DOWNLOAD E-COPY HERE
ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Galatia, o ṣalaye lẹkunrẹrẹ fun wọn pe ipo ẹru ni awọn ti o wa labẹ ofin Moṣe wa. O tilẹ jẹ ki o ye wọn pe nkan ti ofin gan sọ ni eyi. Ara idi si ni yi ti a ṣe ran Jesu Oluwa wa lati gba awọn ti o wa labẹ ofin yi kuro ninu igbekun ati egun rẹ. Ti awọn ti a didi fun ni ofin Mose ba wa nilo irapada kuro labẹ rẹ ati kuro labẹ egun rẹ, ṣe o wa yẹ ki awọn ti a ko fun ni ofin yi fi ara wọn si abẹ igbekun rẹ? Ko yẹ rara. Nitorina, ninu abala lẹta yi ti a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi, Pọọlu tẹsiwaju ninu alaye rẹ lati fi nkan ti o sorọ mọ ki a fi ara wa si abẹ igbekun ofin Mose han awọn ara Galatia. O si wa yẹ ki gbogbo awọn ti o jẹ Kirisitiẹni loni, ti awọn naa si n gbiyanju lati fi ara wọn si abẹ ofin Mose ṣe aṣaro ti o peye lori awọn nkan ti apositeli yi sọ ninu awọn ẹsẹ lẹta ti a fẹ yẹwo naa.
MÁ ṢE TI ỌRÙN BỌ ÀJÀGÀ ÒFIN MÓSÈ
Ewu wo lo wa sorọ mọ ki a fi ara wa sabẹ igbekun ofin Mose? Tabi ki a sọ wipe awọn ọna wo ni ki a fi ara wa sabẹ isinru ofin Mose ṣe le pa igbagbọ wa ninu Kirisiti Jesu lara? Awọn nkan ti Pọọlu sọ lorin ọrọ naa niyi:
“Nitori naa, ẹ duro ṣinṣin ninu ominira naa eyi ti Kirisiti fi sọ wa di ominira, ki ẹma si ṣe tun fi ọrun bọ ajaga ẹru mọ. Kiyesi i, emi Pọọlu ni o wi fun yin pe, bi a ba kọ yin nila, Kirisiti ki yoo lere fun yin ni ohunkohun. Mo si tun sọ fun olukuluku eniyan ti a kọ ni ila pe, o di ajigbese lati pa gbogbo ofin mọ. A ti ya yin kuro lọdọ Kirisiti, ẹyin ti n fẹ ki a da yin lare nipa ofin; pe ẹ ti ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ.” (Galatia 5:1-4)
Nkan akọkọ ti apọsiteli yi jẹ ki o ye wa ni pe Kirisiti ti sọ wa di ominira. Ti a ba wa sọ pe Kirisiti sọ wa di ominira, o yẹ ki a mọ nkan ti O sọ wa di ominira kuro ninu rẹ. Bi a ti fihan ninu bibeli, Kirisiti ti sọ wa di ominira kuro ninu igbekun ẹṣẹ ati igbekun eṣu ati gbogbo iṣẹ ibi rẹ. Nitorina, a gbọdọ ma fi gbogbo igba ri ara wa bi ominira. Yatọ si eyi, Kirisiti tun ti sọ awọn Juu di ominira kuro ninu igbekun ofin Mose. Nitorina, awọn naa gbọdọ ma fi gbogbo igba ri ara wọn gẹgẹ bi ẹni ti o ti di ominira kuro labẹ ofin Mose.
Nkan ekeji ti Pọọlu tun pe akiyesi wa si ni pataki ki a duro ṣiṣin ninu ominira ti a ti ri gba lọwọ Kirisiti. Kirisiti ko sọ wa di ominira ki a ba le ma gbe igbe aye ẹru. Amọ ti a ko ba pinnu lati duro ṣinṣin gẹgẹ bi ẹni ti o ti di ominira, ko si ni ki eṣu, ẹṣẹ, ẹran-ara, aye ati oniruru ofin atọwọda awọn eniyan ma tun fẹ mu wa ni igbekun. Nkan ti a n sọ ni pe, pe a ti sọ wa di ominira ko sọ wipe ki awọn ẹṣẹ ti a ti gba wa lọwọ wọn ma tun fẹ jẹ gaba lori aye wa. Bẹẹ si ni ko sọ wipe ki aisan, airoju, airaye, egun idile, iku-ojiji ati bẹẹbẹẹ lọ ma fẹ ṣe ijọba lori aye wa. Awa ni a gbọdọ mura, ki a si pinnu lọkan wa lati ma fi aye gba ohunkohun tabi ẹnikẹni lati tun ma ṣe ijọba lori aye wa yatọ si Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa.
Siwaju si, pe Jesu sọ awọn Juu di ominira kuro ninu igbekun ofin Mose ko sọ wipe ki ero-ọkan wọn nipa ofin yi ma tun fẹ lo ofin naa lati fi wọn sinu ide. Eyi lo si fa ti a fi ri awọn Juu ni akoko ti Pọọlu kọ lẹta yi ti ko fẹ kọ ofin Mose silẹ gẹgẹ bi ọna lati di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ wipe wọn ti da Kirisitiẹni. Luuku tilẹ sọrọ akoko kan fun wa ninu iwe Iṣe Awọn Apọsiteli ninu eyi ti a ti rọ Pọọlu lati darapọ mọ awọn Juu ẹgbẹ rẹ kan lati tun rubọ ninu Tẹmipili, ni ibamu pẹlu ofin Mose. Kini o fa eyi? Aimuratan lati kọ ofin Mose ati awọn ilana rẹ silẹ gẹgẹ bi ọna fun igbala ati m didi ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun lo fa. (Wo: Iṣe Apọsiteli 21:18-26)
Nikukuru, irufẹ awọn Juu yi naa ni o lọ kaakiri, ti wọn si n gbiyanju lati mu awọn Heleni ti o ti gba Jesu gbọ ni tipatipa lati bẹrẹ si ni pa ofin Mose mọ, paapaa julọ eyi ti o ni i ṣe pẹlu ikọla abẹ. Pọọlu wa n jẹ ki o ye awọn ara Galatia pe ọwọ wọn lo ku si lati ri pe wọn ko fi aye gba awọn eniyan yi lati sọ wọn si abẹ igbekun ofin Mose. Bẹẹ gẹgẹ ni o si gbọdọ ri fun awa naa. Awa naa gbọdọ mura, ki a si ri daju pe a ko fi aye gba ẹnikẹni, bi o ti wu ki ẹni naa lọla to laarin awọn ọmọ Ọlọrun, lati fi wa si abẹ ofin Mose gẹgẹ bi ẹru rẹ.
Ki si ni idi ti a fi gbọdọ mura lati ma ṣe fi aye gba ẹnikẹni lati fi wa si abẹ igbekun ofin Mose? Idi akọkọ, gẹgẹ bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa, ni pe a ko ni jẹ ere iṣẹ irapada ati isọdọmọ ti Kirisiti ṣe fun wa, niwọn igba ti a ba fi aye gba ofin Mose lati jẹ oluwa fun wa. Eyi tunmọ si pe ẹnikẹni ti o ba ro wipe ohun o ri nkankan gba lọwọ Ọlọrun nitori pe oun tẹle ilana ofin Mose kan n tan ara rẹ jẹ ni. Ko le ri ibukun kankan ti o sorọ mọ ki a jẹ ọmọ Ọlọrun nipa igbagbọ ninu Kirisiti gba.
Bawo wa ni ti awọn Kirisitiẹni ti o n fi gbogbo igba jẹri awọn nkan ti Ọlọrun n ṣe fun wọn nipasẹ pipa ofin Mose mọ? Nkan ti awọn wọnyi ko mọ ni pe ko ki i ṣe nitoripe wọn n pa ofin Mose mọ ni Ọlọrun ṣe dara si wọn. Ọlọrun dara si wọn nitoripe alaanu ni, O si ma n ṣe daradara si awọn ika eniyan paapaa lati fi aye ironupiwada silẹ fun wọn (Matiu 5:44-45). Eyi jẹ ki a mọ pe eniyan le ma ṣe nkan ti o tako ifẹ Ọlọrun ki o si tun ma jẹ igbadun didara rẹ ni ọpọlọpọ ọna. Ṣugbọn ọjọ naa n bọ ti Ọlọrun yoo san ẹnikọọkan ni ẹsan fun iṣẹ ọwọ rẹ, yala o ba ifẹ rẹ mu tabi ko ba ifẹ rẹ.
Ki a ma fi ọrọ silẹ sọ nkan miran, koko nkan ti a n sọ ni pe ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni Kirisitiẹni, ti o si tun wa dirọ mọ ofin Mose gẹgẹ bi ọna lati jẹ ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun ko le jẹ igbadun ipese Kirisiti ninu aye rẹ gẹgẹ bi o ti yẹ ki o ma jẹ ẹ. Awọn iṣẹ ti Kirisiti fẹ ṣe ninu aye rẹ ko ni le ṣeeṣe nitoripe igbagbọ rẹ ko si ninu iṣẹ Jesu Kirisiti mọ bikoṣe ninu iṣẹ ọwọ ara rẹ.
Idi keji, gẹgẹ bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa, ti a fi gbọdọ mura lati ma jẹ ki ẹnikẹni fi wa si abẹ ajaga ofin Mose ni pe fifi ara wa jin lati pa abalakabala ninu ofin yi mọ yo sọ wa di onigbese ti o gbọdọ pa gbogbo abala ofin naa mọ. Eyi jasi pe niwọn igba ti a ba ti pinnu lọkan wa pe ofin Mose ni a fẹ tẹle gẹgẹ bi ọna lati di ẹni itẹwọgba tabi idalare niwaju Ọlọrun, a gbọdọ mura lati bẹrẹ si ni pa gbogbo nkan ti ofin naa sọ mọ. Nkan wọnyi ni ko si ye awọn ara Galatia ti wọn fi ara wọn jin pe ki a kọ wọn ni ila abẹ, ni ibamu pẹlu ofin Mose. Wọn ko mọ wipe ko tọna fun wọn lati pa abala ofin yi kan mọ, ki wọn si wa kọ awọn abala yoku silẹ. Eyi yoo fi wọn si abẹ egun ofin naa ti o sọ wipe egbe ni fi ẹni naa ti ko ba tẹsiwaju lati ma pa gbogbo ọrọ ofin yi mọ (Ditaronomi 27:26).
Ṣe o wa mu ọgbọn wa ki eniyan tun lọ fi ara rẹ si abẹ egun ofin Mose lẹyin igba ti Jesu ti ku lati ra awọn ti o wa labẹ egun ofin yi pada? Ko mu ọgbọn wa rara. Nitorina, gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ti wọn n mura kankan loni pe dandanla awọn gbọdọ ma tẹle ofin Mose gbọdọ mura bakanna lati pa gbogbo nkan ti a sọ sinu ofin naa mọ. Aijẹbẹ, abẹ egun ni wọn wa – awọn ibukun ọfẹ Kirisiti ti ẹnikẹni ti o ba gbagbọ ninu rẹ lẹtọ lati jẹgbadun ko si le ṣiṣẹ lọna ti o peye ninu aye wọn.
Idi kẹta ti Pọọlu tun fun wa, eyi ti o ṣe ṣe pataki ki a ma fi ara wa si abẹ ofin Mose ni pe gbogbo Kirisitiẹni ti o ba fi ara wọn si abẹ ofin yi ni a ti ya kuro ni ara Kirisiti, ti wọn si ti ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ rẹ. Bi Adamu ṣe ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ Ọlọrun ninu ọgba Edẹni, ti a si le kuro nibi ipese Ọlọrun lati lọ ma fi oogun oju rẹ wa ounjẹ oojọ rẹ, bẹẹ gẹgẹ naa ni o ṣe ri fun gbogbo awọn ti o ba pa igbagbọ ninu Kirisiti ti lati ma tẹle ofin Mose. Awọn naa yoo nilo lati gboju le iṣẹ ọwọ wọn lati jẹ igbadun ipese Ọlọrun ni –oore-ọfẹ Kirisiti ko le ṣiṣẹ fun wọn mọ.
Lotitọ, irufẹ awọn wọnyi le ma gbadura ni orukọ Jesu, ki wọn ma gbawẹ ni orukọ rẹ, ki wọn si tun ma jọsin pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun miran. Ṣugbọn a ti ya wọn ya Kirisiti nitori ifarajin wọn fun ofin Mose. Bawo wa ni yoo ṣe buru to ki eniyan ro wipe oun wa pẹlu Kirisiti, ki o si ma wa pẹlu rẹ? Bawo ni yoo ṣe bani lọkanjẹ to lati gbọ lati ẹnu Kirisiti Jesu nigba ti O ba de pe Oun ko mọ wa ri, lẹyin igba ti a ti fi ọpọlọpọ ọjọ aye wa jọsin ni orukọ rẹ, ti a si mura gidigidi lati gbe igbe aye olododo? Yoo buru jọjọ. (Wo: Matiu 7:21-23)
Pọọlu wa tẹsiwaju lati jẹ ki eyi ye wa:
“Nitori nipa Ẹmi awa n fi igbagbọ duro de ireti ododo. Nitori ninu Kirisiti Jesu ikọla ko jẹ ohun kan, tabi aikọla; ṣugbọn igbagbọ ti n ṣiṣẹ nipa ifẹ.” (Galatia 5:5-6)
Nibo ni ireti ipadabọ Jesu lati fi idi ijọba ayeraye Ọlọrun mulẹ ti a ni ti wa? O wa nipasẹ Ẹmi Ọlọrun ti O tun wa bi, ti O si n gbe inu wa. Ko ki i ṣe nipasẹ ofin Mose tabi ẹkọ ti o kọ ni a ṣe ni ireti yi. Nitorina ni Pọọlu se wa sọ wipe pipa ofin Mose mọ nipa kikọ ila abẹ ko ja mọ nkankan. Idi si ni pe ikọla abẹ gan ni pataki julọ ninu awọn ofin Mose ti awọn ti o n yọ awọn ara Galatia yi lẹnu n tẹnumọ. Wọn n sọ wipe bi awọn ti ko ki i ṣe Juu ko ba tilẹ ni pa ofin Mose miran mọ, wọn gbọdọ pa ti ikọla abẹ mọ, ki wọn ba le jẹ ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun.
Ṣugbọn, bi Pọọlu ti jẹ ki o ye wa, ninu Kirisiti Jesu ikọla abẹ ko ja mọ nkankan, bẹẹ si ni aikọla abẹ naa ko ja mọ nkankan. Nkan ti o ṣe pataki julọ ni igbagbọ ninu Jesu Kirisiti ti o n gbe igbe aye ifẹ. Ifẹ si ni akoja gbogbo ofin. Nitorina, nkan ti awọn ti o gbagbọ ninu Jesu nilo lati gbaju mọ ni igbe aye ifẹ. Niwọn igba ti afojusun wọn ba ti da lori ki wọn ma ṣe ohun gbogbo ninu ifẹ, ko si ni bi wọn ko ṣe ni gbe igbe aye ti o wu Ọlọrun.
Pọọlu wa pari ọrọ rẹ ni abala ti a n gbe yẹwo ninu ẹkọ yi nipa sisọ eyi:
“Ẹyin ti n sare daradara; ta ni di yin lọwọ lati ṣe igbọran si otitọ? Iyipada yii ko ti ọdọ ẹni ti o pe yin wa. Iwukara diẹ ni i mu gbogbo iyẹfun wu. Mo ni igbẹkẹle si yin ninu Oluwa pe, ẹyin ki yoo ni ero ohun miiran; ṣugbọn ẹni ti n yọ yin lẹnu yoo ru idajọ tirẹ, ẹnikẹni ti o wu ki o jẹ. Ṣugbọn, ara, bi emi ba n waasu ikọla sibẹ, kin ni idi ti a fi n ṣe inunibini si mi ṣibẹ? Njẹ ikọsẹ agbelebu ti kuro. Emi iba fẹ ki awọn ti n yọ yin lẹnu tilẹ ge ẹya-ara wọn kan kuro.” (Galatia 5:7-12)
Njẹ o ri bayi? Awọn ara Galatia yi ti n sare daradara tẹlẹ nipasẹ igbagbọ wọn ninu Jesu. Ṣugbọn awọn aṣinilọna kan ni wọn ko ba wọn, ti wọn si ti wọn ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ Kirisiti. Pọọlu wa n jẹ ki o ye wọn pe o di dandan ki awọn ti o n yọ wọn lẹnu ru ẹru idajọ wọn. Eyi tunmọ si pe Ọlọrun ko ni ṣe alaimajẹwọniya fun yiyọ ijọ rẹ lẹnu. Ti awa naa ba si n yọ ijọ Ọlọrun lẹnu tabi ti a n ṣi awọn ọmọ rẹ lọna, o di dandan ki a ri ijiya ti o tọ si wa, bopẹ-boya.
Ọ̀RỌ̀ ÌKẸ́YÌN
Nibiti ọrọ yi wa ka Pọọlu lara de, o pari ọrọ nipa sisọ wipe ki lo ṣe ti awọn ti o n yọ awọn ara Galatia yi lẹnu ko tilẹ kuku jan ara wọn ni ountẹ, ki wọn si di òkóbó? Nitirẹ, idi ti awọn ju ṣe n ṣe inunibini si ni pe o n jẹ ki awọn eniyan mọ wipe ikọla abẹ ko wulo fun igbala ẹmi wọn. Lotitọ, ikọla abẹ wulo fun eniyan lati jẹ Juu nipa ti ara ati lati jẹ ajogun ilẹ ileri Kenani. Amọ ti a ba n sọrọ nipa Juu ti ẹmi ati ajogun ijọba Ọlọrun, ikọla abẹ ko wulo rara. Igbagbọ ninu Jesu Kirisiti nikan ni o le jẹ ki awọn nkan wọnyi jẹ ti wa. Eyi si ni iyinrere tòótọ́.
ÌBÉÈRÈ
- Pipa Jesu ti lati ma tẹle ofin Mose gẹgẹ bi ọna lati di ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun lewu. Ṣalaye bi eyi ṣe lewu to.
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)