Ọjọ: Owara 10, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 23
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia di pipọsi fun lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọwara 2021. Njẹ ki iro ayọ ati iṣẹgun gba ẹnu rẹ kan ninu ọsẹ naa ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.
Mo fẹ ran ọ leti, bi a ṣe n bẹrẹ ọṣẹ tuntun yi, pe ajigbese ni ọ si Ọlọrun lati tan ihinrere ọrọ rẹ ti o n yi ọ pada, ti o si n gbe ọ soke nipasẹ ijọ yi. Ki ni idi ti Oluwa ṣe n fi gbogbo igba ni ọpọ eniyan ti o n tọ ọ wa lati gbọ ihinrere ati lati gba iwosan? Idi ni pe awọn ti ọrọ rẹ n yi aye wọn pada n tan iroyin nipa rẹ ati awọn nkan ti o n ṣe kalẹ.
Fun apẹrẹ, Maaku sọ eyi nipa iha ti awọn ti o ni anfaani lati gbọ ọrọ rẹ ati lati ri iṣẹ iyanu rẹ kọ si i: “Ẹnu si ya gbogbo wọn, to bẹẹ ti wọn fi n bi ara wọn leere, wi pe, Kin ni eyi? ẹkọ titun ni eyi? nitori ti o fi agbara paṣẹ fun awọn ẹmi aimọ, wọn si gbọ tirẹ. Lojukan naa okiki rẹ si kan yi gbogbo ẹkun Galili ka.” (Maaku 1:27-28) Iwọ na wo bayẹn. Awọn ti o ti ara iṣẹ iranṣẹ Jesu di alabakunfun ni wọn ṣiṣẹ fun iponlogo iṣẹ iranṣẹ naa. Nitorina, Oluwa ko nilo lati tẹ atẹjade, lẹ iwe pelebe kaakiri tabi ṣe ifilọ lori redio, tẹlifiṣan tabi ẹrọ ayelukara ki awọn eniyan to mọ ọn tabi mọ iṣẹ iranṣẹ rẹ.
Ni bakan naa, bi ko tilẹ si nkan ti o buru nipa rẹ, awa naa ko nilo lati tẹ atẹjade tabi le iwe pelebe kaakiri igboro nipa awọn ipade wa tabi nipa awọn nkan ti Ọlọrunn ṣe nipasẹ Ẹmi rẹ laarin wa lọsọọsẹ ki awọn eniyan to mọ nipa rẹ, ki wọn si darapọ mọ wa. Gbogbo wa ti a jẹ alajọpin ninu didara rẹ si wa ninu ijọ yi kan nilo lati gba a gẹgẹ bi iṣẹ lati tan iroyin naa kalẹ ni. Lo ba tan. Ẹmi Ọlọrun yoo si mojuto ohunkohun ti o ba ku.
Bibeli sọ wipe, “Oluwa ti sọrọ: ọpọlọpọ si ni ogun awọn ẹni ti n fi ayọ royin rẹ.” (Saamu 68:11) Ti a ba ka ẹṣẹ yi lati inu Iwe mimọ ti ede Heberu, a ri wipe obinrin gan ni awọn ogun eniyan ti a sọ wipe wọn fi ayọ royin ọrọ Oluwa yi. Nitorina, pe o jẹ obinrin ko tunmọ si pe o ko le tan ihin rere bi Ọlọrun ṣe n yi aye rẹ pada ninu ijọ yi pẹlu ọrọ rẹ ati nipasẹ Ẹmi rẹ kalẹ. O le tan an kalẹ. O si yẹ ki o ma tan an kalẹ.
Njẹ o tilẹ mọ pe awọn ọmọde gan ko gbẹyin ninu ọrọ yi? Fun apẹẹrẹ, igba kan wa ti awọn adari ẹṣin Juu n ṣaroye si Jesu lori pe awọn ọmọ kan n kọrin lati yin. Ki si ni esi ti o fun wọn? Esi ti O fun wọn ni pe, “Ṣe ẹyin ko ri ka ninu iwe mimọ ni pe, ‘Lati ẹnu wọn ọmọ-ọwọ ati awọn ọmọ-ọmu ni iwọ ti mu iyin pe?’” Nitorina, o yẹ ki a fun awọn ọmọ wa gan ni iwuri ati oriyin lati ma tan iroyin bi Ọlọrun ṣe n bukun fun wọn ninu ijọ yi kalẹ. (Matiu 21:14-16)
Amọ ṣa o, ti a ba jẹ alanikanjọpọn ati amọtaraẹninikan, ti a kan n ronu nipa ara wa nikan, ko si bi a ṣe fẹ ni iwuri lati tan iroyin bi Ọlọrun ṣe n bukun fun wa ninu ijọ yi kalẹ. Lafikun, ti a ba ya ojo, a le ma sọ nkankan fun awọn ti o wa ni ayika wa ti o nilo ifọwọkan ọrọ Ọlọrun ati ti Ẹmi rẹ. Nitorina, adura mi ni pe ki a kun ọkan wa pẹlu ifẹ Kirisiti ati pẹlu odiwọn itara ati igboya ti o peye lati tan ihinrere ore-ọfẹ rẹ ti a n jẹ gbadun kalẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọṣẹ alarinrin.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
