J.O. Lawal | Ojo: Igbe 28, 2021 | Nomba: Vol. 9, No. 48
Olufe: Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Igbe 2021. Mo si gbadura pe ki o ni iriri oore-ọfẹ ati ojurere Ọlọrun ti o to bẹẹ, ti o si tun ju bẹẹ lọ, fun itayọ rẹ ninu oṣu na, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ṣe bẹrẹ oṣu tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju lati kọ bi a ṣe n ṣe amulo oore-ọfẹ Ọlọrun lati ma fi ojoojumọ pọ si ni iwulo fun Ọlọrun ati fun ijọ rẹ. Ọlọrun, bi a ṣe fi ye wa ninu iwe mimọ, ko gba wa la, ki O si tun fi wa sinu ara Kirisiti, ki a ba le jẹ alaiwulo ninu ijọba rẹ. Dipo eyi, O gba wa la, O kun wa pẹlu Ẹmi Mimọ rẹ, O si tun bukun fun wa pẹlu oniruuru ẹbun ẹmi, ki a ba le je aṣoju rẹ tootọ ninu aye yi, aṣoju ti O le lo fun irufẹ iṣẹ rere yowu ti O ba fẹ ki o jẹ ṣiṣe.
Ṣugbọn ṣe a n fi ara wa jin lati wulo fun Ọlọrun ati ijọ rẹ bi? Eyi ko ni nkankan ṣe pẹlu bi a ti ṣe pe ninu ijọ to tabi bi ẹbun ẹmi wa ti ṣe pọ to. Dipo bẹ, o ni i ṣe pẹlu itara ọkan wa lati ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ ti o n ṣiṣẹ ninu aye wa ni ọna ti o peye. Fun apẹẹrẹ, ninu lẹta rẹ si Filimoni nipa Onisimu, Pọọlu sọ pe, “Emi bẹ ọ fun ọmọ mi ninu Kirisiti, Onisimu, ẹni ti mo bi ninu ide mi: Ẹni ti o je alailere fun ọ nigba kan ri, ṣugbọn nisinsinyi o lere fun ọ ati fun mi.” (Filimoni 10-11)
Njẹ o ri bayi? Onisimu, nigba ti Jesu ko i ti yi aye rẹ pada, jẹ alaiwulo eniyan kan, bi o tilẹ jẹ pe itunmọ orukọ rẹ gan ni ‘Ọmόlérè’. Nitorina, pe orukọ rẹ tunmọ si ‘Alaasiki’ ko jasi pe o o ṣe orire ni aye. Pe orukọ rẹ si tunmọ si ‘Alaafia’ ko jasi pe o o ni alaafia ninu aye rẹ tabi ninu igbeyawọ rẹ. Ti o ko ba jẹ ki Ọlọrun gba akoso aye rẹ, ki O si ba ọ gbe e, ko si bi orukọ rẹ ṣe dun to leti tabi bi itunmọ rẹ ṣe dara to, o le ma ba aye rẹ dọgba.
Ki a ma fi ọrọ silẹ sọ nkan mi, bi o tilẹ jẹ pe aye Onisimu fi igbakan jẹ aye alaiwulo ati aye ti ko ni itunmọ, nigba ti o fi aye gba ki Jesu gbajọba rẹ, ẹri rẹ bẹrẹ si ni yipada. Nigba ti o si to akoko kan, Pọọlu apositeli gan le fi ọwọ sọya sọ fun ọga arakunrin yi, iyẹn Filimoni, ti o sa kuro lọdọ rẹ, pe ki o gba a pada, nitoripe o ti di ẹni ti o wulo. Ọna ti ọkunrin yi ti wa gba wulo fun Pọọlu ni ko sọ fun wa. Amọ, o wulo fun un debi pe ko tilẹ wu u gan ki o jẹ ki o lọ. Nkan ti a si n sọrọ nipa na ni yẹn. A n ṣo pe Ọlọrun fẹ ki a wulo fun Oun ati fun awọn eniyan rẹ debi pe wọn ko ni fi igba kankan fẹ ki a fi awọn silẹ lọ si ibomiran. Njẹ ṣe bayi ni a ṣe wa n gbe aye wa?
Lafikun, wo nkan ti a kọ silẹ nipa Apolo ti aye igba bibeli: “Nigba ti o (Apolo) si fẹ kọja lọ si Akaya, awọn arakunrin gba a ni iyanju, wọn si kọwe si awọn ọmọ-ẹyin ki wọn ki o gba a: nigba ti o si de, o ran awọn ti o gbagbọ nipa oore-ọfẹ lọwọ pupọ.” (Iṣe Apositeli 18:27) Ki ni idi ti awọn eniyan Ọlọrun ni Efesu ṣe fọwọsọya lori rẹ fun awọn eniyan Ọlọrun ti o wa ni Akaya? Idi ni pe wọn gbagbọ pe yoo wulo fun wọn ti o ba de ọdọ wọn. Ṣe o wa dojuti wọn bi? Rara o! Dipo bẹ, bibeli sọ pe o wulo lọpọlọpọ fun awọn ti o ti ti ipasẹ oore-ọfẹ gbagbọ. Eyi jasi pe o ran awọn eniyan wọnyi lọwọ ni awọn ọna ti o ga pupọ lati dagbasoke si ninu igbagbọ wọn ati lati ma wuwa wu Ọlọrun siwaju ati siwajusi.
Ṣe a wa le sọ nkankanna nipa wa bi? Ṣe a le sọ pe a wulo lọna kankan fun awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ninu ijọ wa, adugbọ gba, ile-iwe wa, ibi iṣẹ wa tabi ibi okowo wa? Ki ni ipa ti a n ko ninu idagbasoke awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ninu aye wa ati ni ayika wa? Ki ni ipa ti a n ko lori ifẹsẹmulẹ awọn ara wa ninu ijọ ti a wa? Ki ni ipa ti a n ko lori ki awọn adari ijọ wa ba le munadoko si ninu iṣẹ iranṣẹ wọn? Ṣe a fi ara wa si ipo ẹni ti o wulo fun Ọlọrun ati awọn eniyan rẹ bi tabi nṣe ni a kan joko tẹtẹrẹ ninu ijọba rẹ, bi o tilẹ je pe oore-ọfẹ rẹ ti ko ni odiwọn ni a ti fi fun wa lọfẹ?
Ni kukuru, ko ki i ṣe Ọlọrun nikan ni o mọ idahun si awọn ibeere wọnyi; awa naa mọ wọn. A mọ boya a wulo fun Ọlọrun ati awọn ọmọ rẹ tabi a ko wulo. Ti a ko ba si fẹ ki Ọlọrun pe wa ni alailere lọjọ kan, a nilo lati jigiri ni bayibayi, ki a si bẹrẹ si ni i ṣe ohun ti o yẹ. Adura mi ni pe ki ọkan wa gba isọji ati okun lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni oṣu Igbe 2021 ti o ga.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
