Má fà sẹ́yìn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 19, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 46
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ẹrẹna. Adura mi pe ki Ọlọrun ma fi gbogbo igba fun ọ ni okun ninu ọrọ ati iwa rere gbogbo, ki o ma ba ṣe jẹ alailere ni ọnakọna. Amin.
Ọkan lara awọn nkan ti a jẹ ki o ye wa yekeyeke ninu iwe mimọ ni pe a ko gbọdọ fa sẹyin ninu iṣoore. Idi si ni pe Ọlọrun yoo pin wa lere fun u. Fun apẹẹrẹ, nigba ti o n kọ lẹta si awọn ara Galatia, Pọọlu sọ wipe, “Ẹ ma si ṣe jẹ ki aarẹ ọkan mu wa ni ṣiṣe rere, ntiori ti a o kore nigba ti akoko ba de, bi a ko ba ṣe aarẹ.” (Gàlátíà 6:9) Njẹ o ri bayi? Ti ko ba ṣeeṣe fun wa lati ṣaarẹ ni ṣiṣe rere ni, a ko ni pa irufẹ aṣẹ yi fun wa. Ti awọn iṣẹlẹ ti o le jẹ ki a rẹwẹsi ni ṣiṣoore ko ba si ni, a ko ni sọ fun wa pe ki a ma ṣaarẹ ni ṣiṣe rere.
Ṣugbọn irufẹ awọn iṣẹlẹ yi wa. Wo awọn idojukọ ti a n ba pade ni orilẹ-ede yi, fun apẹẹrẹ. Owo epo ti lọ soke kọja aala. Ọda owo fun nina tun wa kaakiri. Ojoojumọ ni a tun nilo lati ba ina ọba ti o n ṣe ṣégeṣège finra. Awọn nkan wọnyi si n jẹ ki owó ọjá ati owọ́ ọ̀yà lo soke si lojoojumọ, bi o tilẹ jẹ wipe owo ti ọpọ n pa ko ma a pọ si.
Wayi o, nitori awọn nkan wọnyi, ọpọ ti o lawọ tẹlẹ ninu fififun Ọlọrun ati awọn eniyan ti n fa sẹyin, ti wọn si n lo bi nkan ti ṣe ri gẹgẹ bi awawi wọn lati ma lawọ ṣoore mọ. Ti awọn ti o ba wa lawọ tẹlẹ ri ba n ṣe bayi, ki ni o ro wipe awọn ti ko fi igba kankan lawọ yoo ṣe? Amọ ṣa o, ọrọ Ọlọrun naa ti woye pe awọn nkan ti o le jẹ ki a fa sẹyin ni ṣiṣoore le ṣẹlẹ. Idi si ni yi ti o fi sọ fun wa pe ki a ma ṣe fa ṣẹyin ninu rẹ. Ki si ni idi? Idi nipe nigba ti akoko ba to, Ọlọrun yoo fun wa ni ere gbogbo iṣoore wa. Ko ni fi oju fo ọkankan tabi gbagbe ọkankan lara wọn.
Nitorina, ti o ba ti n fa ṣẹyin ni fififun awọn ti o wa ninu aye rẹ, o nilo lati tun ifarajin rẹ lati ma fifun wọn ṣe. Ti o ba si ti n fa sẹyin ni fififun iṣẹ Ọlọrun ati fififun awọn ti o n bọ ọ pẹlu ọrọ rẹ, o nilo lati tun ifarajin rẹ ni ṣiṣe eyi ṣe. Aijẹbẹ, nṣe ni o o ja ara rẹ lole awọn ere ti o yẹ ki o tẹle fififunni rẹ. Ranti wipe o ko le kore ohun ti o ko ba gbin. Nitorina, ti o ba kọ lati furugbin nitori pe o ro wipe irugbin ti o ni ko to nkan, ti o si jẹ gbogbo rẹ, ko ni si nkankan ti o o kore ni asiko ikore.
Eyi, bi mo ṣe gbagbọ, ni Pọọlu ni ni ọkan nigba ti o sọ nkan wọnyi fun awọn ara Kọrinti nipa ififunni wọn: “Ati ninu eyi ni mo fi imọran mi fun yin: nitori eyi ṣe anfaani fun yin, ẹyin ti o kọkọ bẹrẹ niwọn ọdun ti o kọja, ki i ṣe lati ṣe nnkan, ṣugbọn lati fẹ pẹlu. Njẹ nisinsin yii, ẹ pari ṣiṣe iṣẹ naa pẹlu; ki o baa le ṣe pe, bi imura tẹlẹ fun ṣiṣe ti wa, bẹẹ ni ki ipari si wa lati inu agbara yin. Nitori bi imura tẹlẹ ba wa ṣaaju, o jasi itẹwọgba gẹgẹ bi ohun ti eniyan ba ni, ki i ṣe gẹgẹ bi ohun ti ko ni.” (2Kọrinti 8:10-12)
Pẹlu nkan ti Pọọlu sọ nibi, o han kedere pe awọn ara Kọrinti ti fi igba kan ri fi ara wọn jin fun ṣiṣoore lati ran awọn ijọ Ọlọrun ti o ṣe alaini lọwọ. Pọọlu tilẹ sọ wipe ọrọ awọn ara yi kọja ki a kan ni itara lati fifunni nikan, wọn tun jafafa lati ṣe bẹẹ pẹlu. Ṣugbọn ni ikorita kan, fun awọn idi ti a ko mọ, wọn bẹrẹ si ni fa ṣẹyin ni fififunni, wọn ko si pari nkan ti wọn dawọle.
Nitorina, Pọọlu nilo lati ba wọn sọrọ lori ọrọ yi ninu lẹta rẹ si wọn. O si sọ fun wọn pe ko to ki eniyan fi imura rẹ lati fifunni han; o tun nilo lati jẹ ki ififunni rẹ wa ni idọgba pẹlu imura rẹ, ni ibamu pẹlu nkan ini rẹ. Bi o si tun ṣe tẹsiwaju lati fi han, niwọn igba ti imura lati fifunni ba ti wa, ohun yowu ti a ba fifunni yoo jẹ itẹwọgba ni iwaju Ọlọrun, ni ibamu pẹlu ohun ti a ni dipo eyi ti a ko ni.
Nitorina, niwọn igba ti o ba ti ni nkan lọwọ, ri daju pe o n fifunni lati ara rẹ dipo ti o o fi ma wa awawi. Idi si ni pe ko ki i ṣe awọn awawi rẹ ni Ọlọrun yoo pin ọ lere fun bikoṣe igbọran rẹ si ọrọ rẹ. Adura mi wa ni pe ki o ma ṣe fi igba kankan ba ara rẹ ni ipo ti ọda yoo fi da ọ debi pe o ko ni ni nkankan ti iwọ yoo le fifunni, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọṣẹ alaafia.
Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

