Tan ìhìnrere náà kálẹ̀. | Pst. J.O. Lawal. | Òkúdù 19, 2022. | Vol. 11, No. 7
Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu yi. Mo gbadura pe ki a ka ọ yẹ fun ipe Ọlọrun ti o ti ri gba ninu ọsẹ naa ati ni gbogbo iyoku ọjọ aye rẹ. Amin.
Ọkan lara awọn nkan ti Oluwa n reti ki ẹnikọọkan ti o ti jẹ ajogun didara ati igbala rẹ ma ṣe ni titan ihinrere awọn nkan ti O ti ṣe fun wọn de ọdọ awọn miran. Nipa ṣiṣe eyi, awọn ti wọn ba tan ihin naa de ọdọ wọn yoo le ni iwuri lati wa sọdọ rẹ lati ni iriri didara rẹ ninu aye ti awọn naa. Fun apẹẹrẹ, lẹyin igba ti O ti tu ọkunrin were ti awọn legioni ẹmi eṣu n gbe inu rẹ silẹ tan, Oluwa sọ fun pe, “Lọ si ile rẹ ki o si sọ fun awọn ara ile rẹ, bi Oluwa ti ṣe ohun nla fun ọ, ati bi o si ti ṣaanu fun ọ.” (Maaku 5:19)
Njẹ ọkunrin yi wa ṣe bi Oluwa ti paṣẹ fun bi tabi ko ṣe bẹẹ? O ṣe bẹẹ! Ka tilẹ sọ otitọ, o ṣe ju bi a ti lero pe yoo ṣe lọ. Ko ki i ṣe awọn ara ile rẹ nikan ni o sọ nkan ti Ọlọrun ṣe fun fun. Nṣe ni o tun lọ kaakiri lati ma sọ fun gbogbo awọn ti o bikita lati gbọ tirẹ ni agbegbe kan ti a n pe ni ‘Dekapoli, eyi ti o tunmọ si ‘Ilu Mẹwa’.
Iwọ naa gbe yẹwo. Ọkunrin yi lọ kaakiri agbegbe ilu mẹwa tan, o si n sọrọ nipa nkan ti Jesu ṣe fun nibẹ. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni pe o mọ nkan ti Oluwa ṣe fun loore gidigidi. Ekeji, idi ni pe o fẹ ki awọn miran ti wọn wa labẹ ide Satani naa mọ pe wọn le gba idande nipa titọ Oluwa wa, bi o ti wu ki ọrọ wọn buru to.
Nibakana, ti Oluwa ba ti dara si wa nitootọ ninu ijọ wa, ojuṣe wa si ni lati jẹ ki awọn miran mọ nipa rẹ. Ti o ba jẹ pe nitootọ ni O n yi aye wa pada si rere, ti O si n mu ki a ni itẹsiwaju nipasẹ ọrọ rẹ, o wa yẹ ki a jẹ ki awọn ọrẹ, ẹbi, akẹgbẹ wa ni ibi iṣẹ tabi ni ile-ẹkọ ati aladugbo mọ pe awọn naa le jẹ alajọpin didara rẹ pẹlu wa. Bi mo si ti ṣe sọ siwaju, Ọlọrun funrarẹ n reti pe ki a ṣe eyi. Idi si ni pe ọkan pataki lara awọn idi ti O fi n ṣe rere fun wa ni ki a ba le jẹ ilẹkun fun lati le wọnu aye awọn ti o wa ni ayika wa, ki O si ṣe rere fun awọn naa pẹlu.
Nkan ti eyi wa tunmọ si ni pe ti a ba kọ lati tan ihinrere didara rẹ si wa de ọdọ awọn ti o wa ni ayika wa, ko ki i ṣe pe a n fi ara wa han gẹgẹ bi alanikanjọpọn nikan, nṣe ni a tun n di iṣẹ rẹ lọwọ. Ko si wa si bi a o ṣe ma fi anikanjọpọn di iṣẹ Ọlọrun lọwọ ti a ko si ni jẹ iya rẹ, okere ni o tabi o pọ. Boya eyi gan tilẹ ni idi ti awa kan fi n ni iriri ainitẹsiwaju ninu aye wa. Yoo wa bojumu ti a ba tete ronupiwada, ki a si bẹrẹ si ni fi itara dari awọn ti o wa ni ayika wa lati ni iriri didara Ọlọrun ti a n jẹ igbadun rẹ lọwọlọwọ.
Wayi o, eyi ko wa jasi pe ki a fi túláàsì tabi àrékérekè mu ẹnikẹni lati di alabapin pẹlu wa ninu igbadun didara Ọlọrun. Dipo bẹẹ, o tunmọ si pe ki a ṣe ohun gbogbo ti o wa ni ikawọ wa lati fun iye awọn yowu ti a ba ni oore-ọfẹ lati fun ni iwuri lati wa sọdọ Oluwa funra wọn, ki wọn ba le ri bi O ti ṣe le dara si wọn ati ṣe wọn ni aanu to. Ki Ẹmi Ọlọrun si ma fi gbogbo igba kọ ọkan wa ati fun un ni okun lati mu ọrọ yi ni pataki ninu aye wa, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Tan ìhìnrere náà kálẹ̀. | Pst. J.O. Lawal. | Òkúdù 19, 2022. | Vol. 11, No. 7 Read More »
