AKỌSORI: “Ṣugbọn o dra lati maa fi itara ṣe rere nigba gbogbo, ki i ṣi i ṣe nigba ti mo wa pẹlu yin nikan.” (Galataia 4:16)
ỌRỌ AKỌSỌ
Nkan meji ti o ṣe pataki julọ ni biba Ọlọrun rin ni imọ ati itara. O wa ṣeeṣe ki eniyan ni imọ nkan ti Ọlọrun fẹ ki o si ma ni itara lati ṣe tabi ki o ni itara fun Ọlọrun ki o si ma ni imọ iru ẹni ti o jẹ ati nkan ti o fẹ. O tilẹ ṣeeṣe ki eniyan ma ni mejeeji. A si ri ọpọ laye loni ti wọn ko ni imọ Ọlọrun tabi itara lati sin in tabi lati ṣe ohunkohun fun. Ki wa ni awọn anfaani ti o wa nidi ki a ni imọ Ọlọrun ati ki a si tun fi itara ṣe amulo imọ naa ti a ni? Ki si ni ewu ti o sorọ mọ ki a mọ ni imọ rẹ ati itara fun un? Awọn nkan wọnyi ni a fẹ ṣe agbeyẹwo wọn ninu ẹkọ yi. Mo si gbadura pe ki Ẹmi Ọlọrun ṣi oju wa lati ri awọn nkan ti O fẹ ki a tipasẹ ẹkọ naa ri, ki O si tun fun wa ni okun lati ṣe amulo wọn. Amin.
IDI FUN IMỌ ỌLỌRUN ATI IMỌ IFẸ RẸ
Bi mo ti ṣe sọ siwaju, imọ Ọlọrun ati imọ ifẹ rẹ ṣe pataki pupọ fun ẹnikẹni ti o ba fẹ ba a rin. Ki si ni idi? Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, iwọnyi ni pataki julọ lara idi ti a fi nilo imọ Ọlọrun ati ti ifẹ lati le ba a rin:
- Ki a ba le fi ara wa jin lati sin in: Ki ni idi ti awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose ko jade lati Ijibiti fi ni ọpọlọpọ isoro lati ba Ọlọrun rin? Idi ni pe wọn ko mọ ọn daju. Lotitọ, wọn ti gbọ ọpọlọpọ nkan nipa rẹ ati nipa agbara rẹ lati ẹnu awọn baba wọn ati awọn baba nla wọn. Yatọ si eyi, awọn naa tun ni oniruuru iriri agbara rẹ lọwọ igba ti O bẹ wọn wo ni Ijibiti, ti O si tun ko wọn jade. Ṣugbọn wọn ko ni imọ rẹ ati imọ ifẹ rẹ ti a le pe ni tiwọn. Eyi lo si fa ti wọn ko fi le fi ara wọn jin fun lati sin in tọkantọkan. Fun apẹẹrẹ, lẹyin ọjọ melokan ti Mose fi wọn silẹ lati lo gba iwe ofin lati ọwọ Ọlọrun fun wọn, wọn ba ara wọn sọrọ pe ki wọn gbagbe nipa rẹ ati nipa Ọlọrun ti o lọ ba pade, ki wọn si gbe ere kalẹ fun ara wọn, ti yoo ṣe amọna wọn lọ si ilẹ-ileri ti Ọlọrun fẹ mu wọn lọ (Ẹkisodu 32:1-6). Njẹ iyalẹnu ati kayefi kọ ni eyi jẹ bi? Pẹlu gbogbo iṣẹ iyanu ti wọn ri, ṣe o yẹ ki wọn tun ronu lati ni ọlọrun miran lẹyin Oluwa? Ko yẹ rara. Ṣugbọn nitoripe awọn funra wọn ko mọ Ọlọrun daju ninu ọkan wọn, ko jamọ nkankan loju wọn rara lati sare wa oriṣa ti yoo gba ipo rẹ ninu aye wọn. Nitori eyi ni bibeli ṣe sọ pe, “O fi ọna rẹ han fun Mose, iṣe rẹ fun awọn ọmọ Isiraẹli.” (Saamu 103:7) A si ri ọpọ loni naa to jẹ wipe foniku-fọlande ni wọn ninu ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun. Ijọsin ti wọn si Ọlọrun ko dawọ lilọ si ile alawo tabi ile alufa ẹlẹṣin yowu ti wọn ba ri duro. Awọn wọnyi ko i ti ni imọ Ọlọrun. Nitorina wọn ko le fi ọkan tabi ara wọn jin fun patapata. Ka wa kiyesi eyi: wipe eniyan n ni iriri agbara Ọlọrun ko tunmọ si pe o mọ Ọlọrun tabi pe yoo ba Ọlọrun jọba titi ayeraye.
- Ki a ma ba ti ara rẹ kọsẹ: Ọpọ igba ni awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose ko jade lati Ijibiti ti ara Ọlọrun kọsẹ, ti wọn si ba ijiya pade. Pọọlu tilẹ sọ fun wa ninu lẹta rẹ kan si awọn ara Kọrinnti pe inu Ọlọrun ko dun si ọpọ ninu awọn eniyan yi. Nitorina, O pa wọn run ninu aṣalẹ ti wọn wa. Ki lo fa? Idi ni pe wọn ko ni imọ rẹ ati imọ ifẹ rẹ fun wọn. Oye ko ye wọn pe Ọlọrun ti O mu wọn jade lati Ijibiti jẹ Ọlọrun daradara, ti O si jẹ pe ohun gbogbo ti O n ṣe wa fun ilọsiwaju, ayọ ati ifọkanbalẹ wọn. Aiwa ni imọ yi jẹ ki wọn ṣi ọrọ sọ, ki wọn si tun ṣi iwa wu ni ọpọ igba, eyi ti o si ja si iparun fun ọpọ ninu wọn. Nibakanna, ọpọ loni ni o n ṣi ẹṣẹ gbe, ti o si n sọ ọrọ odi si Ọlọrun nitoripe wọn ko mọ ọn. Ti awọn wọnyi ko ba si ri aanu gba, ko si ni ki aini imọ Ọlọrun yi ma yọri si iparun fun wọn bopẹboya. (Wo: Numeri 11; 1Kọrinnti 10:1-5)
- Ki ijọsin wa ba le ṣe itẹwọgba: Jesu sọ fun arabinrin kan ni ọjọkan pe, “Ẹyin n sin ohun ti ẹyin ko mọ, awa n sin ohun ti awa mọ…” (Johanu 4:22) Pọọlu naa, nigba ti o n ba awọn ara Atẹni sọrọ lori ihinrere Jesu pe akiyesi wọn si ọkan lara awọn pẹpẹ wọn ti o ni akole ti o ka bayi: “Si Ọlọrun aimọ.” Bawo wa ni eniyan ṣe fẹ sin Ọlọrun ti ko mọ ni ọna ti o tọ ati ti o yẹ? Ko le e ṣeeṣe rara. Gẹgẹ bi ọrọ Jesu Oluwa wa, Ọlọrun ti o yẹ ki a ma sin jẹ ẹmi, ẹmi ti ko ṣe fojuru ṣugbọn ti o wa. Nitorina, ẹnikẹni ti yoo ba sin gbọdọ mura lati sin ninu ẹmi ati pẹlu otitọ. Ka ma tilẹ fọrogun, Jesu sọ wipe awọn ti yoo sin Ọlọrun ninu ẹmi ati ninu otitọ ni O n wa kiri. Awọn wọnyi nikan si ni iṣẹ isin wọn le jẹ itẹwọgba, ti wọn yoo si ri oriyin gba fun isin wọn. (Wo: Johanu 4:22-24; Iṣe Apọsiteli 17:22-23)
IDI FUN ITARA NI SISIN ỌLỌRUN
Siwajusi, bi o ti ṣe jẹ pataki fun wa lati ni imọ Ọlọrun naa ni o tun jẹ pataki fun wa lati ni itara fun un ati lati sin in. Pataki lara idi ti o si ṣe yẹ ki a ni itara fun un ni iwọnyi:
- Awọn onitara ni Ọlọrun ma n fi ara rẹ han: Bibeli sọ wipe, “Nigba naa ni ni awa o mọ, bi a ba tẹramọ ọna lati mọ Oluwa…” (Hosia 6:3). O tun sọ siwaju pe, “Bi ẹnikẹni ba fẹ lati ṣe ifẹ rẹ, yoo mọ niti ẹkọ naa, bi o ba jẹ ti Ọlọrun, tabi emi ba n sọ ti ara mi.” (Johanu 7:17) Ki ni eyi fi n ye wa? O n fi ye wa pe nini itara lati mọ Ọlọrun ati lati mọ ifẹ rẹ wa lara awọn nkan ti O ma n wo lati fi imọ ati oye otitọ rẹ han eniyan. Ara idi ti Mose ṣe mọ ọn bi o ti ṣe mọ ọn nipe o ni itara ti o ga lati mọ (Ẹkisodu 33:12-23). Pọọlu naa n kọ? Ki ni idi ti o fi ni imọ Ọlọrun ati ifẹ rẹ ti o ga bi o ṣe ni? Yatọ si pe, Ọlọrun nifẹ lati fi ara rẹ han, oun naa ni itara ti o ga lati mọ (Filipi 3:10-15). Ti a ba wa woye pe a ko mọ Ọlọrun to tabi pe a ko ma fi gbogbo igba pọ si ninu imọ rẹ ati imọ ifẹ rẹ ti a ni, a ni lati yẹ ara wo fun itara. Njẹ itara wa fun koju osunwọn to? A si le mọ eyi nipa iha ti a kọ si ọrọ rẹ, adura gbigba, ibadapọ pẹlu awọn ọmọ rẹ ati iṣẹ isin ninu ijọba rẹ.
- Awọn onitara ni Ọlọrun ma n pin ni ere: Bibeli sọ pe, “Ṣugbọn ni aisi igbagbọ ko ṣeeṣe lati wu Ọlọrun: nitori ẹni ti o ba n tọ Ọlọrun wa ko le ṣaigbagbọ pe o n bẹ, ati pe oun ni oluṣẹsan fun awọn ti o ba fi ara balẹ wa a.” (Heberu 11:6) Njẹ o ri bayi? Ọlọrun jẹ oluṣẹsan fun awọn ti o ba fi ara balẹ wa a. Awọn wo ni yoo fi ara balẹ wa a? Awọn onitara ni yoo fi ara balẹ ati tọkantọkan wa. Ọna wo ni yoo wa gba san wọn lẹsan? Oun nikan naa ni O le sọ eyi. Ṣugbọn a fi ye wa daju ninu bibeli pe gbogbo awọn ti o ba fi itara ọkan ati otitọ inu wa Ọlọrun tabi ṣe iṣẹ rẹ ni o ma n jere ṣiṣe bẹ. Nitorina, ti o ba dabi ẹni pe a ko ma fi taratara gbadun Ọlọrun ninu aye wa, o yẹ ki a wo irufẹ itara ti a ni lati mọ ọn daju, lati mọ ifẹ rẹ ati lati ṣiṣẹ sin in.
- Awọn onitara ni o ma n mu ki iṣẹ Ọlọrun tẹsiwaju, ki o si tun fi idi mulẹ: Awọn ti ko ba ni itara fun Ọlọrun ati lati mọ ifẹ rẹ ko ki i ṣaba fi taratara busi iṣẹ rẹ, boya akoko wọ fun wọn tabi ko wọ. Awọn ti o ni itara fun un ni o ma n fi gbogbo lepa lati ri pe iṣẹ rẹ n tẹsiwaju ati pe o n so eso ti o yẹ ki o so, bi o tilẹ lewu lati ṣe bẹẹ. Fun apẹẹrẹ, ki lo fa ti Ọlọrun fi lo Pọọlu ni ọna ti o gba lo? Idi kan pataki ni pe o ni itara ti o ga lati mọ ọn, lati mọ ifẹ rẹ ati lati ri pe ifẹ rẹ wa si imuṣẹ ninu aye ọpọ eniyan. Lara awọn nkan ti o sọ nipa ara rẹ ni eyi: “Nitori pe bi mo ti n waasu iyinrere, emi ko ni ohun ti emi o fi ṣogo: nitori pe aigbọdọ-ma ṣe wa lori mi; ani, mo gbe! Bi emi ko ba waasu iyinrere.” (1Kọrinnti 9:16) Ọrọ onitara ni eyi. Ọrọ ẹni ti o ṣetan lati ṣe ohun gbogbo ti Ọlọrun fun ni amuyẹ ati anfaani lati ṣe ki iṣẹ rẹ ba le tẹsiwaju ni yẹn. A tun ri apẹẹrẹ miran ninu Jesu Oluwa wa nigba ti O le awọn ti wọn ra ati awọn ti wọn n ta jade kuro ninu tẹmpili Ọlọrun ti o wa n Jerusalẹmu. Bibeli ṣi jẹ ki o ye wa pe itara fun ile Ọlọrun ni o jẹ ki o ṣe eyi. Awọn ti o ba ni itara fun ilera ijọ Ọlọrun tabi fun idagbasoko iṣẹ rẹ ko ni ma woran ki nkan bajẹ ki wọn to gbe igbesẹ lati ṣe ohun ti o tọ. Irufẹ awọn wọnyi si ni Ọlọrun ma n fi si ipo adari ati alatunṣe ninu ijọba rẹ. (Wo: Numeri 25; Nehemaya 13; Jeremaya 20:9; Johanu 2:13-17&9:4)
EWU TI SORỌ MỌ ITARA TI KO NI IMỌ
Amọ ṣa o, bi mo ti ṣe ṣalaye siwaju, o lewu lati ni atara fun Ọlọrun lalai ni imọ rẹ ati imọ ifẹ rẹ ti o jinlẹ. Lara awọn ewu ti o si sọrọ mọ ni iwọnyi:
- Ṣiṣe laala lori irọ: Ti a ko ba fi imọ kun itara wa fun Ọlọrun, o ṣeeṣe ki laala wa lati mu inu rẹ dun tabi lati ṣe iṣẹ sin in ja si asan. Fun apẹẹrẹ, ọjọ kan wa ti Jesu de Mata ati arabinrin rẹ Maria ni alejo, gẹgẹ bi akọsilẹ bibeli. Mata si mura gidigidi ni ọjọ yi lati tọju Jesu ati awọn ti o wa pẹlu rẹ. Nigba ti o si n sare siwa ati sẹyin, Maria joko ti Jesu lati kẹkọ lẹsẹ rẹ. Eyi bi Mata ninu tobẹ gẹẹ ti o fi pe akiyesi Jesu si ọrọ naa. Ṣugbọn Jesu jẹ ki o ye wipe bi o tilẹ jẹ pe o n ṣe laala lotitọ lati tọju Oun, laala rẹ ko wa ni ibamu pẹlu ifẹ Oun ni akoko naa. Eyi jasi pe Mata ko ba kọkọ farabalẹ tẹti si Jesu lati mọ nkan ti O n fẹ ki o to ma sare kaakiri. Maria ko sare kaakiri bi Mata lati tọju Jesu. Ṣugbọn Jesu sọ wipe jijoko rẹ lati kẹkọ mọ ifẹ Oun lere lori, o si tun ṣe iyebiye ju gbogbo laala ti Mata n ṣe kaakiri lọ. A tun ri apẹẹrẹ miran ni ti awọn Juu ti ko ri igbala gba bi o tilẹ jẹ pe wọn ni itara ti o ga fun Ọlọrun. Ki si ni idi? Idi ni pe itara wọn jẹ eyi ti ko ni oye ifẹ Ọlọrun. Nitorina, bi o ti wu ki itara wa ga to, niwọn igba ti ko ba ti wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, ko nitunmọ. Laala yowu ti a ba si tipasẹ eyi ṣe ko le lere lori. (Wo: Luuku 10:38-42; Roomu 10:1-3)
- Biba iṣẹ Ọlọrun jẹ: Yatọ si pe laala awọn ti itara wọn ko wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun le ja si asan, awọn gan tun le ba iṣẹ Ọlọrun jẹ. Pọọlu fi igba kan nṣe laala lati pa ijọ Jesu run nitoripe ko ni oye nkan ti o n ṣe (Galatia 1:13-14). Ọpọ losi dabi rẹ loni, ti awọn naa n fi itara ti ko ni imọ ba iṣẹ Ọlọrun jẹ tabi ṣe awọn ọmọ Ọlọrun ni ijamba. Ọjọ ti oju wọn ba si ṣi nkan ti wọn n ṣe ni wọn yoo to gba pe igbe aye basejẹ ni awọn ti n gbe. Boya awa naa tilẹ ti n ba nkan jẹ ninu ijọ Ọlọrun ti a wa tabi ni awujọ wa nitori itara wa fun un. A nilo lati fi ara balẹ kẹkọ lọdọ rẹ, ki a si fi imọ kun itara wa. Aijẹbẹ, awọn nkan ti a ni lọkan lati ṣe ni rere fun le yọri si idibajẹ ti ko ni lere lori fun wa. (Wo: Johanu 16:2)
- Ṣiṣi ilẹkun aye wa fun idajọ Ọlọrun: O tun gbọdọ ye wa pe itara ti ko ni imọ Ọlọrun ninu le ko iya jẹ wa tabi awọn ti o sunmọ wa. Fun apẹẹrẹ, a ri ka ninu bible pe akoko kan wa ti Ọba Sọọlu gbiyanju lati pa awọn ara Gibioni run nitori itara rẹ fun ilẹ Isiraẹli. Ṣugbọn itara rẹ yi lodi si ifẹ Ọlọrun. Eyi si jẹ ki iyan ọdun mẹta mu ni ilẹ naa ni akoko ti Dafidi jẹ ọba. Ki iyan yi si ba le wa si opin, a ni lati pa ọkunrin meje lati idile Sọọlu, awọn ti ko mọwọ ti ko mẹsẹ. Lafikun, Ọba Dafidi naa ṣe aṣiṣe ni igbakan nitori itara ti ko ni imọ. Eyi si yọri si iku ọmọkunrin kan ti a n pe ni Uṣa. Nitorinaa, itara ti ko ni imọ le ko iya jẹ ọpọlọpọ, pẹlupẹlu awọn alaiṣẹ. Idi si ni yi ti a fi gbọdọ ṣọra ṣe ninu iṣẹ isin wa si Ọlọrun, ki a ma ba tipasẹ itara wa da wahala silẹ fun ara wa ati fun awọn miran pẹlu. (Wo: 2Samuẹli 6:1-19 & 21:1-14; 1Kironika 13&15)
EWU TI O SORỌ MỌ IMỌ TI KO NI ITARA
Nibakannaa, o lewu ki a ni imọ ifẹ Ọlọrun ki a si ma wa ni itara lati ṣiṣẹ tọ ọ. Pataki lara awọn ewu ti o sọrọ mọ eyi ni iwọnyi:
- Aidagbasoke ninu ẹmi: Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ẹnikẹni ti o ba ni imọ Ọlọrun ati imọ ifẹ rẹ ti ko si ni itara lati ṣe amulo rẹ ko le dagbasoke ninu ẹmi. Idi si ni pe ilana Ọlọrun ni pe awọn ti o ba n ṣe amulo imọ rẹ tabi ipese rẹ nikan ni o lẹtọ lati ri nkan gba si ni ọwọ rẹ. Awọn wọnyi nikan ni Ọlọrun yoo fi ara rẹ ati ifẹ rẹ han si ni ọna ti o pọ. Ṣugbọn awọn ti ko ni itara lati mọ ọn tabi ifẹ rẹ si ko ni kuro loju kan. Idi si niyi ti a fi ri ọpọ ninu ijọ loni ti ko dagbasoke ninu nkan ti ẹmi tabi pọ si ni iwulo ninu ijọba Ọlọrun. Aye awọn miran ko tilẹ dabi pe wọn mọ Jesu rara. Idi si ni pe ko si itara ti o kojuosuwọn ninu wọn lati mọ ọn si. Boya awa naa ti wa ni ojukanna fun igba diẹ tabi fun ọpọ ọdun ninu ijọ wa. O yẹ ki a kiyesi itara wa, ki o ma ba wa jẹ pe awọn ọmọ inu wa ninu ẹmi ni yoo pada di olukọ fun wa. (Wo: Maaku 4:24-25; Heberu 5:11-14)
- Iku ti ẹmi: Ewu miran ti o sọrọ mọ aifi itara kun imọ Ọlọrun ti a ni lo ni i ṣe pẹlu iku ti ẹmi. A ri ka ninu iwe Heberu pe awọn ti a ti la loju pẹlu imọ Ọlọrun, ti wọn si ti jẹgbadun didara rẹ, ti wọn ba kọ lati ma gbe igbesẹ itara lati dagbasoke wa labẹ ewu iku ti ẹmi ati iparun. Idi si ni pe ti a ko ba ma fi gbogbo igba tun itara wa fun Ọlọrun ṣe, o ṣeeṣe ki a ba ara wa ni akoko tabi igba ti ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ifẹ rẹ yoo fi ọkan wa silẹ, ti a o si pada sẹyin. A si ri awọn ti o wa ni ipo yi loni. Ko si nkan ti ẹ fẹ ba wọn sọ lati inu ọrọ Ọlọrun ti wọn ko i ti fẹ gbọ ri. Ṣugbọn nitori pe wọn sọ itara wọn nu, Eṣu ri aye wọ inu aye wọ lọ lati yi ọkan wọn pada lẹyin Jesu. Bi o si ti ṣe ri fun Judasi ni o ma n pada ri fun iru awọn eniyan bẹ. Nitorina, a nilo lati kiyesara, ki a si ri pe gbogbo igba ni itara wa fun Ọlọrun n pọ si. Aijẹbẹ, ‘Ewu n bẹ loko Longẹ’. (Wo: Heberu 6:1-8)
- Ijiya alailere: Bibeli sọ wipe, “Nitori naa ẹni ti o ba mọ rere ṣe ti ko si ṣe e, ẹṣẹ ni fun un.” (Jemisi 4:17) O tun sọ wipe, “Ati ọmọ-ọdọ naa ti o mọ ifẹ Oluwa rẹ, ti ko si mura silẹ, ti ko si ṣe gẹgẹ bi ifẹ rẹ, oun ni a o naa pupọ.” (Luuku 12:47) Ki ni idi ti eniyan yoo fi mọ nkan ti o tọ lati ṣe ti ko si ni i ṣe? Ọkan lara rẹ ni aini itara fun rere ṣiṣe. Bi a si tun ṣe wa ri ninu bibeli, ara idi ti a ṣe sọ wa di atunbi, ti a wẹ wa mọ, ti a si ṣe wa yẹ ni ki a ba le jẹ onitara lati ṣe iṣẹ rere ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wa lati ṣe. Ti a ko ba wa ma fi itara ṣe nkan ti Ọlọrun fẹ ki a ṣe, a je wipe a n ṣilẹkun silẹ fun ijiya tabi ibawi niyẹn nitoripe a n fi ipese ati amuyẹ rẹ ṣofo. Boya idi ti a ti ṣe padanu awọn ipese tabi anfaani kan ti Ọlọrun fun wa ni pe a ti ṣọ itara wa fun un nu. A nilo lati ronupiwada, ki a si gbadura si ki O sọ itara wa ji, ki a ba le bẹrẹ si ni fi tọkantọkan ṣe ifẹ rẹ. Aijẹbẹ, nkan le buru si fun wa ju bi o ti ṣe wa bayi lọ. (Wo: Luuku 19:11-27; Efesu 2:10; Titu 2:14)
ỌRỌ IPARI
A nilo lati fi itara kun imọ Ọlọrun ati imọ ifẹ rẹ ti a ni ti a ba fẹ ma fi gbogbo igba pọ si ni isesorere ati iwulo ninu ijọba rẹ. Aijẹbẹ, laipẹ, o ṣeeṣe ki a ba ara wa labẹ oniruuru ewu, pẹlupẹlu ewu iku nipa ti ẹmi. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun tun wa ṣe ni gbogbo ibi ti a ba ku si niti imọ ati niti itara fun un ati fun ijọba rẹ. Amin.
IBEERE
- Bawo ni ẹkọ yi ṣe ṣe pataki to fun ijọ Ọlọrun?
- Ki ni o ṣe iyebiye si ọ julọ ninu awọn nkan ti o kọ ninu ẹkọ bibeli yi?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE | ỌJỌRU 12, ṢẸRẸ 2022
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
