Ǹjẹ́ o wúlò fún wọn bí? | Pst. J.O. Lawal | Ọ̀wàrà 16, 2022 | Vol. 11, No. 24
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Owewe 2022. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki o pọ si ni iwulo fun un ati fun awọn ti o wa ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ninu lẹta Pọọlu keji si Timoti, o sọ eyi fun un nipa Johanu Maaku: “…mu Maaku wa pẹlu rẹ: nitori o wulo fun iṣẹ-iransẹ.” (2Timoti 4:11) Ṣugbọn igba kan wa ti Pọọlu ko fẹ mu Maaku kanna yi lati rin irinajo kankan pẹlu rẹ ni ṣiṣe ojuṣẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ. Idi si ni pe o ti fi igba kan ri kọ oun ati Banaba silẹ ni akoko ti wọn nilo rẹ gidigidi. Nitorina, Pọọu ri bi ẹni ti ko wulo fun un ninu iṣẹ iranṣẹ. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 13:13; Ìṣe Àpọ́sítélì 15:36-41)
Ṣugbọn Maaku ko duro sojukan gẹgẹ bi ẹni ti ko wulo fun Ọlọrun tabi fun awọn iransẹ rẹ titi lailai. Oun naa dagba soke si ninu nkan ti ẹmi. Nigba ti o to asiko kan, oun naa ṣe idamọ awọn iwa ati aṣa ti o n mu ki o jẹ alaiwulo fun awọn eniyan Ọlọrun ti o wa ninu aye rẹ, o si mojuto wọn nipasẹ agbara Ẹmi Ọlọrun. Nitorina, lẹyin ọdun melokan si, Pọọlu sọ fun Timoti pe o jẹ dandan fun lati wa Maaku, ki o si mu wa si ọdọ oun, nitori ti o wulo fun ninu iṣẹ iranṣẹ rẹ.
A tun ri ọdọmọkunrin kan ninu bibeli ti itan tirẹ naa fẹ fi ara pẹ eyi. Oun naa ti fi igba kan ri jẹ alaiwulo fun olowo rẹ, bi o tilẹ jẹ wi pe ‘Mowúlò’ ni itunmọ orukọ rẹ. O wa jẹ ẹnikan ti ko wulo, ti ko si ni nkan ṣe to bẹẹ gẹẹ ti o fi sa kuro ni ọdọ oluwa rẹ. Ṣugbọn nigba ti o pade Pọọlu, o di atunbi. Lati igba yi lọ wa ni aye rẹ ti bẹrẹ si ni gba ọna ara ọtọ, ti o si bẹrẹ si ni gbe aye rẹ ni ibamu pẹlu orukọ rẹ, ‘mowúlò’. O wa wulo to bẹẹ gẹẹ fun Pọọlu ti o fi gbero lọkan rẹ lati jẹ ki o wa pẹlu oun titi lailai. Ṣugbọn nitoripe o fẹ ki olowo rẹ ri bi Ọlọrun ti ṣe yi aye rẹ pada, ki o dárí gbogbo nkan buburu ti o ti ṣe si ji i, ki o si tun gbadun iwulo rẹ, o ran an pada lọ si ọdọ rẹ. Ọrọ ẹni ti mo si n ṣọ ko ju ti Onesimu, iranṣẹ Filemoni, lọ. (Filemoni 1)
A wa ri aridaju bayi pe Ọlọrun ni agbara lati sọ awọn ti ko wulo di ẹni ti o wulo ati awọn alainikanṣe eniyan di ẹni ti o n ṣe ojuṣe rẹ, ti wọn ba fi aye wọn jin fun. O si fẹ sọ iwọ naa di ẹni ti o wulo ati ẹni ti o mọ ojuṣe rẹ ninu gbogbo ibaṣepọ rẹ. Ṣugbọn ṣe iwọ funrarẹ fẹ wulo, ki o si jẹ ẹni ti o n ṣe ojuṣe rẹ si Ọlọrun ati ninu gbogbo awọn ibaṣepọ rẹ? Ayafi ti o ba ṣetan lati wulo siwaju ati siwaju si, o ni oju nkan ti Ọlọrun le ṣe fun ọ. Awọn ti wọn ba ṣetan lati wulo nikan ni Ọlọrun le ṣe yẹ lati le ṣe awọn nkan ti o tọ fun wọn lati ṣe lati jẹ ẹni ti o wulo ninu aye wọn ati ti o n fi igba gbogbo pọ si ni iwulo.
Ni kukuru, gẹgẹ bi Pọọlu, awọn adari ijọ Ọlọrun kọọkan naa nilo awọn eniyan ti o wulo lati ran wọn lọwọ ninu iṣẹ iranṣẹ wọn ati lati jẹ ki iṣẹ wọn ma tẹsiwaju. Wọn nilo awọn ti wọn le gbe ara le lati ran wọn lọwọ pẹlu asiko wọn, ẹbun ẹmi wọn, owo wọn, amuyẹ wọn ati ohunkohun ti wọn ba ni. Ṣe o wa jẹ ọkan lara awọn wọnyi bi? Ṣe o wulo fun awọn adari ijọ rẹ ni ọna kankan? Ti wọn ba n ronu nipa awọn ti wọn le gbe ara le lati ṣe awọn iṣẹ kan, ṣe orukọ rẹ yo tilẹ wa si wọn lọkan bi? Ti eyi ko ba ri bẹ, a jẹ wipe o ko wulo fun wọn niyẹn. Ti o ko ba si wulo fun awọn adari ijọ rẹ, afaimọ ki o ma jẹ wipe o ko wulo fun Ọlọrun ti O yan wọn le ọ lori naa pẹlu.
Ṣe o wa fẹ duro si ipo ẹni ti ko wulo fun wọn ni tabi o fẹ di ẹni ti o wulo? Eyi jẹ ibere ti o nilo lati dahun bi o ti ṣe doju kọ ọsẹ tuntun yi. O si wa kọja ki o ma bere lọwọ wọn, “Ọna wo ni mo le gba wulo fun yin?” O tun ni i ṣe pẹlu ki o fi awọn ọna ti o le gba wulo fun wọn han wọn pẹlu iṣe rẹ. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun dari rẹ kuro ninu ohun gbogbo ti o n ṣe ọ ni alaiwulo fun un ati fun awọn ti o wa ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ eleso rere.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Ǹjẹ́ o wúlò fún wọn bí? | Pst. J.O. Lawal | Ọ̀wàrà 16, 2022 | Vol. 11, No. 24 Read More »

