Onidajọ ododo | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Owewe 12, 2021 | Atẹlera: Latori tabili | Nọmba: Vol. 10, No. 19

Olufẹ: ki oore-ofẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Owewe 2021. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ri daju pe o gba idajọ ododo lọsẹ yi ni gbogbo abala aye rẹ ti a ti n yan o jẹ lọwọlowọ bayi, ni orukọ Jesu. Amin.

Gẹgẹ bi a ti ṣe mọ, aye ti a n gbe ninu rẹ yi jẹ ọkan ti o kun fun oniruuru aiṣododo. Ko si fẹrẹ si ibi naa ti a wa, bi o tilẹ jẹ ile wa gan, ti a ko ti ni ba aiṣododo kan tabi omiran pade. Eyi si n pa awujọ wa lara, nitoriti o n fi aye silẹ fun awọn ti ko yẹ lati jẹgbadun tabi ṣakoso awọn nkankan ti ko tọ si wọn. Ibikibi ti ọrọ ba ti wa ri bayi, ko si ni ki yanpanyarin ma ṣẹlẹ nibẹ.

Nitorina, ti a ko ba fẹ ki yanpanyarin fa awọn ile wa, adugbo wa, ibi iṣẹ wa, ile-iwe wa, ile ijọsin wa ati awujọ wa lapapọ ya, a gbọdọ bẹrẹ si ni fi idi idajọ ododo mulẹ. Bẹẹni, ẹnikọọkan wa gbọdọ pinnu lati lo ipo rẹ tabi nkan ini rẹ lati fi idi ododo lẹlẹ nibikibi ti a ba wa. Eyi tunmọ si pe a gbọdọ ri daju saka pe nkan ti o tọ si awọn eniyan ni a n fun wọn dipo ki a ma fun wọn ni nkan ti wọn ko ni amuyẹ fun tabi fun wọn ni nkan ti o kere jọjọ si amuyẹ wọn.

O wa ṣe ni laanu pe, ni ọpọ igba, eyi ko ri bẹ pẹlu wa. Ọpọ eniyan ti o wa ni ipo ti wọn ti le gbe idajọ ododo ro, ki wọn si fi idi rẹ mulẹ, ni ko ṣetan lati ṣe bẹ ẹ. Ti awọn eniyan ba si ba wọn wijọ tabi fi ehonnu han tabi gba ile ẹjọ lọ fun idajọ ododo, ko si aridaju pe wọn yoo ri idajọ ododo gba rara tabi nigba ti o ba yẹ. Idi si ni yi ti ọpọ ni orilẹ-ede wa, fun apẹẹrẹ, ko ṣe ti ni itẹsiwaju ninu aye yi bi o ṣe tọ. Idi si tun niyi ti ọpọ miran ti ba ọkan jẹ, ti gbigbe igbe aye ododo si ti su wọn. Awọn wọnyi lo ti wa bẹrẹ si ni ti ọwọ bọ awọn ti wọn ti fi igba kan sọ wipe ko dara (Oniwaasu 8:11).

Boya iwọ na tilẹ ti pa igbe aye ododo ti tabi nṣe ni o n gbero lati pa a ti nitori iyanjẹ ti o ti fi ara gba lati ọwọ awọn eniyan. Ṣiṣe eyi ko yatọ rara si fifi aye gba ibi lati bori rẹ. Ṣugbọn bibeli sọ wipe, “Ma ṣe jẹ ki buburu ṣẹgun rẹ, ṣugbọn fi iṣẹ rere rẹ ṣẹgun buburu.” (Roomu 12:21) Nitorinaa, ma ṣe pa igbe aye ododo ti nitori aiṣoodo ti inu aye yi. Dipo eyi, tẹsiwaju lati ma gbe igbe aye ododo nibikibi ti o ba ti ba ara rẹ. Lafikun, tẹramọ gbigba adura si Ọlọrun pe ki O ṣe idajọ ododo fun ọ ati fun gbogbo awọn ti a n yanjẹ nilẹ yi. Yoo si dahun adura rẹ.

Bibeli sọ wipe, “Ọpọlọpọ eniyan ni o n wa ojurere ijoye: ṣugbọn idajọ eniyan ni o n ti ọdọ Oluwa wa.” (Owe 29:26). Njẹ o ri bayi? Ọdọ ẹnikan ṣoṣo ti a ti le ri idajọ ododo gba ni aye yi ni Ọlọrun. Ti ko ba si fun wa ni idajọ ododo, ko si iye awọn alagbara tabi ọlọla eniyan ti a le lọ ba tabi fi ẹhonu han si, a ko ni ri i gba. Ṣe eyi wa jasi pe ki a ma wulẹ lọ ba eniyan kankan fun idajọ ti o tọ ni? Rara o! A ni anfaani lati lọ ba ẹnikẹni ti a ba ri pe o wa ni ipo lati fun wa ni idajọ ododo lori ohunkohun ti o ba n dun wa lọkan. Amọ a ko gbọdọ gbagbe pe ti Ọlọrun funrarẹ ko ba ru ẹni naa lọkan soke, ki O si tun fun un ṣe lati fun wa ni idajọ ododo, o le ma fun wa titi lailai.

Nitorina, nibikibi ninu aye rẹ ti o ba ti woye pe a ti rẹ ọ jẹ tabi ja o lole, ẹni akọkọ ti o yẹ ki o fi ọrọ naa lọ ni Ọlọrun. Ti o ba si ti ṣe eyi, ti awọn eniyan ba tilẹ kọ lati fun ọ ni idajọ ododo, o didan ki Oun ṣe ohun ti o tọ ati ti o yẹ fun ọ lalai fi akoko ṣofo. Ranti pe Jesu Oluwa wa sọ wipe, “Ọlọrun ki yoo ha si gbẹsan fun awọn ayanfẹ ti n fi ọsan ati oru kigbe pe e, ti o si mu suuru fun wọn. Mo wi fun yin, yoo gbẹsan wọn kankan. Ṣugbọn nigba ti ọmọ-eniyan ba de, yoo ha ba igbagbọ ni aye bi?” (Luke 18:7-8) Njẹ o ri bayi? Ọlọrun ko ni fi igba kankan ti wa danu, ti a ba wa oju rẹ fun idajọ ododo. Ṣugbọn ṣe a o wa oju rẹ? Njẹ iwọ yoo wa oju rẹ? Mo gbadura pe ki a mu igbagbọ wa le lati ma fi gbogbo igba wa oju Ọlọrun nibikibi ninu aye wa ti a ti nilo idajọ ododo, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Onidajọ ododo | Paitọ J.O. Lawal Read More »