Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lai ni odiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo fi ọpẹ fun Ọlọrun fun bi O ti ṣe mu wa wọ inu ọsẹ ti o kẹyin oṣu yi, oṣu Ẹrẹ́nà 2023 lalaafia. Mo si gbadura pe ki O tun ṣe aṣeyọri ni ṣiṣe aye wa bi O ti ni lọkan pe ki wọn ri, ni ibamu pẹlu ete rere rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, eniyan le ma wo pe ṣe Ọlọrun tilẹ le kuna ni tootọ ni mimu nkan ti O fẹ ṣẹ ninu aye awọn eniyan? Ṣugbọn ọrọ Ọlọrun fi han wa pe Ọlọrun le kuna lotitọ ni mimu ete rẹ rere wa si imuṣẹ ninu aye eniyan. Ki si ni idi? Idi ni pe imuṣẹ ete rere Ọlọrun ninu aye wa ko ni i ṣe pẹlu Ọlọrun nikan; o ni i ṣe pẹlu awa naa. Bẹẹni, imuṣẹ ete rẹ ninu aye wa ni i ṣe pẹlu iha ti awa naa ba kọ si ọrọ oore-ọfẹ rẹ.
Bibeli sọ wipe ọrọ oore-ọfẹ Ọlọrun le gbe wa ro, ki o si tun fa ini wa ninu Kirisiti Jesu le wa lọwọ (Iṣe Apọsiteli 20:32). Ṣugbọn ọrọ rẹ ko kan ni dede gbe wa ro, ti a ko ba rẹ ara wa silẹ lati tẹwọgba ati lati ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu rẹ. Lafikun, ọrọ ko ni jẹ ki a gba ini wa ninu Kirisiti, ki a si tun jẹ igbadun rẹ, ti a ko ba fi tọkantọkan tẹwọgba ati ṣe amulo rẹ.
Fun apẹẹrẹ, bi a tun ṣe fi han ninu bible, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun mu awọn ọmọ Isiraẹli jade lati Ijibiti fun idi kan ṣoṣo, eyi ti o si ni i ṣe pẹlu ki O mu wọn wọ ilẹ ti o n ṣan fun wara ati oyin, ko le e mu ọpọ ninu wọn wọ ibẹ. Ki ni idi? Idi naa ni i ṣe pẹlu iha ti wọn kọ si ọrọ rẹ. Ọpọ lara wọn ni ko mu ọrọ rẹ ti o n tọ wọn wa ni pataki. Iha ti wọn si kọ si ọrọ rẹ buru to bẹẹ gẹẹ ti Mose fi sọ fun wọn ni igba kan pe, “Lati igba ti mo ti mọ yin ni ẹ ti n ṣọtẹ si Oluwa.” (Ditarónómì 9:24)
Iwọ naa wa roonu jinlẹ lori ọrọ yi. Moṣe dari awọn eniyan yi niwọn ogoji ọdun tabi ki o le diẹ, o si tun kọ wọn ni ohun gbogbo ti wọn nilo lati mọ nipa ifẹ Ọlọrun. Ṣibẹsibẹ, ẹri rẹ nipa wọn ni pe wọn ya ọlọtẹ ati ẹni ti ko ṣetan lati tẹle Oluwa tọkantọkan. Nitorina, fun ogoji ọdun, awọn eniyan wọnyi gbọ ọrọ Ọlọrun ṣugbọn kọ lati tẹwọgba tabi lati jẹ ki o yi wọn pada. Alabajọ ti wọn ko fi dagba ninu ẹmi. Alabajọ ti ọpọ wọn ko fi de ile ini wọn.
O wa ṣeni laanu pe ọpọ ọmọ Ọlọrun loni ni ko yatọ pupọ si awọn ara Isiraẹli yi ti Mose dari. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn ti wa ninu ijọ fun ọpọ ọdun, wọn ti kọ lati rẹ ara wọn silẹ niwaju ọrọ Ọlọrun. Nitorina, ti awọn adari wọn yoo ba jẹri nipa wọn, o ṣeeṣe ki ọ jẹ wipe nkan ti awọn naa yoo sọ ni pe, “Ọlọtẹ ni ọ lati igba ti mo ti mọ ọ,” tabi “Alagbere ni ọ lati igba ti mo ti mọ ọ,” tabi “Ahun ati aladanikanjọpọn ni o jẹ lati igba ti mo ti mọ ọ.
O wa ṣeeṣe pe bi ọrọ ti ri pẹlu rẹ leyi. O ṣeeṣe ki o jẹ wipe irufẹ ẹri ti ko dara yi ni awọn adari rẹ ni lati jẹ nipa rẹ. Ọrọ Ọlọrun n tọ ọ wa lẹkan si lọwọlọwọ yi, o si n sọ pe, “O ko nilo lati tẹsiwaju bayi, niwọn igba ti o le ronupiwada, ki a si tun ọ ṣe.” Ti o ba si gbọ ohun ti O n ṣọ fun ọ, ti o rẹ ara rẹ silẹ, ti o si tun yipada kuro ninu aṣiṣe rẹ, Oun yoo dariji ọ, yoo si tun fọ ọ mọ kuro ninu gbogbo aiṣododo rẹ. Igba naa ni ete rere rẹ yoo wa bẹrẹ si ni jẹyọ lẹkunrẹrẹ ninu aye rẹ.
Amọ ti o ba kọ lati gbọ ohun ti Ọlọrun n sọ fun, ti o si tẹsiwaju ninu ọna iṣọtẹ, igberaga, iṣekuṣe, anikanjọpọn, ahun tabi imẹlẹ, nṣe ni ki o mọ pe o le tẹsiwaju bi eyi fun gbogbo iyoku ọjọ aye rẹ ki o si ma da ẹni ti Ọlọrun fẹ ki O da tabi gbadun awọn nkan ti O fẹ ki o gbadun laye yi. Adura mi wa ni pe ki a ya ọkan rẹ ya ohunkohun ti o ni iṣe pẹlu agidi ti o n di ọ lọwọ lati fi rẹ ara rẹ silẹ niwaju Ọlọrun ati niwaju ọrọ rere rẹ ti o n tọ ọ wa. Amin.
Ki o ni ọṣẹ ibukun.
Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
