olurapada wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun yi. Adura mi si nipe ki a ṣe ni aṣepe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ni kiakia, ki aye rẹ ba le wa ni ibi ti Ọlọrun fẹ ki o wa, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, o dami loju saka pe bi nkan yoo ṣe ri gẹlẹ fun ọ niyi nitori pe ẹni ti o n ṣiṣẹ ninu rẹ jẹ Ọlọrun funrarẹ. Pọọlu, nigba ti o n ba awọn Kirisitian ilu Filipi sọrọ lori pataki ki wọn mu ọrọ igbala wọn ni ọkunkundun, ran wọn leti wipe wọn le ṣe eyi nitori pe Ọlọrun n ṣiṣẹ ninu wọn lati fẹ ati lati ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu ete rere rẹ fun wọn (Filipi 2:12-13). Iwọ naa ro wo. Igbala awọn ara yi ko ki i ṣe bukata wọn nikan bi ko ṣe ti Ọlọrun naa pẹlu. Lotitọ, awọn nkankan wa ti o yẹ ki awọn naa maa ṣe lati le ni ẹkunrẹrẹ iriri igbala ti Jesu ti ra fun wọn. Ṣugbọn awọn nikan kọ ni yoo ma ṣe awọn nkan wọnyi. Wọn ko tilẹ nikan le da awọn nkan wọn yi, ohun yowu ti wọn jẹ, ṣẹ. Ẹni ti yoo jẹ ki wọn le ṣe wọn ni Ọlọrun. Pọọlu si wa fi da wọn loju pe o didan ki Ọlọrun ri pe iṣẹ naa jẹ ṣiṣe. Njẹ eyi ko wa dara pupọ lati mọ bi? O dara.
Ni ọna kaana, nitori pe awọn naa ti di ọmọ Ọlọrun nipasẹ Jesu Kirisiti, O ti bẹrẹ si ni ṣiṣẹ ninu aye wa. Ki o too di pe a di ọmọ rẹ, Eṣu ni o n ṣiṣẹ ninu aye wa, ti o si n ṣe wọn radarada ni oniruuru ọna. Idi niyi ti bibeli ṣe pe ni ẹmi ti o n ṣiṣẹ ninu awọn alaigbọran si Ọlọrun (Efesu 2:2). Ṣugbọn nibayi ti a ti di ọmọ Ọlọrun, O ti wa lati gbe ninu wa ati lati gba akoso aye wa. Bẹẹni, O ti wa lati gbe ninu wa lati ṣiṣẹ. Iru iṣẹ wo si ni O wa gbe inu wa ṣe? Ohun gbogbo ti o wa ni ibamu pẹlu ete rẹ ni rere fun wa!
Nitorina, wiwa si imuṣẹ ete Ọlọrun ni rere fun wa ko da lori akitiyan wa nikan; o tun ni i ṣe pẹlu akitiyan rẹ pẹlu. Idi si niyi ti a fi le mọ daju pe aye wa yoo pada da nkan ti o yẹ ki wọn da naa ni, bi o ti wu ki ibi ti a wa lọwọlọwọ yi ri. Njẹ eyi ye ọ bi? Ọlọrun le sọ aye wa da nkan ti o yẹ ki o da, lalai fi ti ibi ti O ti ri aye naa he ṣe. Nitorina, Pọọlu sọ fun awọn ara Filipi pe, “Ohun kan yii ṣaa da mi loju pe, Ọlọrun ẹni ti o ti bẹrẹ iṣẹ rere ninu yin, yoo ṣe aṣepe rẹ titi di ọjọ naa ti Jesu Kirisiti yoo de.” (Filipi 1:6) Dafidi naa tun sọ wipe, “Oluwa yoo ṣe oun ti i ṣe ti emi ni aṣepe…” (Saamu 138:8)
Njẹ o ri bayi? A le fọkan tan Ọlọrun lati pari nkan ti O bẹrẹ ninu wa. Bẹẹni, a le fi ọkan tan lati ṣe laṣepe ete rẹ rere si wa. A kan nilo lati fọwọsowọpọ pẹlu rẹ ni gbogbo ọna ni. Oun yoo fi sinu ọkan wa gbogbo erongba ti o wa ni ibamu pẹlu ete rẹ fun wa, yoo si tun pese ohun gbogbo ti a nilo lati mu awọn erongba naa wa si imuṣẹ. Ṣugbọn a nilo lati fẹran ara ti O fẹ fi aye wa da, ki a si tun ṣetan lati gbe igbese yowu ti O ba fẹ ki a gbe lati jẹ ki eyi wa si imuṣẹ (Isaiah 1:19).
Njẹ a wa nifẹ si nkan ti Ọlọrun fẹ ṣe pẹlu aye wa bi? Ṣe a si tun ṣetan lati jẹ ohun gbogbo ti O n ṣiṣẹ ninu wa lati jẹ? Ti o ba jẹ bẹ, a o mu ọrọ rẹ ni ọkunkundun. A o ma ka ọrọ rẹ, gbe yẹwo ati ṣe aṣaro ninu rẹ, ki a ba le ṣe gẹgẹ bi o ti wi (Jọshua 1:8). Siwaju si, a ko ni jẹ agberaga, alagidi tabi ẹniti ara rẹ kọ ibawi nigbakigba ti O ba n ba wa wi. Dipo eyi, a o tẹwọgba ibawi rẹ pẹlu ifẹ ati ọwọ, niwọn igba ti a mọ pe, gẹgẹ bi Baba wa ti o jẹ, nkan ti o dara julọ fun wa ni O ni lọkan ati pe ibawikibawi ti O ba fun wa ninu ifẹ ni o ti jẹyọ (Heberu 12:5-13).
Kini idi ti pupo-julọ ninu awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose mu jade lati Ijibiti ko ṣe de ilẹ ileri, pẹlu ohun gbogbo ti Ọlọrun ṣe fun wọn ati ni aarin wọn? Idi akọkọ ni pe wọn ko mu ọrọ Ọlọrun ni ọkunkundun. Idi keji ni pe wọn kọ lati gba ibawi rẹ. Ti awa naa ko ba wa fẹ ki iṣẹ rẹ ti O n ṣe ninu aye wa ja si pabo, a ko gbọdọ ri bi ti wọn. Dipo eyi, a gbọdọ tọ ara wa lati mu ọrọ rẹ ati ibawi rẹ ni ọkunkundun. Adura mi si pe ki ọkan rẹ gba okun lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ ologo.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Ọlọrun n ṣiṣẹ ninu rẹ | Paito J.O. Lawal Read More »
