October 2021

Má sọ ààyè rẹ nù

Titun yin kọ lẹẹkan si | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Owara 31, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 26

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati aanu jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun yi. Mo si tun gbadura pe ki ayọ ati alaafia Ẹmi Ọlọrun kun ọkan ati ile rẹ ni gbogbo ọsẹ naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Ni igba kan ri, mo gbọ ti oniwaasu kan n sọrọ lori bi igbimọ alagba ijọ kan ṣe kọ lẹta ni akoko kan si olu-ile iṣakoso ijọ wọn pe ki wọn tiransifa paitọ wọn kuro lọdọ wọn. Idi ti wọn si ṣe ṣe eyi ni pe paitọ naa ko ni iwaasu miran lati igba ti o ti de ọdọ wọn ju ‘ronupiwada, ki a si gba ọ la’ lọ. Nigba ti wọn si ni ki paitọ yi ṣalaye ara rẹ, o sọ wipe ko ki i kuku ṣe pe ohun ko ni nkan miran lati waasu le lori si awọn ara yi bi ko ṣe pe wọn ko i ti fi igba kankan ṣiṣẹ lori nkan ẹyọkan ṣoṣo ti oun ti n fi i waasu si wọn. “Ki wa ni idi,” gẹgẹ bi o tun ṣe sọ siwaju, “ti o fi yẹ ki oun kọ wọn ni awọn nkan tuntun miran, nigba ti wọn kọ lati ṣe amulo nkan ẹyọkan ṣoṣo ti oun ti n kọ wọn?”

Ki wa ni koko ọrọ yi? Oun naa ni pe laijẹpe awọn ọmọ Ọlọrun bẹrẹ si ni fi ori pipe ṣe amulo awọn nkan ti wọn n kọ wọn, awọn oniwaasu ti wọn ba mọ nkan ti wọn n ṣe ko ni dẹkun ati ma tun wọn kọ. Idi si ni yi ti Pọọlu ṣe sọ fun awọn ara Filipi pe, “Ni akotan, ara, ẹ maa yọ ninu Oluwa. Ki i sii ṣe inira fun mi lati kọwe ohun kan naa si yin, ṣugbọn eyi jẹ ohun ti o dara fun yin.” (Filipi 3:1) Njẹ o ri bayi? Pọọlu ko ri gẹgẹ bi inira rara lati ṣe agbeyẹwo awọn nkan ti o ti kọ awọn ara yi tẹlẹ lẹkaansi. Ki si ni idi? Idi ni pe ṣiṣe bẹẹ yoo ran wọn lọwọ lati duro ṣinṣin ninu ifẹ Ọlọrun.

Wayi o, mo mọ pe o ma n saba bi ọpọ wa ninu ti awọn paito wa ba n ran wa leti tabi tun wa kọ ni awọn nkan ti a ti mọ tẹlẹtẹlẹ. Ṣugbọn a tun gbọdọ jẹ ki o ye wa pe ti a ba n ṣiṣẹ lọna ti o tọ pẹlu awọn nkan ti a mọ gẹgẹ bi otitọ Ọlọrun si wa, a ko ni nilo ẹnikẹni lati ran wa leti tabi tun wa kọ lati ṣe bẹẹ. Igba ti a ba n ṣe bi ẹni ti oye nkan ti wọn kọ wa ko ye tabi bi alakọgbagbe tabi bi alagidi akẹkọ ni o jẹ didan ki a tun wa kọ tabi ran wa leti nkan ti a ti kọ sẹyin.

Fun apẹẹrẹ, mo woye pe bi o tilẹ jẹ wipe ẹkọ lori ki a ma mọ riri awọn paitọ wa ati awọn adari ijọ wa miran bi ti wọn, awọn ti wọn n bọ wa loorekoore pẹlu ọrọ Ọlọrun ati ti wọn n mojuto wa nipa agbara Ọlọrun, ni a ti fi ọpọlọpọ igba kọ ọpọ ọmọ Ọlọrun, perete lara wọn ni o mu ni ọkunkundun. Nkan ti mo n sọ ni pe ọpọ ninu awọn ijọ wa ni o jẹ pe diẹ lara awọn ti o wa nibẹ ni o ma n ṣaba mọọmọ pinnu lọkan wọn lati mọ riri awọn adari wọn, ki i si ṣe pẹlu ọrọ ẹnu lasan ṣugbọn pẹlu awọn nkan ini wọn pẹlu. (Wo: Luuku 10:1-8; 1Kọrinnti 9:14; Galatia 6:6)

Yoo tilẹ ya ọ lẹnu pe pupọ ninu awọn ọmọ Ọlọrun ni ko i ti fi igba kankan ri mọọmọ lọ ba awọn paitọ wọn lati sọ fun pe, “Ẹ ma ṣeun sa fun iṣẹ rere ti ẹ n ṣe,” tabi ṣe nkankan fun wọn ti yoo mu inu wọn dun. Ṣugbọn ti awọn ara kan naa yi ba gbọ pe awọn adari ijọ wọnyi ṣe aṣemaṣe kan ti o ni i ṣe pẹlu agbere tabi ikowojẹ, wọn ko ni lọra rara lati tan iroyin ibi naa kalẹ tabi lati lo ohunkohun ti o ba wa ni ikawọ wọn lati ba aye awọn adari naa jẹ. Ko wa jẹ iyalẹnu, ẹwẹ, pe adura ati iṣure awọn oniwaasu yi ko le duro lori awọn ọmọ ijọ wọnyi lati ṣiṣẹ fun wọn.

Njẹ o tilẹ ro nitootọ pe gbogbo ọrọ adura tabi ire ti a ba su fun awọn eniyan naa ni o le ba le wọn lori tabi ṣiṣẹ ni rere fun wọn? Rara o! Jesu ti fi igba kan ri sọ eyi fun awọn apọsiteli rẹ: “Ni ilekile ti ẹyin ba wọ, ki ẹ kọ wi pe, Alaafia fun ile yii. Bi ọmọ alaafia ba si wa nibẹ, alaafia yin yoo ba le e: ṣugbọn bi ko ba si, yoo tun pada sọdọ yin. Ni ile kan naa ni ki ẹyin ki o si gbe, ki ẹ maa jẹ, ki ẹ si maa mu ohunkohun ti wọn ba fi fun yin; nitori owo iṣẹ alagbaṣe tọ si i. Ẹ ma ṣe ṣi lati ile de ile.” (Luuku 10:5-7) Ṣe iwọ naa ri bayi? Ọrọ iṣure le pada sọdọ ẹni ti o sọ, ti ẹni ti o sọ ọ si ko ba tẹwọgba bi o ṣe yẹ. Nitorina, bi paitọ rẹ ba tilẹ n fi gbogbo igba gbadura fun ọ lati ṣorire ati lati ṣe aṣeyọri ni aye yi, niwọn igba ti o ko ba ba a lopọ gẹgẹ bi Ọlọrun ṣe fẹ ki o ṣe, adura ibukun rẹ le ma duro sori aye rẹ, ki o si ṣiṣẹ fun ọ bi o ṣe tọ ati bi o ṣe yẹ.

O wa ṣenu laanu pe ọpọ ọmọ Ọlọrun ni oye ko ye pe idi ti aye wọn ko fi gbooro si labẹ awọn paitọ ni ọpọ igba kọ ni pe nkan n ṣe awọn paitọ naa ninu ẹmi. Dipo eyi, idi ni pe wọn ko ba wọn lopọ bi Ọlọrun ṣe fẹ ki wọn ma ṣe. Ti wọn ba si ronupiwada kuro ninu aigbọran wọn yi, ti wọn si dẹkun lati ma ko awọn nkan ti o yẹ ki wọn fi ran awọn paitọ wọn lọwọ lọ si awọn ori-oke kan, wọn yoo bẹrẹ si ni ri pe awọn tilẹ le ṣe rere daradara labẹ iṣẹ iranṣẹ ojoojumọ awọn paitọ naa ju bi wọn ti le ṣe lọ labẹ iṣẹ-iranṣẹ ẹkọọkan awọn ẹni amin ororo wolii ti wọn fẹ titori wọn ku. Njẹ wọn yoo wa ronupiwada bi? (Wo: Matiu 10:40-42)

Ka ma fọrọgun, koko nkan ti mo n sọ lati atẹyinwa naa ni pe ti paitọ rẹ ba nilo lati tun ọ kọ ni awọn ẹkọ bibeli kan lẹkaansi, iyẹn ko tunmọ si pe ko ni nkan miran ti o le kọ ọ; dipo eyi, o le jẹ wipe nitoripe o ko i ti ma ṣe amulo nkan ti o ti kọ bi o ti tọ ni. Ti o ko ba si ma ṣe amulo ti o peye awọn nkan ti a ti kọ ọ daradara, o le jẹ wipe awọn nkan naa ko i ti ye ọ to ni tabi ki o jẹ alakọgbagbe tabi ki o jẹ alagidi kan. Ko wa si eyi ti o bojumu ninu awọn nkan wọnyi. Nitori naa, dẹkun jijẹ ẹni ti o lọra lati kẹkọ, alakọgbagbe tabi alagidi, ki o si bẹrẹ si ni mu awọn nkan ti a n kọ ọ ni ọkunkundun. Nipa ṣiṣe eyi, iwọ naa yoo le fi awọn ẹkọ ipilẹ ti igbagbọ Kirisitiẹni silẹ, ki o si di ẹni ti o to oju bọ ninu ẹmi (Heberu 5:11-6:3).

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Titun yin kọ lẹẹkan si | Paitọ J.O. Lawal Read More »

Iranṣẹ gbogbo eniyan | Paito J.O. Lawal

Ọjọ: Owara 24, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 25

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Ọwara 2021. Adura mi si pe ki o lo eyi ti o ku ninu ọdun yi ninu ẹkunrẹrẹ ayọ Ẹmi, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ṣe n bẹrẹ ọsẹ yi, jẹ ki n ran ọ leti ọrọ Jesu Oluwa wa ti o sọ wi pe, “…Bi ẹnikẹni ba n fẹ ṣe ẹni iwaju, oun naa ni yoo ṣe ẹni ikẹyin gbogbo wọn, ati iranṣẹ gbogbo wọn.” (Maaku 9:35) Pẹlu nkan ti Oluwa sọ nibiyi, kedere ni a ri pe Ọlọrun ko lodi si ki awọn ọmọ rẹ di asiwaju tabi ẹni akọkọ ninu aye yi. Bi a tilẹ ṣe ri, lara awọn nkan ti o ṣeleri lati ṣe fun awọn ọmọ Isiraẹli, ti wọn ba pa aṣẹ rẹ mọ, ni lati sọ wọn di ori dipo iru ni aarin awọn orilẹ-ede aye gbogbo (Ditaronomi 28:13). Nitorina, ko lodi si erongba rẹ ki iwọ ati emi jẹ ori dipo iru nibikibi ti a ba ti ba ara wa ninu aye yi.

Amọ ọna wo wa ni a le gba jẹ irufẹ ori ti Ọlọrun fẹ ki a jẹ, ti ko si ni mọ ni aye yi nikan sugbọn ti yoo tun jẹ bẹẹ gẹgẹ ninu ijọba ayeraye rẹ pẹlu? Bawo ni a ṣe le di ipo pataki mu ninu eto rẹ fun ohun gbogbo? Oun naa ni Oluwa n ba wa sọrọ le lori ninu ẹsẹ bibeli yẹn. O si sọ wipe nipa jijẹ iranṣẹ gbogbo eniyan ni.

Ki wa ni o tunmọ si lati jẹ iranṣẹ fun gbogbo eniyan? Ṣe o wa ja si pe ki a di ọmọ ti gbogbo eniyan a ma pe ran niṣẹ ni bi? A bi ṣe o wa jasi pe ki a di akitan fun gbogbo eniyan, ki a di ẹni ti ẹnikẹni le ṣe baṣabaṣa bi o ba ṣe wu wọn? Rara o! Ki wa ni o tunmọ si?

Ni kukuru, a le mọ nkan ti o tunmọ si nipa wiwo bi Jesu Oluwa wa ṣe ṣe nigba ti o wa laye yi. Ranti pe O sọ wipe Oun ko wa sinu aye ki wọn ba le sin Oun ṣugbọn ki Oun ba le sin awọn eniyan, ki Oun si fi ẹmi Oun silẹ fun irapada ọpọ (Maaku 10:45). Bawo wa ni O si ṣe sin awọn eniyan? Ṣe nipa dida ọmọ ti gbogbo wọn n pe ran niṣẹ ni tabi dida ẹni ti wọn kan le ṣe bi o ba ṣe wu wọn si ni? Rara o! Dipo eyi, o sin wọn nipa lilọ lati ibikan si ibikan lati ṣe awọn nkan ti yoo mu ki ifẹ Ọlọrun wa si imuṣẹ ninu aye wọn.

Lotitọ, awọn akoko kan wa ti awọn eniyan bu u, ti wọn si tun gan an nitori awọn nkan ti O sọ nipa ibaṣepọ rẹ pẹlu Ọlọrun. Ki a tilẹ sọ otitọ, wọn papa wuwa aidara si, ti wọn si tun pa a nitori ti o pe ara rẹ ni Ọmọ Ọlọrun. Ṣugbọn ni gbogbo akoko ti O fi ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laarin awọn eniyan rẹ, gbogbo wọn pata ni o bọwọ fun ati awọn ọta rẹ gan paapaa.

Nitori naa, jijẹ iranṣẹ gbogbo eniyan ko tunmọ si pe ki a sọ ara wa di ẹni ti ko naani ara rẹ ati ti awọn eniyan le ṣe bi o ba ṣe wu wọn si. Dipo eyi, o tunmọ si pe ki a gbe aye wa ni ọna ti o jẹ wipe awọn nkan ti a ba ṣe tabi sọ yoo mu ete Ọlọrun wa si imuṣẹ ninu aye awọn ti o wa ni ayika wa ati awọn ti a n ba ṣepọ, lọna kan tabi omiran. Ti o ba si jẹ pe bi eyi ni a ṣe n ṣe, ko wa ni ja mọ nkankan ni oju wa lati ṣiṣẹ ẹru tabi ti ọmọ aperannisẹ, niwọn igba ti yoo ba yọri si imuṣẹ ete Ọlọrun ninu aye awọn ẹlomiran.

Igba kan wa, fun apẹẹrẹ, ti Jesu Oluwa wa fọ ẹsẹ awọn apọsiteli rẹ, nkan ti o jẹ iṣẹ fun awọn ẹru. O ṣe eyi lati fi han wọn pe oye tabi ipo lasan kọ ni o ma n sọ eniyan di giga bikoṣe igbaradi rẹ lati ṣe ohunkokun ti o ba tọ fun lati ṣe lati sin awọn ti o wa ni abẹ akoso rẹ, bi o tilẹ ni i ṣe pẹlu fifọ ẹsẹ wọn. Ṣe eyi wa jẹ ki awọn apọsiteli yi ri fin? Rara! Dipo bẹẹ, o jẹ ki wọn bọwọ fun gidigidi si ni. Yatọ si eyi, o tun jẹ apẹẹrẹ fun wọn lori nkan ti O ti n kọ wọn tẹlẹ pe ẹnikẹni ti o ba fẹ di ẹni akọkọ tabi ẹni giga ninu ijọba Baba rẹ gbọdọ ṣetan lati sin awọn miran ni ọnakọna ti yoo mu ki ifẹ Ọlọrun wa si imuṣẹ ninu aye wọn. (Wo: Johanu 13:1-17)

Ti awa naa, ẹwẹ, ba fẹ di ipo ti o ga ninu ijọba Ọlọrun Baba wa mu, a gbọdọ ṣetan lati sin awọn ara wa ati awọn ti o wa ninu aye yi pẹlu wa ni ọnakọna ti ifẹ Ọlọrun yoo fi wa si imuṣẹ ninu aye wọn. Ṣugbọn ṣe a o rẹ ara wa silẹ lati ṣe eyi bi abi nṣe ni a o tunbọ ma ro pe a to nkan ti a ko to? Adura mi ni pe ki a ṣe ọkan wa ni rirẹ silẹ lati sin gbogbo awọn ti Ọlọrun fẹ ki a si ni ọna ti yoo yọri si igbega wa ninu ijọba ayeraye rẹ. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Iranṣẹ gbogbo eniyan | Paito J.O. Lawal Read More »

Ọlọrun n ṣiṣẹ ninu rẹ | Paito J.O. Lawal

Ọjọ: Owara 17, 2021 | Nọmba: Vol. 10, No. 24

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Olurapada wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun yi. Adura mi si nipe ki a ṣe ni aṣepe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ni kiakia, ki aye rẹ ba le wa ni ibi ti Ọlọrun fẹ ki o wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, o dami loju saka pe bi nkan yoo ṣe ri gẹlẹ fun ọ niyi nitori pe ẹni ti o n ṣiṣẹ ninu rẹ jẹ Ọlọrun funrarẹ. Pọọlu, nigba ti o n ba awọn Kirisitian ilu Filipi sọrọ lori pataki ki wọn mu ọrọ igbala wọn ni ọkunkundun, ran wọn leti wipe wọn le ṣe eyi nitori pe Ọlọrun n ṣiṣẹ ninu wọn lati fẹ ati lati ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu ete rere rẹ fun wọn (Filipi 2:12-13). Iwọ naa ro wo. Igbala awọn ara yi ko ki i ṣe bukata wọn nikan bi ko ṣe ti Ọlọrun naa pẹlu. Lotitọ, awọn nkankan wa ti o yẹ ki awọn naa maa ṣe lati le ni ẹkunrẹrẹ iriri igbala ti Jesu ti ra fun wọn. Ṣugbọn awọn nikan kọ ni yoo ma ṣe awọn nkan wọnyi. Wọn ko tilẹ nikan le da awọn nkan wọn yi, ohun yowu ti wọn jẹ, ṣẹ. Ẹni ti yoo jẹ ki wọn le ṣe wọn ni Ọlọrun. Pọọlu si wa fi da wọn loju pe o didan ki Ọlọrun ri pe iṣẹ naa jẹ ṣiṣe. Njẹ eyi ko wa dara pupọ lati mọ bi? O dara.

Ni ọna kaana, nitori pe awọn naa ti di ọmọ Ọlọrun nipasẹ Jesu Kirisiti, O ti bẹrẹ si ni ṣiṣẹ ninu aye wa. Ki o too di pe a di ọmọ rẹ, Eṣu ni o n ṣiṣẹ ninu aye wa, ti o si n ṣe wọn radarada ni oniruuru ọna. Idi niyi ti bibeli ṣe pe ni ẹmi ti o n ṣiṣẹ ninu awọn alaigbọran si Ọlọrun (Efesu 2:2). Ṣugbọn nibayi ti a ti di ọmọ Ọlọrun, O ti wa lati gbe ninu wa ati lati gba akoso aye wa. Bẹẹni, O ti wa lati gbe ninu wa lati ṣiṣẹ. Iru iṣẹ wo si ni O wa gbe inu wa ṣe? Ohun gbogbo ti o wa ni ibamu pẹlu ete rẹ ni rere fun wa!

Nitorina, wiwa si imuṣẹ ete Ọlọrun ni rere fun wa ko da lori akitiyan wa nikan; o tun ni i ṣe pẹlu akitiyan rẹ pẹlu. Idi si niyi ti a fi le mọ daju pe aye wa yoo pada da nkan ti o yẹ ki wọn da naa ni, bi o ti wu ki ibi ti a wa lọwọlọwọ yi ri. Njẹ eyi ye ọ bi? Ọlọrun le sọ aye wa da nkan ti o yẹ ki o da, lalai fi ti ibi ti O ti ri aye naa he ṣe. Nitorina, Pọọlu sọ fun awọn ara Filipi pe, “Ohun kan yii ṣaa da mi loju pe, Ọlọrun ẹni ti o ti bẹrẹ iṣẹ rere ninu yin, yoo ṣe aṣepe rẹ titi di ọjọ naa ti Jesu Kirisiti yoo de.” (Filipi 1:6) Dafidi naa tun sọ wipe, “Oluwa yoo ṣe oun ti i ṣe ti emi ni aṣepe…” (Saamu 138:8)

Njẹ o ri bayi? A le fọkan tan Ọlọrun lati pari nkan ti O bẹrẹ ninu wa. Bẹẹni, a le fi ọkan tan lati ṣe laṣepe ete rẹ rere si wa. A kan nilo lati fọwọsowọpọ pẹlu rẹ ni gbogbo ọna ni. Oun yoo fi sinu ọkan wa gbogbo erongba ti o wa ni ibamu pẹlu ete rẹ fun wa, yoo si tun pese ohun gbogbo ti a nilo lati mu awọn erongba naa wa si imuṣẹ. Ṣugbọn a nilo lati fẹran ara ti O fẹ fi aye wa da, ki a si tun ṣetan lati gbe igbese yowu ti O ba fẹ ki a gbe lati jẹ ki eyi wa si imuṣẹ (Isaiah 1:19).

Njẹ a wa nifẹ si nkan ti Ọlọrun fẹ ṣe pẹlu aye wa bi? Ṣe a si tun ṣetan lati jẹ ohun gbogbo ti O n ṣiṣẹ ninu wa lati jẹ? Ti o ba jẹ bẹ, a o mu ọrọ rẹ ni ọkunkundun. A o ma ka ọrọ rẹ, gbe yẹwo ati ṣe aṣaro ninu rẹ, ki a ba le ṣe gẹgẹ bi o ti wi (Jọshua 1:8). Siwaju si, a ko ni jẹ agberaga, alagidi tabi ẹniti ara rẹ kọ ibawi nigbakigba ti O ba n ba wa wi. Dipo eyi, a o tẹwọgba ibawi rẹ pẹlu ifẹ ati ọwọ, niwọn igba ti a mọ pe, gẹgẹ bi Baba wa ti o jẹ, nkan ti o dara julọ fun wa ni O ni lọkan ati pe ibawikibawi ti O ba fun wa ninu ifẹ ni o ti jẹyọ (Heberu 12:5-13).

Kini idi ti pupo-julọ ninu awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose mu jade lati Ijibiti ko ṣe de ilẹ ileri, pẹlu ohun gbogbo ti Ọlọrun ṣe fun wọn ati ni aarin wọn? Idi akọkọ ni pe wọn ko mu ọrọ Ọlọrun ni ọkunkundun. Idi keji ni pe wọn kọ lati gba ibawi rẹ. Ti awa naa ko ba wa fẹ ki iṣẹ rẹ ti O n ṣe ninu aye wa ja si pabo, a ko gbọdọ ri bi ti wọn. Dipo eyi, a gbọdọ tọ ara wa lati mu ọrọ rẹ ati ibawi rẹ ni ọkunkundun. Adura mi si pe ki ọkan rẹ gba okun lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ologo.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ọlọrun n ṣiṣẹ ninu rẹ | Paito J.O. Lawal Read More »

Tan iroyin naa ka | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Owara 10, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 23

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia di pipọsi fun lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọwara 2021. Njẹ ki iro ayọ ati iṣẹgun gba ẹnu rẹ kan ninu ọsẹ naa ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Mo fẹ ran ọ leti, bi a ṣe n bẹrẹ ọṣẹ tuntun yi, pe ajigbese ni ọ si Ọlọrun lati tan ihinrere ọrọ rẹ ti o n yi ọ pada, ti o si n gbe ọ soke nipasẹ ijọ yi. Ki ni idi ti Oluwa ṣe n fi gbogbo igba ni ọpọ eniyan ti o n tọ ọ wa lati gbọ ihinrere ati lati gba iwosan? Idi ni pe awọn ti ọrọ rẹ n yi aye wọn pada n tan iroyin nipa rẹ ati awọn nkan ti o n ṣe kalẹ.

Fun apẹrẹ, Maaku sọ eyi nipa iha ti awọn ti o ni anfaani lati gbọ ọrọ rẹ ati lati ri iṣẹ iyanu rẹ kọ si i: “Ẹnu si ya gbogbo wọn, to bẹẹ ti wọn fi n bi ara wọn leere, wi pe, Kin ni eyi? ẹkọ titun ni eyi? nitori ti o fi agbara paṣẹ fun awọn ẹmi aimọ, wọn si gbọ tirẹ. Lojukan naa okiki rẹ si kan yi gbogbo ẹkun Galili ka.” (Maaku 1:27-28) Iwọ na wo bayẹn. Awọn ti o ti ara iṣẹ iranṣẹ Jesu di alabakunfun ni wọn ṣiṣẹ fun iponlogo iṣẹ iranṣẹ naa. Nitorina, Oluwa ko nilo lati tẹ atẹjade, lẹ iwe pelebe kaakiri tabi ṣe ifilọ lori redio, tẹlifiṣan tabi ẹrọ ayelukara ki awọn eniyan to mọ ọn tabi mọ iṣẹ iranṣẹ rẹ.

Ni bakan naa, bi ko tilẹ si nkan ti o buru nipa rẹ, awa naa ko nilo lati tẹ atẹjade tabi le iwe pelebe kaakiri igboro nipa awọn ipade wa tabi nipa awọn nkan ti Ọlọrunn ṣe nipasẹ Ẹmi rẹ laarin wa lọsọọsẹ ki awọn eniyan to mọ nipa rẹ, ki wọn si darapọ mọ wa. Gbogbo wa ti a jẹ alajọpin ninu didara rẹ si wa ninu ijọ yi kan nilo lati gba a gẹgẹ bi iṣẹ lati tan iroyin naa kalẹ ni. Lo ba tan. Ẹmi Ọlọrun yoo si mojuto ohunkohun ti o ba ku.

Bibeli sọ wipe, “Oluwa ti sọrọ: ọpọlọpọ si ni ogun awọn ẹni ti n fi ayọ royin rẹ.” (Saamu 68:11) Ti a ba ka ẹṣẹ yi lati inu Iwe mimọ ti ede Heberu, a ri wipe obinrin gan ni awọn ogun eniyan ti a sọ wipe wọn fi ayọ royin ọrọ Oluwa yi. Nitorina, pe o jẹ obinrin ko tunmọ si pe o ko le tan ihin rere bi Ọlọrun ṣe n yi aye rẹ pada ninu ijọ yi pẹlu ọrọ rẹ ati nipasẹ Ẹmi rẹ kalẹ. O le tan an kalẹ. O si yẹ ki o ma tan an kalẹ.

Njẹ o tilẹ mọ pe awọn ọmọde gan ko gbẹyin ninu ọrọ yi? Fun apẹẹrẹ, igba kan wa ti awọn adari ẹṣin Juu n ṣaroye si Jesu lori pe awọn ọmọ kan n kọrin lati yin. Ki si ni esi ti o fun wọn? Esi ti O fun wọn ni pe, “Ṣe ẹyin ko ri ka ninu iwe mimọ ni pe, ‘Lati ẹnu wọn ọmọ-ọwọ ati awọn ọmọ-ọmu ni iwọ ti mu iyin pe?’” Nitorina, o yẹ ki a fun awọn ọmọ wa gan ni iwuri ati oriyin lati ma tan iroyin bi Ọlọrun ṣe n bukun fun wọn ninu ijọ yi kalẹ. (Matiu 21:14-16)

Amọ ṣa o, ti a ba jẹ alanikanjọpọn ati amọtaraẹninikan, ti a kan n ronu nipa ara wa nikan, ko si bi a ṣe fẹ ni iwuri lati tan iroyin bi Ọlọrun ṣe n bukun fun wa ninu ijọ yi kalẹ. Lafikun, ti a ba ya ojo, a le ma sọ nkankan fun awọn ti o wa ni ayika wa ti o nilo ifọwọkan ọrọ Ọlọrun ati ti Ẹmi rẹ. Nitorina, adura mi ni pe ki a kun ọkan wa pẹlu ifẹ Kirisiti ati pẹlu odiwọn itara ati igboya ti o peye lati tan ihinrere ore-ọfẹ rẹ ti a n jẹ gbadun kalẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọṣẹ alarinrin.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Tan iroyin naa ka | Paitọ J.O. Lawal Read More »

AKỌRI: ILANA FUN IRANWỌ GBIGBA NINU IJỌ AYỌKA: 1Timoti 5:3-16

IṢẸ IRANṢẸ ẸMI MIMỌ SI AWỌN TI AYE | Paito J.O. Lawal

ỌJỌRU 06, ỌWARA 2021 | AYỌKA: JOHANU 16:7-11

AKỌSORI: Nitori naa mo fẹ ki ẹ mọ pe, ko si ẹni ti n sọrọ nipasẹ Ẹmi Ọlọrun ki o wi pe, Ẹmi ifibu ni Jesu: ati pe, ko si ẹni ti o le wi pe, Oluwa ni Jesu n ṣe, bi ko ṣe nipasẹ Ẹmi mimọ.”

ỌRỌ AKỌSỌ
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ẹmi mimọ jẹ ọkan pẹlu Ọlọrun ati Jesu Kirisiti (1John 5:7). O ti wa pẹlu Ọlọrun lati atetekọse (Jẹnẹsisi 1:2). O jẹ Ẹmi ti o n ti ọdọ Ọlọrun funrarẹ jade (Johanu 16:26; Ifihan 5:6). Nipasẹ rẹ si ni Ọlọrun da ohun gbogbo (Joobu 33:4; Saamu 104:30). Oun gan ni O n jẹ ki wiwa, imọ ati agbara Ọlọrun jẹ mimọ fun awọn eniyan. Ṣugbọn, iwe mimọ jẹ ki o ye wa pe awọn alaigbagbọ ko mọ Ẹmi yi, bi o tilẹ jẹ pe a ri lara wọn ti wọn n ni ibaṣepọ pẹlu awọn ẹmi okunkun (Johanu 14:16-17). Nitorina, wọn ko le gba nkan ti Ẹmi Ọlọrun n sọ fun wọn (1Kọrinnti 2:14). Igba ti wọn ba si to gba nkan ti O n sọ fun wọn, ti wọn si ṣe amulo rẹ ni wọn to le ni iriri igbala, iwẹnumọ ati itunnibi sinu ijọba Ọlọrun (Titu 3:5). O wa yẹ ki awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun mọ ipa ti Ẹmi yi n ko tabi iṣẹ ti O n ṣe lati ri pe ifẹ Ọlọrun wa si imuṣẹ ninu awọn eniyan ki a ma ba di i lọwọ tabi ba iṣẹ rẹ jẹ. Eyi si ni ẹkọ yi da le lori.

IṢẸ IRANṢẸ ẸMI MIMỌ SI TI AYE
Ki wa ni koko iṣẹ iranṣẹ Ẹmi Ọlọrun si awọn ti aye yi? Gẹgẹ bi a ti ri ninu bibeli, iṣẹ iranṣẹ rẹ ni i ṣe pẹlu awọn nkan iwọnyi:

  • Fifi oye ye wọn: Jesu, nigba ti akoko rẹ lati fi ara rẹ silẹ fun igbala araye sunmọ tan, sọ eyi fun awọn ọmọ ẹyin rẹ: “Ṣugbọn otitọ ni emi n sọ fun yin; Anfaani ni yoo jẹ fun un yin bi emi ba lọ: nitori bi emi ko ba lọ Olutunu ki yoo tọ yin wa: Ṣugbọn bi mo ba lọ, emi o ran an si yin. Nigba ti oun ba si de, yoo fi oye ye araye ni ti ẹṣẹ, ati ni ti ododo, ati ni ti idajọ. Ni ti ẹṣẹ nitori ti wọn ko gba mi gbọ. Ni ti ododo, nitori ti emi n lọ sọdọ Baba, ẹyin ko si ri mi mọ; Ni ti idajọ, nitori ti a ti ṣe idajọ alade aye yii.” (Johanu 16:7-11) Pẹlu nkan ti Oluwa sọ nibi yi, a ri wipe Ẹmi mimọ nikan ni o le fe oye ẹṣẹ araye han wọn. Eyi tunmọ si wipe Oun nikan ni o le ba wọn wi, ki O si jẹ ki wọn ri ara wọn gẹgẹ bi ẹlẹsẹ ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. Opọ ni ko mọ pe olori ẹṣẹ eniyan ni aigba Jesu gbọ gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun ti a ran lati fun araye ni iye ainipẹkun. Wọn ro pe irọ pipa, eke ṣiṣẹ, iwa eeri, agbere ati bẹẹbẹẹ lọ nikan ni ẹṣẹ ati pe ẹni ti ko ba ti ṣe awọn nkan wọnyi ko ni iṣoro kankan pẹlu Ọlọrun. Ṣugbọn bi o tilẹ jẹ pe ẹṣẹ ni awọn nkan wọnyi nitootọ, ti Ọlọrun yoo ṣi ṣe idajọ awọn eniyan nitori wọn, idi ti ọpọ yoo fi ku ati jiya fun wọn ni pe wọn kọ lati gba ẹbun ọfẹ ọmọ Ọlọrun, Jesu gbọ, gẹgẹ bi ẹni ti Ọlọrun fa kalẹ lati ku fun awọn ẹṣẹ yi ati lati da awọn ti o ba gbaagbọ lare. Amọ, nipasẹ iṣẹ iranṣẹ Ẹmi mimọ, awọn eniyan le mọ awọn nkan wọny ni ọkan wọn.

Yatọ si eyi, iṣẹ Ẹmi mimọ ni lati jẹ ki oye ododo ti Ọlọrun tẹwọgba ye awọn eniyan. O si n ṣe eyi nipa pipe akiyesi wọn si igbasoke Jesu si ọwọ ọtun Ọlọrun. Ki ni o fa ti Ọlọrun fi gba Jesu ti o ku fun wa soke sọdọ rẹ? Idi ni wipe Oun nikan ni ododo rẹ peye niwaju rẹ. Ẹnikẹni ti o ba wa fẹ wa pẹlu Ọlọrun titi ayeraye bi Jesu naa gbọdọ gbagbọ ninu rẹ, ki O si fi ṣe ipilẹ ododo rẹ. Ọpọ lo n tẹle awọn ti ododo wọn ko peye niwaju Ọlọrun ati awọn ti wọn ko tilẹ mọ ibi ti wọn yoo pari igbesi aye wọn si. Awọn wọnyi yoo kabamọ nigbẹyin ni ayafi ti Ẹmi Ọlọrun ba fi ye wọn pe Jesu nikan ni O le ṣe wa yẹ lati duro niwaju Ọlọrun gẹgẹ bi olododo ki o to pẹ ju. (Wo: Johanu 14:1-6; Efesu 1:20-22; Heberu 1:3)

Siwaju si, iṣẹ Ẹmi mimọ ni lati jẹ ki oye idajọ Ọlọrun ye awọn eniyan. Ọpọ ni ko gbagbọ pe ọjọ idajọ Oluwa n bọ wa, ti ko si ni yẹ. Ṣugbọn ọjọ idajọ yi n bọ ni tootọ, ti Ọlọrun yoo ṣi ṣe idajọ gbogbo awọn oniṣẹ ẹṣẹ nipasẹ ọmọ rẹ Jesu (Iṣe Apọsiteli 10:42 & 17:30-31). O si ti fi apẹẹrẹ eyi han nipa ṣiṣe idajọ Eṣu ti o jẹ alade aye yi. Niwọn igba ti Ọlọrun ti ṣe idajọ Ẹsu ti o jẹ alade yi ati awọn angẹli rẹ, ti O si ti pese ina ainipẹkun fun wọn, o yẹ ki o ye wa pe bẹẹ gẹgẹ naa ni yoo ṣe ṣe idajọ gbogbo awọn ti o dẹsẹ, ti yoo si sọ awọn naa sinu ina ayeraye nigba ti akoko ba to. Ṣugbọn oye awọn nkan wọnyi ko le ye awọn eniyan, oye ewu ti o rọ dẹdẹ le wọn lori ko le ye wọn ti ko ba ṣe pe Ẹmi Ọlọrun ba fi ye wọn. Eyi lo fa ti awọn miran ṣe ma n fi ọrọ idajọ Ọlọrun ṣe ẹfẹ tabi ki wọn fi da apara. Ṣugbọn ojo idajọ Ọlọrun ṣu si ori wọn, o si di dandan ki o rọ ni akoko rẹ. (Wo: Matiu 25:31-46)

  • Mimu wọn wa si ironipiwada ati igbagbọ ninu Kirisiti: Ọtọ ni ki Ẹmi Ọlọrun fi oye ipo ti eniyan wa han; ọtọ tun si ni pe ki ẹni naa ṣiṣẹ tọọ nkan ti a fi han an. Ọpọ loni lo mọ pe igbe aye ti awọn n gbe ko nitunmọ, ti o si di dandan ki a pa aye wọn run nikẹyinkẹyin. Ṣugbọn ṣe wọn wa ti gbe igbesẹ atunṣe bi? Rara o! Ọpọ ni o si ti ipa aigbe igbesẹ lakoko ti o wọ lori igbala aye wọn ṣegbe. Nitori idi eyi, ko ki i ṣe gbogbo awọn ti o wa ni ayika wa ti ko gbagbọ ninu Jesu Kirisiti naa ni ko mọ pe o yẹ ki awọn fi igbagbọ wọn sinu rẹ. Awọn miran mọ, sugbọn ti o jẹ wipe ibẹru, ifẹ aye, ilọra ati bẹẹbẹẹ lọ ni ko i ti jẹ ki wọ gbe igbesẹ ti o tọ. Ti Ẹmi Ọlọrun ko ba wa pari iṣẹ rẹ lori awọn wọnyi, ki O si mu wọn wa si ironipiwada, wọn ko ni ronupiwada titi wọn yoo fi ṣegbe. Idi niyi ti Jesu fi sọ wi pe, “Ko si ẹnikẹni ti o le wa sọdọ mi, bi ko ṣe pe Baba ti o ran mi fa a…” (Johanu 6:44) Oun naa lo si fa ti Pọọlu fi sọ wipe, “Nitori naa mo fẹ ki ẹ mọ pe, ko si ẹni ti n sọrọ nipasẹ Ẹmi Ọlọrun ki o wi pe, Ẹni ifibu ni Jesu: ati pe, ko si ẹni ti o le wi pe, Oluwa ni Jesu n ṣe, bi ko ṣe nipasẹ Ẹmi Mimọ.” (1Kọrinnti 12:3) Nitori naa, gbogbo awa ti a gbagbọ ninu Jesu loni gbagbọ nitoripe Ẹmi Mimọ ṣiṣẹ lori aye wa lati sọ wa ji, ki a ba le gbagbọ ni, ko ki i ṣe nitoripe a gbọn tabi nimọ ju awọn ti ko gbagbọ lọ. Idi niyi ti a ko fi le ṣogo lọna kankan lori igbala tabi igbagbọ wa — ẹbun Ọlọrun nipasẹ Ẹmi Mimọ rẹ ni awọn nkan wọnyi jẹ fun wa. Ti oye yi ba si ye wa, a ko ni ro wipe akitiyan wa le sọ ẹnikẹni di onigbagbọ ninu Kirisiti. Dipo eyi, nṣe ni a o ma fi gbogbo igba fa ọkan awọn ti a ba n waasu si le Ọlọrun lọwọ, ki O ba le tipasẹ Ẹmi rẹ yi wọn pada sọdọ rẹ. (Wo: Efesu 2:1-9)
  • Sisọ wọn di atunbi: Yatọ si awọn nkan ti a ti mẹnu ba nipa iṣẹ Ẹmi Ọlọrun laarin awọn ti aye yi, iṣẹ rẹ tun ni lati sọ awọn eniyan di atunbi. Ranti wipe, Jesu, ninu iwaasu rẹ kan si Nikodemu, sọ wipe, “Bi ko ṣe pe a fi omi ati Ẹmi bi eniyan, oun ko le wọ ijọba Ọlọrun.” (Johanu 3:6) Nitori naa, iṣẹ Ẹmi Mimọ ni lati sọ eniyan di atunbi, lati sọ di eda tuntun, lati yọ ọkan okuta kuro ninu rẹ, ki O si fi ọkan ẹran dipo rẹ. Laisi jẹ pe O ba tun eniyan bi, ẹni naa ko le di ọmọ Ọlọrun tabi ero ijọba rẹ. Wo nkan ti Pọọlu sọ lori eyi: “Nitori awa pẹlu ti jẹ omugo nigbakan ri, alaigbọran, aṣako, ẹni ti n ṣin oniruuru ifẹkufẹẹ ati adun aye, a n gbe ninu arakan ati ilara, a jẹ ẹni irira, a si n koriira awọn ọmọnikeji wa. Ṣugbọn nigba ti iṣeun Ọlọrun Olugbala wa ati ifẹ rẹ si eniyan farahan, Kii ṣe nipa iṣẹ ti awa ṣe ninu ododo, ṣugbọn gẹgẹ bi aanu rẹ ni o gba wa la, nipa iwẹnu, atunbi ati isọdi tuntun Ẹmi Mimọ, Ti o da si wa lori lọpọlọpọ nipasẹ Jesu Kirisiti Olugbala wa.” (Titu 3:3-6) Njẹ o ri bayi pe Ẹmi Ọlọrun ni O ma n yi eniyan pada, ti O si ma n sọ aye wọn di ọtun. Laisi jẹ pe O ba ṣe eyi, gbogbo akitiyan ati ọrọ ẹnu wa lati yi ẹnikẹni pada di dandan ki o jasi pabo.
  • Sisọ wọn di ẹya ara Kirisiti: Wayi o, niwọn igba ti o jẹ wipe Ẹmi Ọlọrun ni o ma n tun eniyan bi, o wa jasi pe Oun nikan naa ni O le sọ wa di ọmọ ijọba Ọlọrun, ki O si tun sọ wa di ẹya ara Kirisiti, Ẹni ami ororo Ọlọrun. Pọọlu sọ eyi fun wa lori ọrọ yi: “Nitori gẹgẹ bi ara ti jẹ ọkan, ti o si ni ẹya pupọ, ṣugbọn ti gbogbo ẹya ara ti i ṣe pupọ jẹ ara kan; bẹẹ si ni Kirisiti pẹlu. Nitori pe ninu Ẹmi kan ni a ti batisi gbogbo gba sinu ara kan, ibaa ṣe Juu, tabi Heleni, ibaa ṣe ẹru, tabi ominira; a si ti fun gbogbo wa ni Ẹmi kan.” (1Kọrinnti 12:12-13) Njẹ o ri bayi? Ẹmi Ọlọrun ni O ma n sọ awọn eniyan di alabapin ninu Kirisiti ati alabapin ninu ogun awọn eniyan mimọ Ọlọrun. Nitori naa, didarapọ mọ awọn ọmọ Ọlọrun kan tabi omiran kọ ni o n sọ eniyan di alabapin ninu Kirisiti; Ẹmi Mimọ ni O ma n sọ eniyan di ọkan pẹlu rẹ. Ẹni ti Ẹmi Ọlọrun ko ba si ti i ṣọ di ara Kirisiti, ko si irufẹ nkan ti a le ṣe fun wọn tabi ipo ti a le fun wọn ninu ijọ Ọlọrun ti o le sọ wọn da.

ỌRỌ IPARI
Ki wa ni koko gbogbo awọn nkan ti a ṣe agbeyẹwo wọn yi nipasẹ iṣẹ Ẹmi Ọlọrun laarin awọn ti aye yi? Koko rẹ naa ni pe o yẹ ki awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun mọ daju ṣaka pe a ko le da ohunkohun ṣe lati jẹ ki awọn ti aye yi ri igbala ninu Jesu Kirisiti. Ohun ti Ẹmi Ọlọrun ba ṣe funrarẹ tabi ti o ba tipasẹ wa ṣe nikan naa ni o le yọri si igbala wọn. Njẹ eyi wa tunmọ si pe ki a fọwọ lẹran, ki a si ma woye igba ti Ẹmi rẹ yoo gbera lati ṣiṣẹ ninu aye awọn alaigbagbọ bi? Rara o! Dipo bẹẹ, nkan ti eyi n sọ fun wa ni pe ki a fi sọkan pe a gbọdọ gbe gbogbo ọkan ati ara wa ati akitiyan yowu ti a ba n ṣe lori igbala awọn eniyan le Ọlọrun lọwọ, pẹlu oye pe awọn ti O ba gbala nikan naa ni yoo di ẹni igbala.

IBEERE

  • Awọn ọna wo ni ẹkọ yi gba ran oye ti o ni lori iṣẹ iranṣẹ Ẹmi Mimọ lọwọ?
  • Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

IṢẸ IRANṢẸ ẸMI MIMỌ SI AWỌN TI AYE | Paito J.O. Lawal Read More »

Má sọ ààyè rẹ nù

Oluwa wa pẹlu rẹ | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Owara 03, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 22

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Nkan ayọ ti o ga ni o jẹ fun mi lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Owara 2021. Adura mi si ni pe ki ọkan rẹ gba okun lati ma fi gbogbo igba rin pẹlu afiyesi diduro ṣinṣin Ọlọrun pẹlu rẹ, ki o ma ba ba sọ ireti nu tabi ba ọkan jẹ, bi o ti wu ki asiko ri fun ọ. Amin.

Iwọ na mọ pe awọn igba ma n wa ti awọn idojukọ aye wa le sun wa debi ti a o ti ro pe Ọlọrun ti pa wa ti ati pe awa nikan la n da dojukọ awọn nkan ti o n lepa lati pa wa run. Ṣugbọn eyi ko jẹ tuntun. A ri awọn eniyan mimọ igbaani ti awọn naa ro bẹẹ gẹgẹ ni awọn akoko kan ni igba aye wọn. Fun apẹẹrẹ, nigba ti Angẹli Oluwa kọkọ farahan Gidioni, ti O si sọ fun pe, “Oluwa wa pẹlu rẹ, iwọ ọkunrin alagbara,” idahun rẹ ni wipe, “Ti Oluwa ba pẹlu wa, ki lo wa fa ti a fi wa ni ipo radarada yi, ki si ni o fa ti ko fi ṣe iṣẹ ami tabi iṣẹ iyanu oniruuru fun ominira wa, bi O ti ṣe ṣe fun awọn baba nla wa? O daju ṣaka pe O ti kọ wa silẹ” (Wo: Onidajọ 6:11-13)

Iwọ naa gbe yẹwo. Ọlọrun tikararẹ n ba ọmọkunrin yi sọrọ lojukoroju wipe Oun wa pẹlu rẹ. Sibẹsibẹ o ni i lara lati gba a gbọ. Ki ni idi? Idi ni pe o n wo bi igba ṣe ri fun aye rẹ ati fun orilẹ-ede rẹ. Ko ye rara idi ti Ọlọrun fi le wa pẹlu wọn, ki O si tun fi aye gba ki gbogbo nkan lọjupọ fun wọn bi o ti ṣe ri ni akoko naa. Ṣugbọn Ọlọrun ko ni O wa nidi bi nkan ṣe lojupọ fun aye wọn. Awọn ni o fa a. Awọn ni o kọ Ọlọrun silẹ, ti wọn si bẹrẹ si ni rin ninu ọgbọn ara wọn. Nitorina, O fi wọn silẹ lati ri atunbọtan kikọọ silẹ lati rin ni ọna ti ara wọn.

Ṣugbọn nigba ti wọn kigbe pe nitori inira wọn, O da wọn lohun nipa bibẹ Gidioni wo ati nipa jijẹ ki o mọ pe Oun ko fi igba kankan fi wọn silẹ. Ṣugbọn ẹṣẹ wọn ni o n di ifarahan wiwa rẹ pẹlu wọn lọwọ. Pẹlu awọn ẹri ma jẹmi niso melokan, O misi ọmọkunrin yi, O si tun fun ni iwuri lati dari awọn eniyan rẹ lati ni iriri ominira kuro lọwọ awọn ti o n niwọn lara. (Wo: Onidajọ 6-8)

Nibakan naa, ti awa naa ba kan tẹjumọ idojukọ aye wa nikan, o ṣeeṣe ki a sọ wipe Ọlọrun ko si pẹlu wa tabi pe ko tilẹ naani ibi ti ọrọ wa ba ja si. Ṣugbọn Ọlọrun ko ki i fi igba kankan fi awọn ọmọ rẹ silẹ tabi kọ wọn silẹ. Idi si ni pe O ti ṣeleri pe Oun ko ni fi igba kankan fi wa silẹ tabi kọ wa silẹ. Niwọn igba ti ko ki si kuna lati pa ọrọ rẹ mọ, a le fi ọkan balẹ pe O wa pẹlu wa, bi o ti wu ki igba ri fun aye wa. (Wo: Heberu 13:5-6)

Amọ ṣa o, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun wa pẹlu wa, a le ma ni iriri ifarahan agbara rẹ lati yi asiko pada fun wa tabi lati gba wa kuro lọwọ awọn asiko kan. Nkan meji pataki ni o si le fa eyi. Akọkọ ni ẹṣẹ. Ti awa naa, bi awọn ọmọ Isiraẹli aye igba Gidioni, ba fi aye gba ẹṣẹ lati kọ ẹyin wa si Ọlọrun, a le ba ara wa labẹ ipọniloju Eṣu, bi o tilẹ jẹ wipe iwaju Ọlọrun gan an la wa, ti Oun ko si ni ṣe nkankan lori rẹ. Ṣugbọn ti a ba tun wa rẹ ara wa silẹ, bi awọn naa ṣe rẹ ara wọn silẹ nigba to ya, ti a si ronupiwada kuro ninu ẹṣẹ wa, Oun yoo dari ji wa, yoo ṣaanu fun wa, yoo si tun jẹ ki a ni iriri idande rẹ. Eyi, bi mo ṣe gbagbọ, ni gbogbo wa nilo lati ṣe ni kankan ni orilẹ-ede yi, ti a ba fẹ ni iriri ominira tootọ kuro lọwọ awọn nkan ati awọn eniyan ti wọn n pọn wa loju lọwọlọwọ yi.

Nkan keji ti o le diwa lọwọ la ti ni iriri agbara Ọlọrun lori awọn idojukọ wa ni ki a tẹjumọ awọn idojukọ naa dipo ki a tẹjumọ Ọlọrun. Ti o ba jẹ awọn iṣoro aye wa ni a tẹjumọ, o ṣeeṣe ki wọn papa pa wa run, bi a ko tilẹ gbe ninu ẹṣẹ. Ṣugbọn ti o ba jẹ pe Ọlọrun ni a tẹjumọ, Ọlọrun ti O wa pẹlu wa, ti O wa fun wa, ti O wa ninu wa, ti O si tun ni agbara lori asiko aye wa gbogbo, o di dandan ki a ni iriri agbara ati iṣẹgun rẹ lori awọn nkan ti o n lepa lati han wa ni eemọ tabi pa wa run.

Pọọlu so wipe a n ri nipa igbagbọ dipo nkan ti a fojuri (2Kọrinnti 5:7). Ṣugbọn ko ki i ṣe gbogbo wa naa ni a le sọ eyi, nitori pe ko ki i ṣe gbogbo wa naa ni o n ri nipa igbagbọ dipo nkan ti a fojuri. Rinrin nipa igbagbọ ni i ṣe pẹlu pe ki a ma gbe aye wa lori gbedeke nkan ti Ọlọrun sọ fun wa dipo lori gbedeke nkan ti a fojuri, feti gbọ tabi mọ lara. Niwọn igba ti o ba si jẹ pe a n gbe aye wa lori gbedeke nkan ti O sọ fun wa nipa ara rẹ, ara wa ati aye yi lapapọ, a ko ni fi igba kankan ba idojuti pade, bi gbogbo ọrun apadi tilẹ dide gbogun ti wa. Adura mi si wa ni pe ki ọkan rẹ gba okun lati ma fi gbogbo igba gboju kuro lara idojukọ rẹ lati tẹjumọ Ọlọrun, Baba rẹ, ti o lagbara lori ohun gbogbo, ki o ma ba tun fi igba kankan padanu ifarahan agbara rẹ ninu aye rẹ mọ.

Alaafia ni fun ọ.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Oluwa wa pẹlu rẹ | Paitọ J.O. Lawal Read More »