September 2022

ÀLÀKALẸ̀ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ÀTI ÀLÀYÉ ỌJỌ́RÚ 28, ÒWEWÉ 2022 ÀKỌ́RÍ: Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (ÌJỌ ÒTÍTỌ́ BÍBÉLÌ) ÀLÀKALẸ̀ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ÀTI ÀLÀYÉ ỌJỌ́RÚ 28, ÒWEWÉ 2022 ÀKỌ́RÍ: Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ

ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 2:1-10

ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Galatia, a ri awọn nkan ti a le pe ni ẹri igbala apọsiteli yi. Gẹgẹ bi o ti ṣe fi ye wa, oun tikararẹ ti fi igbakanri gbogun ti awọn ọmọ Ọlọrun ati iyinrere Jesu nitori itara rẹ fun ẹsin awọn Juu ati ofin Mose. Ti oun yi kanna, ti o ti kọkọ fi gbogbo okun ati agbara gbiyanju lati pa iyinrere Jesu run, ba wa n lọ kaakiri lati polongo iyinrere ti o ti fi igbakanri tiraka lati parun, o yẹ ki a mọ pe o gbọdọ ni idi. Idi naa si ni pe o ti ba Jesu pade, o si ti di ẹni igbala. Iyinrere ti Jesu si wa gbe le lọwọ ni o n waasu kaakiri ibi gbogbo ti o ba lọ. Iyinrere yi naa ni o waasu si awọn ara Galatia ti wọn fi di ẹni igbala. Ṣugbọn, bi o ti jẹ ki o ye wa ninu lẹta rẹ yi si wọn, awọn Juu kan ti wa sọdọ wọn, wọn si ti bu ẹnu atẹ lu iyinrere otitọ ti wọn tẹwọgba, ti o si sọ wọn di ẹni igbala ati olododo niwaju Ọlọrun. Awọn yi n jẹ ki o ye wọn pe ayafi ti wọn ba pa awọn abala ofin Mose kan mọ, paapaa julọ eyi ti o n sọrọ nipa ikọla abẹ, wọn ko ni di ẹni igbala, bi o tilẹ jẹ wipe wọn ti gba Jesu gbọ. Eyi ni o fa ti Pọọlu fi kọ lẹta yi si wọn, ki o ba le pe wọn pada sọdọ Jesu, ẹni ti o gba wọn la.

ÌFÌDÍMÚLẸ̀ ÌYÌNRERE ÒTÍTỌ́ Ki Pọọlu ba wa le fi idi otitọ iyinrere ti o n waasu mulẹ fun awọn ara Galatia yi, o tẹsiwaju ninu lẹta yi lati jẹ ki wọn mọ lara awọn igbesẹ ti o ti gbe sẹyin lori rẹ. Irufẹ igbesẹ wo ni o gbe? O fi akoko kan ṣe ipade pẹlu awọn ti o ti jẹ apọsiteli ṣiwaju rẹ, ti wọn si jẹ opomulero laarin awọn apọsiteli yoku lati fi iyinrere ti o n waasu laarin awọn Keferi han wọn. Ki wa ni idi ti o fi ṣe eyi? Ṣe ẹru n ba pe iyinrere ti o n waasu ko dangajia to ni, ti o si nilo alaye ti o peye si i lati ọdọ wọn? A bi ṣe o fẹ oriyin lati ọdọ wọn ni? Bi o ti ṣe fi han wa ninu lẹta yi, ko ki i ṣe nitori pe ẹru n ba tabi nitori ki wọn ba le gbe oriyin fun ni o ṣe tẹ́ koko iyinrere ti o n waasu siwaju wọn. Idi mẹta pataki ni o ṣe ṣe eyi, bi a ti ri ninu awọn ọrọ wọnyi:

“Lẹyin ọdun mẹrinla, nigba naa ni mo tun lọ si ilu Jerusalẹmu pẹlu Banaba, mo si mu Titu lọ pẹlu mi. Mo si lọ nitori ohun ti Ọlọrun fi han mi, mo si fi iyinrere naa ti mo n waasu laarin awọn Keferi ye awọn ti o jẹ ẹni nla ninu wọn, ẹyiini ni ikọkọ, ki emi ma baa sare, tabi ki o ma baa jẹ pe mo ti sare lasan. Ṣugbọn a ko fi agbara mu Titu ti o wa pẹlu mi, ẹni ti i ṣe ara Heleni, lati kọla: Ati nitori awọn eke arakunrin ti wọn yọ wọ aarin wa gẹgẹ bi amí lati mọ eredi ominira eyi ti a ni ninu Kirisiti Jesu, ki wọn ki o le mu wa wa sinu ide ilana ẹsin Juu. Awọn ẹni ti a ko fun ni anfaani lati gbọ ọrọ wọn fun iṣẹju kan; ki ẹyin o le maa tẹ siwaju ninu otitọ iyinrere naa. Ṣugbọn ni ti awọn ti wọn dabi ẹni-nla, ohunkohun ti o wu ki wọn jẹ, ko jẹ nnkan kan fun mi: Ọlọrun kii ṣe ojusaaju ẹnikẹni: ani awọn ti o dabi ẹni-nla naa, ko kọ mi ni nkankan.” (Gàlátíà 2:1-6)

Pẹlu akọsilẹ Pọọlu yi, a ri pe idi akọkọ ti o ṣe lọ ṣe ipade ikọkọ pẹlu awọn ti o jẹ bi opomulero laarin awọn ti o jẹ apọsiteli saaju rẹ ni pe Ọlọrun kọ si lati ṣe bẹẹ. O sọ wipe oun lọ ni ibamu pẹlu ifihan ti Ọlọrun fun oun. Ki wa lo le fa a ti Ọlọrun fi sọ fun apọsiteli yi lati la ṣe ipade pẹlu awọn apọsiteli Oluwa miran, ki o si tẹ iyinrere ti o n waasu kaakiri kalẹ fun wọn lati ṣe agbeyẹwo rẹ? Nkan kan ti o le fa ni pe Ọlọrun fẹ ki wọn wa ni iṣọkan; Ọlọrun fẹ ki gbogbo wọn ri ara wọn gẹgẹ bi ọkan ninu Kirisiti. Niwọn igba ti o jẹ wipe Jesu Kirisiti kan naa ni wọn jọ gbagbọ fun igbala ẹmi wọn, ti o si tun jẹ wipe iyinrere rẹ kan naa ni wọn dijọ n polongo, ko si nkan naa ti o ni ki wọn ma wa ni irẹpọ.

Yatọ si eyi, ko si iyapa ninu Kirisiti. Ara kan naa ni gbogbo awọn ti o gbagbọ ninu rẹ. Nitori naa, bi awa ti a gbagbọ ninu rẹ ko tilẹ si ni ilu kan naa tabi ki a dijọ ma jọsin papọ, eyi ko tunmọ si pe iyapa wa laarin wa tabi pe a ko ki i ṣe ara kan naa mọ. A wa gbọdọ jẹ ki eyi ki o ye wa daradara, ki a si ma sọ ara wa di ọta awọn ọmọ Ọlọrun miran nitori pe wọn ko jọsin pẹlu wa tabi nitori pe wọn ko tẹle awọn adari kan ti awa n tẹle. (Wo: 1Kọrinnti 3 & 12)

Idi keji ti Pọọlu tun ṣe lọ ni wipe oun funrarẹ fẹ ri aridaju pe iyinrere ti o n waasu kaakiri ko yatọ tabi lodi si eyi ti awọn ti o ti di apọsiteli Oluwa ṣaaju rẹ n waasu. Bi o ti ṣe fi ye wa ninu abala lẹta yi ti a n gbe yẹwo ati eyi ti a ti gbe yẹwo sẹyin, ko si ẹnikẹni ti o kọ ni iyinrere ti o n waasu; Jesu funrarẹ ni O fun ni ifihan iyinrere yi, ti O si tun kọ ọ ni awọn nkan ti o n ṣe, ti o si n sọ. Nitorina, o mọ daju-ṣaka pe iyinrere otitọ ni o n waasu. Amọ ẹru tun n ba ni ọna kan pe ti awọn ti o jẹ apọsiteli ṣaaju rẹ ba ti lọ pa iyinrere ti Jesu gbe le wọn lọwọ ti ṣegbẹ kan, ti wọn si n waasu adamọdi iyinrere rẹ, o ṣeeṣe ki laala rẹ laarin awọn Keferi ja si asan. Idi si ni wipe yoo rọrun fun awọn eniyan lati gba awọn ti o jẹ apọsiteli Oluwa saaju rẹ gbọ ju lọ. Eyi si le jẹ ki gbogbo iṣẹ ti o ti ṣe silẹ parun, bi o tilẹ jẹ wipe o ṣe awọn iṣẹ yi lori otitọ Jesu. Nibakan naa, o yẹ ki awa na kọbiara si ohunkohun ti o le pa iṣẹ iranṣẹ wa lara, ki a si mojuto. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a ṣe laala lasan ninu ijọba Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ wipe ori ododo ni iṣẹ ti a n ṣe da le.

Idi kẹta ti Pọọlu ṣe tun ṣe ipade pẹlu awọn apọsiteli yi ni lati fi opin si gbogbo awuyewuye awọn Juu ti wọn n lọ sọdọ awọn Keferi ti o gba Jesu gbọ, ti wọn si n gbiyanju lati fi wọn si abẹ ide ilana ẹsin awọn Juu (Iṣe Apọsiteli 15:1-34). Nkan ti o wa lọkan rẹ si ni pe ki o fi idi rẹ mulẹ pe awọn apọsiteli Jesu yoku ko lọwọ si fifi awọn Keferi ti o gbagbọ si abẹ ilana ẹsin awọn Juu, bi o tilẹ jẹ wipe Juu ni awọn naa. Niwọn igba ti o ba si ti fi idi eyi mulẹ, awọn Keferi ti o gbagbọ yoo le mu iduro wọn ninu Jesu ṣinṣin, wọn ko si ni gba ibọde awọn Juu yi ti o n tiraka lati sọ iyinrere Jesu di alailagbara. Eyi si jẹ ki o ye wa pe iduro-ṣinṣin awọn ti o gbagbọ ninu Jesu jẹ Pọọlu logun gidigidi. Idi si ni yi ti ko fi fi akoko kankan fi aye gba awọn ti o gbiyanju lati fi ẹnu tẹnbẹlu tito Jesu fun igbala awọn eniyan ati fun itẹwọgba wa niwaju Ọlọrun.

Wayi o, bawo wa ni ipade Pọọlu pẹlu awọn apọsiteli ti o pade yi ṣe lọ? Didun ni ọsan ipade naa so, gẹgẹ bi akọsilẹ rẹ. Akọkọ, o jẹ ki o ye wa pe bi o tilẹ jẹ wipe oun mu Titu lọwọ, ẹni ti o jẹ Keferi ti o gbagbọ, awọn apọsiteli yi, Jemiisi, Peteru ati Johanu, ko fi tipa-tipa mu un lati kọ ila abẹ. Eyi si n fi han pe awọn kọ ni o ran awọn Juu ti o n lọ kaakiri lati sọ wipe awọn Keferi ti o gbagbọ gbọdọ kọ ila abẹ, ni ibamu pẹlu ofin Mose, ki wọn to di ẹni igbala.

Siwaju si, o tun sọ eyi nipa ipade naa: “Ṣugbọn kaka bẹẹ, nigba ti wọn rii pe Ọlọrun ti fi iṣẹ iyinrere ti awọn alaikọla le mi lọwọ, bi a ti fi iṣẹ iyinrere ti awọn ikọla le Peteru lọwọ. Nitori Ọlọrun, ẹni ti o ṣiṣẹ ninu iṣẹ iranṣẹ Peteru gẹgẹ bi Apọsiteli si awọn Juu, oun kan naa ni o ṣiṣẹ ninu iṣẹ iranṣẹ mi gẹgẹ bi Apọsiteli si awọn alaikọla. Jakọbu, Peteru ati Johanu, awọn ẹni ti o dabi ọwọn, fun emi ati Banaba ni ọwọ ọtun idapọ nigba ti wọn ri oore-ọfẹ ti a fi fun mi, wọn si gba pe ki awa naa tọ awọn alaikọla lọ, nigba ti awọn naa lọ sọdọ awọn Juu. Ohun gbogbo ti wọn beere fun ni wi pe ki a maa ranti awọn talaka, ohun kan naa gan-an ti mo n lakaka lati ṣe.” (Galatia 2:7-10)

Pẹlu nkan ti o sọ yi, daju-ṣaka ni pe awọn apọsiteli yi ti Pọọlu pẹlu Banaba ba ṣe ipade tẹwọgba wọn tọwọ-tẹsẹ. Nigba ti wọn gbọ iyinrere ti Pọọlu waasu, wọn ri wipe ko yatọ rara si nkan ti Jesu gbe le wọn lọwọ. O tilẹ gbọdọ ya wọn lẹnu pe ọkunrin yi ti ko wa pẹlu wọn nigba ti Jesu wa ninu aye yi mọ gbogbo nkan ti awọn mọ, titi kan nkan ti o ṣẹlẹ ni alẹ ọjọ ti a mu Jesu, ti a si kan mọ agbelebu. Ni kukuru, wọn fi tayọtayọ gba Pọọlu gẹgẹ bi apọsiteli Oluwa ti a ran si awọn Keferi. Wọn si gba oun ati Banaba ni iyanju lati tẹramọṣẹ ati lati maa ranti awọn alaini ni ibi gbogbo ti wọn ba lọ.

Nitorina, iyinrere Pọọlu ko yatọ rara si iyinrere awọn apọsiteli Jesu yoku. Peteru tilẹ sọ eyi lati kin ọrọ Pọọlu lẹyin ninu lẹta rẹ keji, ori ikẹta, lati ẹsẹ ikarundinlogun: “Ki ẹ si maa ka a si pe, suuru Oluwa wa igbala ni; bi Pọọlu pẹlu arakunrin wa olufẹ, ti kọwe si yin gẹgẹ bi ọgbọn ti a fi fun un. Bi o ti n sọrọ nnkan wọnyi pẹlu ninu iwe rẹ gbogbo ninu eyi ti ohun miiran ṣoro lati ye ni gbe wa, eyi ti awọn ope ati awọn alaiduro nibikan ń lọ́, bi wọn ti n lọ iwe-mimọ iyoku , si iparun ara wọn.” (2Peteru 3:15-16)

Njẹ o ri bayi pe awọn apọsiteli yoku gba Pọọlu gẹgẹ bi apọsiteli otitọ, wọn si tun gba ọrọ rẹ gẹgẹ bi otitọ ọrọ Ọlọrun. Ti a ba ri ẹnikẹni loni, bi a ti ri ni igba aye Pọọlu, ti o sọ pe ti Pọọlu bawo, a jẹ wipe ope ni ẹni naa, gẹgẹ bi ọrọ Peteru. O ṣi wa ṣeni laanu pe a ri irufẹ awọn wọnyi kaakiri inu awọn ijọ wa loni, ti wọn ro wipe ọrọ Pọọlu tako ọrọ Jesu ati ọrọ awọn apọsiteli yoku. Eṣu ni o si n ya awọn wọnyi lo lati di iyinrere Jesu lọwọ ati lati fi awọn ọmọ Ọlọrun si abẹ igbekun ẹsin awọn Juu ati awọn nkan miran ti o fara pẹ ẹ. A ko wa gbọdọ fi aye gba wọn lati fiwa tabi lati fi awọn ọmọ Ọlọrun miran ti a jọ n ṣepọ sinu ide wọn.

ỌRỌ IPARI Pọọlu tiraka, ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, lati fi idi rẹ mulẹ nigba ti o wa laye pe oun ati awọn apọsiteli Jesu yoku ko tako ara wọn lọna kankan lori iyinrere Jesu ati igbagbọ ninu rẹ. Awa naa wa gbọdọ ri daju pe igbagbọ wa, iwaasu wa ati iṣẹ iṣin wa, bi o ti wu ki o dawa loju to, ko tako tabi yatọ si nkan ti awọn apọsiteli yi gbe kalẹ fun wa lọna kankan. Aijẹbẹ, a ti rin jin na si Jesu. Ti a ko ba si ṣọra, ki a si pada ni kiakia sọdọ rẹ, ere ije igbagbọ wa di dandan ki o ja si asán.

IBEERE – Bawo ni o ṣe ṣe pataki si fun wa lati ri daju pe igbagbọ wa ninu Kirisiti ati iṣẹ isin wa ninu rẹ wa ni ibamu pẹlu alakalẹ awọn apọsiteli rẹ ti o ti kọja lọ?

Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ÀLÀKALẸ̀ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ÀTI ÀLÀYÉ ỌJỌ́RÚ 28, ÒWEWÉ 2022 ÀKỌ́RÍ: Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ Read More »

Má ṣe jà wọ́n lólè | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Owéwè 25, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 21

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Òwewè 2022. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun pa ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ ati ohun gbogbo tí Ó ti yàn fun igbadun rẹ lọdun yi mọ fun ọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Mo gba adura yi fun ọ nitori pe o wa ni ibamu pẹlu ọrọ Dafidi ninu Saamu rẹ ti o wi pe, “Oluwa ni ipin ini mi, ati ti aago mi: iwọ ni o mu ipin mi duro.” (Saamu 16:5) Tani o pa ipin Dafidi mọ fun un? Ọlọrun! Ta si ni ẹnikan ṣoṣo naa ti o le pa ipin wa, èrè wa, iṣẹ́ wa, ipò wa, ayọ̀ wa, alaafia wa, ibaṣepọ wa ati aye wa mọ fun wa? Ọlọrun! Idi si ni yi ti a fi gbọdọ kọ lati ma fi ojoojumọ ko ohun gbogbo ti a ni ati ti o jẹmọ aye wa le lọwọ.

Amọ ṣa o, bi a ti ṣe n fi igbekẹle wa sinu Ọlọrun lati pa ipin wa ninu aye yi mọ fun wa ati lati ri pe a ko ja wa lole tabi yan wa jẹ, awa naa gbọdọ ri daju pe a ko ma ji nkan awọn miran tabi ja wọn lole. Ọrọ Ọlọrun sọ wipe, “Ki ẹni ti n jale ma ṣe jale mọ: ṣugbọn ki o kuku maa ṣe laalaa, ki o maa fi ọwọ rẹ ṣiṣẹ ohun ti o dara, ki oun ki o le ni lati pin fun ẹni ti o ṣe alaini.” (Efesu 4:28) Nitorina, ti o ba n ja awọn ti o wa ni ayika rẹ lole lọnakọna, o ni lati fi opin si.

O si yẹ ki o mọ pe a ko nilo lati gbe ibọn ki a to ji nkan awọn eniyan. Igbakigba ti a ba mu fun ara wa ohunkohun ti a ko fun wa ni aye, aṣẹ tabi oore-ọfẹ lati mu lati ọdọ elomiran, nṣe ni a n jale. Lafikun, igbakigba ti a ba kọ lati san owo ọya awọn eniyan, ile-iṣẹ tabi ijọba fun nkan ti wọn ba wa ṣe tabi iṣẹ ti wọn ṣe fun wa, nṣe ni a n ja wọn lole. O si di dandan ki awọn nkan wọnyi pa ipamọ awọn nkan ti o jẹ ti wa lara ni ọna kan tabi omiran.

Siwaju si, bi a ti ṣe n fi igbẹkẹle wa sinu Ọlọrun lati pa ipin wa mọ fun wa, a tun nilo lati ṣo ara wa lati ma ja a lole. Bawo ni a ṣe le ja Ọlọrun lole? Ṣe nipa mimu owo fun ara wa ninu apo ọrẹ ni tabi nipa fifọ ilẹ ijọsin, ki a si ko owo tabi awọn ohun elo ti a ba ba nibẹ lọ ni? Bẹẹni, nṣe ni a n ja Ọlọrun lole ti a ba ṣe ọkankan ninu awọn eyi. Eyi yoo si pa ipamọ wa ati ipamọ awọn nkan ini wa lara. Ṣugbọn, jija Ọlọrun lole le ju awọn nkan wọnyi lọ. Jija Ọlọrun lole tun ni i ṣe pẹlu ki a fi awọn nkan ti o yẹ ki a fun awọn iranṣẹ rẹ ti O ran si wa lati tọju wa pamọ fun ara wa.

Ki ni idi ti Ọlọrun fi pe awọn Juu igba aye Málákì ni ole? Ṣe nitori pe wọn fọ ilẹ iṣura Tẹmpili ni, ti wọn si ji awọn nkan ti o wa nibẹ? Rara! Idi ni pe wọn kọ lati fun awọn alufa Ọlọrun ti o n tọju wọn ni idamẹwa ati ọrẹ ti o yẹ fun itọju wọn. Ki wa ni idi ti a fi sọ fun wọn pe ki wọn ma fun awọn alufa yi ni idamẹwa ati ọrẹ wọn? Idi ni pe Ọlọrun ko fun wọn ni ipin kankan ni ilẹ wọn ati wipe O ti pa a laṣẹ fun wọn lati fi ara wọn jin lati sin awọn eniyan yi. Nitorina, nipa kikọ lati fun awọn alufa yi ni awọn nkan ti o tọ si wọn, awọn eniyan wọnyi n ja wọn lole ni, wọn si tun n ja Ọlọrun ti O yan wọn lati sin wọn lole pẹlu. Abalajọ ti awọn ati awọn nkan ini wọn ko ṣe wa ni ipamọ kuro lọwọ iṣẹ awọn ajẹnirun.

Ni bakan naa, Oluwa ti pa a laṣẹ fun awa naa lati tọju awọn ti O ran lati mojuto wa pẹlu nkan ini wa. Nitorina, nigba ti O n ran awọn apọsiteli rẹ jade lati waasu, ko fun wọn ni owo kankan lati mu lọwọ lọ. Lafikun, ko fi owo kankan silẹ fun wọn nigba ti O n goke wọn inu awọn ọrun lọ. Idi si ni pe O n reti ki awọn ti wọn yoo ṣiṣẹ sin lati tọju wọn. Ọrọ rẹ ni eyi: “Owo ọya alagbaṣe tọ si.” Nitorina, ti awọn ti wọn n ṣiṣẹ sin ko ba tọju wọn, a jẹ wipe wọn n ja wọn lole niyẹn. O si di dandan, bi Oluwa wa ti sọ siwaju, ki eyi ma jẹ ki awọn Ibukun ti o sorọ mọ iṣẹ iranṣẹ wọn sọkale ni kikun sori aye wọn. (Wo: Luuku 10:1-7; 1Kọrinnti 9:14; Galatia 6:6)

Nitorina, ti a ko ba mu fifi fun awọn iranṣẹ Ọlọrun wa lati gbe wọn ro ni ọkunkundun (AWỌN PERETE NI WỌN SI SABA MA N MU EYI NI ỌKUNKUNDUN NI ỌPỌ AWỌN IJỌ WA), nṣe ni a n ja wọn lole, ti a si tun n ja Ọlọrun lole pẹlu. Bawo wa ni a ṣe fẹ reti pe ki awọn Ibukun iṣẹ iranṣẹ wọn ṣiṣẹ ni kikun ninu wa tabi reti pe ki awọn nkan ti Ọlọrun fun wa wa ni ipamọ kuro lọwọ awọn ajẹnirun? Eyi gan si jẹ alaye fun bi awọn ọmọ Ọlọrun ko ki ṣe fi taratara di ọlọrọ ninu awọn ijọ ti wọn ki ti i fi tayọtayọ tọju awọn adari wọn ni ọna ti o peye. Irufẹ awọn ara yi le fi ara wọn jin lotitọ lati takete si ẹṣẹ ati lati ma rin ninu ododo. Ṣugbọn wọn ko ni lu aluyọ bi awọn ọmọ Ọlọrun miran ti wọn ko fi ara wọn jin lati ma gbe igbe aye ododo bi ti wọn ṣugbọn ti wọn fi ara wọn jin fun titọju awọn adari wọn.

Ni kukuru, kokọ nkan ti a n sọ ni pe ti o ba n ja Ọlọrun lole nipa jija awọn iranṣẹ rẹ lole awọn nkan ti o yẹ ki o ma a fifun wọn tabi ṣe fun wọn, yoo pa ifarahan ati ipamọ iṣoriire rẹ lara ni ọna ti ko dara. Nitorina, ronupiwada bayi, ki o si bẹrẹ si ni ṣe ohun ti o tọ. Aijẹbẹ, Satani ko ni ye ri anfaani lati ja iwọ naa lole.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí ó lárinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Má ṣe jà wọ́n lólè | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Owéwè 25, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 21 Read More »

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 1:11-24 | ÀLÀKALẸ̀ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ÀTI ÀLÀYÉ | ỌJỌ́RÚ 21, ÒWEWÉ 2022

DOWNLOAD THE PDF FILE HERE

ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kọja lọ ninu iwe Galatia, a ri wipe lẹta ibawi ni lẹta yi ti Pọọlu kọ si awọn ara Galatia jẹ. Ki ni o si fa? Nkan ti o fa naa ni wipe ko pẹ si igba ti apọsiteli yi kuro ni ọdọ awọn ara Galatia yi ti wọn fi pa iyinrere ti o mu tọ wọn wa, ti wọn si gbagbọ, ti si ẹgbẹ kan, ti wọn si wa dirọ mọ iyinrere miran ti ko ki i ṣe iyinrere rara. Ki si ni iyinrere ti wọn dirọ mọ yi da le lori? Bi a o ti ṣe ri ninu lẹta yi, o da leri pipa awọn abala ofin Mose kan mọ, paapaa julọ eyi ti o ni ṣe pẹlu kikọ ilá abẹ́. Pọọlu wa n jẹ ki o ye wọn pe kikọ iyinrere Jesu Kirisiti ti a mu tọ wọn wa silẹ ko yatọ si kikọ Jesu Kirisiti Oluwa wa funrarẹ silẹ ati wipe egbe ni fun ẹnikẹni ti o ba wa nidi ki a ma polongo iyinrere miran ti o yatọ si eyi ti o fi Jesu han bi ẹnikan ṣoṣo ti Ọlọfun fa kalẹ fun igbala ati iṣelogo awọn ọmọ eniyan.

ẸRI IGBALA PỌỌLU
Ninu ẹkọ eyi ti a wa mu yi, ẹwẹ, Pọọlu jẹ ki o ye awọn ara Galatia ti o kọ iwe yi si irufẹ iyinrere ti o n tan kalẹ ni ibi gbogbo ti o n lọ ati ọna ti o gba gba iyinrere yi. O tun jẹ ẹri ranpẹ lori igbala rẹ ati iha ti awọn ti o mọ ọn tabi gbọ nipa rẹ ki o to di ẹni igbala kọ si iṣẹlẹ igbala rẹ ati awọn igbesẹ ti o bẹrẹ si ni gbe lẹyin ti o di ẹni igbala. Iwọ naa wo awọn nkan ti o sọ:

“Ṣugbọn, ara, mo fẹ ki ẹ mọ pe iyinrere ti mo ti waasu kii ṣe nipa ti eniyan. Nitori kii ṣe lọwọ eniyan ni mo ti gba a, bẹẹ ni a ko fi kọ mi, ṣugbọn nipa ifihan Jesu Kirisiti. Nitori ẹyin ti gburo igbe-aye mi ti atijọ, nigba naa ti mo n tẹle ẹsin awọn Juu, bi mo ti ṣe inunibini si ijọ eniyan Ọlọrun re kọja ala, ti mo si ba a jẹ. Mo si ta ọpọlọpọ awọn ojugba mi yọ ninu ẹsin awọn Juu laarin awọn ara ilu mi bakan naa, mo ni itara ọpọlọpọ si ofin atọwọdọwọ awọn Baba mi. Ṣugbọn nigba ti o wu Ọlọrun, ẹni ti o ya mi sọtọ lati inu iya mi wa, ti o si pe mi nipa oore-ọfẹ rẹ, Lati fi ọmọ rẹ han nipasẹ mi ki emi le maa waasu rẹ laarin awọn Keferi loju kan naa emi ko ba ara ati ẹjẹ gbimọ pọ. Bẹẹ ni emi ko goke lọ si Jerusalẹmu tọ awọn ti ṣe Apọsiteli ṣaaju mi; ṣugbọn mo lọ si Arebia, mo si tun pada wa si Damasiku. Lẹyin ọdun mẹta, mo lọ si ilu Jerusalẹmu lati lọ ki Peteru, mo si gbe ọdọ rẹ fun ọjọ mẹẹdogun. Ṣugbọn emi ko ri awọn Apọsiteli miiran, bi ko ṣe Jemisi arakunrin Oluwa. Otitọ ni awọn ohun ti mo n kọ si yin wọnyi, kiyesi i, Niwaju Ọlọrun emi ko ṣeke. Lẹyin naa ni mo si lọ si ẹkun Siria ati ti Siliṣia; Awọn ijọ ti o wa ninu Kirisiti ni Judia ko si mọ oju mi: Kiki ohun wọn-ọn-ni ti awọn eniyan n sọ ni wọn ti gbọ wi pe Ẹni ti o ti n ṣe inunibini si wa ri, ti n waasu igbagbọ naa nisinsinyi ti oun n bajẹ nigba kan ri. Wọn si yin Ọlọrun logo nitori mi.” (Galatia 1:11-24)

Pẹlu awọn nkan ti Pọọlu sọ silẹ yi, akọkọ, a ri dimu pe ẹnikẹni ko kọ tabi ṣalaye iyinrere ti o n waasu fun. Jesu Oluwa wa funrarẹ ni O fi awọn nkan wọnyi han an, ti O si fi oye wọn ye e. Ara idi niyi ti o fi sọ wipe lẹyin igba ti oun gbagbọ tan, oun ko lọ ba ọkankan lara awọn ti o jẹ apọsiteli ṣaaju rẹ. Dipo eyi, nṣe ni o gba Arebia lọ. Lẹyin ọdun melokan si lo to ṣẹ ẹ lọ ki Peteru ati Jemisi, arakunrin Jesu Oluwa.

Nitorinaa, awọn ti o ti jẹ apọsiteli ṣaaju Pọọlu kọ ni o kọ ni iyinree ti o n tan kalẹ. Awọn kọ ni wọn ṣe alaye igbagbọ, ireti ati ifẹ ninu Jesu fun. Awọn kọ ni wọn kọ ni bi a ti ṣe le di olododo, ki a si tun ma gbe igbe aye olododo. Awọn kọ ni wọn ṣalaye fun nipa iku, ajinde ati igbasoke Jesu. Awọn kọ ni wọn kọ nipa ipadabọ Jesu ati igbasoke awọn ayanfẹ rẹ. Bẹẹ si ni awọn kọ ni wọn ṣalaye fun nipa ounjẹ alẹ Oluwa ati awọn nkan ti o ṣẹlẹ lalẹ ọjọ ti a kọkọ jẹ ounjẹ yi. A si ri pe o mọ gbogbo awọn nkan wọnyi daju, o si tọka si wọn ninu awọn lẹta rẹ si ijọ Ọlọrun. Bawo lo ṣe wa mọ wọn? Nipasẹ ifihan Jesu Kirisiti ni! (Wo: 1Kọrinnti 15:3-7; 2Kọrinnti 12:1-4)

Ṣe nkan ti Jesu wa fi han apọsiteli yi, ti O si tun kọ lodi tabi yatọ si awọn nkan ti O ti kọ ati fi han awọn aṣiwaju rẹ ninu igbagbọ? Rara o! Nitorina, ẹnikẹni ti o ba n sọ wipe a fi awọn nkankan han oun nipa igbagbọ ninu Jesu tabi lori iyinrere rẹ gbọdọ ri daju pe ohun ti a fi han wa ni ibamu pẹlu awọn nkan ti Jesu fa le awọn aṣiwaju wa ninu igbagbọ lọwọ. Aijẹbẹ, irọ pata-porongodo ni ohun yowu ti a fi han an.

Nkan keji ti Pọọlu tun mẹnuba ninu awọn ẹsẹ lẹta rẹ yi, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, ni ẹri igbala rẹ. Ki si ni idi? O fẹ ki o ye awọn ara Galatia ti o kọ iwe yi si pe ohun funra oun ti kọkọ gbe ẹsin awọn Juu ka ori nigbakan ri, ti oun si tayọ gidigidi ninu rẹ ju awọn ti o jẹ akagbẹ rẹ lọ. Yatọ si eyi, o tun ti ṣe inunibini awọn ọmọ Ọlọrun ti o gbagbọ ninu Jesu ri, ti o si mura tan lati pa igbagbọ ninu Jesu run.

Ki lo wa fa ti o fi pa gbogbo nkan wọnyi ti, ti o si bẹrẹ si ni waasu ni ijẹri nkan ti o ti fẹ parun tẹlẹ? Ifarahan Jesu Kirisiti si ni o fa. Jesu, ni ọjọ kan ti ọkunrin yi n lọ si Damasiku lati tun lọ ti awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa nibẹ mọle, fi ara rẹ han lati jẹ ki o mọ wipe igbe aye ti a ya a sọtọ lati inu iya rẹ wa lati gbe kọ ni o n gbe. A ya a sọtọ lati inu iya rẹ ki o ba le fi Jesu han si gbogbo araye gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, iyẹn ninu ọrọ, ninu iwa ati ninu iṣe rẹ. Eyi si lo fa ti oun naa fi bẹrẹ si ni fi gbogbo okun ati agbara rẹ jẹ ki awọn eniyan mọ pe ko si igbala ninu ẹlomiran, ayafi ninu Jesu. Nṣe si ni inu gbogbo awọn ti o mọ tẹlẹ, ti wọn si gbọ si ọrọ yi bẹrẹ si ni dun, ti wọn si n gbe orukọ Ọlọrun ga lati ara rẹ. (Wo: Iṣe Apọsiteli 9:1-30, 22:1-21; 26:1-32)

Njẹ awọn ti o mọ awa naa tẹlẹ tilẹ ni idi loni lati ma gbe orukọ Ọlọrun ga nipasẹ wa bi? Njẹ wọn tilẹ le sọ daju-ṣaka pe iyatọ wa gedegbe laarin igbe aye ti a n gbe ki a to di atunbi ati igbe aye ti a n gbe nisinsinyi ti a sọ wipe a ti di atunbi? Awọn eniyan n fi ogo fun Ọlọrun nitori aye tuntun ti Pọọlu n gbe lẹyin ti o ti di atunbi. Ti ko ba wa si ẹni ti o n fi ogo fun Ọlọrun lori aye wa, nṣe ni o yẹ ki a yẹ ara wa wo.

Wayi o, ti Pọọlu ba wa n jẹ ki o ye awọn eniyan pe Jesu ti to fun igbala wọn ati wipe wọn ko nilo lati pa ohunkohun ninu ofin Mose mọ ki wọn to di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun, o mọ nkan ti o n sọ. Ko sọ eyi nitori pe ko ni imọ rara tabi imọ to ninu ofin Mose. O ni imọ ti o jinlẹ ninu ofin Mose. O tilẹ ti fi igba kan jẹ ọkan lara awọn Farisi ri (Iṣe Apọsiteli 23:6-8; Filipi 3:5). Ṣugbọn Ọlọrun ti jẹ ki o ni oye ti o jinlẹ ninu ọmọ rẹ Jesu Kirisiti. Idi si ni yi ti o fi n lo gbogbo itara lati jẹ ki o ye awọn eniyan, paapaa julọ awọn Juu pe wọn ko nilo lati pa abala ofin Mose kankan ma lati di ẹni igbala ati ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun. Jesu Kirisiti ati iṣẹ ti Ọlọrun ran wa ṣe ti to fun wọn.

O wa ṣeni laanu pe awọn ara Galatia, ni akoko ti a kọ lẹta yi si wọn, ko ni oye awọn nkan wọnyi. Nitorina, wọn ti gbe igbagbọ ninu Jesu gẹgẹ bi ọna lati jẹ ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun ju si ẹgbẹ kan, wọn si ti bẹrẹ si ni tẹle ofin Mose ati awọn ilana ti o wa ninu rẹ. Pọọlu wa nilo lati mu wọn pada wa sinu otitọ pẹlu lẹta yi, ki wọn ma ba di ẹni itanu ni ikẹyinkẹyin.

Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Bi o ti ṣe ri pẹlu awọn ara Galatia ni akoko ti Pọọlu kọ lẹta si wọn naa ni o ti ṣe ri pẹlu ọpọ ijọ Ọlọrun loni. Awọn naa ti gbe igbagbọ ninu Jesu gẹgẹ bi ọna lati di ẹni igbala ati ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun ju sẹgbẹ kan, wọn si ti dirọ mọ ofin Mose. Nkan ti ko si ye wọn ni pe ti ofin Mose ba le fun awọn eniyan ni igbala pipe, ki o si sọ wọn di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun, iwasaye Jesu, iku rẹ ati ajinde rẹ ko ni itunmọ niyẹn. Amọ awọn nkan yi ni itumọ ti o ga, ti a si gbọdọ dirọmọ. Aijẹbẹ, bi awọn ara Galati ṣe tipasẹ ailoye otitọ ọrọ Ọlọrun kẹyin si Jesu naa ni awa naa yoo ṣe kẹyin si, bi o tilẹ jẹ wipe a n ṣe oniruuru nkan ni orukọ rẹ. Boya a tilẹ ti kọ ẹyin si?

IBEERE

  • Bawo ni ijẹri igbala awọn ọmọ Ọlọrun ṣe wulo si?
  • Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 1:11-24 | ÀLÀKALẸ̀ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ÀTI ÀLÀYÉ | ỌJỌ́RÚ 21, ÒWEWÉ 2022 Read More »

Lílé ìṣẹ́ kúrò nínú ìjọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal |Ọjọ́: Owéwè 11, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 20

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Owéwè 2022. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun kun ọkan rẹ pẹlu ọgbọn ti o peye lati rin pẹlu awọn ọmọ rẹ ti o wa ninu aye rẹ pẹlu ifẹ ati oye, ki ibaṣepọ rẹ pẹlu wọn ba le ma fi gbogbo igba yọri si iwuri ati ìṣoríire fun wọn dipo ikoro. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ko si talaka kankan ninu ijọ ni awọn ọjọ wọnni. Ki si ni idi? Luuku sọ fun wa pe idi ni pe, lati igba de igba, awọn ọmọ ijọ ti wọn ni nkan ini n ta wọn, wọn si n mu owo ti wọn pa nidi rẹ wa fun awọn Apọsiteli Oluwa lati pin fun awọn ti o ṣe alaini. Eyi tunmọ si pe ko ki i ṣe ipade akanṣe adura ati awẹ tabi ipade ìfowólọ́lẹ̀ ni o fọ ìṣẹ́ danu kuro laarin awọn ọmọ Ọlọrun ni igba yẹn. Dipo eyi, nipasẹ lilawọ ni a ṣe fọ ìṣẹ́ danu kuro laarin wọn. Ki lo si fa ti awọn ara ti wọn lawọ yi ṣe lawọ bi wọn ti ṣe lawọ? Ifẹ Kirisiti ninu wọn ni o fa. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 4:34-35; 2Kọ́rínntì 5:14)

Ṣugbọn ṣe lilawọ nikan to lati fọ ìṣẹ́ danu kuro laarin awọn ọmọ Ọlọrun tabi ni ibikibi? Rara o! Ti awọn eniyan ko ba fi iṣẹ́ ọwọ́ ti o ni itunmọ kun irufẹ ififunni yowu ti wọn ba ri gba, o ṣeeṣe ki ififunni na ma ja mọ nkankan ninu aye wọn. Nṣe ni wọn yoo kan ma ko nkan ti a n fun jẹ lasan dipo ki wọn ma sọ di pupọ si. Idi si ni yi ti o fi jẹ wipe ko ki i ṣe fifi funni nikan ni awọn apọsiteli igbaani kọ awọn ara; wọn tun kọ wọn lati jẹ oṣiṣẹ ti o mura ṣiṣẹ, ti o si n ṣiṣẹ takuntakun pẹlu. Wọn tilẹ mu ni ọranyan pe ẹnikẹni ti ko ba ni ṣiṣẹ ko gbọdọ jẹun. Idi si ni pe wọn ko fẹ ki awọn ti o n gba iranwọ ninu ijọ fi iranwọ ti wọn n gba ṣofo tabi ki wọn sọ ara wọn di bukuta ti ko nidi si ọrun awọn miran. (Wo: Ìṣe àpọ́sítélì 20:34-35; Éfésù 4:28; 1Tẹsalóníkà 4:11-12; 2Tẹsalóníkà 3:6-10)

O wa ṣeni laanu pe ọpọ loni ti o fẹ ki ijọ ran wọn lọwọ ni ko ṣetan lati mu iṣẹ kankan ti o ni itunmọ, ti yoo si jẹ ki wọn le sọ iranwọ yowu ti wọn ba ri gba di gbigboro si ṣe. Nṣe ni wọn kan fẹ ki ijọ ma gbe bukata ti awọn funralara wọn ko mura tabi ṣetan lati gbe. Eyi ko si le ṣiṣẹ. Eyi gan paapaa jẹ ọkan lara awọn idi ti ọpọ ninu awọn ijọ wa loni ko fi ni alakalẹ ti o lojutu kankan fun iranlọwọ awọn ọmọ Ọlọrun ti o kudiẹ-kaato fun. Iriri ti kọ wọn pe ọpọ ti o n fẹ iranwọ lati ọwọ ijọ ni o jẹ ọlẹ tabi alainikanṣe eniyan, ti wọn kan n wa aye lati ṣi oore-ọfẹ Ọlọrun lo. O tilẹ di dandan ki awọn miran lara awọn wọnyi parẹ́ ni kete ti wọn ba ti ri iranwọ ti wọn fẹ gba. Nitorina ti o ba fẹ ki ijọ ran ọ lọwọ ni ọna kan tabi omiran, o nilo lati fi han daju ṣaka pe o ko ni lu ijọ Ọlọrun ni jibiti ati wipe iwọ yoo jẹ ki iranwọ ti o ba ri gba ja mọ nkan.

Nkan miran ti o jẹ ki lilawọ awọn eniyan mimọ igbaani yi ṣe aṣeyọri lati le ìṣẹ́ kuro laarin wọn ni pe lilawọ wọn ko fi si apa kan. Eyi tunmọ si pe ko ki i ṣe wipe awọn ti wọn n fifunni n fifunni lati sọ awọn kan di ọlọrọ nigba ti awọn n da otoṣi. Lafikun, ko ki i ṣe pe awọn ti wọn n fifunni nikan naa ni wọn n fifunni, gẹgẹ bi ko si ki i ṣe pe awọn ti wọn ri gba naa kan n fi gbogbo igba tẹwọgba ififunni awọn miran. Dipo eyi, nṣe ni ẹkọkọọkan n kopa ninu riran ara wọn lọwọ ni ibamu pẹlu bi nkan ini wọn ti pọ to ati ni ibamu pẹlu aini wọn. (Wo: 2Kọrinnti 8:13-15)

Ki lo wa fa ti eyi ko ṣe ri bẹ ni ọpọ ijọ wa loni? Idi ni pe awọn adari wa ko ma kọ wa lati ma jẹ alanikanjọpọn ninu ibaṣepọ wa pẹlu ara wa bi awọn apọsiteli igbani ti ṣe kọ awọn ará wọn. Fun apẹrẹ, Pọọlu sọ eyi fun awọn ara Fílípì: “Ki olukuluku yin ki o ma ṣe wa ohun tirẹ nikan, ṣugbọn olukuluku ohun ti ẹlomiran.” (Fílípì 2:4) Njẹ o ri bayi? A kọ awọn ara yi lati ma mọ ti ara wọn nikan, lati ma fi ọkan si kiki nkan ti wọn le ri gba lati ọwọ awọn ẹlomiran ṣugbọn lati tun fi ọkan si nkan ti awọn naa le ṣe fun awọn miran tabi fun wọn. Ṣugbọn ọpọ ninu ijọ loni ni o jẹ wipe kiki nkan ti wọn yoo ri gba lọwọ awọn miran ni wọn ma n wa, wọn ko ki i wa nkan ti awọn naa le ṣe fun awọn miran. Niwọn igba ti a ba si ri bayi, ko si ni ki iṣeṣi wa ma rin awọn ti wọn n ran wa lọwọ lara, ki awọn naa ṣi wa yi iṣeṣi wọn si wa pada to ba ya.

Nitorina ti a ba fẹ fọ ìṣẹ́ danu kuro ninu awọn ijọ wa, a gbọdọ kọbiara si awọn nkan mẹta yi, yatọ si pe ki a fi ọkan wa tẹ Ọlọrun lati pese fun aini wa gbogbo. Àkọ́kọ́, a gbọdọ jẹ ki ifẹ mu wa lọkan le lati lawọ si ara wa. Èkejì, gbogbo awa ti ara ati ọkan wa pe perepere ni a gbọdọ wa iṣẹ kan ti o ni itunmọ ṣe, ki a ma ba di bukata aye wa le ẹnikẹni lori lalai ni idi. Ẹ̀kẹta, ko gbọdọ jẹ kiki nkan ti a fẹ ri gba lọwọ ijọ tabi lọwọ awọn miran ni ko ma wa ni ọkan wa ṣugbọn nkan ti awa naa le fun awọn miran pẹlu. Ki Ẹmi Ọlọrun ṣi jẹ ki a ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Lílé ìṣẹ́ kúrò nínú ìjọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal |Ọjọ́: Owéwè 11, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 20 Read More »

Mú ìtẹríba ní pàtàkì | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Owewe 04, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 18

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Òwewè 2022. Adura mi si ni pe ohunkohun ko ni di ọkankan lara awọn nkan daradara ti Ọlọrun ti pese silẹ fun igbadun rẹ ninu oṣu naa lọwọ lati jẹ tirẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ti a ba n sọ wipe awọn eniyan n ni iriri idilọwọ, ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni o jẹ wipe Satani ni o wa nidi rẹ. Ni igba miran, Ọlọrun funrarẹ gan ni O ma n wa nidi rẹ. Ki wa ni idi ti Ọlọrun, ti o fẹ araye to bẹ gẹẹ ti O fi fi ọmọ bibi rẹ kan ṣoṣo fun wọn, le fẹ di ọkunrin tabi obinrin kan lọwọ lati ma ni itẹsiwaju laye? Igberaga lo ma n fa a.

Ati Jemisi ati Peteru ni wọn jọ dijọ sọ fun wa ninu episiteli wọn pe Ọlọrun a ma kọ oju-ija si agberaga ṣugbọn a si fi oore-ọfẹ fun onirẹlẹ (Jémìsì 4:6; 1Pétérù 5:5). Nitorina, ti o ba gberaga, o yẹ ki o ma reti Ọlọrun lati di ilọsiwaju rẹ lọwọ ni awọn abala aye rẹ kan tabi ni gbogbo abala aye rẹ. Ọna kan ti a si ma n ṣaba gba fi igberaga han ninu aye wa, lalai tilẹ mọ, ni nipa kikọ lati tẹriba fun awọn alaṣẹ.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, awọn eniyan wa ti Ọlọrun ti pa aṣẹ fun wa lati tẹriba fun. Fun apẹẹrẹ, awọn obi wa, awọn ọkọ wa, awọn agbaniṣiṣẹ ati ọga wa, awọn adari ilu wa ati awọn adari ijọba wa wa lara awọn ti O fẹ ki a ma tẹriba fun. Ko fẹ ki a tabuku awọn wọnyi tabi ki a ṣe aigbọran si wọn, niwọn igba ti awọn aṣẹ wọn ko ba ti tako ọrọ rẹ ati ilana rẹ fun igbe aye ododo. Ti a ba wa kọ eti didi si eyi, ti a si bẹrẹ si ni tabuku wọn, nṣe ni a n rin ninu igberaga; o si di dandan ki a bẹrẹ si ni ri iṣẹ Ọlọrun lodi si ilọsiwaju wa. Oun nikan lo si wa mọ iye awa ti a n ni idaduro ati idilọwọ laye nitori eyi. (Wo: Róòmù 13:1-5; Éfésù 5:22; Éfésù 6:1-3; 1Pétérù 2:13-14; 1Pétérù 3:1-2)

Siwaju si, ninu ijọ, Oluwa kọ wa lati tẹriba fun awọn adari wa ni ibọwọ fun Kirisiti. Eyi tunmọ si pe ijọ Ọlọrun ko ki i ṣe ibi ti o ti le ma gun ejika, ki o si tun ma ṣe bo ba ti ṣe wu ẹ. Awọn eniyan wa nibẹ ti Ọlọrun ti yan si ori rẹ lati ṣọna lori ọkan rẹ ati lati mojuto ọ, ki o ba le da ohun gbogbo ti O fẹ ki o da. O wa ṣe pataki ki o tẹriba fun awọn wọnyi, ki o si ma jẹ ki o ṣoro fun wọn lati dari rẹ, niwọn igba ti ko ba ki i ṣe pe wọn fẹ dari rẹ kuro ninu otitọ Ọlọrun. Aijẹbẹ, bi bibeli ti ṣe fi ye wa, ko le ṣe ọ ni anfaani rara. Dandan ni ki Ọlọrun ba ọ wi ni ibamu pẹlu igberaga rẹ. (Wo: Hébérù 13:17)

O wa ṣeni laanu pe ọpọ ninu ijọ loni ni igberaga kọ jẹ ki wọn fi ara balẹ kọ awọn nkan ti yoo ṣe wọn ni anfaani tabi ti yoo jẹ ki wọn ni iriri ẹkunrẹrẹ didara Ọlọrun ti ko ba jẹ ti wọn nipasẹ awọn adari wọn. Awọn wọnyi dabi awọn gbajumọ aarin awọn ọkunrin Tẹ́kóà ti a mẹnuba ninu iwe Nehemáyà, ti wọn kọ lati teriba fun awọn adari wọn ni akoko ti gbogbo awọn eniyan n tun odi Jerusalẹmu mọ (Nehemáyà 3:5). Iru awọn eniyan yi n ma n di ilọsiwaju iṣẹ Ọlọrun laarin awọn eniyan rẹ lọwọ laimọ. Nitorina, Oun naa a si din ọwọ iṣẹ rẹ ku ninu aye wọn.

Ṣe o wa ri bayi pe iṣọtẹ si awọn alaṣẹ ko le ṣe ọ ni anfaani rara. Nitorina, ri daju pe o mojuto irufẹ igberaga yowu ti o le wa ninu rẹ, ti o si n jẹ ki o ṣe orikunkun si awọn ti Ọlọrun ti yan gẹgẹ bi adari fun ọ. Ki Ẹmi Ọlọrun dari rẹ, ki O si tun fun ọ ni okun lati ṣe ohun ti o tọ lori ọrọ yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Mú ìtẹríba ní pàtàkì | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Owewe 04, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 18 Read More »

Mú ìtẹríba ní pàtàkì | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Owewe 04, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 18

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Òwewè 2022. Adura mi si ni pe ohunkohun ko ni di ọkankan lara awọn nkan daradara ti Ọlọrun ti pese silẹ fun igbadun rẹ ninu oṣu naa lọwọ lati jẹ tirẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ti a ba n sọ wipe awọn eniyan n ni iriri idilọwọ, ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni o jẹ wipe Satani ni o wa nidi rẹ. Ni igba miran, Ọlọrun funrarẹ gan ni O ma n wa nidi rẹ. Ki wa ni idi ti Ọlọrun, ti o fẹ araye to bẹ gẹẹ ti O fi fi ọmọ bibi rẹ kan ṣoṣo fun wọn, le fẹ di ọkunrin tabi obinrin kan lọwọ lati ma ni itẹsiwaju laye? Igberaga lo ma n fa a.

Ati Jemisi ati Peteru ni wọn jọ dijọ sọ fun wa ninu episiteli wọn pe Ọlọrun a ma kọ oju-ija si agberaga ṣugbọn a si fi oore-ọfẹ fun onirẹlẹ (Jémìsì 4:6; 1Pétérù 5:5). Nitorina, ti o ba gberaga, o yẹ ki o ma reti Ọlọrun lati di ilọsiwaju rẹ lọwọ ni awọn abala aye rẹ kan tabi ni gbogbo abala aye rẹ. Ọna kan ti a si ma n ṣaba gba fi igberaga han ninu aye wa, lalai tilẹ mọ, ni nipa kikọ lati tẹriba fun awọn alaṣẹ.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, awọn eniyan wa ti Ọlọrun ti pa aṣẹ fun wa lati tẹriba fun. Fun apẹẹrẹ, awọn obi wa, awọn ọkọ wa, awọn agbaniṣiṣẹ ati ọga wa, awọn adari ilu wa ati awọn adari ijọba wa wa lara awọn ti O fẹ ki a ma tẹriba fun. Ko fẹ ki a tabuku awọn wọnyi tabi ki a ṣe aigbọran si wọn, niwọn igba ti awọn aṣẹ wọn ko ba ti tako ọrọ rẹ ati ilana rẹ fun igbe aye ododo. Ti a ba wa kọ eti didi si eyi, ti a si bẹrẹ si ni tabuku wọn, nṣe ni a n rin ninu igberaga; o si di dandan ki a bẹrẹ si ni ri iṣẹ Ọlọrun lodi si ilọsiwaju wa. Oun nikan lo si wa mọ iye awa ti a n ni idaduro ati idilọwọ laye nitori eyi. (Wo: Róòmù 13:1-5; Éfésù 5:22; Éfésù 6:1-3; 1Pétérù 2:13-14; 1Pétérù 3:1-2)

Siwaju si, ninu ijọ, Oluwa kọ wa lati tẹriba fun awọn adari wa ni ibọwọ fun Kirisiti. Eyi tunmọ si pe ijọ Ọlọrun ko ki i ṣe ibi ti o ti le ma gun ejika, ki o si tun ma ṣe bo ba ti ṣe wu ẹ. Awọn eniyan wa nibẹ ti Ọlọrun ti yan si ori rẹ lati ṣọna lori ọkan rẹ ati lati mojuto ọ, ki o ba le da ohun gbogbo ti O fẹ ki o da. O wa ṣe pataki ki o tẹriba fun awọn wọnyi, ki o si ma jẹ ki o ṣoro fun wọn lati dari rẹ, niwọn igba ti ko ba ki i ṣe pe wọn fẹ dari rẹ kuro ninu otitọ Ọlọrun. Aijẹbẹ, bi bibeli ti ṣe fi ye wa, ko le ṣe ọ ni anfaani rara. Dandan ni ki Ọlọrun ba ọ wi ni ibamu pẹlu igberaga rẹ. (Wo: Hébérù 13:17)

O wa ṣeni laanu pe ọpọ ninu ijọ loni ni igberaga kọ jẹ ki wọn fi ara balẹ kọ awọn nkan ti yoo ṣe wọn ni anfaani tabi ti yoo jẹ ki wọn ni iriri ẹkunrẹrẹ didara Ọlọrun ti ko ba jẹ ti wọn nipasẹ awọn adari wọn. Awọn wọnyi dabi awọn gbajumọ aarin awọn ọkunrin Tẹ́kóà ti a mẹnuba ninu iwe Nehemáyà, ti wọn kọ lati teriba fun awọn adari wọn ni akoko ti gbogbo awọn eniyan n tun odi Jerusalẹmu mọ (Nehemáyà 3:5). Iru awọn eniyan yi n ma n di ilọsiwaju iṣẹ Ọlọrun laarin awọn eniyan rẹ lọwọ laimọ. Nitorina, Oun naa a si din ọwọ iṣẹ rẹ ku ninu aye wọn.

Ṣe o wa ri bayi pe iṣọtẹ si awọn alaṣẹ ko le ṣe ọ ni anfaani rara. Nitorina, ri daju pe o mojuto irufẹ igberaga yowu ti o le wa ninu rẹ, ti o si n jẹ ki o ṣe orikunkun si awọn ti Ọlọrun ti yan gẹgẹ bi adari fun ọ. Ki Ẹmi Ọlọrun dari rẹ, ki O si tun fun ọ ni okun lati ṣe ohun ti o tọ lori ọrọ yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Mú ìtẹríba ní pàtàkì | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Owewe 04, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 18 Read More »