Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin ọdun yi, ọdun 2023. Adura mi ni pe ki o ri aṣepe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ninu ọdun yi lati ọdọ Ọlọrun. Amin.
Wayi o, bi a ti ṣe wọ inu awọn ọjọ ti o kẹyin ọdun yi, o ṣe pataki ki a ya aye rẹ ya ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ẹtanu, ikorira, ikanra ati adanikanjọpọn, ki o ba le ni iriri ẹkunrẹrẹ obukun Ọlọrun ti a tu si ori wa ninu Kirisiti Jesu. Lotitọ, o le jẹ nitori oniruuru iya ti o ti jẹ lọwọ awọn eniyan ni o ṣe ni ẹtanu, ikorira, imọtaraẹninikan ati ikanran si awọn miran. Ṣugbọn ti o ba ranti pe iwọ naa ti fi igba kan ri ba Ọlọrun lo pọ pẹlu ikanran, ikorira, arakan ati adanikanjọpọn ti O si tun papa dari ji ọ, ko yẹ ki o jẹ iṣoro fun ọ lati ya ara ya awọn nkan wọnyi ni biba awọn ti o wa ninu aye rẹ lo pọ.
Ni igba ti O n ba awọn ọmọ Isiraẹli ṣọrọ lori pataki ki wọn ma tu awọn arakunrin wọn ti o wa ṣiṣẹ labẹ wọn gẹgẹ bi ẹru ṣilẹ lẹyin ọdun meje-meje, Ọlọrun sọ eyi: “Ẹ ranti pe ẹ ti fi igba kan jẹ ẹru ni Ijibiti, Oluwa Ọlọrun yin si ra yin pada, idi niyi ti mo fi pa aṣẹ yii fun un yin loni.” (Ditaronomi 15:15) Njẹ o ri bayi? Ọlọrun fẹ ki awọn eniyan wọnyi fi si ọkan ibi ti wọn ti n bọ ati bi a ṣe mu wọn wa si ibi ti wọn wa. Awọn naa ti jẹ ẹru ri. Aanu Ọlọrun ni o si tu wọn silẹ, ko ki i ṣe agbara, ipa tabi ọgbọn wọn. Nitorina, ni biba awọn ẹru wọ lo pọ, Ọlọrun fẹ ki wọn ma ranti eyi, ki wọn ma ba le mọ wọn tabi fi ominira wọn dun wọn ni akoko ti o tọ.
O wa ṣeni laanu pe, lẹyin ọpọlọpọ ọdun lẹyin eyi ti awọn eniyan ti fi idi mulẹ daadaa ni ilẹ wọn, iwa ika wọn si awọn ẹru wọn gan tun wa fẹ buru ju iwa ika ti awọn ara Ijibiti wu si awọn baba nla wọn lọ. Iwa wọn si buru si awọn ẹru yi to bẹẹ gẹẹ ti wọn fi kọ lati tu wọn silẹ ni akoko ti Ọlọrun yan fun wọn. Nigba ti ọrọ Ọlọrun si tun tọ wọn wa lati ẹnu Jeremaya lori eyi, wọn ko gbọ. Nṣe ni awọn ti o ti kọkọ tu awọn ẹru wọn silẹ tun pada lọ fi agbara mu wọn lati tun fi wọn si abẹ igbekun. Nitori eyi, wọn fa idajọ Ọlọrun sori ara wọn. (Wo: Jeremaya 34)
Nibakanna, ọpọ wa loni ni o ti gbagbe bi Ọlọrun ṣe dara si wa to ni gbigba wa la kuro lọwọ ẹṣẹ wa ati ni yiyọ wa kuro ninu ẹrọfọ idojuti ati iṣẹ ti a wa tẹlẹ. A ma n tete gbagbe awọn ọjọ wọnni ninu eyi ti a ti n ke pe Ọlọrun pe ki O gba wa lọwọ inira wa ati bi O ti ṣe da wa lohun, ti O si gba wa la. Nitorina, nṣe ni a n ṣe awọn ti o wa ninu aye wa ati awọn ti o wa labẹ wa ṣibaṣibo, pẹlu ẹmi ika ati ẹmi ailaanu. A si tun n ṣe ọkan wa le lati ma dariji wọn tabi fi aanu ba gbogbo awọn ti o ṣẹ wa tabi ti o ti fi igba kan ṣẹyin pa wa lara lo. Ṣibẹsibẹ a n fẹ ki oore-ọfẹ ati didara Ọlọrun pọ si lori wa. Bawo ni eyi yoo ti ṣe ri bẹ?
Ni kukuru, ọrọ Ọlọrun n tọ wa wa bayi, o si n paṣẹ fun wa lati ranti bi Ọlọrun ṣe dara si wa to, ki a si titori eyi ya ara ya ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu arankan, ikorira, ẹtanu ati ikanra ninu bi a ti ṣe n ba awọn ti o wa laye wa lo, bi o ti wu ki wọn buru tabi jẹ alaiṣododo si wa to. Bi a si ṣe n ṣe eyi, paapaa julọ ni awọn ọjọ ti o gbẹyin ọdun yi, gbogbo awọn ibukun Ọlọrun ti o ti kọ lati jẹyọ ninu aye wa ni yoo bẹrẹ si ni jẹyọ. Ọdun tuntun ti o si wa niwaju wa naa yoo si ṣan fun oyin ati wara fun wa ni gbogbo ọna.
Keresi ayọ o.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
