Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òwewè 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ ṣe ọ yẹ pẹlu ohun gbogbo ti yoo ṣe ọ ni olujọsin tọọtọ ni iwaju rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, Ọlọrun ma n fi gbogbo igba wo ọkan awọn eniyan ni ibi gbogbo. Nkan ti O ba si ri ninu ọkan wọn jẹ ọkan lara awọn nkan ti yoo sọ iha ti yoo kọ si wọn. Fun apẹrẹ, lẹyin igba ti Ọba Asa bẹrẹ si ni wuwa igberaga, Ọlọrun ran wolii kan lati sọ eyi fun un:
“Nitoriti oju Oluwa nlọ siwa sẹhin ni gbogbo aiye, lati fi agbara fun awọn ẹni ọlọkàn pípe si ọdọ rẹ̀…” (2 Kíróníkà 16:9)
Njẹ o ri bayẹn? Oju Ọlọrun ma n fi igba gbogbo wa lori ilẹ aye lati wa awọn ti ọkan wọn ṣe olootọ si, iyẹn awọn ti ọkan wọn ko ni lailai gbẹkẹle elomiran tabi ohun miran yatọ si. Ki si ni idi ti O ṣe n wa irufẹ awọn wọnyi? O n wa wọn ki o ba a le fi agbara rẹ han lori ọrọ wọn. O n wa wọn ki O ba a le fi ara rẹ han gẹgẹ bi ẹni ti o lagbara to lati mojuto wọn, lalai ka irufẹ idojukọ yowu ti wọn n ba finra laye si.
Lafikun, nigba ti Jesu n ba arabarin Samaria kan sọrọ, O sọ eyi fun un:
“Ṣugbọn wakati mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn olusin tõtọ yio ma sìn Baba li ẹmí ati li otitọ: nitori irú wọn ni Baba nwá ki o ma sìn on.” (Jòhánù 4:23)
Iru awọn olujọsin wo ni Ọlọrun n wa? O n wa awọn ti yoo ma a sin ni ẹmi ati ni otitọ. Eyi ja si pe, O n wa awọn ti yoo sin pẹlu gbogbo ọkan wọn, ti wọn ko si ni ṣe alaiṣootọ si ni ọna kankan ninu ibaṣepọ wọn pẹlu rẹ. Irufẹ awọn wọnyi ni O le fi ọkan tan lati fun ni ifihan ara rẹ ati agbara rẹ. Irufẹ awọn wọnyi ni O le fi ọkan tan lati gbe awọn iṣẹ rere ti O fẹ ṣe laye le lọwọ. Idi si ni pe awọn nikan ni yoo sin-in lotitọ, bi o ti wu ki igba ati asiko aye wọn ri, yala o rọrun fun wọn tabi ko rọrun fun wọn lati sin in.
Awọn miran lara wa le ma woye idi ti Ọlọrun ko ṣe ma a fi ara rẹ han wa tabi lo wa lati ṣe awọn iṣẹ rere kan ti O n tipasẹ awọn miran ṣe, bi o tilẹ jẹ wipe a n lọ si ipade ijọ deede tabi fi ọrẹ ati idamẹwa silẹ deede. Nkan ti ko ye wa ni pe ko ki i ṣe awọn ti yoo ma a wa si ipade ijọ tabi fi ọrẹ silẹ deede ni Ọlọrun n wa, bi o tilẹ jẹ wipe awọn nkan wọnyi ṣe pataki. Dipo eyi, nṣe ni O n wa awọn ti yoo ma a sin in tọkan-tọkan, bi o ti wu ki igba tabi asiko aye wọn le e ri. Ti a ko ba si ki i ṣe iru eniyan yi, awọn nkan kan wa ti Ọlọrun ko ni lailai ka wa yẹ fun un.
Nitorina, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, bere lọwọ ara rẹ, “Ti Ọlọrun ba n wa ẹni ti o le fọkan tan lati fun mi imọ ara rẹ, imọ ifẹ rẹ, imọ ipese rẹ tabi awọn iṣẹ rere kan ti O fẹ ki o jẹ ṣiṣe nibi ti mo wa, njẹ yoo ka mi yẹ fun un?” Ranti wi pe Ọlọrun ko ki i ṣoju-ṣaaju. Nitorina, bi O tilẹ jẹ wipe O fẹran gbogbo wa bakan naa, kiki awọn ti o ba n fi tọkantọkan fi ara wọn jin fun ni yoo le gbẹkele lati ṣe ohunkohun ti o ba ṣe pataki si i. Idi si ni yi ti a ṣe gbọdọ ma a fi igba gbogbo gbadura pe ki Ọlọrun ya wa ya ohunkohun ti o le ma di wa lọwọ lati fi gbogbo ọkan wa jin lati sin in. Eyi ni yoo jẹ ki O bẹrẹ si ni ri wa gẹgẹ bi awọn ti O le ka yẹ fun oniruuru iṣẹ rere.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)