Ohungbogbo kọ́ ni búrẹ́dì | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 28, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 4
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo fi tayọtayọ ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Èbìbí ati Òkúdù 2023 pọ mọ ara wọn. Mo si gbadura pe ki oju rẹ ṣi lati mọ ohun gbogbo ti o wa ni ọwọ rẹ ti o yẹ ki o gbin gẹgẹ bi irugbin iṣoriire ati pe ki ọkan rẹ gba okun ati itọni lati gbin awọn nkan wọnyi si ibi ti wọn yoo ti dagba, ti wọn yoo si tun mu ikore ti o ga wa fun ọ, ni orukọ Jesu. Amin.
Jesu Oluwa wa, nigbakan ti O n waasu si awọn Juu, sọ eyi: “Loootọ, loootọ ni mo wi fun yin, bi ko ṣe pe alikama ba bọ si ilẹ, ti o ba si ku, o wa ni oun nikan; ṣugbọn bi o ba ku, a si so ọpọlọpọ eso.” (Johanu 12:24) O si sọ awọn ọrọ wọnyi lati jẹ ki o ye awọn eniyan bi o ti ṣe ṣe pataki to fun un, gẹgẹ bi ọmọ bibi kan ṣoṣo Ọlọrun, lati ku ki Ọlọrun ba le ni ọpọlọpọ ọmọ ninu ogo rẹ (Heberu 2:10). Nitorina, nṣe ni ohun ti O sọ ni asiko yi n tọka si nkan ti ẹmi.
Amọ ṣa o, a ko gbọdọ gbagbe pe awọn ọrọ Oluwa wa wọnyi n kọkọ tọka si nkan ti ara, eyi ti gbogbo awọn ti o jẹ agbẹ si mọ. Agbẹ kọọkan ni o mọ pe lati sọ irugbin kan di ẹgbẹlẹgbẹ irugbin, a kọkọ gbọdọ gbin in sibikan. Eyi jasi pe, a kọkọ gbọdọ jọwọ irugbin naa fun iku. Aijẹbẹ, ko ni kuro ni irugbin kan debi pe yoo wa di ilọpọ lọwọ wa. Ṣugbọn ni kete ti a ba ti gbin sinu ilẹ ti o dara, a ti fun un ni anfaani niyẹn lati dagba ati lati sọ ara rẹ di ilọpo-ilọpo lọwọ wa.
Wayi o, ko ki i ṣe idi iṣẹ ọgbin nikan ni ilana yi ti wulo. Ko fẹrẹ si abala aye yi ti ko ti wulo. Fun apẹrẹ, ti o ba fẹ ki ọrọ rẹ pọ si, ọkan lara nkan ti o gbọdọ fi ara rẹ jin fun ni gbigbin owo rẹ sori okowo kan tabi omiran. Aijẹbẹ, ohun ti o ni ko ni pọsi. Ayafi ti yoo ba tun dinku si.
O wa ṣeni laanu pe ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun ni oye nkan yi ko ye. Lotitọ, wọn fẹ pọ si ni ọrọ, ki wọn si le ṣe gbogbo awọn nkan nla ti Ọlọrun fẹ ki wọn fi owo ṣe. Nitorina, wọn a ma gbadura, gbaawẹ ati pẹlupẹlu fun awọn eniyan Ọlọrun ni nkan. Ṣugbọn wọn ko ma gbin owo ti Ọlọrun fun wọn sori okowo tabi katakara kankan, ki o ba le pada tọ wọn wa ni ilọpo-ilọpo. Dipo eyi, ni ọpọ igba, nṣe ni wọn a ko ohun gbogbo ti o ba ti ọdọ Ọlọrun tọ wọn wa jẹ, ti wọn a si tun ma duro ki O fi awọn nkan miran ranṣẹ.
Eyi ko wa le yọri si ki wọn ni ọrọ. O dara lotitọ ki a ma gbadura, nitori, nipasẹ adura, a le ri awọn ipese Ọlọrun fun wa lati gbadun aye wa gba. O si tun dara ki a ma fifun awọn ti o n bọ wa pẹlu ọrọ Ọlọrun, nitori nipa ṣiṣe eyi, a le gba awọn iṣẹ iyanu ti yoo gba wa lọwọ iyan tabi ti yoo fun wa ni iyara lati ṣe aṣeyọri. Amọ, a tun gbọdọ ni oye pe adura ko le jẹ ki irugbin ti a ko gbin dagba. Bẹẹ si ni, awọn iṣẹ iyanu ipese kan wa ti Ọlọrun ko ki i ṣe lojoojumọ. Iṣẹ iyanu Mana gan ko waye titi lailai fun awọn ọmọ Isiraẹli. O wa si opin ni asiko kan. O wa si opin nigba ti awọn ọmọ Isiraẹli de ibi ti wọn ti le ṣiṣẹ ọgbin lati kore wara ati oyin ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wọn.
Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ṣetan lojoojumọ lati ṣe iṣẹ iyanu lati pese ohun ti a nilo ati lati sọ wọn di ilọpo-ilọpo fun wa, O tun jẹ ki o ye wa lati ipasẹ ọrọ rẹ pe ko ki i ṣe gbogbo nkan ti O ba fun wa naa ni burẹdi fun wa lati jẹ. Apa kan lara ipese rẹ fun wa jẹ irugbin ti a nilo lati gbin, ki a ba le gbe ipese rẹ fun aye wa ro. Ṣugbọn ti a ba tẹsiwaju lati ma fi aimoye jẹ ohun ti o yẹ ki a gbin, ko si bi a o ti ṣe le sọ ipese Ọlọrun fun wa di ilọpo-ilọpo, ti a o si tun le gbe ipese rẹ fun wa ro. Nitorina, dipo ti a o fi ma fi igba gbogbo ri ikore awọn nkan ti a gbin gba, eyi ti o jẹ iṣẹ iyanu funrarẹ, nṣe ni a o kan ri pe ọpọ igba ni a o ma duro de iṣẹ iyanu ipese miran ti a o tun ko jẹ bi a ti ṣe ma n ṣe. (Wo: 2Kọrinti 9:9-10)
O wa yẹ ki iwọ naa ri bayẹn idi ti ọpọ awọn eniyan Ọlọrun ṣe ma n pada ku sinu iṣẹ. Eyi ko yẹ ki o ri bẹ rara. Ṣugbọn ko ni ye ribẹ niwọn igba ti a ko ba ti mọ ifẹ Ọlọrun fun wa lori ilọrọ wa. Ki si ni ifẹ rẹ fun wa lori ilọrọ wa? Akọkọ, ifẹ rẹ ni pe ki a fi igbẹkẹle wa sinu rẹ nikan fun ọrọ wa, nitori Oun ni O ma n fun eniyan ni amuyẹ lati di ọlọrọ. Ekeji, ifẹ rẹ ni ki a ya irugbin wa sọtọ kuro lara burẹdi wa. Ẹkẹta ni pe ki a gbin irugbin wa si ibi ti o tọ, iyẹn sori okowo ti o tọ ati sinu awọn eniyan ti o tọ. Nipa ṣiṣe eyi, aṣẹ ibukun rẹ ti o sọ pe, “Niwọn igba ti aye ba ṣi wa, igba ọgbin ati ikore ko ni ṣe alaima wa,” ko ni kuna lati ṣiṣẹ ninu aye wa fun ilọrọ wa (Jẹnẹsisi 8:22).
Ki o ni ọsẹ ti o ga.
Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)



