Da wọn mọ; tẹwọ gba wọn; bukun fun wọn | Paito J.O. Lawal

Ọjọ: Agẹmọ 18, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 11

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Agẹmọ 2021. Mo gbadura pe ki Ẹmi Ọlọrun ṣe ọkan rẹ yẹ, ki o ma ba fi igba kankan padanu ibẹwo rẹ sinu aye rẹ nipasẹ kikọ silẹ tabi ainani awọn eniyan ti O ti yan fun igbega, isorire ati ibalẹ-ọkan rẹ. Amin.

Bi a ṣe ri ninu bibeli, Ọlọrun ni eto daradara fun gbogbo awọn ọmọ rẹ. Bi Pọọlu tilẹ ṣe sọ fun wa, awọn eto Ọlọrun fun wa tobi, wọn si tun dara tobẹẹ gẹẹ ti ọkan wa ko fi le mọ bi wọn ṣe tobi tabi dara to. Nitorina, Ẹmi rẹ nikan naa ni o wa ni ipo lati fi wọn han wa ati lati tọka wọn si wa, ki a ba le gbadun wọn daradara. (Wo: 1Korinnti 2:9-12) Amọ ṣa o, Ẹmi Ọlọrun ko ki i fi gbogbo igba da a ṣiṣẹ lati mu ete Ọlọrun wa si imuṣẹ ninu aye awọn eniyan. Ọpọ igba, nṣe ni O ma n lo awọn miran ti O ti tọ, fun ni ẹbun ati ṣe ye ni awọn ọna kan lati mu ifẹ rẹ wa si imuṣẹ ninu aye awọn eniyan. Ti wọn ko ba si wa mọ wọn, tẹwọgba wọn, ki wọn si ba wọn lo pọ ni ọna ti o tọ, awọn ti O ti gbe dide lọna yi fun imuṣẹ eto rẹ daradara fun aye wọn, wọn le kuna lati ri imuṣẹ awọn eto yi.

Fun apẹẹrẹ, Ọlọrun ran Jesu Oluwa wa lati kọkọ ṣe awari awọn aguntan Israẹli ti O ṣọnu, ki O to tọ awọn araye yoku lọ pẹlu ẹbun ọfẹ igbala rẹ (Matiu 10:5-6 & 15:24). Idi niyi ti o fi jẹ wipe awọn ni wọn kọkọ gbọ awọn iwaasu oore-ọfẹ rẹ, ti wọn si tun kọkọ jẹ igbadun ifamin-ororo yan rẹ lati wosan, tu silẹ ati mu padabọ sipo. Ṣugbọn ṣe wọn tẹwọgba a, ki wọn si tun ba a lopọ ni ọna ti o peye bi? Rara o! Dipo eyi, gẹgẹ bi orilẹ-ede, nṣe ni wọn kọ ọ silẹ, tabuku rẹ, ṣe inunibini si, ti wọn si tun pa a nigbẹyingbẹyin. (Wo: Johanu 1:10-13)

Bawo wa ni ti awọn eniyan rẹ, awọn ti ilu abinibi rẹ, nibi ti a ti wo o dagba? Njẹ awọn naa tẹwọ gba bi, bi o tilẹ jẹ ẹya wọn ọn ni? Rara o! Dipo eyi, iriri rẹ laarin wọn gan tilẹ tun buru ju ti eyi ti O ri ni awọn ibomiran. Iwọ naa wo nkan ti Maaku sọ lori eyi: “Oun ko si le ṣe iṣẹ agbara kan nibẹ ju pe o gbe ọwọ rẹ le awọn alaisan diẹ, o si mu wọn larada. Ẹnu si ya a nitori aigbagbọ wọn…” (Maaku 6:5-6)

Ni aifọrọgun, nigba ti o ku diẹ ki iṣẹ iranṣẹ rẹ laarin awọn eniyan orilẹ-ede rẹ wa si opin, O sukun fun olu-ilu wọn, Jerusalẹmu, O si tun sọ awọn ọrọ sunukun yi: “I ba ṣe pe iwọ mọ lonii yii, ani iwọ, ohun tii ṣe ti alaafia rẹ! ṣugbọn nisinsinyi wọn pamọ kuro ni oju rẹ. Nitori ọjọ n bọ fun ọ, ti awọn ọta rẹ yoo wa yara ka ọ, wọn o si yi ọ ka, wọn o si ka ọ mọ niha gbogbo. Wọn o si wo ọ palẹ ati awọn ọmọ rẹ ninu rẹ; wọn ki yoo si fi okuta kan silẹ lori ara wọn; nitori ti iwọ ko mọ ọjọ ibẹwọ rẹ.” (Luuku 19:42-44) Lafikun, O tun sọ wipe, “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, iwọ ti o pa awọn wolii, ti o si sọ okuta lu awọn ti a aran si ọ; igba meloo ni emi n fẹ radọ bo awọn ọmọ rẹ, gẹgẹ bi agbebọ ti i radọ bo awọn ọmọ rẹ labẹ apa rẹ, ṣugbọn ẹyin ko fẹ! Ṣa wo o, a fi ile yin silẹ fun yin ni ahoro. Mo wi fun yin, ẹyin ki yoo ri mi mọ lati isinsinyi lọ, titi ẹyin o fii wi pe, Olubukun ni ẹni ti n bọ wa ni orukọ Oluwa.” (Matiu 23:37-39)

Iwọ naa wo ọrọ yi. Tipẹtipẹ ni awọn eniyan wọnyi ti n gbadura, ti wọn si tun duro de Ọlọrun lati wa gba wọn la. Ṣugbọn nigba ti O ran Olugbala ti wọn nilo si wọn, wọn ko tẹwọ gba a. Ki si ni idi? Idi ni pe wọn ko da a mọ gẹgẹ bi Olugbala wọn. Nitorina, O sọ fun wọn pe ile wọn ni a o fi silẹ ni ahoro titi wọn o fi da mọ, tẹwọgba, ki wọn si tun bukunfun.

Ni bakan naa, niwọn igba ti awa naa ko ba da wọn mọ, tẹwọgba wọn, ki a si tun bukun fun wọn, awọn ti Ọlọrun tipasẹ Ẹmi rẹ ran lati tọ wa, gbe wa ro, wo wa san ati gbe wa ga, nṣe ni aye wa yoo wa ni ojukan, ti yoo si tun jẹ ahoro ni ọna pupọ. Idi si ni yi ti o fi jẹ pe olori adura kan ti o yẹ ki a ma fi gbogbo igba gba fun ara wa ni pe ki awọn eniyan ati nkan ti Ọlọrun ti pese tabi ran fun aye wa lati jẹ nkan ti o yẹ ki wọn jẹ ma ṣe farasin fun wa. Nitori naa, lẹkan si, adura mi fun ọ, bi o ṣe n tẹsiwaju ninu irinajo aye rẹ, ni pe ki a ṣe ọkan rẹ yẹ lati da wọn mọ, ki o si tun tẹwọgba wọn ni ọna ti o yẹ, awọn eniyan ati nkan ti Ọlọrun ti pese fun aye rẹ lati jẹ nkan ti o yẹ ki o jẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Da wọn mọ; tẹwọ gba wọn; bukun fun wọn | Paito J.O. Lawal Read More »