Njẹ o ma ja Ọlọrun lole bi?
J.O. Lawal | Ojo: Erẹna 28, 2021 | Nomba: Vol. 9, No. 47
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun yi. Adura mi si ni pe gbogbo ilẹkun ire ati igbega ti a ti mọ ọ ni ki Ọlọrun ṣi gbayawu fun ọ ninu ọsẹ na, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, yatọ si adura gbigba, ọna gbankọgbi miran ti a le gba mu ki Ọlọrun ṣi ilẹkun oju rere fun wa ni ki a ma ja a lole, ṣugbọn ki a ma fun ni ohunkohun ti O ba n bere lọwọ wa. Njẹ a tilẹ le ja Ọlọrun lole? Ṣe o tilẹ ṣeeṣe? Bẹẹni, o ṣeeṣe. Fun apẹẹrẹ, Ọlọrun fi ẹsun kan awọn Juu igba aye Malaki pe wọn n ja Oun lole nipa ṣiṣe alaiṣootọ niti idamẹwa ati ọrẹ wọn. Amọ tani awọn idamẹwa ati ọrẹ wọnyi wa fun? Ṣe Ọlọrun ni? Rara o! Dipo eyi, wọn wa fun awọn aluufa ti o ṣiṣẹ sin awọn eniyan yi, awọn ọmọ Lefi ti o wa kaakiri ilu wọn, awọn opo, awọn alainibaba, awọn ajoji ati awọn akuṣẹ ti o wa ni ilu. (Wo: Ditaronomi 14:28-29&26:12-15; Malaki 3:8-9)
Sibẹsibẹ, nigba ti awọn Juu yi kọ lati jẹ olootọ ni dida idamẹwa ati ọrẹ wọn fun awọn ti Ọlọrun ti pa a laṣẹ fun wọn lati ma da wọn fun, O pe wọn ni adigunjale. Nitoripe wọn si n ja a lole ni ọna yi, awọn ilẹkun ibukun kan di titi mọ wọn. Yatọ si iyẹn, awọn ajẹnirun naa tun n jẹ ere iṣẹ ọwọ wọn, wọn si jẹ ki wọn ma ṣe aṣedanu. Bi O ti wa fi ye wọn, ọna abayọ kan ṣoṣo ti o wa fun wọn naa ni ki wọn ronupiwada, ki wọn si bẹrẹ si ni ṣe ohun ti o tọ (Malaki 3:10-12).
Ni afikun, nigba ti O n ba awọn Juu igba aye Hagaii sọrọ, Ọlọrun sọ fun wọn pe idi kan pataki ti gbogbo wọn fi n ni iriri aṣedanu, bi o tilẹ jẹ pe wọn n ṣiṣẹ karakara, ni pe wọn pa kikọ tẹmipili rẹ ti. Awọn eniyan yii ni akoko ati owo lati kọ ile daradara fun ara wọn. Ṣugbọn gbogbo igba ni wọn n sun kikọ tẹmipili Ọlọrun si ọjọ iwaju ti ko ni gbedeke. Nitorina, O binu si wọn, O si ti ọpọlọpọ ilẹkun aṣeyọri mọ wọn. Bi O ṣe wa fi ye wọn nipasẹ Hagaii, ayafi ti wọn ba ronupiwada, ti wọn si bẹrẹ si ni ṣe ohun ti o tọ, wọn ọn o ni bọ ninu iṣẹ. (Wo: Hagaii 1)
Ni bakanna, bi o tilẹ jẹ pe awa ti a wa ninu Kirisiti Jesu ko gba iru ofin kanna lori fififunni bi ti awọn Juu ti o wa ni abẹ majẹmu atijọ, awa na gba awọn aṣẹ ti o daju lori fifi fun awọn ti o n bọ wa pẹlu pẹlu ọrọ Ọlọrun, iṣẹ iranṣẹ wọn ati awọn alaini ti o wa ni aarin wa (Roomu 12:13&15:16; 1Korinnti 9:14; Galatia 6:6). Lotitọ, ohunkohun ti a ba fun wọn gbọdọ wa lati ọkan wa, pẹlu inu didun ati ni iwọn bi nkan ini wa ṣe pọ to (1Korinnti 16:2; 2Korinnti 8:12&9:7). Ṣugbọn a ko gbọdọ kuna lati ma ṣe OJUṢE wa, lati jẹ OLOOTỌ, lati jẹ ẸNI TI O NIPINNU lati ṣe ohun ti o tọ ati lati jẹ ẸNI TI O N ṢE DEEDE lori ọrọ yi. Aijẹbẹ, awọn naa yoo di ẹni ti n ja Ọlọrun lole.
Wayi o, a le wa ma ja Ọlọrun lole lọnakọna, ki a si tun ma reti pe ki Ibukun rẹ ma a ṣan bi omi odo ninu aye wa. Lotitọ, a le ni oriṣiriṣi awawi fun bi a ṣe n ja a lole. A le sọ pe nitoripe a ko ni nkankan ni tabi nitori pe a ko ni iṣẹ lọwọ ni tabi nitoripe bukata pọ jọọjọ lọrun wa ni tabi nitoripe ọmọ ile-iwe si ni wa ati pe a tun kere lọjọ ori pupọ. Ṣugbọn nkankan ni o daju, eyi si nipe, niwọn igba ti a ba n ja Ọlọrun lole, ko si bi a ṣe fẹ ni iriri asẹyọri ti o yẹ ki a ni laye yi.
Wo o, bi o ba tilẹ jẹ pe nṣe ni a n fun un ni ohun ti o kere si nkan ti a lagbara lati fun un, nṣe ni a n ja a lole, ti o si di dandan ki a ri bi o ṣe n ri fun awọn ti o ba n ja a lole. Boya idi ti eto iṣuna rẹ ko ṣe gbera soke tabi fi gbogbo ara yatọ lati bi ọdun melokan sẹyin ni pe o n ja Ọlọrun lole. Tabi boya idi ti awọn ilẹkun kan ti o ti n kan fun ọpọ ọdun ṣe wa ni titipa ni pe o ti n lo awọn nkan ti o jẹ ti Ọlọrun fun ara rẹ. O nilo lati ronupiwada loni, ki o si bẹrẹ si ni ṣe ohun ti o yẹ. Aijẹbẹ, ki Ọlọrun ma jẹ ko ribẹ fun ọ o, afaimọ ki ọrọ rẹ ma tun lọ buru si.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Njẹ o ma ja Ọlọrun lole bi? Read More »

