Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo fi tayọtayọ ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ẹrẹna 2023. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma fi gbogbo igba ri ọ lo lati fu didara rẹ han si gbogbo awọn ti o wa ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ọlọrun, bi a ti ṣe ri ninu Bibeli, ma n fi gbogbo igba foju silẹ wa awọn ti yoo lo lati fi ifẹ rẹ ati didara rẹ si awọn ọmọ eniyan han. Nkan ti O si fẹ ni awọn ti yoo fi ara wọn silẹ fun tọkantọkan lati lo wọn. Bi wọn ko tilẹ wa ni amuyẹ pataki kankan ti o le ya wọn sọtọ laarin awọn eniyan, yoo ṣe wọn yẹ pẹlu ohun gbogbo ti wọn nilo lati le mu ete rẹ ṣẹ. Ti wọn ba si tẹsiwaju lati ma sin pẹlu otitọ, o ṣeeṣe ki orukọ wọn di eyi ti gbogbo aye yoo mọ.
Amuyẹ pataki wo ni Peteru, Jemisi ati Johanu ni ti wọn fi di ẹni ti Ọlọrun n lo lati fi ogo rẹ han kaakiri agbaye? Ko si amuyẹ pataki kankan ti wọn ni ti a mọ nipa rẹ! Lotitọ bibeli sọrọ awọn eniyan bi Josẹfu, Solomọni ati Daniẹli ti wọn tayọ ninu ọgbọn, imọ ati oye. Ṣugbọn a ko ṣe apejuwe awọn ọkunrin ti Jesu kọkọ pe lati jẹ apọsiteli rẹ ni mimu iyinrere oore-ọfẹ Ọlọrun kaakiri agbaye gẹgẹ bi awọn ti o ni amuyẹ pataki kankan. Dipo eyi, a sọ fun wa ninu bibeli pe ọpọ ninu wọn ni ko lọ ile ẹkọ. Sibẹsibẹ Ọlọrun lo wọn lati ṣe awọn nkan babara, awọn nkan ti o kọja nkan ti ọgbọn araye le gbe.
Ki wa lo fa ti Ọlọrun ṣe lo irufẹ awọn eniyan yi? Bibeli sọ wipe nitori ki ẹnikẹni ma ba le sogo pe nitori awọn amuyẹ kan ti oun ni ni Ọlọrun ṣe n lo oun. Ọlọrun le lo ẹnikẹni, lalai fi ti amuyẹ tabi aleebu rẹ ṣe. Bibeli tilẹ jẹ ki o ye wa pe Ọlọrun le lo awọn ope eniyan lati dojuti awọn ọlọgbọn eniyan ati awọn ti a ko ka si nkankan lati doju ti awọn eniyan pataki. (Wo: 1Kọrinti 1:26-29)
Njẹ ki wa ni Ọlọrun nilo lati le lo irufẹ awọn eniyan yi? Akọkọ, O nilo ki wọn wa ni arọwọto rẹ. Ki a wa wa ni arọwọto Ọlọrun niru ọna yi kọja ki a kan wa ni ibi ti O wa. O tun ni i ṣe pẹlu ki a jẹ ki O mọ pe a wa ni arọwoto rẹ fun iwulo rẹ. Eniyan le wa ni ibikan, ki o si ma fi ara rẹ silẹ lati ran ẹnikẹni lọwọ tabi lati sin ẹnikẹni. Nitorina, ti o ba fẹ ki Ọlọrun lo ọ, lalai fi nkan ti o ni tabi ti o ko ni ṣe, ma fi gbogbo igba fi ara rẹ han bi ẹni ti o wa ni arọwọto rẹ fun lilo rẹ. (Wo: Aisaya 6:1-8)
Ekeji, Ọlọrun nilo awọn ti yoo lo lati fi tọkantọkan fi ara rẹ jin fun un (Róómù 12:1; Jèmíísì 4:7). Eyi tunmọ si pe wọn gbọdọ rẹ ara wọn silẹ fun lati ṣe awọn nkan ti O fẹ ki wọn ṣe gẹgẹ bi O ti fẹ ki wọn ṣe e yatọ si bi wọn ti ro o lọkan ara wọn. O wa jasi pe ẹnikẹni ti ko ba ṣetan lati rẹ ara rẹ silẹ niwaju Ọlọrun ati lati ṣe iṣẹ rẹ bi O ti ṣe fẹ ko le jẹ lilo fun lati mu ete rẹ ṣẹ, bi ẹni naa tilẹ wa ni arọwọto rẹ.
Ẹkẹta, Ọlọrun nilo ki irufẹ awọn ti yoo lo ṣetan lati ṣe afọmọ ara wọn. Nkan ti Ọlọrun n fẹ kọja nkan ti a le ṣe fun un; o tun ni i ṣe pẹlu iru ọkan ti a fi ṣe e. Iru ọkan ti a fi ṣe iṣẹ rẹ ni yoo so boya iṣẹ naa yoo munadoko to lati mu ete rẹ ṣẹ tabi boya yoo fi idibajẹ si iṣẹ naa. Nitorina, a gbọdọ mura silẹ fun lati fọ wa mọ kuro ninu ohunkohun ti o le ba iṣẹ rẹ jẹ tabi sọ di alailere lati ọwọ wa. Ẹnikẹni ti o ba wa lodi si ọrọ ibawi, ọrọ ikilọ tabi ọrọ itọni ko yẹ ni ẹni ti O le lo fun iṣẹ rẹ, bi o ti wu ki ẹni naa ni ẹbun to. (Wo: 2Tímótì 2:20-21)
Ni kukuru, awọn apọsiteli igbaani yi ni awọn nkan ti Ọlọrun n wo yi, bi o tilẹ jẹ wipe wọn ko ki ṣe ọjọgbọn, gbajumọ tabi ọlọrọ eniyan ni akoko ti Oluwa pe wọn. Gbogbo wọn fi ara wọn si arọwọto fun Oluwa lati lo, wọn rẹ ara wọn silẹ lati sin in bi O ti ṣe fẹ, wọn si tun jọwọ ara wọn fun lati wẹ wọn ati lati ṣọ wọn di mimọ. Nitorina, O mu wọn, O gbe wọn ro, O si tun lo wọn ni awọn ọna ti ẹnikẹni ko ro wipe o ṣeeṣe. Ti awa naa ba si fẹ ki O lọ wa ni ọna kanna, nṣe ni ki awa naa ṣe bi wọn ti ṣe ṣe.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
