April 2023

Kíló dé tí ò ń ṣe èyí sí ara rẹ? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 30, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 52

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Mo fi tayọtayọ ki ọ kaabọ si ọjọ Isinmi ti o kẹyin oṣu Igbe 2023. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun la ọna fun ohun gbogbo ti O fẹ ki o ni ninu oṣu yi ti o ko i ti ri gba lati tọ ọ wa ki oṣu naa to pari, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe wọ inu ọsẹ tuntun yi, mo fẹ ran ọ leti nkan ti Pọọlu sọ fun wa nipa bi o ti ṣe ṣeeṣe ki eniyan ma fi gbogbo igba kọ ọrọ Ọlọrun, ki o si tun ma mọ ohunkohun nipa rẹ tabi nipa otitọ rẹ (2Tímótì 3:7). Ki wa lo le fa ti ẹnikan yoo ma wa si awọn ipade ijọ, ti yoo si maa gbọ Ọlọrun, sibẹsibẹ ti ko ni ni imọ Ọlọrun tabi imọ awọn otitọ nipa ile aye ti o ṣe pataki ju lọ? Ara awọn nkan ti o ma n fa ni ki eniyan ma gbajumọ nkan ti o n kọ.

Ti ọrọ Ọlọrun ba n tọ ọ wa, ti o ko si ma fi ọkan ba nkan ti a n kọ ọ lọ, ṣugbọn ti o n ronu nipa nkan miran tabi ti o n sun, ko si bi o ṣe fẹ ri nkankan mu jade ninu ohun ti o n kọ. O wa ṣeni laanu pe ki wọn ma ma kọbiara si ọrọ Ọlọrun ti o n tọ wọn wa tabi ki wọn ma sun nigba ti ọrọ Ọlọrun ba n tọ wọn wa ti di aṣa fun ọpọ ti a n pe ni Kirisitiẹni loni. Eyi tunmọ si pe nkan ti wọn n fi gbogbo igba ṣe ni eyi. Ko wa jẹ iyalẹnu pe lati igba ti wọn ti di Kirisitiẹni, ti wọn si ti n wa si ipade ijọ Ọlọrun, ko si iyipada kankan ti o ṣe fi oju ri ninu aye wọn.

Idi miran ti awọn eniyan tun ṣaba fi ma n kọ ọrọ Ọlọrun, sibẹsibẹ ti wọn ko ni mọ otitọ Ọlọrun ni ailoye nkan ti wọn n kọ. Jesu Oluwa sọ fun wa taratara pe ti eniyan ba gbọ ọrọ Ọlọrun, ti ko si ye, Satani yoo tọ ọ wa, yoo si ja ọrọ ti o ti gbọ gba kuro lọwọ rẹ. Nitorina, ko si bi ọrọ ti o gbọ ṣe fẹ gbe ohun rere kankan ṣe ninu aye rẹ — nṣe ni yoo ja si pabo. (Wo: Mátíù 13:19)

Wayi o, o ṣe e gbọ ti ẹni ti ko ki i ṣe ọmọ Ọlọrun ba gbọ ọrọ Ọlọrun, ti ko si ye. Idi si ni pe ko ni Ẹmi Ọlọrun ti o ma n fun awọn eniyan ni oye awọn otitọ ẹmi ninu rẹ (1Kọ́rínntì 2:12). Ṣugbọn ti ẹni ti o jẹ ọmọ Ọlọrun, ti o si ni Ẹmi rẹ ninu, ba wa n gbọ ọrọ rẹ, sibẹsibẹ ti oye nkan ti o n gbọ ko ye, a jẹ wipe o ṣeeṣe ki nkan ma ṣe tabi ki nkan ma ṣe olukọ rẹ. Nkan ti o n ṣe si le jẹ pe ko ki i lakakaka lati ni oye nkan ti o n kọ. Nitorina, ko ni gbiyanju lati ronu nipa ohun ti o gbọ tabi lati ṣe aṣaro le lori. Ko si tun ni gbiyanju lati wa inu Iwe mimọ lati ri boya nkan ti o gbọ otitọ ni tabi bẹẹkọ. Ki si ni idi? Idi ni pe o ya ọlẹ. Nitorina, bi awọn ara Heberu, ko ni ifẹ si nini imọ otitọ. Irufẹ ẹni bayi ko si le lailai dagba ninu nkan ti ẹmi. (Wo: Heberu 5:11-14)

Ṣiwaju si, a tun ni awọn ti o n gbọ ọrọ Ọlọrun, ti o si n ye wọn, ṣugbọn ti wọn ko ni lọkan lati ṣiṣẹ le lori. Ki wa ni yoo fa ti eniyan yoo gbọ ọrọ Ọlọrun, ti yoo si ye, sibẹsibẹ ti ko ni pinu lọkan rẹ lati ṣe amulo rẹ? Nkan ti o ṣaba ma n fa ni ki eniyan ma gbagbọ pe oun ni ọrọ ti o n gbọ wa fun. O le ri ọrọ yi pe o wa fun ẹlomiran lati ṣiṣẹ le lori, ṣugbọn ko ni ri bi igba ti o wa fun oun tikararẹ. Idi si ni yi ti awọn eniyan fi n gbọ ọrọ Ọlọrun ati awọn aṣẹ miran ninu awọn ipade ijọ wọn lọsọọsẹ, sibẹsibẹ ti wọn a jade lọ, ti wọn a si ṣe bi igba ti wọn ko gbọ nkankan tabi ki wọn lọ se idakeji nkan ti wọn gbọ.

Ibere wa ni pe, “Ki ni o de ti o n ṣe eyi si ara rẹ?” Ki lo fa ti o n fi akoko rẹ ṣofo lati ma kọ ọrọ Ọlọrun, ti o si jẹ wipe o ko ni lọkan lati ṣe amulo rẹ tabi ti o ko ni ifẹ lati ri pe ọrọ naa ṣiṣẹ ninu aye rẹ? Wo o, ọrọ Ọlọrun ko ni ṣe anfaani kankan fun ọ, ti o ko ba tẹwọgba, ki o si ṣe ohun ti o sọ. Rara o, ọrọ rẹ ko ni ṣi oju rẹ si otitọ ti o nilo lati di ominara laye, ti o ko ba kọ iha ti o tọ lati tẹwọgba ati lati ṣe amulo rẹ. Nitorina, ti o ba wa lara awọn ti o ti n gbọ ọrọ Ọlọrun fun bi ọdun melokan, sibẹsibẹ ti wọn ko dangajia ninu nkan ti Ọlọrun, o nilo lati tun ero rẹ pa lori nkan ti o n ṣe si ara rẹ, ki o si yi ọna rẹ pada. Aijẹbẹ, o ko ni dẹkun lati ma lu igbadi irọ eṣu ati aṣiṣe awọn ọdanran eniyan.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí ó ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Kíló dé tí ò ń ṣe èyí sí ara rẹ? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 30, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 52 Read More »

Àdúrà àti ìfifúnni – kì í ṣe àdúrà nìkan | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 23, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 51

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati aanu jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Igbe 2023. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ya ọkan rẹ ya ohun gbogbo ti o ni ṣe pẹlu ṣiṣe ahun si i, ki gbogbo orisun ibukun rẹ̀ ti o ti di ninu aye rẹ ba le jẹ ṣiṣi fun isoriire rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọpọ igba ni o ma n jẹ iyalẹnu fun ọpọ ninu wa pe awọn kan ti ko ki i ṣe Kirisitiẹni rara n jẹ igbadun ojurere Ọlọrun fun igbega, ipamọ ati iṣoriire ni ọna ti o jẹ wipe awọn ti o jẹ onigbagbọ ti o wa ni ayika wọn gan ko jẹ igbadun rẹ. Idi kan pataki ti eyi si ṣe ri bẹ, bi a ti ṣe ri ninu iwe mimọ, ni ififunni. Ṣe o ri, nigba ti bibeli sọ wipe Ọlọrun fẹran oninudidun ọlọrẹ, ko tunmọ si pe Kirisitiẹni nikan ni ọrọ yi bawi (2Kọrinti 9:7). Ti alaigbagbọ kan naa ba jẹ oninudidun ọlọrẹ, Ọlọrun yoo fi ifẹ rẹ han si ni ọna ti o jọju ati ti o han kedere pẹlu.

Fun apẹrẹ, a sọ eyi fun wa ninu bibeli nipa ọkunrin kan ti a n pe ni Kọneliu:

Ọkunrin kan si wa ni Kesaria ti a n pe ni Kọneliu, balogun ọrun ti ẹgbẹ ọmọ-ogun ti a n pe ni Itali. Olufọkansi, ati ẹni ti o bẹru Ọlọrun tile tile rẹ gbogbo, ẹni ti o n tọrẹ aanu pupọ fun awọn eniyan, ti o si n gbadura sọdọ Ọlọrun nigba gbogbo. Niwọn wakati kẹsan-an ọjọ, o ri ninu iran kedere angẹli Ọlọrun kan wọle tọ ọ wa, o si wi fun un pe, “Kọneliu!” Nigba ti o si tejumọ ọn, ti ẹru si ba a, o ni, “Ki ni, Oluwa?” O si wi fun un pe, “Adura rẹ ati ọrẹ-aanu, tirẹ goke lọ siwaju Ọlọrun fun iranti.”” (Iṣe Apọsiteli 10:1-4)

Tani Kọneliu, bi a ti ṣe ri ninu akọsilẹ yi? Ṣe Kirisitiẹni ni! Irọ! Ṣe Juu ni? Irọ! Dipo awọn nkan yi, o jẹ jagunjagun keferi. Ṣibẹsibẹ, angẹli Ọlọrun kan farahan an lati sọ fun pe Ọlọrun da a mọ. Ki ni Ọlọrun da a mọ fun? O da a mọ fun adura rẹ ati pẹlu fun ififunni rẹ.

Dajudaju, Kọneliu, gẹgẹ bi jagungun, ni lati jẹ ọkunrin kan ti iṣẹ kun ọwọ rẹ. Sibẹsibẹ ko jẹ ki iṣẹ gba aye rẹ debi pe ko ni raaye lati gbadura. Ka tilẹ so otitọ, o fi ara rẹ jin lati gbadura to bẹẹ gẹẹ ti Ọlọrun fi da mọ gẹgẹ bi aladura. Njẹ Ọlọrun da iwọ naa bi aladura bi? Tabi iṣẹ ko jẹ ki o raaye lati ma ba a sọrọ?

Siwaju si, bi o tilẹ jẹ wipe jagunjagun ni Kọneliu, ko lo ipo rẹ lati ma lọ awọn eniyan lọwọ gba, bi ọpọ awọn ṣọja wa ati awọn oṣiṣẹ eleto aabo lọkunrin ati lobirin ṣe ma n ṣaba ṣe e. Dipo eyi, nṣe ni o n fi owo ti ara ran awọn alaini lọwọ. O wa lawọ́ si awọn alaini debi wipe Ọlọrun damọ gẹgẹ bi ọlọrẹ oninudidun ati ẹni ti o n fi tọkantọkan fun ni. Nitorina, eniyan ko ni lati jẹ Kirisitiẹni ki Ọlọrun to mu ni pataki. Ti ẹni naa ba mu Ọlọrun ni pataki nipa gbigba adura si ati lílawọ́ si awọn miran, Oun naa yoo mu ni pataki, yoo si tun fi ara rẹ han an.

Bi a ti ṣe ri ni ti Kọneliu, nitoripe o n fi lemọ-lemọ gbadura si Ọlọrun ati fifun awọn alaini, ọjọ kan de ti Ọlọrun ranti gbogbo nkan ti o ti n ṣe, ti O si pinu pe Oun gbọdọ ṣe nkankan lori ọrọ igbala ayeraye rẹ. Wa ranti pe bibeli sọ fun wa pe ki a ma rẹwẹsi ni ṣiṣoore fun awọn miran nitoripe, ni akoko ti o tọ, Ọlọrun yoo ranti wa, yoo si pin wa lere (Galatia 6:9). Bawo ni Ọlọrun yoo ṣe san wa ni ere fun lilawọ wa? Ko si ẹni ti o le sọ. Ọwọ rẹ ni o wa. Ṣugbọn o di dandan ki O pin wa ni ere fun un, yala Kirisitiẹni ni wa tabi bẹẹ kọ.

Nigba ti Ọlọrun ranti Kọneliu ni asiko ti a n sọ yi, ko ki i ṣe adura rẹ nikan ni O ranti rẹ fun. O tun ranti rẹ fun lilawọ rẹ pẹlu, O si ran angẹli rẹ si lati dari rẹ sọdọ Peteru, ọkunrin naa ti yoo fi ọna igbala han an. Nitorina, adura gbigba ko to fun wa lati ri awọn nkankan gba lọwọ Ọlọrun; a tun gbọdọ fi lilawọ kun adura wa. A si ri awọn ti ko ki i ṣe Kirisitiẹni ti o ni oye eyi, ti o si ma n ṣe amulo rẹ. Ki si ni idi? Ìrírí ti jẹ ki o ye wọn pe irufẹ nkan bayi ma n ṣiṣẹ.

O wa ṣeni laanu pe ọpọ awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ni oye ilana ẹmi yi ko ye rara. A ko mọ pe awọn asiko kan wa ti ko ki i ṣe adura wa ni Ọlọrun yoo lo lati ṣiṣẹ fun wa bikoṣe lilawọ wa. Nitorina, mejeeji ni o yẹ ki a fi ara wa jin fun. Nitoripe a ko mọ igba ti adura wa tabi (ati) lilawọ wa loni ni kọkọrọ ti yoo ṣi ilẹkun igbega tabi igbala wa lọla. Adura mi ni wipe o ko tun ni fi igba kankan padanu igbega tabi igbala rẹ mọ nitori aigbadura to tabi aififunni to. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Àdúrà àti ìfifúnni – kì í ṣe àdúrà nìkan | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 23, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 51 Read More »

Tan ìyìnrere náà kálẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 16, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 50

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. O dun mọ mi ninu lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Igbe 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ma fi gbogbo igba ri ọ lo lati tan iyinrere ọmọ rẹ Jesus Kirisiti kalẹ. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ọkan lara idi ti ọpọ fi tipasẹ iṣẹ iranṣẹ Jesu Kirisiti Oluwa wa di alabukunfun ni pe awọn ti a bukunfun nipasẹ rẹ n tan iyinrere rẹ kaakiri ọdọ gbogbo awọn ti o wa ni ayika wọn ati ni ibikibi ti wọn ba lọ. Fun apẹrẹ, lẹyin igba ti Jesu ti wo ọkunrun were kan san tan, O sọ eyi fun: “Lọ si ile si ọdọ awọn ẹbi rẹ, ki o si sọ fun wọn bi Ọlọrun ti ṣe ohun nla fun ọ, ati bi o si ti ṣaanu fun ọ.” (Maaku 5:19) Ṣe ọkunrin wa lọ tabi ko lọ? O lọ. Bibeli sọ wipe, “Nitori naa, ọkunrin yii pada lọ, o bẹrẹ si royin ni Dekapolisi nipa ohun nla ti Jesu ṣe fun un. Ẹnu si ya gbogbo eniyan.” (Maaku 5:20)

Wayi o, nkankan naa ni a n reti lati ọdọ wa. Bi Oluwa ti n bọ wa pẹlu ọrọ rẹ, ti O n yi aye wa pada, ti O si tun n ṣe oniruuru nkan iyanu fun wa ninu ijọ wa, nṣe ni o yẹ ki a ma tan iroyin didara rẹ si wa kaakiri. Ki ni idi? Idi ni ki awọn ti o ba gbọ wa naa ba le gba iwuru lati darapọ mọ wa lati ni iriri didara rẹ.
Njẹ o tilẹ mọ pe awọn ti Oluwa pa aṣẹ fun lati ma sọ ohunkohun nipa rẹ fun ẹnikẹni gan si papa tan iroyin didara rẹ kaakiri ibi gbogbo ti wọn lọ? Luuku, fun apẹrẹ, fi eyi han wa nipa nkan ti o ṣẹlẹ lẹyin ti Jesu ti wo ọkunrin adẹtẹ kan san:

“O si kilọ fun u pe, “Ki o ma ṣe sọ fun ẹnikan: ṣugbọn ki o lọ, ki o s fi ara rẹ han fun alufaa, ki o si ta ọrẹ fun iwẹnumọ rẹ, gẹgẹ bi Mose ti paṣẹ fun ẹri si wọn.” Ṣugbọn okiki rẹ n kan kalẹ: tobẹẹ ti ọpọ ijọ eniyan si jumọ pade lati gbọ ọrọ rẹ, ati lati gba dida ara lọdọ rẹ kuro lọwọ ailera wọn. Ṣugbọn Jesu a maa yẹra kuro, oun a si maa dawa lati gbadura.” (Luuku 5:14-16)

Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe Oluwa paṣẹ fun okunrin adẹtẹ yi lọna ti o ye yekeyeke pe ki o ma sọ ohun kan fun ẹnikẹni nipa Oun, ọkunrin yi ko dakẹ jẹ nipa ọrọ naa. Dipo eyi, bi awọn ti O ti wosan tẹlẹ, nṣe ni ọkunrin yi naa n lọ kaakiri, ti o si n sọrọ laibikita nipa rẹ ati nkan ti o ṣe fun un fun awọn eniyan. Eyi si jẹ ki ọpọ eniyan wa si ọdọ rẹ lati wa gbọ ọrọ rẹ ati lati gba iwosan fun awọn aisan wọn.

Ṣe o wa tọna fun ọkunrin yi lati ṣe aigbọran si Jesu Oluwa gẹgẹ bi o ti ṣe? Rara! Ninu akọsilẹ Maaku lori iṣẹlẹ yi kanna, o jẹ ki o ye wa pe aigbọran ọkunrin yi ko jẹ ki o ṣeeṣe fun Jesu lati wọ ibi kankan lalai da boolọ-ooya silẹ. Nitorina, aigbọran rẹ da rugudu silẹ fun Oluwa. Ṣugbọn ọkunrin yi ko ro wipe oun ṣe nkan ti ko dara rara ni asiko yi. O kan ro lọkan rẹ pe alanikanjọpọn ni oun yoo jẹ ti oun ba fi otitọ nipa ẹni ti o wo oun san, ti o si mu oun larada pamọ. (Wo: Maaku 1:40-45)

Ni kukuru, ọkunrin yi, ti Oluwa pasẹ fun lati ma sọ ohunkohun fun ẹnikẹni nipa rẹ woye lọkan rẹ pe alanikanjọpọn ni oun yoo jẹ ti oun ko ba sọ fun ẹnikẹni nitootọ ohun ti Jesu ṣe fun oun. Ṣe awa gan ko wa ni jẹ alanikanjọpọn ti o ga ju ti a ba kọ lati tan iyinrere didara rẹ si wa kaakiri, awa ti a ko gba aṣẹ kankan ti o jọ mọ eyi ti ọkunrin yẹn gba?

Nitorina, ti o ba ti n ni iriri didara ati agbara Ọlọrun ninu aye rẹ lati igba ti o ti dara pọ wa ninu ijọ yi, alanikanjọpọn ni ọ ti o ba panumọ lori rẹ, ti o ko tan iroyin naa kalẹ de ọdọ awọn miran. Lotitọ, ti o ba le fi idi rẹ mulẹ pe iwọ ko i ti ni iriri didara ati agbara Ọlọrun lati igba ti o ti darapọ mọ wa, yoo ye wa ti o ba ni ọ lara lati tan iroyin naa kalẹ. Idi si ni pe ko si iroyin kankan ti o fẹ tan kalẹ. Ṣugbọn ti o ko ba le fi idi rẹ mulẹ (ti mo si mọ pe o ko le fi idi rẹ mulẹ), o nilo lati bẹrẹ lati maa tan iroyin awọn nkan ti Ọlọrun n ṣe fun ọ ati si ọ ninu awọn ipade wa de ọdọ awọn ti o wa ni ayika rẹ. Nipa ṣiṣe eyi, awọn naa yoo le darapọ mọ wa lati ni iriri didara Ọlọrun ninu aye wọn.

Wayi o, mo fẹ ki o mọ pe Ọlọrun n fi ọkan tan ọ lati ṣe eyi. O si di dandan ki O pin ọ lere fun isododo rẹ ni didari awọn miran si ọdọ rẹ̀ lati ni iri igbala, iwosan, itusilẹ ati isọdọtun. Nitorina, mu ọrọ yii ni pataki. Njẹ ki a ṣe ọkan rẹ le lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Tan ìyìnrere náà kálẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 16, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 50 Read More »

Níbo ni inú dídùn rẹ́ wà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 09, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 49

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Igbe 2023. Adura mi si ni pe ki ayọ Ọlọrun ma fi gbogbo igba kun akunwọsilẹ ninu aye rẹ ninu ọsẹ naa ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi. Amin.

Wayi o, bi o ti ṣe mọ, loni yi, awọn Kirisitiẹni kaakiri agbaye n ṣe ajọyọ ajinde Jesu Kirisiti Oluwa wa. Njẹ nkan ti o dara kọ ni eyi bi? Nkan ti o dara ni. Mo n sọ wipe ko buru rara lati ya ọjọ kan sọtọ lati sọ awọn eniyan agbaye ji nipa iku, isinku, ajinde ati igbasoke Jesu Kirisiti Oluwa wa ati iwulo awọn nkan wọnyi. Nitori, mo ki ọ ku ayọ ajinde, ti iwọ naa ba n kopa ninu ajọyọ naa.

Amọ ṣa o, nkan ti Ọlọrun n fẹ lati ọdọ wa ju eyi lọ. Nkan ti O n fẹ lati ọdọ wa ni ki a ma fi ojoojumọ ran ara wa leti iwulo nkan ti Jesu ṣe fun wa, ki a si tun ma fi tayọtayọ fi ara jin lati sin in nitori rẹ. Idi kan pataki si niyi ti bibeli fi sọ fun wa pe ijọba Ọlọrun ko wa nipa ti ododo ati alaafia nikan biko tun ṣe nipa ti ayọ ti Ẹmi Mimọ n fun ni pẹlu (Roomu 14:17).

O wa ṣeni laanu pẹ ọpọ awọn eniyan Ọlọrun ni ko ki i ṣaba fi ayọ han ninu ijọsin wọn tabi iṣẹ iṣin wọn si i. Igba kan ṣoṣo ti diẹ miran lara wọn ma n fi ayọ tabi idunnu han rara lori ọrọ ti o ba ni i ṣe pẹlu Ọlọrun ni asiko ti wọn ba n kọ ori iyin tabi orin ọpẹ ninu awọn ipade ijọ wọn. Yatọ si eyi, ko si nkan miran ti wọn le ṣe fun Ọlọrun ti yoo jẹ pẹlu inu didun tabi ayọ. Inu wọn ko ki i dun lati gbadura. Inu wọn ko ki i dun lati fifunni. Inu wọn ko ki i dun lati gba ọrọ Ọlọrun. Inu wọn ko si ki i dun lati ke si ẹnikẹni lati wa tọ́ dídára Ọlọrun wo pẹlu wọn. Dipo eyi, ohunkohun ti wọn ba ṣe fun Ọlọrun ṣaba ma n jẹ pẹlu ikunsinu.

Ki ni idi? Idi pataki julọ ni pe inu wọn ko dun si ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun. Ti inu awọn eniyan ba dun si mimọ Ọlọrun ati wiwa ni ibaṣepọ pẹlu rẹ, ko si nkan ti wọn yoo ṣe fun un ti ko ni jẹ pẹlu ayọ. Wọn tilẹ ma fẹ ku fun pẹlu ayọ paapaa. Wo awọn apọsiteli igbaani. A sọ ninu bibeli pe igba kan wa ti a na wọn nitori iwaasu iyinrere. Sibẹsibẹ, wọn pada lọ si ile olukuluku wọn pẹlu ayọ pe a ka wọn yẹ lati jiya ati lati ṣẹsin nitori orukọ Jesu. Ki ni o fa ti wọn fi ṣe bayi? Oun naa ni pe ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun ati ọmọ rẹ Jesu Kirisiti n mu inu wọn dun. (Wo: Iṣe Apọsiteli 5:40-41)

Lafikun, a sọ fun wa ninu bibeli pe nigba ti Jesu pe Lefi agbowo-ode lati tẹle e, inu rẹ dun to bẹẹ gẹẹ ti o fi ṣe ase fun un (Luuku 5:27-28). Sakeu nkọ? Iha wo ni o kọ si ibẹwo Oluwa si ile rẹ? Iha ẹni ti iduunu rẹ ga pupọ ni o kọ si (Luuku 19:1-10). A si tun ri ọkan lara ti o kọ awọn Sáàmù wa ti oun naa sọrọ nipa idunnu rẹ si Ọlọrun pẹlu awọn ọrọ wọnyi: “Inu mi dun nigba ti wọn wi fun mi pe Ẹ jẹ ki a lọ sile Oluwa.” (Sáàmù 122)

Wayi o, awọn ti inu wọn ba dun si Ọlọrun ati ohunkohun ti o ba ni i ṣe pẹlu rẹ ni awọn ọna yi naa ni yoo ma fi gbogbo igba fi ara rẹ han, ti yoo si tun ma gbe ro lati ṣe oniruuru iṣẹ rere (Johanu 14:21). Nitorina, ti Ọlọrun ko ba ma fi ara rẹ han ọ siwaju ati ṣiwaju si, ti ko si tun ma ṣe ohunkohun lati bukun fun awọn miran nipasẹ rẹ, o yẹ ki o yẹ ara rẹ wo lati mọ boya inu rẹ dun si i. Ti inu rẹ ko ba si dun si i, a jẹ wipe awọn nkan kan wa ti inu rẹ dun si niyẹn. Bẹẹni, ti inu rẹ ko ba dun lati sin Ọlọrun ati lati gbe aye rẹ fun un, daju-ṣaka ni pe nkankan tabi ẹnikan wa ti inu rẹ dun si lati sin ati lati gbe aye rẹ fun. Ṣugbọn ṣe eyi yoo lere fun ọ nikẹyinkẹyin bi?

Iwọ naa wo nkan ti Mose sọ fun awọn ọmọ Israẹli lori ọrọ yi: “Nitori iwọ ko sin Oluwa Ọlọrun rẹ ni ayọ ati inu didun ni akoko alaafia. Nitori naa ninu ebi ati oungbẹ, ninu ihooho ati aini buburu, iwọ yoo sin awọn ọta a rẹ ti Oluwa ran si ọ. Yoo si fi ajaga irin bọ ọ ni ọrun, titi yoo fi run ọ.” (Ditarónómì 28:47-48) Ṣe o ri bayẹn? Awọn ti ko ba ni sin Ọlọrun pẹlu inu didn ati ayọ yoo pada sin Satani ati awọn ọmọ ogun rẹ ninu inira ati ibanujẹ. Mo wa gbadura pe ọrọ tirẹ ko ni yọri si eyi. Ṣugbọn ti o ba ri pe o ko ni inu didun tabi itara fun Ọlọrun rara tabi mọ, nṣe ni ko bọ si ori ekun rẹ, ki o si gbadura pe ki a da itara ati inu didun rẹ si i pada fun ọ ni kiakia. A o si gbọ ohun rẹ. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Níbo ni inú dídùn rẹ́ wà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 09, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 49 Read More »

Jẹ́ olótítọ́ àti olódodo nínú ìjọ́sìn rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 02, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 48

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu tuntun, oṣu Igbe 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki o pọ si gidigidi ninu ohun rere ati ohun ti o lere gbogbo ninu oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, bi a ti ṣe bẹrẹ oṣu tuntun yi, mo fẹ rọ ọ lati pa ọkan rẹ pọ lati fi ara rẹ jin lati fun Ọlọrun ni ijọsin otitọ. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni pe awọn ti yoo fun un ni ijọsin otitọ ni O n wa. Jesu sọ wipe, “Ṣugbọn akoko n bọ, o si de tan nisinsin yii, nigba ti awọn olusin tootọ yoo maa sin Baba ni ẹmi ati ni otitọ: nitori iru wọn ni Baba n wa ki o maa sin oun. Ẹmi ni Ọlọrun: awọn ẹni ti n sin in ko le ṣe alaisin in ni ẹmi ati ni otitọ.” (Jòhánù 4:23-24)

Njẹ o ri bayẹn? Ko ki i ṣe gbogbo awọn ti o n sunmọ Ọlọrun lati jọsin fun naa ni O ma n gba ijọsin wọn. Dipo eyi, kiki awọn ti ọkan wọn ba wa ni pipe ninu ijọsin wọn, ti wọn si jẹ olotitọ si ninu ohun gbogbo ti wọn n ṣe fun un nikan ni O ma n gba ijọsin wọn. Awọn wọnyi, ki a tilẹ sọ otitọ, ni O ma n wa kaakiri lati fi ara rẹ ati agbara rẹ han.

Ni Kironika, ori 16, ẹsẹ 9, a sọ eyi fun wa: “Nitori oju Oluwa yi gbogbo aye ka lati fi agbara fun awọn ẹni ti o ni ọkan pipe si i…” Iwọ naa ronu nipa ọrọ yi daradara. Ọlọrun ma n fi gbogbo igba foju silẹ wa awọn ti ọkan wọn jẹ olotitọ si i. Ki si ni idi? Idi ni ki O ba le fi agbara rẹ han nitori wọn. Nitorina, ti iwọ ko ba ma fi ojoojumọ ri ifarahan agbara Ọlọrun ninu aye rẹ, bi o tilẹ jẹ pe ninu awọn nkan aye yi ti a ko ka si babara ni, yi o fẹ dara ki o yẹ ara rẹ wo boya o jẹ olotitọ si nitootọ, boya ọkan rẹ n fi gbogbo igba gbe ara le fun ohunkohun ti o nilo tabi ti o fẹ ki o jẹ ṣiṣe.

Wo o, awọn ti ọkan wọn ko ba jẹ olotitọ si Ọlọrun kan n fi ijọsin wọn ṣofo ni (Máàkù 7:6-7). Eyi tunmọ si pe, asan ni ijọsin wọn, eyi ti Ọlọrun ko si le pin wọn ni ere fun. Njẹ Ọlọrun pin Kaini lere fun ọrẹ ti o mu wa fun bi? Rara o! Tabi ṣe Ọlọrun wo laala ti o ṣe lori ọrẹ ti o mu wa ki O si ti itori eyi fojufo otitọ ti o sorọ mọ ọkan rẹ ti ko wa ni pipe? Rara! Dipo eyi, gbogbo nkan ti o ṣe ni Ọlọrun kan si asan. Bi yoo si ti ṣe ri niyi fun ẹnikẹni ti ọkan rẹ ko ba wa ni pipe ninu ijọsin rẹ si Ọlọrun. Ohun gbogbo ti wọn ba n ṣe ni a o ka si asan. (Wo: Jẹnẹsisi 4:3-7)

Idi miran ti o tun ṣe ṣe pataki ki a fun Ọlọrun ni ijọsin otitọ ni pe ewu wa ninu ki a ma ṣe bẹ ẹ. A fun wa ni akọsilẹ iku ọkunrin kan ti a n pe ni Ananaya ati iyawo rẹ Safira ninu Iwe Ise Awọn Apọsiteli, ori 5. Ki ni idi ti wọn ṣe ku iku aitọjọ ti wọn ku? Idi ni pe ọkan wọn ko ṣe olotitọ si Ọlọrun. Wọn mu ẹtan wọ inu ijọsin wọn, a si ṣe idajọ wọn fun eyi lẹsẹkẹsẹ.

Wayi o, Ọlọrun le ma ṣe idajọ eniyan fun bi ko ṣe jẹ olotitọ si lẹsẹkẹsẹ. Iyẹn ko tunmọ si pe a ko ni ṣe idajọ ẹni naa ni asiko kan. O le jẹ wipe ago aiṣododo rẹ ni ko i ti kun. O si le jẹ wipe Ọlọrun n fun ni akoko lati ronupiwada ni. Tabi kẹ ki o jẹ wipe awọn eniyan kan n ṣipẹ fun iru ẹni yi, ti wọn si n bẹ Ọlọrun ki o ṣe aanu fun un. Ṣugbọn Ọlọrun ko ni kawọ-gbera titi lailai ki O si ma ṣe idajọ awọn alaiṣotitọ olujọsin, ti wọn ko ba ronupiwada. Ti o ba to asiko kan, yoo da ṣeria fun wọn ni ibamu pẹlu aiṣododo wọn, ki awọn miran ba le ti ara wọn kẹkọ.

Nitorina, ti ọkan rẹ ko ba ṣe deede pẹlu Ọlọrun ninu ijọsin rẹ, o nilo lati rẹ ara rẹ silẹ nisinsinyi, ki o si mojuto aisododo tabi ẹtan ti o wa ninu rẹ, ni igba ti asiko si wa fun ọ lati ṣe bẹ ẹ. Nipa ṣiṣe eyi, awọn nkan ti o n ṣe ni orukọ jijọsin fun Ọlọrun ko ni pada ja si asan tabi ki iwọ funrarẹ ṣi ilẹkun ṣilẹ fun idajọ rẹ lati wa sori rẹ. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun, ninu aanu rẹ, mojuto ohunkohun ti o ba jẹ aleebu ninu ijọsin ti o n fun un, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Jẹ́ olótítọ́ àti olódodo nínú ìjọ́sìn rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 02, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 48 Read More »

Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ ọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 26, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 47

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lai ni odiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo fi ọpẹ fun Ọlọrun fun bi O ti ṣe mu wa wọ inu ọsẹ ti o kẹyin oṣu yi, oṣu Ẹrẹ́nà 2023 lalaafia. Mo si gbadura pe ki O tun ṣe aṣeyọri ni ṣiṣe aye wa bi O ti ni lọkan pe ki wọn ri, ni ibamu pẹlu ete rere rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, eniyan le ma wo pe ṣe Ọlọrun tilẹ le kuna ni tootọ ni mimu nkan ti O fẹ ṣẹ ninu aye awọn eniyan? Ṣugbọn ọrọ Ọlọrun fi han wa pe Ọlọrun le kuna lotitọ ni mimu ete rẹ rere wa si imuṣẹ ninu aye eniyan. Ki si ni idi? Idi ni pe imuṣẹ ete rere Ọlọrun ninu aye wa ko ni i ṣe pẹlu Ọlọrun nikan; o ni i ṣe pẹlu awa naa. Bẹẹni, imuṣẹ ete rẹ ninu aye wa ni i ṣe pẹlu iha ti awa naa ba kọ si ọrọ oore-ọfẹ rẹ.

Bibeli sọ wipe ọrọ oore-ọfẹ Ọlọrun le gbe wa ro, ki o si tun fa ini wa ninu Kirisiti Jesu le wa lọwọ (Iṣe Apọsiteli 20:32). Ṣugbọn ọrọ rẹ ko kan ni dede gbe wa ro, ti a ko ba rẹ ara wa silẹ lati tẹwọgba ati lati ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu rẹ. Lafikun, ọrọ ko ni jẹ ki a gba ini wa ninu Kirisiti, ki a si tun jẹ igbadun rẹ, ti a ko ba fi tọkantọkan tẹwọgba ati ṣe amulo rẹ.

Fun apẹẹrẹ, bi a tun ṣe fi han ninu bible, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun mu awọn ọmọ Isiraẹli jade lati Ijibiti fun idi kan ṣoṣo, eyi ti o si ni i ṣe pẹlu ki O mu wọn wọ ilẹ ti o n ṣan fun wara ati oyin, ko le e mu ọpọ ninu wọn wọ ibẹ. Ki ni idi? Idi naa ni i ṣe pẹlu iha ti wọn kọ si ọrọ rẹ. Ọpọ lara wọn ni ko mu ọrọ rẹ ti o n tọ wọn wa ni pataki. Iha ti wọn si kọ si ọrọ rẹ buru to bẹẹ gẹẹ ti Mose fi sọ fun wọn ni igba kan pe, “Lati igba ti mo ti mọ yin ni ẹ ti n ṣọtẹ si Oluwa.” (Ditarónómì 9:24)

Iwọ naa wa roonu jinlẹ lori ọrọ yi. Moṣe dari awọn eniyan yi niwọn ogoji ọdun tabi ki o le diẹ, o si tun kọ wọn ni ohun gbogbo ti wọn nilo lati mọ nipa ifẹ Ọlọrun. Ṣibẹsibẹ, ẹri rẹ nipa wọn ni pe wọn ya ọlọtẹ ati ẹni ti ko ṣetan lati tẹle Oluwa tọkantọkan. Nitorina, fun ogoji ọdun, awọn eniyan wọnyi gbọ ọrọ Ọlọrun ṣugbọn kọ lati tẹwọgba tabi lati jẹ ki o yi wọn pada. Alabajọ ti wọn ko fi dagba ninu ẹmi. Alabajọ ti ọpọ wọn ko fi de ile ini wọn.

O wa ṣeni laanu pe ọpọ ọmọ Ọlọrun loni ni ko yatọ pupọ si awọn ara Isiraẹli yi ti Mose dari. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn ti wa ninu ijọ fun ọpọ ọdun, wọn ti kọ lati rẹ ara wọn silẹ niwaju ọrọ Ọlọrun. Nitorina, ti awọn adari wọn yoo ba jẹri nipa wọn, o ṣeeṣe ki ọ jẹ wipe nkan ti awọn naa yoo sọ ni pe, “Ọlọtẹ ni ọ lati igba ti mo ti mọ ọ,” tabi “Alagbere ni ọ lati igba ti mo ti mọ ọ,” tabi “Ahun ati aladanikanjọpọn ni o jẹ lati igba ti mo ti mọ ọ.

O wa ṣeeṣe pe bi ọrọ ti ri pẹlu rẹ leyi. O ṣeeṣe ki o jẹ wipe irufẹ ẹri ti ko dara yi ni awọn adari rẹ ni lati jẹ nipa rẹ. Ọrọ Ọlọrun n tọ ọ wa lẹkan si lọwọlọwọ yi, o si n sọ pe, “O ko nilo lati tẹsiwaju bayi, niwọn igba ti o le ronupiwada, ki a si tun ọ ṣe.” Ti o ba si gbọ ohun ti O n ṣọ fun ọ, ti o rẹ ara rẹ silẹ, ti o si tun yipada kuro ninu aṣiṣe rẹ, Oun yoo dariji ọ, yoo si tun fọ ọ mọ kuro ninu gbogbo aiṣododo rẹ. Igba naa ni ete rere rẹ yoo wa bẹrẹ si ni jẹyọ lẹkunrẹrẹ ninu aye rẹ.

Amọ ti o ba kọ lati gbọ ohun ti Ọlọrun n sọ fun, ti o si tẹsiwaju ninu ọna iṣọtẹ, igberaga, iṣekuṣe, anikanjọpọn, ahun tabi imẹlẹ, nṣe ni ki o mọ pe o le tẹsiwaju bi eyi fun gbogbo iyoku ọjọ aye rẹ ki o si ma da ẹni ti Ọlọrun fẹ ki O da tabi gbadun awọn nkan ti O fẹ ki o gbadun laye yi. Adura mi wa ni pe ki a ya ọkan rẹ ya ohunkohun ti o ni iṣe pẹlu agidi ti o n di ọ lọwọ lati fi rẹ ara rẹ silẹ niwaju Ọlọrun ati niwaju ọrọ rere rẹ ti o n tọ ọ wa. Amin.

Ki o ni ọṣẹ ibukun.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ ọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 26, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 47 Read More »