Sa fun iṣekuṣe | Paito J.O. Lawal
Ọjọ: Ogun 01, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 13
Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu kẹjọ ọdun yi, oṣu Ogun. Mo gbadura pe ki a ba ọ to aye rẹ lọna ti o o fi le ni iriri ẹkunrẹrẹ ibukun Ọlọrun ninu oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ṣe n bẹrẹ oṣu yi, jẹ ki n ran ọ leti ọrọ Apositeli Pọọlu ti o sọ pe, “Ẹ maa sa fun agbere. Gbogbo ẹṣẹ ti eniyan n da o jẹ ti ode ara; ṣugbọn ẹnikẹni ti o n ṣe agbere, o n ṣe si ara oun tikararẹ. Tabi, ẹyin ko mọ pe ara yin ni tẹmpili Ẹmi mimọ, ti n bẹ ninu yin, ti ẹyin ti gba lọwọ Ọlọrun? Ẹyin kii ṣi i ṣe ti ara yin mọ. Nitori Ọlọrun ti ra yin ni iye kan: nitori naa, ẹ lo ara yin lati yin Ọlọrun logo, ati ẹmi yin pẹlu, ti i ṣe ti Ọlọrun.” (1Korinnti 6:17-20) Ki ni aṣẹ ti a ri gba nibiyi? Oun naa ni pe ki a sa fun agbere. Ki wa ni itumọ ki a sa fun nkan? O tunmọ si pe ki a fi ẹsẹ fẹ ti a ba ti kẹfin nkan naa.
Nitori naa, nigba ti Pọọlu sọ fun wa pe ki a sa fun agbere, nkan ti o n sọ ni pe ki a fi ẹsẹ fẹ ti a ba ti kẹfin ohunkohun ti o ni i ṣe pẹlu agbere. Fun apẹẹrẹ, nigbati aya Potifa bẹrẹ si ni yọ Josẹfu lẹnu pẹlu ifẹkufẹ, oun naa bẹrẹ si ni yẹra fun. Bibeli sọ wipe,“Bi o ti n sọ fun Josẹfu lojoojumọ, ti oun ko si gbọ tirẹ lati dubulẹ ti i, tabi lati ba a lo pọ.” (Jẹnẹsisi 39:10) Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ pe obinrin yi fi ojoojumọ fi ṣe iṣẹ ṣe lati tan Josẹfu lati ba a lopọ, oun kọ gbọ tirẹ tabi duro si gberigberi rẹ. Mo mọ daju pe ti o ba jẹ pe ko ki i ṣe ẹru Potifa ni, ti o kan jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ rẹ, nṣe ni ko ba fi iṣẹ silẹ ba tirẹ lọ. Ṣugbọn nigba ti ko wa ti ṣeeṣe fun lati fi iṣẹ silẹ, ti o si jẹ dandan ki o ri obirin yi lojoojumọ, oun naa wa fi ṣe iṣẹ ṣe lati ma yago fun.
Ni ikẹyin, ọjọ kan de ti gbogbo awọn ọmọ ọdọ ile naa ko si nile. Ojọ yi gan ni arabinrin yi gba aṣọ rẹ mu, ti o sọ fun pe, “Ani wa ba mi lopọ!” Ṣugbọn o fi asọ rẹ silẹ si lọwọ, o si sa jade kuro ninu ile naa. Ki ni idi ti o ṣe salọ? Idi ni pe o le ko sinu panpẹ agbere ti ko ba ṣe bẹẹ. Wo o, iṣekuṣe jẹ ẹṣẹ ti o ma n gba ọkan ati ara eniyan. Nitori naa, o ko le sọ akoko ti o o dẹ ara rẹ silẹ fun un, ti o ba n fi gbogbo igba wa pẹlu ẹnikẹni ti o n fi gbogbo igba dan ọ wo pẹlu rẹ. Idi ni yi ti a fi pa a laṣẹ fun wa lati sa fun un. Aijẹbẹ, a o ti ṣubu sinu rẹ tan ki a to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ.
Ṣugbọn ki wa ni idi ti a fi pa a laṣẹ fun wa lati sa fun oniruuru iṣekuṣe? Kini idi ti a fi paṣẹ fun wa lati jinna rere si nkan ti o da bi ẹni pe o dun un gbadun? Idi ni pe o n ba agọ ara wa, ti o jẹ ti Ọlọrun, jẹ, o si tun n sọ di eleeri. Gẹgẹ bi Pọọlu ṣe fi ye wa ninu awọn ẹṣẹ bibeli yẹn, agọ ara wa ko ki i ṣe tiwa bikoṣe ti Ọlọrun ti o san gbese fun irapada wa. Niwọn igba ti o si ti jẹ pe tirẹ ni wọn n ṣe, Oun naa ti wa bẹrẹ sini gbe inu wọn nipasẹ Ẹmi Mimọ rẹ. Nitori naa, awa nikan kọ ni a n gbe inu agọ ara yi; Ẹmi Ọlọrun naa n gbe inu rẹ pẹlu wa. Idi si niyi ti a ko fi gbọdọ sọ di idibajẹ tabi ki a tabuku rẹ ni ọnakọna. Aijẹbẹ, a le tipasẹ eyi di ẹni iparun, nitoripe Pọọlu sọ fun wa siwaju si pe ti ẹnikẹni ba ba tẹmpili Ọlọrun jẹ, Ọlọrun naa yoo pa ẹni naa run (1Korinnti 3:16-17).
Wayi o, o wa yẹ ki o ye wa pe ibalopo takọtabo gan kọ ni a ni ki a sare jinna si bikoṣe agbere. Nitori naa, ibalopọ takọtabo kọ ni iyọnu; aṣilo rẹ gan an ni wahala. Ipongbẹ fun ibalopo, bi ebi ati ongbẹ, jẹ ẹbun ti Ọlọrun tikararẹ fun wa lati ma fi ifẹ wa han. Ṣugbọn ninu igbeyawo nikan ni a ti fun wa ni aye lati fi ifẹ han nipa pipongbẹ fun ibalopọ. Nitori naa, ti o ko ba i ti lọkọ tabi laya, aṣiṣe gba a ni yoo jẹ fun ọ lati fi ara rẹ jin fun irufẹ ibalopọ yowu ti o ba fi ara rẹ jin fun, yala ibalọpọ laarin ọkunrin si obinrin, ibalopọ laarin ọkunrin si ọkunrin, ibalopọ laarin obinrin si obinrin, ibalopọ laarin ọkunrin si ẹranko tabi ibalopọ laarin obinrin si ẹranko. O tilẹ bu ọ ku paapaa lati ma ba ara rẹ ni ibalopọ, eyi ti wọn n pe loni ni masitọbesan.
Wo o, nṣe ni o n ba agọ ara rẹ jẹ, ti o ba n kopa ninu ọkankan ninu awọn nkan wọnyi. Bi mo si ṣe sọ fun ọ siwaju, ara rẹ ko ki i ṣe tirẹ bi ko ṣe ti Ọlọrun. Nitori naa, igbakugba ti o ba fi nkan ibajẹ rẹ, nṣe ni oun ṣilẹkun aye rẹ silẹ fun iparun. Irufẹ iparun ti o wa le jẹ tabi akoko ti yio wa sori rẹ ni n ko le sọ. O le jẹ iparun idile rẹ lọjọ iwaju tabi iparun ete Ọlọrun lati gbe ọ ga tabi iparun agọ ara rẹ nipaṣẹ awọn aisan buburu kan tabi omiran. Ṣugbọn o di dandan ki iparun naa wa, ti o ba kọ lati ronupiwada ni igba ti o ni anfaani lati ṣe bẹẹ.
Nitori naa, sa fun ẹnikẹni tabi ohunkohun ti o ba le fa ọ wọnu ẹṣẹ agbere. Ma si ṣe fi aye gba irọ ti awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, paapaa julọ awọn oṣere wa, n tan kalẹ nipa ibalopọ lati dari rẹ sinu iparun afọwọfa. Ifẹ Ọlọrun ni ki o ko ara rẹ nijanu, ki o si jina si agbere (1Tẹsalonika 4:3-6). Nitori naa, ko si nkankan ti o ṣe ọ, ti o ba yẹra fun agbere, ti o si wa ni mimọ. Ki Ọlọrun si tẹsiwaju lati ma fi okun kun ọkan rẹ lati ṣe eyi, bi o ti wu ki awọn ti o wa ni ayika rẹ ya ọniṣekuṣe to, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni oṣu Ogun 2021 alarinrin.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Sa fun iṣekuṣe | Paito J.O. Lawal Read More »
