January 2022

Ko ki i ṣe ẹbun ẹmi rẹ nikan | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Sẹrẹ 30, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 39

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun 2022. Adura mi si ni pe, bi o ti ṣe n la ọsẹ yi kọja lọ, ki a ṣi oju rẹ lati ri awọn nkan ti o nilo lati fi ara rẹ jin si lọdun yi, ki o ba le pọ si ni iwulo ni ọwọ Ọlọrun, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ọna kan gbogi lati pọ si ni iwulo ni ọwọ Ọlọrun, yatọ si pe ki a ma gbadura si i, ni ki a mọ awọn ẹbun rẹ ti o wa ninu aye wa, ki a si ṣe amulo ti o peye wọn. Bi bibeli ti ṣe fi han wa, kiki awọn ti o ba n ṣe amulo ti o nitunmọ awọn nkan ti Ọlọrun fun wọn, yala nipa ti ẹmi ni tabi nipa ti ara, ni yoo fun ni nkan si, ki wọn ba le pọ si ni iwulo pẹlu wọn. Awọn ti ko ba ṣe nkan to jọju tabi ti ko ṣe nkankan pẹlu nkan ti O fun wọn ko ni ri afikun ifihan, amuyẹ, iṣura tabi anfaani gba si lọwọ rẹ. Ti wọn ko ba tilẹ ṣọ ara wọn, o ṣeeṣe ki o gba awọn nkan ti O ti fun wọn kuro lọwọ wọn. (Wo: Maaku 4:24-25; Luke 19:11-26)

Nitorina, ti a ba fẹ pọ si ni iwulo ninu ijọba Ọlọrun ninu ọdun yi, a gbọdọ fi ara balẹ wo aye wa lati ri awọn nkan ti O ti fun wa ti a le lo lati sin in tabi lati ṣe iṣẹ rẹ. Eleyi si kọja lilo ẹbun ẹmi wa lati sin in. O tun ni i ṣe pẹlu ki a lo awọn amuyẹ wa, ẹkọ wa, nkan ini wa ati ipo wa lati sin in.

Fun apẹẹrẹ, Luuku, ẹni ti o kọ ọkan lara awọn iwe ihinrere bibeli ati iwe ‘Iṣe Awọn Apọsiteli’, ni a ko mọ gẹgẹ bi apọsiteli, wolii, ajinhinrere tabi pasitọ. Dipo eyi, a mọ ọn gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ oniṣegun ilera. Ṣugbọn o ṣe amulo ẹkọ rẹ ati ifẹ ti o ni si itan sisọ lati sin Oluwa nipa kikọ akọsilẹ igbe aye Jesu Kirisiti Oluwa wa ati iṣẹ iranṣẹ rẹ ni ẹsẹẹsẹ. O si tun ṣe amulo awọn nkan wọnyi ni fifun wa ni akọsilẹ ranpẹ itan ijọ ati itankalẹ ihinrere Jesu Kirisiti kaakiri gbogbo agbaye. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe ko ki i ṣe oniwaasu, o fi ara rẹ si ipo iwulo fun Ọlọrun lati pa otitọ ihinrere Jesu Kirisiti mọ fun wa. (Wo: Luuku 1:1-4; Iṣe Apọsiteli 1:1-2; Kolose 4:14)

Yatọ si eyi, Dọkasi ko ki i ṣe oniwaasu tabi adari ijọ. Ṣugbọn o n fi gbogbo igba lo awọn nkan ini rẹ lati ran awọn alaini lọwọ, paapaa julọ awọn ti o wa ninu ijọ. Eyi si jẹ ki o di gbajumọ laarin awọn ara ijọ rẹ. Nitorina, nigba ti o ku, wọn kọ jalẹ lati faramọ iku rẹ. Ni kiakia ni wọn ranṣẹ si Peteru, ẹni ti o wa lati gbadura fun un ki o ba le pada si aye. Ọlọrun si dahun adura rẹ. Ki ni idi? Idi ni pe O mọ pe ti oun ba fun arabinrin yi ni ọdun diẹ si lati gbe ile aye, ko ni fi ṣofo lori igbe aye alailere. Dipo bẹẹ, nṣe ni yoo lo awọn ọdun naa lati pọ si ni iwulo ati isesorere. (Wo: Iṣe Apọsiteli 9:36-42)

Nitorina, o ko nilo lati jẹ oniwaasu tabi ẹni ti o ni ẹbu iwosan ki o to wulo ninu ijọba Ọlọrun tabi ki o to le pọ si ni iwulo ninu ijọba rẹ. O kan nilo lati ma fi gbogbo igba ṣe amulo ti o peye ẹbun ẹmi yowu ti o ni ni. Yoo si ya ọ lẹnu awọn nkan ti Ọlọrun yoo tipasẹ rẹ ṣe. Siwaju si, bi o tilẹ wa woye pe o ko mọ ẹbun ẹmi pato ti o ni lọwọlọwọ yi, bẹrẹ si ni ro awọn ọna ti o le gba lo ẹkọ rẹ, awọn amuyẹ rẹ tabi nkan ini rẹ lati mu ki iṣẹ rẹ tẹsiwaju.

Fun apẹẹrẹ, ti o ba jẹ gbẹnagbẹna, wo nkan ti o le ṣe fun iwulo ijọ Ọlọrun tabi ki o wo awọn ọna ti o le gba lo awọn amuyẹ rẹ lati yọ ijọ kuro ninu awọn inawo ainitunmọ kan. Boya ounkọwe si ni iwọ tabi oniṣẹọna. Ronu si awọn ọna ti o le gba ma lo awọn amuyẹ yi lati ran ijọ lọwọ ati lati jẹ ki ihinrere gbooro si, dipo eyi ti o fi ma fi gbogbo igba ṣe awawi fun aiwulo rẹ fun Ọlọrun ni ọna kankan. O wa ṣeni laanu lọpọlọpọ pe ọpọ eniyan ninu awọn ijọ wa loni ni ko ki i fẹ lo awọn amuyẹ wọn lati sin Ọlọrun, ti ko ba ti ni yọ ere ti o pọ fun wọn. Otitọ tilẹ ni pe awọn kan ko kọ lati lu ijọ ni jibiti lori ọrọ yi. Idi si ni pe ifun wọn ni ọlọrun wọn. (Wo: Ẹkisodu 35:4-36:3; Filipi 3:18-19)

Wayi o, mo mọ pe nkan ti ko dara ni ki ijọ naa ma rẹ awọn ti o ba n baa ṣiṣẹ jẹ tabi ki o ma san owo ọya wọn pe, paapaa julọ nitoripe wọn jẹ ọmọ ijọ tabi onigbagbọ. Ti onigbagbọ kan ba fẹ din ijọ lowo lori ọja ti o ta tabi iṣẹ ti o ṣe fun ijọ, ko buru rara. Ṣugbọn o gbọdọ ti ọkan rẹ wa lati ṣe eyi ni, ko ki i ṣe pe ki a wa tan an jẹ, dẹruba tabi mu ni dandan lati ṣe e (2Kọrinnti 9:7). Sibẹsibẹ gbogbo wa ni a gbọdọ kọ lati ma lo ohunkohun ti a ni ti o wulo fun iṣẹ Ọlọrun lati ṣe iṣẹ rẹ ati lati pọsi ni iwulo ninu ijọba rẹ. Aijẹbẹ, afaimọ ki O ma pe wa ni iranṣẹ ọlẹ ati alailere ni ọjọ kan. Mo si gbadura pe ki nkan ma ṣe yọri si eyi fun iwọ ati emi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ko ki i ṣe ẹbun ẹmi rẹ nikan | Paitọ J.O. Lawal Read More »

Ki o ma ba ya ara rẹ lẹnu |Pst. J.O. Lawal |Sẹrẹ 23, 2022 |Vol. 10, No. 38

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. O dun mọ mi ninu lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Ṣẹrẹ 2022. Adura mi fun ọ si ni pe ki a kọ ọkan rẹ, ki a si tun fun ni okun lati ṣe amulo wiwa Ọlọrun ninu aye rẹ ni ọna ti o peye ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọjọ aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọkan lara awọn ọrọ bibeli ti o peni nija julọ ni eyi ti a ri ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Roomu ti o sọ wipe, “Bi Ọlọrun ba wa fun wa, ta ni yoo le kọju ija si wa?” (Roomu 8:31) Njẹ Ọlọrun wa fun wa bi? Njẹ iha wa ni o wa bi? Ti O ba wa fun wa, lotitọ O si wa fun wa, ta wa ni o le doju ija kọ wa? Ko si! Nkan ti mo n sọ ni pe ko si ẹni naa ti o lagbara to lati pọn wa loju tabi ṣe wa ni ibi lori nkan yowu ti ko ba jẹ, niwọn igba ti Ọlọrun wa fun wa. A kan nilo lati jẹ ki ọrọ yi gba ọkan wa kan ni, ki a si tun ma rin ni ibamu pẹlu rẹ.

Fun apẹẹrẹ, nitori pe Ọlọrun wa pẹlu Aburahamu, Isaki ati Jakọbu ko si ẹnikẹni ti o ṣe aṣeyọri lati rẹ wọn jẹ tabi pọn wọn loju. Bibeli sọ wipe, “Oun ko jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni ibi: Nitootọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn. Pe, Ẹ ma ṣe fi ọwọ kan ẹni ororo mi; ẹ ma si ṣe awọn wolii mi ni ibi.” (Saamu 105:14-15) Iwọ naa ro wo. Ọlọrun ko gba ki ẹnikẹni pọn awọn wọnyi loju nitori pe eniyan rẹ ni wọn jẹ. O si tun ṣetan lati fi iya jẹ wọn tabi pa wọn run, iyẹn ẹnikẹni ti o ba gbiyanju lati ṣe bẹẹ.

Ko wa jẹ iyalẹnu pe nigba ti Mose n dari awọn ọmọ Isiraẹli wọ inu Ilẹ-ileri lọ, ko bere ọrọ, ounjẹ, omi tabi aabo lọwọ Ọlọrun fun awọn eniyan naa. Dipo eyi, o bere fun wiwa rẹ pẹlu wọn. Kedere ni o tilẹ sọ fun pe ti ko ba ni wa pẹlu awọn titi wọn yoo fi wọ Ilẹ-ileri naa, ki o ma wulẹ jẹ ki awọn goke lọ. Ki ni idi? Idi ni pe o mọ pe wiwa Ọlọrun pẹlu wọn ni kiki ohun ti wọn nilo. Eyi tunmọ si pe o mọ pe niwọn igba ti Ọlọrun ba wa pẹlu wọn, gbogbo ounjẹ, omi, ọrọ, ilera ati aabo ti wọn nilo ati ju bẹẹ lọ pẹlu ni wọn yoo ni. (Wo: Ẹkisodu 33:12-17)

Wayi o, awa ko nilo lati bere fun wiwa Ọlọru pẹlu wa. Idi si nipe a ti ni wiwa rẹ pẹlu wa nipasẹ igbagbọ wa ninu Jesu Kirisiti Oluwa wa. Oun ti wa pẹlu wa, ninu wa ati fun wa. Bibeli tilẹ sọ pe, “…Ọlọrun tikararẹ ti wi pe, Emi ko jẹ fi ọ silẹ, bẹẹ ni emi ko jẹ kọ ọ silẹ. Nitori naa ni awa ṣe n fi igboya wi pe, Oluwa ni oluranlọwọ mi, emi ki yoo bẹru; kin ni eniyan le ṣe si mi?” Njẹ o ri bayi? Ọlọrun funrarẹ ti sọ pe Oun ko jẹ fi igba kankan fi wa silẹ tabi kọ wa silẹ. Eyi tunmọ si pe gbogbo igba ni oju rẹ yoo ma wa pẹlu wa.

Iha wo wa ni o yẹ ki a kọ si ọrọ yi? Ni kukuru, bi a ti tun ṣe fi han wa ninu ẹsẹ bibeli yẹn, nṣe ni o yẹ ki a fi igboya ma sọ pe, “Emi ki yoo bẹru. Ki ni nkan ti ẹnikẹni le fi mi ṣe?” Iṣẹ ta ni lati ma fi igboya sọ pe emi ki yoo bẹru? Iṣẹ mi ni. Iṣẹ rẹ ni. Isẹ ta si tun ni lati ma fi igboya sọ pe ko si nkankan ti ẹnikẹni le fi mi ṣe? Iṣẹ mi ni lati sọ bẹẹ. Iṣẹ rẹ ni lati sọ bẹẹ.

Amọ ko ki i ṣe pe ki a wa ma sọ awọn nkan yi nitoripe a fẹ ki awọn eniyan woye pe a laya. Dipo eyi, nṣe ni ki a ma sọ wọn nitoripe a mọ pe Ọlọrun wa pẹlu wa ni gbogbo ọna lati ri daju pe a tọju wa ni ọna ti o peye ati pe a da aabo bo wa kuro lọwọ ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ipọniloju Satani tabi ti eniyan. Ti iwọ ba wa mọ eyi, nṣe ni o yẹ ki o bi gbogbo ẹru rẹ danu. Bẹẹni, bi gbogbo ẹru rẹ danu, ẹru awọn iṣẹlẹ tabi eniyan ti o n dun mọhuru-mọhuru mọ ọ, ti o n yan ọ jẹ tabi ti o n pọn ọ loju. Idi si ni pe Ọlọrun yoo ba wọn wi fun ọ ati pe yoo tun gba ohun ti o jẹ tirẹ fun ọ.

Ranti pe O ba awọn ọba wi, pẹlupẹlu awọn ọba ti awọn ẹmi aimọ ti oṣo ati ti ajẹ n dari, fun awọn eniyan mimọ rẹ igbaani. Nitorina, ko ja mọ nkankan fun lati ba wọn wi fun iwọ naa, ohunkohun tabi ẹnikẹni ti o n ṣe ilodi si ibalẹ-ọkan, ilera tabi ilọsiwaju rẹ, bi o ti wu ki iru ẹni bẹẹ ma fi ẹmi okunkun paṣẹ to. Iwọ ṣa ri daju pe oun fi gbogbo igba ran ara rẹ leti pe O wa pẹlu rẹ. O o si ma fi gbogbo igba ri ifarahan agbara rẹ ti o ga lori ọrọ rẹ.

Ki o ni ọsẹ aladun.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ki o ma ba ya ara rẹ lẹnu |Pst. J.O. Lawal |Sẹrẹ 23, 2022 |Vol. 10, No. 38 Read More »

Ki o ma ba ya ara rẹ lẹnu. | Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Sẹrẹ 16, 2022 | Atẹlera: Latori tabili | Nọmba: Vol. 10, No. 37

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ṣere 2022. Adura mi si pe ki a fi gbogbo igba ṣe ọ yẹ ati fun ọ ni okun lati rin ni iṣẹgun lori gbogbo awọn nkan ti o n gbogun ti ọkan rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti o n fi gbogbo igba gbogun ti ọkan wa gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun ni agbere. O si wa wọpọ loni tobẹ gẹẹ ti o fi jẹ pe ko fẹrẹ si ibi ti o le lọ tabi dojukọ ti o ko ti ni ri nkankan ti yoo pa pe ọ lati kopa ninu rẹ. Ti o ba wa kọ lati ṣe nkan ti ọrọ Ọlọrun sọ lori rẹ, afaimọ ki o ma ya ara rẹ lẹnu nipa ṣiṣe nkan ti o ko fi igbakankan ri lero pe o le ṣe. Eyi ti n ṣẹlẹ si ọpọ ninu awọn ọmọ Ọlọrun lọwọlọwọ yi. Si iyalẹnu wọn, wọn ti turasilẹ fun ẹṣẹ agbere, ni eyi ti wọn ti fi igbakan gbe oju agan si, ti wọn si sọ pe ko sunwọn. Ti wọn ko ba si pada lati lọ bẹrẹ si ni ṣe nkan ti ọrọ Ọlọrun sọ lori agbere, wọn ko ni bọ lọwọ rẹ.

Ki o ba le mọ bi nkan ti mo n sọ ti ṣe buru si, laipe yi, mo ri stetọsi (bi o ti ṣe ri lọkan mi lọwọlọwọ) ti ẹnikan ti o pe ara rẹ ni Kirisitiẹni fi si ori ẹrọ ayelujara, eyi ti o ti n sọ pe oun ṣa fẹ ba ẹnikan sun, eni yowu ti o le jẹ. Lẹyin eyi ni o tun wa fi stetọsi miran sori ẹrọ yi, eyi ti o n fi awọn onigbagbọ kan ti wọn nkọrin nipa iye ayeraye ti a ni ninu Kirisiti Jesu han. Mo wa bere lọwọ ara mi pe, “Njẹ ọmọkunrin yi gbadun bi? Lati ori agbere sori ijọsin Kiristiẹni – bawọ ni wọn ṣe jọ ara wọn?”

Afi bi igba ti mi o ti ri nkankan, niwọn akoko yi naa ni mo tun ri stetọsi ti ẹlomiran ti oun naa pere rẹ ni onigbagbọ tun fi sori ẹrọ ayelukara yi. Nkan ti oun si n sọ ni pe ti ẹnikẹni ba ṣeesi ri oun ninu awọn sinnima iṣekuṣe, eyi ti wọn pe ni sinnima awọn to ti balaga, ki wọn mọ pe iṣẹ owo lo gbe oun de ibẹ – ki wọn ma fi ṣe ibinu rara. Lotitọ, lẹsẹkẹsẹ naa ni mo fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si lati bere boya o gbadun. Ṣugbọn awọn nkan wọnyi n tọka si nkankan ni o, eyi si nipe aye ti a wa ninu rẹ yi jẹ eyi ti iṣekuṣe ti gbilẹ, ti o ti di tọrọfọnkale. Nitorina, ti awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ko ba ṣọ ara wa, a o kan dede ri lọjọ kan pe a ya ara wa lẹnu pẹlu ikopa wa ninu iwa ati nkan eeri ni.

Awọn nkan ti a si wa n sọ yi kọja pe ki a kan ma gbadura si Ọlọrun pe ki O pa wọn mọ kuro ninu ẹṣẹ agbere. O tun ni i ṣe pẹlu pe ki a ma ṣe amulo awọn nkan ti O sọ fun wa nipa ẹṣẹ yi. Ki si ni O sọ fun wa nipa rẹ? O sọ wipe, “Ẹ maa sa fun agbere…” (1Kọrinnti 6:18) Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun ni agbara lati daabo bo wa kuro lọwọ gbogbo iṣoro, O wa n sọ fun wa pe ọna ti Oun la kalẹ fun ipamọ wa kuro ninu ẹṣẹ agbere ni ki a sa a fun. Bẹẹni, yoo fun wa ni okun, yoo si tun ri pe ọna lati sa fun ẹṣẹ yi wa fun wa. Amọ ojuṣe wa ni lati sa a fun. Aijẹbẹ, afaimọ ki a ma jọ ara wa loju nigba ti a ba ba ara wa ninu rẹ.

Wo Josefu igba aye bibeli. Bawo ni ko ṣe ko sinu panpẹ ẹṣẹ agbere pẹlu iyawo ọga rẹ? Ṣe nipa jijoko lati ba fomijomitoro ọrọ ni bi? Rara o! O ti kọkọ gbiyanju lati ba fi ọrọ jomitoro ọrọ, ṣugbọn ko ṣiṣẹ. Idi si nipe ifọrọjomitoro-ọrọ ko ki i ṣiṣẹ rara nibiti ara awọn eniyan ba ti n pongbẹ fun ibalopọ. Idi si ni yi ti a fi ri awọn kan ti wọn ti gbeyawo tabi wa nile ọkọ, ti ile wọn n dun, ti wọn ko si ni idi kankan lati ma ṣe agbere, ti wọn si n tun n ṣe e. Nigba ti awọn wọnyi ba to pa ile wọn run tan ni wọn yoo ṣẹṣẹ wa bẹrẹ si ni bere lọwọ ara wọn pe, “Kini mo ṣe yi? Ki lode ti mi o ba ara mi fọrọjomitoro-ọrọ ki n to lọ ṣe iru aṣiṣe yi?”

Nitorina, ma ṣe ro pe ifọrọjomitoro ọrọ, ọgbọn inu tabi ọkan-akin le pa ọ mọ kuro ninu ẹṣẹ agbere. Ko si ikankan ninu wọn ti o ni agbara lati pa ọ mọ kuro ninu rẹ. Ẹnikan ṣoṣo ti o le pa ọ mọ kuro ninu rẹ naa ni Ọlọrun. O si n sọ fun wa lọwọlọwọ yi pe, “Niwọn igba ti o ba ti ni i ṣe pẹlu ẹṣẹ agbere, sa asala fun ẹmi rẹ.” Nkan ti Josẹfu ṣe ni eyi. Akọkọ, o ri daju pe oun ko fi igba kankan da wa pẹlu iyawo ọga rẹ. Nigba ti obinrin yi si wa ri anfaani lati fa a sinu agbere, nṣe ni o fi ere ge e, lalai wo pe ko yẹ ki oun fi aṣọ ti o gba lọrun oun silẹ fun un. Lotitọ, inu tubu loti ba ara rẹ nitori ọrọ yi. Amọ ko ba iwa mimọ rẹ jẹ. Ọlọrun ṣi da a lare nigba ti o ya. (Wo: Jẹnẹsisi 39:6-15)

Nibakan naa, nṣe ni ki iwọ naa ri daju pe o jinna rere si ẹnikẹni tabi ohunkohun ti o ba le fi aye gba agbere ninu aye rẹ. O ko nilo lati wa pẹlu ọkunrin tabi obinrin yowu ti o ba ma n fẹ ti ọ sinu agbere pẹlu ọrọ eeri tabi ifọwọkan ti ko boju mu. O ko si nilo lati wo sinnima yẹn tabi ki o fi ohun amuṣiṣẹ foonu yowu ti o ba n fi gbogbo igba pe ọ si ẹṣẹ agbere si ori foonu rẹ. Nitorina, ṣe ohun ti o tọ, ki o si fere ge, ti ọkan rẹ ba ṣe iyebiye si ọ, ti o ko si fẹ ko parun. Njẹ ki o ma fi gbogbo igba kun fun okun, igboya ati ọgbọn ti o nilo lati ṣe eyi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ki o ma ba ya ara rẹ lẹnu. | Paitọ J.O. Lawal Read More »

ITARA ATI IMỌ NI SINSIN ỌLỌRUN | AYỌKA: ROOMU 10:1-2

AKỌSORI: “Ṣugbọn o dra lati maa fi itara ṣe rere nigba gbogbo, ki i ṣi i ṣe nigba ti mo wa pẹlu yin nikan.” (Galataia 4:16)

ỌRỌ AKỌSỌ
Nkan meji ti o ṣe pataki julọ ni biba Ọlọrun rin ni imọ ati itara. O wa ṣeeṣe ki eniyan ni imọ nkan ti Ọlọrun fẹ ki o si ma ni itara lati ṣe tabi ki o ni itara fun Ọlọrun ki o si ma ni imọ iru ẹni ti o jẹ ati nkan ti o fẹ. O tilẹ ṣeeṣe ki eniyan ma ni mejeeji. A si ri ọpọ laye loni ti wọn ko ni imọ Ọlọrun tabi itara lati sin in tabi lati ṣe ohunkohun fun. Ki wa ni awọn anfaani ti o wa nidi ki a ni imọ Ọlọrun ati ki a si tun fi itara ṣe amulo imọ naa ti a ni? Ki si ni ewu ti o sorọ mọ ki a mọ ni imọ rẹ ati itara fun un? Awọn nkan wọnyi ni a fẹ ṣe agbeyẹwo wọn ninu ẹkọ yi. Mo si gbadura pe ki Ẹmi Ọlọrun ṣi oju wa lati ri awọn nkan ti O fẹ ki a tipasẹ ẹkọ naa ri, ki O si tun fun wa ni okun lati ṣe amulo wọn. Amin.

IDI FUN IMỌ ỌLỌRUN ATI IMỌ IFẸ RẸ
Bi mo ti ṣe sọ siwaju, imọ Ọlọrun ati imọ ifẹ rẹ ṣe pataki pupọ fun ẹnikẹni ti o ba fẹ ba a rin. Ki si ni idi? Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, iwọnyi ni pataki julọ lara idi ti a fi nilo imọ Ọlọrun ati ti ifẹ lati le ba a rin:

  • Ki a ba le fi ara wa jin lati sin in: Ki ni idi ti awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose ko jade lati Ijibiti fi ni ọpọlọpọ isoro lati ba Ọlọrun rin? Idi ni pe wọn ko mọ ọn daju. Lotitọ, wọn ti gbọ ọpọlọpọ nkan nipa rẹ ati nipa agbara rẹ lati ẹnu awọn baba wọn ati awọn baba nla wọn. Yatọ si eyi, awọn naa tun ni oniruuru iriri agbara rẹ lọwọ igba ti O bẹ wọn wo ni Ijibiti, ti O si tun ko wọn jade. Ṣugbọn wọn ko ni imọ rẹ ati imọ ifẹ rẹ ti a le pe ni tiwọn. Eyi lo si fa ti wọn ko fi le fi ara wọn jin fun lati sin in tọkantọkan. Fun apẹẹrẹ, lẹyin ọjọ melokan ti Mose fi wọn silẹ lati lo gba iwe ofin lati ọwọ Ọlọrun fun wọn, wọn ba ara wọn sọrọ pe ki wọn gbagbe nipa rẹ ati nipa Ọlọrun ti o lọ ba pade, ki wọn si gbe ere kalẹ fun ara wọn, ti yoo ṣe amọna wọn lọ si ilẹ-ileri ti Ọlọrun fẹ mu wọn lọ (Ẹkisodu 32:1-6). Njẹ iyalẹnu ati kayefi kọ ni eyi jẹ bi? Pẹlu gbogbo iṣẹ iyanu ti wọn ri, ṣe o yẹ ki wọn tun ronu lati ni ọlọrun miran lẹyin Oluwa? Ko yẹ rara. Ṣugbọn nitoripe awọn funra wọn ko mọ Ọlọrun daju ninu ọkan wọn, ko jamọ nkankan loju wọn rara lati sare wa oriṣa ti yoo gba ipo rẹ ninu aye wọn. Nitori eyi ni bibeli ṣe sọ pe, “O fi ọna rẹ han fun Mose, iṣe rẹ fun awọn ọmọ Isiraẹli.” (Saamu 103:7) A si ri ọpọ loni naa to jẹ wipe foniku-fọlande ni wọn ninu ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun. Ijọsin ti wọn si Ọlọrun ko dawọ lilọ si ile alawo tabi ile alufa ẹlẹṣin yowu ti wọn ba ri duro. Awọn wọnyi ko i ti ni imọ Ọlọrun. Nitorina wọn ko le fi ọkan tabi ara wọn jin fun patapata. Ka wa kiyesi eyi: wipe eniyan n ni iriri agbara Ọlọrun ko tunmọ si pe o mọ Ọlọrun tabi pe yoo ba Ọlọrun jọba titi ayeraye.
  • Ki a ma ba ti ara rẹ kọsẹ: Ọpọ igba ni awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose ko jade lati Ijibiti ti ara Ọlọrun kọsẹ, ti wọn si ba ijiya pade. Pọọlu tilẹ sọ fun wa ninu lẹta rẹ kan si awọn ara Kọrinnti pe inu Ọlọrun ko dun si ọpọ ninu awọn eniyan yi. Nitorina, O pa wọn run ninu aṣalẹ ti wọn wa. Ki lo fa? Idi ni pe wọn ko ni imọ rẹ ati imọ ifẹ rẹ fun wọn. Oye ko ye wọn pe Ọlọrun ti O mu wọn jade lati Ijibiti jẹ Ọlọrun daradara, ti O si jẹ pe ohun gbogbo ti O n ṣe wa fun ilọsiwaju, ayọ ati ifọkanbalẹ wọn. Aiwa ni imọ yi jẹ ki wọn ṣi ọrọ sọ, ki wọn si tun ṣi iwa wu ni ọpọ igba, eyi ti o si ja si iparun fun ọpọ ninu wọn. Nibakanna, ọpọ loni ni o n ṣi ẹṣẹ gbe, ti o si n sọ ọrọ odi si Ọlọrun nitoripe wọn ko mọ ọn. Ti awọn wọnyi ko ba si ri aanu gba, ko si ni ki aini imọ Ọlọrun yi ma yọri si iparun fun wọn bopẹboya. (Wo: Numeri 11; 1Kọrinnti 10:1-5)
  • Ki ijọsin wa ba le ṣe itẹwọgba: Jesu sọ fun arabinrin kan ni ọjọkan pe, “Ẹyin n sin ohun ti ẹyin ko mọ, awa n sin ohun ti awa mọ…” (Johanu 4:22) Pọọlu naa, nigba ti o n ba awọn ara Atẹni sọrọ lori ihinrere Jesu pe akiyesi wọn si ọkan lara awọn pẹpẹ wọn ti o ni akole ti o ka bayi: “Si Ọlọrun aimọ.” Bawo wa ni eniyan ṣe fẹ sin Ọlọrun ti ko mọ ni ọna ti o tọ ati ti o yẹ? Ko le e ṣeeṣe rara. Gẹgẹ bi ọrọ Jesu Oluwa wa, Ọlọrun ti o yẹ ki a ma sin jẹ ẹmi, ẹmi ti ko ṣe fojuru ṣugbọn ti o wa. Nitorina, ẹnikẹni ti yoo ba sin gbọdọ mura lati sin ninu ẹmi ati pẹlu otitọ. Ka ma tilẹ fọrogun, Jesu sọ wipe awọn ti yoo sin Ọlọrun ninu ẹmi ati ninu otitọ ni O n wa kiri. Awọn wọnyi nikan si ni iṣẹ isin wọn le jẹ itẹwọgba, ti wọn yoo si ri oriyin gba fun isin wọn. (Wo: Johanu 4:22-24; Iṣe Apọsiteli 17:22-23)

IDI FUN ITARA NI SISIN ỌLỌRUN
Siwajusi, bi o ti ṣe jẹ pataki fun wa lati ni imọ Ọlọrun naa ni o tun jẹ pataki fun wa lati ni itara fun un ati lati sin in. Pataki lara idi ti o si ṣe yẹ ki a ni itara fun un ni iwọnyi:

  • Awọn onitara ni Ọlọrun ma n fi ara rẹ han: Bibeli sọ wipe, “Nigba naa ni ni awa o mọ, bi a ba tẹramọ ọna lati mọ Oluwa…” (Hosia 6:3). O tun sọ siwaju pe, “Bi ẹnikẹni ba fẹ lati ṣe ifẹ rẹ, yoo mọ niti ẹkọ naa, bi o ba jẹ ti Ọlọrun, tabi emi ba n sọ ti ara mi.” (Johanu 7:17) Ki ni eyi fi n ye wa? O n fi ye wa pe nini itara lati mọ Ọlọrun ati lati mọ ifẹ rẹ wa lara awọn nkan ti O ma n wo lati fi imọ ati oye otitọ rẹ han eniyan. Ara idi ti Mose ṣe mọ ọn bi o ti ṣe mọ ọn nipe o ni itara ti o ga lati mọ (Ẹkisodu 33:12-23). Pọọlu naa n kọ? Ki ni idi ti o fi ni imọ Ọlọrun ati ifẹ rẹ ti o ga bi o ṣe ni? Yatọ si pe, Ọlọrun nifẹ lati fi ara rẹ han, oun naa ni itara ti o ga lati mọ (Filipi 3:10-15). Ti a ba wa woye pe a ko mọ Ọlọrun to tabi pe a ko ma fi gbogbo igba pọ si ninu imọ rẹ ati imọ ifẹ rẹ ti a ni, a ni lati yẹ ara wo fun itara. Njẹ itara wa fun koju osunwọn to? A si le mọ eyi nipa iha ti a kọ si ọrọ rẹ, adura gbigba, ibadapọ pẹlu awọn ọmọ rẹ ati iṣẹ isin ninu ijọba rẹ.
  • Awọn onitara ni Ọlọrun ma n pin ni ere: Bibeli sọ pe, “Ṣugbọn ni aisi igbagbọ ko ṣeeṣe lati wu Ọlọrun: nitori ẹni ti o ba n tọ Ọlọrun wa ko le ṣaigbagbọ pe o n bẹ, ati pe oun ni oluṣẹsan fun awọn ti o ba fi ara balẹ wa a.” (Heberu 11:6) Njẹ o ri bayi? Ọlọrun jẹ oluṣẹsan fun awọn ti o ba fi ara balẹ wa a. Awọn wo ni yoo fi ara balẹ wa a? Awọn onitara ni yoo fi ara balẹ ati tọkantọkan wa. Ọna wo ni yoo wa gba san wọn lẹsan? Oun nikan naa ni O le sọ eyi. Ṣugbọn a fi ye wa daju ninu bibeli pe gbogbo awọn ti o ba fi itara ọkan ati otitọ inu wa Ọlọrun tabi ṣe iṣẹ rẹ ni o ma n jere ṣiṣe bẹ. Nitorina, ti o ba dabi ẹni pe a ko ma fi taratara gbadun Ọlọrun ninu aye wa, o yẹ ki a wo irufẹ itara ti a ni lati mọ ọn daju, lati mọ ifẹ rẹ ati lati ṣiṣẹ sin in.
  • Awọn onitara ni o ma n mu ki iṣẹ Ọlọrun tẹsiwaju, ki o si tun fi idi mulẹ: Awọn ti ko ba ni itara fun Ọlọrun ati lati mọ ifẹ rẹ ko ki i ṣaba fi taratara busi iṣẹ rẹ, boya akoko wọ fun wọn tabi ko wọ. Awọn ti o ni itara fun un ni o ma n fi gbogbo lepa lati ri pe iṣẹ rẹ n tẹsiwaju ati pe o n so eso ti o yẹ ki o so, bi o tilẹ lewu lati ṣe bẹẹ. Fun apẹẹrẹ, ki lo fa ti Ọlọrun fi lo Pọọlu ni ọna ti o gba lo? Idi kan pataki ni pe o ni itara ti o ga lati mọ ọn, lati mọ ifẹ rẹ ati lati ri pe ifẹ rẹ wa si imuṣẹ ninu aye ọpọ eniyan. Lara awọn nkan ti o sọ nipa ara rẹ ni eyi: “Nitori pe bi mo ti n waasu iyinrere, emi ko ni ohun ti emi o fi ṣogo: nitori pe aigbọdọ-ma ṣe wa lori mi; ani, mo gbe! Bi emi ko ba waasu iyinrere.” (1Kọrinnti 9:16) Ọrọ onitara ni eyi. Ọrọ ẹni ti o ṣetan lati ṣe ohun gbogbo ti Ọlọrun fun ni amuyẹ ati anfaani lati ṣe ki iṣẹ rẹ ba le tẹsiwaju ni yẹn. A tun ri apẹẹrẹ miran ninu Jesu Oluwa wa nigba ti O le awọn ti wọn ra ati awọn ti wọn n ta jade kuro ninu tẹmpili Ọlọrun ti o wa n Jerusalẹmu. Bibeli ṣi jẹ ki o ye wa pe itara fun ile Ọlọrun ni o jẹ ki o ṣe eyi. Awọn ti o ba ni itara fun ilera ijọ Ọlọrun tabi fun idagbasoko iṣẹ rẹ ko ni ma woran ki nkan bajẹ ki wọn to gbe igbesẹ lati ṣe ohun ti o tọ. Irufẹ awọn wọnyi si ni Ọlọrun ma n fi si ipo adari ati alatunṣe ninu ijọba rẹ. (Wo: Numeri 25; Nehemaya 13; Jeremaya 20:9; Johanu 2:13-17&9:4)

EWU TI SORỌ MỌ ITARA TI KO NI IMỌ
Amọ ṣa o, bi mo ti ṣe ṣalaye siwaju, o lewu lati ni atara fun Ọlọrun lalai ni imọ rẹ ati imọ ifẹ rẹ ti o jinlẹ. Lara awọn ewu ti o si sọrọ mọ ni iwọnyi:

  • Ṣiṣe laala lori irọ: Ti a ko ba fi imọ kun itara wa fun Ọlọrun, o ṣeeṣe ki laala wa lati mu inu rẹ dun tabi lati ṣe iṣẹ sin in ja si asan. Fun apẹẹrẹ, ọjọ kan wa ti Jesu de Mata ati arabinrin rẹ Maria ni alejo, gẹgẹ bi akọsilẹ bibeli. Mata si mura gidigidi ni ọjọ yi lati tọju Jesu ati awọn ti o wa pẹlu rẹ. Nigba ti o si n sare siwa ati sẹyin, Maria joko ti Jesu lati kẹkọ lẹsẹ rẹ. Eyi bi Mata ninu tobẹ gẹẹ ti o fi pe akiyesi Jesu si ọrọ naa. Ṣugbọn Jesu jẹ ki o ye wipe bi o tilẹ jẹ pe o n ṣe laala lotitọ lati tọju Oun, laala rẹ ko wa ni ibamu pẹlu ifẹ Oun ni akoko naa. Eyi jasi pe Mata ko ba kọkọ farabalẹ tẹti si Jesu lati mọ nkan ti O n fẹ ki o to ma sare kaakiri. Maria ko sare kaakiri bi Mata lati tọju Jesu. Ṣugbọn Jesu sọ wipe jijoko rẹ lati kẹkọ mọ ifẹ Oun lere lori, o si tun ṣe iyebiye ju gbogbo laala ti Mata n ṣe kaakiri lọ. A tun ri apẹẹrẹ miran ni ti awọn Juu ti ko ri igbala gba bi o tilẹ jẹ pe wọn ni itara ti o ga fun Ọlọrun. Ki si ni idi? Idi ni pe itara wọn jẹ eyi ti ko ni oye ifẹ Ọlọrun. Nitorina, bi o ti wu ki itara wa ga to, niwọn igba ti ko ba ti wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, ko nitunmọ. Laala yowu ti a ba si tipasẹ eyi ṣe ko le lere lori. (Wo: Luuku 10:38-42; Roomu 10:1-3)
  • Biba iṣẹ Ọlọrun jẹ: Yatọ si pe laala awọn ti itara wọn ko wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun le ja si asan, awọn gan tun le ba iṣẹ Ọlọrun jẹ. Pọọlu fi igba kan nṣe laala lati pa ijọ Jesu run nitoripe ko ni oye nkan ti o n ṣe (Galatia 1:13-14). Ọpọ losi dabi rẹ loni, ti awọn naa n fi itara ti ko ni imọ ba iṣẹ Ọlọrun jẹ tabi ṣe awọn ọmọ Ọlọrun ni ijamba. Ọjọ ti oju wọn ba si ṣi nkan ti wọn n ṣe ni wọn yoo to gba pe igbe aye basejẹ ni awọn ti n gbe. Boya awa naa tilẹ ti n ba nkan jẹ ninu ijọ Ọlọrun ti a wa tabi ni awujọ wa nitori itara wa fun un. A nilo lati fi ara balẹ kẹkọ lọdọ rẹ, ki a si fi imọ kun itara wa. Aijẹbẹ, awọn nkan ti a ni lọkan lati ṣe ni rere fun le yọri si idibajẹ ti ko ni lere lori fun wa. (Wo: Johanu 16:2)
  • Ṣiṣi ilẹkun aye wa fun idajọ Ọlọrun: O tun gbọdọ ye wa pe itara ti ko ni imọ Ọlọrun ninu le ko iya jẹ wa tabi awọn ti o sunmọ wa. Fun apẹẹrẹ, a ri ka ninu bible pe akoko kan wa ti Ọba Sọọlu gbiyanju lati pa awọn ara Gibioni run nitori itara rẹ fun ilẹ Isiraẹli. Ṣugbọn itara rẹ yi lodi si ifẹ Ọlọrun. Eyi si jẹ ki iyan ọdun mẹta mu ni ilẹ naa ni akoko ti Dafidi jẹ ọba. Ki iyan yi si ba le wa si opin, a ni lati pa ọkunrin meje lati idile Sọọlu, awọn ti ko mọwọ ti ko mẹsẹ. Lafikun, Ọba Dafidi naa ṣe aṣiṣe ni igbakan nitori itara ti ko ni imọ. Eyi si yọri si iku ọmọkunrin kan ti a n pe ni Uṣa. Nitorinaa, itara ti ko ni imọ le ko iya jẹ ọpọlọpọ, pẹlupẹlu awọn alaiṣẹ. Idi si ni yi ti a fi gbọdọ ṣọra ṣe ninu iṣẹ isin wa si Ọlọrun, ki a ma ba tipasẹ itara wa da wahala silẹ fun ara wa ati fun awọn miran pẹlu. (Wo: 2Samuẹli 6:1-19 & 21:1-14; 1Kironika 13&15)

EWU TI O SORỌ MỌ IMỌ TI KO NI ITARA
Nibakannaa, o lewu ki a ni imọ ifẹ Ọlọrun ki a si ma wa ni itara lati ṣiṣẹ tọ ọ. Pataki lara awọn ewu ti o sọrọ mọ eyi ni iwọnyi:

  • Aidagbasoke ninu ẹmi: Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ẹnikẹni ti o ba ni imọ Ọlọrun ati imọ ifẹ rẹ ti ko si ni itara lati ṣe amulo rẹ ko le dagbasoke ninu ẹmi. Idi si ni pe ilana Ọlọrun ni pe awọn ti o ba n ṣe amulo imọ rẹ tabi ipese rẹ nikan ni o lẹtọ lati ri nkan gba si ni ọwọ rẹ. Awọn wọnyi nikan ni Ọlọrun yoo fi ara rẹ ati ifẹ rẹ han si ni ọna ti o pọ. Ṣugbọn awọn ti ko ni itara lati mọ ọn tabi ifẹ rẹ si ko ni kuro loju kan. Idi si niyi ti a fi ri ọpọ ninu ijọ loni ti ko dagbasoke ninu nkan ti ẹmi tabi pọ si ni iwulo ninu ijọba Ọlọrun. Aye awọn miran ko tilẹ dabi pe wọn mọ Jesu rara. Idi si ni pe ko si itara ti o kojuosuwọn ninu wọn lati mọ ọn si. Boya awa naa ti wa ni ojukanna fun igba diẹ tabi fun ọpọ ọdun ninu ijọ wa. O yẹ ki a kiyesi itara wa, ki o ma ba wa jẹ pe awọn ọmọ inu wa ninu ẹmi ni yoo pada di olukọ fun wa. (Wo: Maaku 4:24-25; Heberu 5:11-14)
  • Iku ti ẹmi: Ewu miran ti o sọrọ mọ aifi itara kun imọ Ọlọrun ti a ni lo ni i ṣe pẹlu iku ti ẹmi. A ri ka ninu iwe Heberu pe awọn ti a ti la loju pẹlu imọ Ọlọrun, ti wọn si ti jẹgbadun didara rẹ, ti wọn ba kọ lati ma gbe igbesẹ itara lati dagbasoke wa labẹ ewu iku ti ẹmi ati iparun. Idi si ni pe ti a ko ba ma fi gbogbo igba tun itara wa fun Ọlọrun ṣe, o ṣeeṣe ki a ba ara wa ni akoko tabi igba ti ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ifẹ rẹ yoo fi ọkan wa silẹ, ti a o si pada sẹyin. A si ri awọn ti o wa ni ipo yi loni. Ko si nkan ti ẹ fẹ ba wọn sọ lati inu ọrọ Ọlọrun ti wọn ko i ti fẹ gbọ ri. Ṣugbọn nitori pe wọn sọ itara wọn nu, Eṣu ri aye wọ inu aye wọ lọ lati yi ọkan wọn pada lẹyin Jesu. Bi o si ti ṣe ri fun Judasi ni o ma n pada ri fun iru awọn eniyan bẹ. Nitorina, a nilo lati kiyesara, ki a si ri pe gbogbo igba ni itara wa fun Ọlọrun n pọ si. Aijẹbẹ, ‘Ewu n bẹ loko Longẹ’. (Wo: Heberu 6:1-8)
  • Ijiya alailere: Bibeli sọ wipe, “Nitori naa ẹni ti o ba mọ rere ṣe ti ko si ṣe e, ẹṣẹ ni fun un.” (Jemisi 4:17) O tun sọ wipe, “Ati ọmọ-ọdọ naa ti o mọ ifẹ Oluwa rẹ, ti ko si mura silẹ, ti ko si ṣe gẹgẹ bi ifẹ rẹ, oun ni a o naa pupọ.” (Luuku 12:47) Ki ni idi ti eniyan yoo fi mọ nkan ti o tọ lati ṣe ti ko si ni i ṣe? Ọkan lara rẹ ni aini itara fun rere ṣiṣe. Bi a si tun ṣe wa ri ninu bibeli, ara idi ti a ṣe sọ wa di atunbi, ti a wẹ wa mọ, ti a si ṣe wa yẹ ni ki a ba le jẹ onitara lati ṣe iṣẹ rere ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wa lati ṣe. Ti a ko ba wa ma fi itara ṣe nkan ti Ọlọrun fẹ ki a ṣe, a je wipe a n ṣilẹkun silẹ fun ijiya tabi ibawi niyẹn nitoripe a n fi ipese ati amuyẹ rẹ ṣofo. Boya idi ti a ti ṣe padanu awọn ipese tabi anfaani kan ti Ọlọrun fun wa ni pe a ti ṣọ itara wa fun un nu. A nilo lati ronupiwada, ki a si gbadura si ki O sọ itara wa ji, ki a ba le bẹrẹ si ni fi tọkantọkan ṣe ifẹ rẹ. Aijẹbẹ, nkan le buru si fun wa ju bi o ti ṣe wa bayi lọ. (Wo: Luuku 19:11-27; Efesu 2:10; Titu 2:14)

ỌRỌ IPARI
A nilo lati fi itara kun imọ Ọlọrun ati imọ ifẹ rẹ ti a ni ti a ba fẹ ma fi gbogbo igba pọ si ni isesorere ati iwulo ninu ijọba rẹ. Aijẹbẹ, laipẹ, o ṣeeṣe ki a ba ara wa labẹ oniruuru ewu, pẹlupẹlu ewu iku nipa ti ẹmi. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun tun wa ṣe ni gbogbo ibi ti a ba ku si niti imọ ati niti itara fun un ati fun ijọba rẹ. Amin.

IBEERE

  • Bawo ni ẹkọ yi ṣe ṣe pataki to fun ijọ Ọlọrun?
  • Ki ni o ṣe iyebiye si ọ julọ ninu awọn nkan ti o kọ ninu ẹkọ bibeli yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE | ỌJỌRU 12, ṢẸRẸ 2022

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ITARA ATI IMỌ NI SINSIN ỌLỌRUN | AYỌKA: ROOMU 10:1-2 Read More »

O mu ṣiṣe olotitọ lọkunkundun | Pst. J.O. Lawal

Ọjọ: Sẹrẹ 09, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 36

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji ọdun yi, ọdun 2022. Mo si gbadura pe ki Ẹmi Mimọ ro ọ lagbara lati jẹ olotitọ ninu gbogbo iṣẹ isin rẹ si Ọlọrun ninu ọdun naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ko ki i ṣe nkan ti a ṣe fun Ọlọrun nikan ni o jẹ ẹ logun; ọkan ti a fi ṣe ohunkohun ti a ba ṣe fun naa jẹ ẹ logun pẹlu. Nitorinaa, ere ti yoo ba fun wa ko ni da lori bi nkan ti a ṣe fun ti ṣe pọ to nikan ṣugbọn pẹlu lori bi a ṣe jẹ olotitọ si to ni ṣiṣe ohun na. Idi si ni yi ti o ko fi gbọdọ jẹ ki oju rẹ wa lara ṣiṣe eleyi tabi tọhun fun Ọlọrun nikan; dipo bẹẹ, jẹ ki o tun wa lori ṣiṣe ohunkohun ti o ba n ṣe fun pẹlu ọkan ti o ja fafa, ti o si tun jẹ olotitọ.

Ki ni idi ti a fi kọ ọrẹ Keeni silẹ? Idi ni pe ọkan rẹ ko dọgba pẹlu Ọlọrun. Lotitọ, ọpọ lo ti sọ pe idi ni pe ko mu ọrẹ ti o koju oṣuwọn wa fun Ọlọrun. Awọn miran si ti sọ pe idi ni pe ọrẹ rẹ ko ki i ṣe nkan ẹlẹjẹ. Ṣugbọn bibeli ko sọ ohunkohun to jọ mọ awọn nkan wọnyi fun wa. Ko sọ wipe Ọlọrun paṣẹ fun Keeni ati arakunrin rẹ Abẹli lori nkan ti wọn yoo mu wa fun Oun. Dipo eyi, o sọ fun wa pe awọn mejeji mu ọrẹ wa lati inu iṣẹ ọwọ wọn. Nitorina, o ni lati jẹ pe ọrẹ atọkanwa ni wọn mu wa fun un. (Wo: Jẹnẹsisi 4:3-5)

Ki a ma fọrọgun, bi o tilẹ jẹ pe awọn mejeji lo ṣe laala lati mu nkan wa fun Ọlọrun, Abẹli ati ọrẹ rẹ nikan ni Ọlọrun wo pẹlu ojurere; ko wo Keeni ati ọrẹ rẹ pẹlu ojurere. Nigba ti O si ri pe Keeni rẹwẹsi nitori eyi, O sọ fun kedere pe, “Ti iwọ ba n ṣe ohun ti o tọ, njẹ o ko ni jẹ ẹni itẹwọgba bi?” Nitorina, ọrọ yi ko fi taratara ni nkankan ṣẹ pẹlu ọrẹ rẹ bikoṣe pẹlu oun tikararẹ. O ti pẹ ti nkankan ko ti ṣe deede pẹlu ọkan rẹ. Ẹyi ni o si ba ọrẹ rẹ jẹ. Nigbati ti o si tun wa kọ lati gbọ ikilọ Ọlọrun, nkan naa ti o n yọ ọkan rẹ lẹnu papa wa sọ di apaniyan. (Wo: Jẹnẹsisi 4:6-8)

Nitorina, nkan ti Ọlọrun n wo kọja nkan ti a n ṣe fun un tabi ti a n fi fun un. O n wo ọkan wa pẹlu. Nkan ti O ba si ri ninu ọkan wa ni yoo sọ bọya yoo tẹwọgba nkan ti a n ṣẹ fun, ki O si tun pin wa lere lori rẹ tabi ko ni ṣe bẹẹ. Bi a tilẹ ti ṣe ri ninu bibeli, awọn igba wa ti O tilẹ ma n jẹ awọn eniyan niya lori pe wọn ko jẹ olotitọ si ninu iṣẹ iṣin wọn. Fun apẹẹrẹ, ni ọjọ kannaa, Nadabu ati Abihu, meji lara awọn ọmọkunri Aarọni, ni Ọlọrun ṣe idajọ iku fun nitoripe wọn lo ina ti ko tọna lati rubọ si. Lotitọ, wọn jade lati wa sin in ni. Ṣugbọn nikẹyinkẹyin nṣe ni wọn fi iku ṣe ifa jẹ nibi ti wọn ti n sin in dipo ki wọn gba oriyin ati ere lọwọ rẹ. (Wo: Lẹfitiku 10:1-3)

Ananaya ati Safira aya rẹ nkọ? Awọn mejeji ni Oluwa pa lọjọ kannaa nitori aiṣododo wọn ni fifi funni (Iṣe Apọsiteli 5:1-10). Nitorina, a nilo lati ma fi gbogbo igba mu iṣododo ninu iṣẹ isin wa si Ọlọrun ni ọkunkundun. Pọọlu, nigba ti o n sọrọ lori eyi, sọ wipe, “Oun kan naa ti o tọ fun iriju pẹlu, ni ki o jẹ oloootọ.” (1Kọrinnti 4:2) Njẹ o ri bẹyẹn? Ti a ba n sọrọ iṣẹ isin, iṣododo ṣe pataki; ko ṣe foju fo tabi foju rena.

Nitorina, bi o ṣe n lọ ninu ọdun yi, jẹ ki ododo jẹ akọmọna rẹ ninu gbogbo iṣẹ isin rẹ si Ọlọrun. Eyi si ni yoo jẹ ki O lo iṣẹ iṣin naa lati mu ete rẹ ni rere ṣe ninu aye awọn eniyan. Lafikun, eyi yoo jẹ ki o gba oriyin ati ere lọwọ rẹ fun iṣẹ isin rẹ dipo ikọsilẹ tabi ibawi. Njẹ ki a kọ ọkan rẹ, ki a si tun fun ni okun lati jẹ olotitọ si ni gbogbo ọna ati ni gbogbo igba, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

O mu ṣiṣe olotitọ lọkunkundun | Pst. J.O. Lawal Read More »