Won

Ǹjẹ́ o wúlò fún wọn bí? | Pst. J.O. Lawal | Ọ̀wàrà 16, 2022 | Vol. 11, No. 24

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Owewe 2022. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki o pọ si ni iwulo fun un ati fun awọn ti o wa ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ninu lẹta Pọọlu keji si Timoti, o sọ eyi fun un nipa Johanu Maaku: “…mu Maaku wa pẹlu rẹ: nitori o wulo fun iṣẹ-iransẹ.” (2Timoti 4:11) Ṣugbọn igba kan wa ti Pọọlu ko fẹ mu Maaku kanna yi lati rin irinajo kankan pẹlu rẹ ni ṣiṣe ojuṣẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ. Idi si ni pe o ti fi igba kan ri kọ oun ati Banaba silẹ ni akoko ti wọn nilo rẹ gidigidi. Nitorina, Pọọu ri bi ẹni ti ko wulo fun un ninu iṣẹ iranṣẹ. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 13:13; Ìṣe Àpọ́sítélì 15:36-41)

Ṣugbọn Maaku ko duro sojukan gẹgẹ bi ẹni ti ko wulo fun Ọlọrun tabi fun awọn iransẹ rẹ titi lailai. Oun naa dagba soke si ninu nkan ti ẹmi. Nigba ti o to asiko kan, oun naa ṣe idamọ awọn iwa ati aṣa ti o n mu ki o jẹ alaiwulo fun awọn eniyan Ọlọrun ti o wa ninu aye rẹ, o si mojuto wọn nipasẹ agbara Ẹmi Ọlọrun. Nitorina, lẹyin ọdun melokan si, Pọọlu sọ fun Timoti pe o jẹ dandan fun lati wa Maaku, ki o si mu wa si ọdọ oun, nitori ti o wulo fun ninu iṣẹ iranṣẹ rẹ.

A tun ri ọdọmọkunrin kan ninu bibeli ti itan tirẹ naa fẹ fi ara pẹ eyi. Oun naa ti fi igba kan ri jẹ alaiwulo fun olowo rẹ, bi o tilẹ jẹ wi pe ‘Mowúlò’ ni itunmọ orukọ rẹ. O wa jẹ ẹnikan ti ko wulo, ti ko si ni nkan ṣe to bẹẹ gẹẹ ti o fi sa kuro ni ọdọ oluwa rẹ. Ṣugbọn nigba ti o pade Pọọlu, o di atunbi. Lati igba yi lọ wa ni aye rẹ ti bẹrẹ si ni gba ọna ara ọtọ, ti o si bẹrẹ si ni gbe aye rẹ ni ibamu pẹlu orukọ rẹ, ‘mowúlò’. O wa wulo to bẹẹ gẹẹ fun Pọọlu ti o fi gbero lọkan rẹ lati jẹ ki o wa pẹlu oun titi lailai. Ṣugbọn nitoripe o fẹ ki olowo rẹ ri bi Ọlọrun ti ṣe yi aye rẹ pada, ki o dárí gbogbo nkan buburu ti o ti ṣe si ji i, ki o si tun gbadun iwulo rẹ, o ran an pada lọ si ọdọ rẹ. Ọrọ ẹni ti mo si n ṣọ ko ju ti Onesimu, iranṣẹ Filemoni, lọ. (Filemoni 1)

A wa ri aridaju bayi pe Ọlọrun ni agbara lati sọ awọn ti ko wulo di ẹni ti o wulo ati awọn alainikanṣe eniyan di ẹni ti o n ṣe ojuṣe rẹ, ti wọn ba fi aye wọn jin fun. O si fẹ sọ iwọ naa di ẹni ti o wulo ati ẹni ti o mọ ojuṣe rẹ ninu gbogbo ibaṣepọ rẹ. Ṣugbọn ṣe iwọ funrarẹ fẹ wulo, ki o si jẹ ẹni ti o n ṣe ojuṣe rẹ si Ọlọrun ati ninu gbogbo awọn ibaṣepọ rẹ? Ayafi ti o ba ṣetan lati wulo siwaju ati siwaju si, o ni oju nkan ti Ọlọrun le ṣe fun ọ. Awọn ti wọn ba ṣetan lati wulo nikan ni Ọlọrun le ṣe yẹ lati le ṣe awọn nkan ti o tọ fun wọn lati ṣe lati jẹ ẹni ti o wulo ninu aye wọn ati ti o n fi igba gbogbo pọ si ni iwulo. 

Ni kukuru, gẹgẹ bi Pọọlu, awọn adari ijọ Ọlọrun kọọkan naa nilo awọn eniyan ti o wulo lati ran wọn lọwọ ninu iṣẹ iranṣẹ wọn ati lati jẹ ki iṣẹ wọn ma tẹsiwaju. Wọn nilo awọn ti wọn le gbe ara le lati ran wọn lọwọ pẹlu asiko wọn, ẹbun ẹmi wọn, owo wọn, amuyẹ wọn ati ohunkohun ti wọn ba ni. Ṣe o wa jẹ ọkan lara awọn wọnyi bi? Ṣe o wulo fun awọn adari ijọ rẹ ni ọna kankan? Ti wọn ba n ronu nipa awọn ti wọn le gbe ara le lati ṣe awọn iṣẹ kan, ṣe orukọ rẹ yo tilẹ wa si wọn lọkan bi? Ti eyi ko ba ri bẹ, a jẹ wipe o ko wulo fun wọn niyẹn. Ti o ko ba si wulo fun awọn adari ijọ rẹ, afaimọ ki o ma jẹ wipe o ko wulo fun Ọlọrun ti O yan wọn le ọ lori naa pẹlu.

Ṣe o wa fẹ duro si ipo ẹni ti ko wulo fun wọn ni tabi o fẹ di ẹni ti o wulo? Eyi jẹ ibere ti o nilo lati dahun bi o ti ṣe doju kọ ọsẹ tuntun yi. O si wa kọja ki o ma bere lọwọ wọn, “Ọna wo ni mo le gba wulo fun yin?” O tun ni i ṣe pẹlu ki o fi awọn ọna ti o le gba wulo fun wọn han wọn pẹlu iṣe rẹ. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun dari rẹ kuro ninu ohun gbogbo ti o n ṣe ọ ni alaiwulo fun un ati fun awọn ti o wa ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ eleso rere.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ǹjẹ́ o wúlò fún wọn bí? | Pst. J.O. Lawal | Ọ̀wàrà 16, 2022 | Vol. 11, No. 24 Read More »

Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́ láìsi mọ nkànkan | Pst. J.O. Lawal | Ọ̀wàrà 09, 2022 | Vol. 11, No. 23

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Ọwara 2022. Mo gbadura pe ki Ẹmi Ọlọrun lo ọrọ rẹ ti o n tọ ọ wa ninu ijọ yi lati fọ wọn danu kuro ninu aye rẹ ohun gbogbo ti o n di isesorere rẹ lọwọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Pọọlu, ninu lẹta rẹ keji si Timoti, sọ eyi nipa awọn kan ninu ijọ ti ko gbọdọ ni nkankan ba ṣe pọ: “Nitori ninu iru eyi ni awọn ti n rako wọ inu ile, ti wọn si n di awọn obinrin alailọgbọn ti a di ẹṣẹ ru ni igbekun, ti a si n fi oniruuru ifẹkufẹẹ fa kiri. Wọn n fi igba gbogbo kẹkọọ, wọn ko si le de oju imọ otitọ.” (2Timoti 3:6-7) Pẹlu nkan ti apọsiteli yi sọ nibiyi, a ri wipe ọkan lara awọn idi ti o fi sọ fun Timoti lati ma ni nkankan ba awọn ara wọnyi ṣe pọ ni pe ọga ni wọn ninu ki a ma jẹ awọn eniyan mọlẹ, paapaa julọ awọn obinrin, ati ki a ma tan wọn jẹ.

Ki wa ni o jẹ ki o ma fi ọpọ igba rọrun fun wọn lati tan awọn eniyan jẹ ati lati tun gba akoso aye wọn? Idi ni pe awọn ti o n fi igba gbogbo kẹkọọ ṣugbọn ti imọ otitọ ko wọle si lori ni wọn ma n ṣaba lọ fun. Eyi tunmọ si pe wọn ki fojusun gbogbo eniyan. Dipo eyi, awọn ti wọn lọra lati ni oye otitọ nkan ti ẹmi ati lati mu wọn lo ni wọn ma n fojusun.

Mo gbọ ni igbakan pe wolii kan ni aṣa ki o ma ba awọn abilekọ ti o ba wa sọdọ rẹ fun adura nipa iṣoro aye wọn sun. Ki lo fa ti ọkunrin yi fi n ṣe aṣeyọri ni ṣiṣe eyi? Idi naa ni pe awọn ti o n lugbadi rẹ gba igbakugba. Ki lo si fa ti wọn fi gba igbakugba? Idi naa ni pe wọn kọ lati tẹwọgba otitọ Ọlọrun ti wọn n kọ. 

Ṣe wọn ko mọ ifẹ Ọlọrun lori agbere ni? A bi ṣe ko si ẹnikẹni ti o fi igba kankan kọ wọn pe nini ibaṣepọ pẹlu ẹni ti eniyan ko fẹ kọ tọna ni? A ti gbọdọ kọ wọn ni awọn nkan wọnyi lera-lera, paapaa julọ ti wọn ba jẹ Kirisitiẹni. Ṣugbọn ọtọ ni ki awọn eniyan ma kọ otitọ lati ọdọ Ọlọrun; ọtọ si tun ni ki otitọ ti wọn n kọ ye wọn, ki wọn si mọ ibi ti o ti ba aye ti wọn n gbe lojoojumọ mu. 

Ti awọn eniyan ba kọ lati ni oye iwulo otitọ ti wọn n kọ ninu ijọ, o ṣeeṣe ki wọn ma ṣe amulo rẹ. Irufẹ awọn wọnyi si ni wọn ma n di eran ijẹ fun awọn eke olukọ ati eke wolii. Iru awọn eniyan yi ni wọn ma n tete ṣubu sinu ẹtan Eṣu, ti wọn a si fi idibajẹ ṣinu aye wọn, rẹ wọn jẹ tabi ṣe wọn ni ijamba.

Iwọ naa wa bere lọwọ ara rẹ, “Njẹ mo n kọ nkankan bi lati ara awọn nkan ti a n kọ mi ninu awọn ipade ijọ wa?” O n wa lọsọọsẹ fun ipade ijọ lati gbadura, lati sin Ọlọrun ati lati kọ ọrọ rẹ. Ṣugbọn ṣe o n kọ nkankan bi? Ṣe o n ni imọ-kun-imọ ninu otitọ Jesu nipasẹ awọn nkan ti o n kọ? Ṣe o si n ri bi o ti yẹ ki o ṣe amulo awọn otitọ ti o n kọ yi ninu aye re?

Ti idahun rẹ si awọn ibere yi ko ba ki i ṣe ‘Bẹẹni’, a jẹ wipe ọkan lara awọn ti o ma n fi gbogbo igba kẹkọọ ṣugbọn ti imọ otitọ ko ki wọ ọkan wọn ni o jẹ niyẹn. Nitorina, a ko le ni igbekele ninu rẹ lati ṣiṣẹ lori ọrọ Ọlọrun ti o n kọ. Bẹẹ si ni  adura wa le ma le daabo bo ọ kuro lọwọ awọn ti o n lepa lati yan ọ jẹ ati lati pa aye rẹ run. Adura mi fun ọ wa ni pe ki Ọlọrun ma kun ọkan rẹ pẹlu oye ọrọ rẹ ti o peye ni igbakigba ti o ba ti gbọ ọrọ naa, ki O si tun fun ọ ni okun lati ṣiṣẹ tọ ọrọ ti o ba gbọ, ki o ma ba tun ṣe fi igba kankan jẹ ẹran ijẹ fun awọn opurọ tabi ẹlẹtan yowu ti Satani le ran lati ba aye rẹ jẹ mọ, ni orukọ Jesu. Amin. 

Ki o ni ọsẹ atata.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́ láìsi mọ nkànkan | Pst. J.O. Lawal | Ọ̀wàrà 09, 2022 | Vol. 11, No. 23 Read More »

Wu wọn lori lati jẹ ki Ibukun rẹ ṣiṣẹ | Pst. J.O. Lawal | Igbe 03, 2022 | Vol. 10, No. 48

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu tuntun miran ninu ọdun yi, iyẹn oṣu Igbe. Adura mi si ni pe ki o ri ifarahan ẹkunrerẹ Ibukun Ọlọrun ninu aye rẹ ni gbogbo oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Gẹgẹ bi a ti sọ fun wa ninu bibeli, ti o si jẹ okodoro ọrọ, Ọlọrun ti bukun fun wa pẹlu gbogbo ibukun ẹmi ti o wa ninu awọn ọrun (Efesu 1:3). Nitorina, ko si ẹnikankan ti o tun le fun ọ ni ibukun miran tabi ibukun ara ọtọ kan tabi ibukun ti o ga ju eyi ti Ọlọrun ti fun ọ lọ. O ti ni gbogbo Ibukun ti o nilo ninu aye yi lati jẹ ohun gbogbo ti o yẹ ki o jẹ ati lati gbadun ara rẹ ni ọna ti o peye.

Amọ ṣa o, niwọn igba ti o jẹ wipe nkan ẹmi pọnbele ni Ibukun jẹ, a gbọdọ mọ bi a ti ṣe le jẹ ki o ṣiṣẹ, ki iriri rẹ ti a o ni ma ba jẹ ninu ẹmi nikan. Eyi jasi pe, a nilo lati ri ifarahan awọn Ibukun ti a ti rigba lati ọwọ Ọlọrun ninu ẹmi nipa ti ara pẹlu. Aijẹbẹ, awọn ti aye yi ko ni ri wa bi alabukunfun rara ati pe awọn naa gan paapaa ko ni jẹ igbadun aye wa bi o ti ṣe tọ gẹgẹ bi ẹni ti a bukun fun.

Bawo wa ni a ṣe le jẹ ki Ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ? Akọkọ, a le jẹ ki wọn ṣiṣẹ nipa sisọ nkankanna pẹlu Ọlọrun nipa aye wa ati nipa ṣiṣiṣẹ tọ ọrọ wa lẹyin. Nkan ti eyi tunmọ si ni pe nigbakugba ti a ba n sọ nkankanna pẹlu Ọlọrun lori ododo wa, alaafia wa, ilera wa, iṣoriire wa, aabo wa ati awọn nkan daradara ti aye yi miran, ti a si tun n gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu nkan ti a n sọ, nṣe ni a n mu ki Ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ. Bopẹ bosiya, a o bẹrẹ si ni ri ifarahan nipa ti ara awọn nkan ti o jẹ otitọ nipa aye wa ninu ẹmi.

Ekeji, a le mu ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ nipasẹ adura gbigba. Jesu sọ wipe, “Ẹ beere, ẹ o si ri gba, ayọ yin yoo si kun.” Eyi tunmọ si pe nipasẹ adura a le ri ifarahan awọn nkan ti Ọlọrun ti wulẹ fun wa ninu ẹmi lojutaye. Eyi, bi Jesu Oluwa wa si ṣe sọ, jẹ ọna kan ti a fi le jẹ ki ayọ wa kun lori awọn oniruuru nkan ti o ni i ṣe pẹlu aye wa. (Wo: Johanu 16:24)

Ọna miran lati mu Ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ ninu aye wa ni ki awọn miran, paapaa julọ awọn ti o ni aṣẹ kan tabi omiran lori aye wa, pe Ibukun rẹ sori wa. Ma ṣe gbagbe pe mo ti sọ siwaju pe ko si ẹni naa ti o le fun wa ni Ibukun ti o ga, dara tabi pọ ju eyi ti Ọlọrun ti fun wa lọ. Ṣugbọn, awọn kan wa, nitoripe Ọlọrun ti fun wọn ni aṣẹ kan tabi omiran lori wa, le mu ki awọn ibukun rẹ kan ti o ti jẹ tiwa tẹlẹ ṣiṣẹ nipasẹ ọrọ adura wọn. Eyi yoo si jẹ ki a bẹrẹ si ni ri ifarahan awọn Ibukun naa ninu aye wa.

Nkan ti mo n sọ ni pe awọn ti o ni aṣẹ nitootọ lori aye wa lọna kan tabi omiran, gẹgẹ bi awọn obi wa, adari ijọ wa, ọkọ wa, olugbawaṣiṣẹ, ọga wa lẹnu iṣẹ ati awọn adari ilu tabi ti ijọba wa, le mu awọn ibukun Ọlọrun kan tabi omiran ṣiṣẹ ninu aye wa nipaṣẹ ire ti wọn ti ọkan ṣu fun wa. Idi si niyi ti a fi gbọdọ kọ lati ma mu inu wọn dun, ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, ki ori wọn ba le ma ya loorekoore lati pe ire Ọlọrun sori wa.

Fun apẹẹrẹ, bi o tilẹ jẹ wipe ibukun ti a fun Aburahamu ti fikalẹ sori ẹbi rẹ, a nilo lati mu ṣiṣẹ ninu aye ọkọọkan ninu awọn arọmọdọmọ rẹ ki wọn to le ni iriri tabi ifarahan rẹ. Fun apẹẹrẹ, ti a ba wo aye Isaki, a ri wipe igbọran rẹ si Ọlọrun ni akoko iyan buruku kan ni o kẹ ki Ibukun yi ṣiṣẹ fun iṣoriire rẹ laye (Jẹnẹsisi 26). Lafikun, adura rẹ fun aya rẹ tun jẹ ki Ibukun yi ṣiṣẹ lodi si iyagan wọn, ti awọn naa si di ọlọmọ laye (Jẹnẹsisi 25:21). Ṣugbọn ni ti Isọ, a ri wipe ire Isaki ni o yẹ ki o mu Ibukun yi ṣiṣẹ ninu aye rẹ. Nitorina, Isaki paṣẹ fun lati pese ounjẹ adidun ti yoo mu ki inu oun dun to bẹẹ gẹẹ ti oun yoo gbadura pataki ti yoo mu ki Ibukun baba oun ṣiṣẹ ninu aye rẹ fun. Bi o wa  tilẹ jẹ wipe Isọ kọ ni o pada gba Ibukun yi, Jakọbu, ẹni ti o gba a, ko kuna rara lati mu inu baba wọn, Isaki, dun pẹlu ounjẹ ara ọtọ ti o gbe wa fun. Nitorina, Ibukun naa di titu silẹ lati ṣiṣẹ ninu aye rẹ nipa ire Isaki, aye rẹ ko si ri bakanna mọ lati igba naa lọ.

Nibakanna, ti awa naa ba kọ lati ma mu ki inu awọn ti o ni aṣẹ lori wa dun nipasẹ awọn nkan ti a n ṣe fun wọn ati ṣi wọn, ọpọ igba ni a o ri pe ori wọn yoo wu lati sọ awọn ọrọ ti yoo jẹ ki awọn Ibukun Ọlọrun kan ṣiṣẹ ninu aye wa, ti a o si bẹrẹ si ni ri ifarahan awọn Ibukun naa lojutaye. Ṣugbọn ti a ba ro pe ọrọ ire wọn ko ja mọ nkankan si wa, boya nitori imọ ti a ni pe a kuku ti gba gbogbo Ibukun ọrun lati ọwọ Ọlọrun, a jẹ wipe awọn ifarahan awọn Ibukun Ọlọrun kan wa ti a le ma ni titi ọjọ aye wa yoo fi tan lorilẹ niyẹn. Nitorina, ẹ jẹ ka kẹkọ lati ara Jakọbu, ki a si ma wo, loorekoore, awọn ọna ti a le gba wu awọn ti o ni aṣẹ lori wa lori  lati mu Ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ ninu aye wa. Ki Ọlọrun si rẹ ọkan wa silẹ lati mu ọrọ yi lọkunkundun, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọsẹ ire o.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Wu wọn lori lati jẹ ki Ibukun rẹ ṣiṣẹ | Pst. J.O. Lawal | Igbe 03, 2022 | Vol. 10, No. 48 Read More »