Òun yó wá ẹlòmíràn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 21, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 3

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Èbìbí 2023. Mo si gbadura pe ki ọkan rẹ ma fi gbogbo ṣe ifẹ Ọlọrun fun ọ pẹlu iyara ati otitọ ni gbogbo asiko, ki ẹlomiran ma ba gba ààyé rẹ ninu ijọba ayeraye Ọlọrun. Amin.

Johanu Onitẹbọmi, nigbakan ti o n waasu fun awọn ọmọ Isiraẹli, sọ eyi fun wọn: “Ẹ so eso ti o yẹ fun ironupiwada. Ki ẹ ma si ṣe ro ninu ara yin pe, ‘Awa ni Abrahamu ni baba.’ Emi wi fun yin, Ọlọrun le mu awọn ọmọ jade lati inu awọn okuta wọnyi wa fun Abrahamu.” (Mátíù 3:8-9) Ki ni idi ti o fi sọ awọn ọrọ wọnyi si wọn? Idi ni pe bi o tilẹ jẹ wipe a ti fi ifẹ Ọlọrun han wọn nipasẹ awọn Iwe mimọ wọn, wọn ko ma gbe ni ibamu pẹlu rẹ. Sibẹsibẹ wọn ko dẹkun a ti ma dunnu lori wipe wọn jẹ arọmọdọmọ Aburahamu.

O wa ṣeni laanu wipe ọpọ loni lo dabi awọn wọnyi. Orukọ ati iyi awọn obi wọn tabi ti awọn baba ati iya awọn obi wọn ni wọn n fi ṣaye. Ṣugbọn awọn funrawọn ko ni orukọ rere tabi iyi kankan ti o le jẹ ki ẹnikẹni ti o ba mọ nkan ti o n ṣe fẹ da nkankan pọ pẹlu wọn. Nkan ti wọn ko si mọ ni pe ti wọn ko ba gbe igbe aye wọn ni ibamu pẹlu orukọ rere ati iyi awọn ti wọn ti ara wọn jade, asiko kan n bọ ti ko ni si ẹnikẹni ti yoo ka ibaṣepọ wọn pẹlu awọn ti wọn ti ara wọn jade wa si mọ. Dipo eyi, nṣe ni wọn yoo yi oju pada sọdọ awọn ti o n rin ni ipasẹ awọn ẹni nla yi, ti wọn yoo si bẹrẹ si ni kan sara si orukọ wọn.

Eyi gan wa ni nkan ti Johanu Onitẹbọmi n fi han awọn eniyan rẹ, awọn ara Isiraẹli, nigbati o sọ awọn ọrọ inu Iwe mimọ ti o wa loke yi fun wọn. O fẹ ki wọn mọ pe wọn ko le jẹ ogun ibaṣepọ Aburahamu pẹlu Ọlọrun. Nṣe ni awọn naa yoo nilo lati fidi ibaṣepọ wọn pẹlu rẹ mulẹ nipa mimu un ni pataki gẹgẹ bi Aburahamu ti ṣe. Ki si ni idi? Idi ni wipe nṣe ni a ma n fi idi ibaṣepọ lọlẹ ni, a ki i jogun rẹ.

Wo o, pe ẹnikan jẹ ọrẹ ti o dara si awọn obi rẹ ti o ti ku ko tunmọ si pe yoo jẹ ọrẹ daradara si iwọ naa pẹlu. Ti o ko ba ba ẹni naa lo bi awọn obi rẹ ti ṣe ba a lo, ti o ba ya, o le yi ọkan rẹ pada nipa rẹ, ki o si ma ni nkankan ṣe pẹlu rẹ mọ. Ṣe eyi wa jasi pe o ti yi ọkan rẹ pada nipa awọn obi rẹ naa? Rara o! Ọrọ ibaṣepọ rẹ pẹlu awọn obi rẹ ko ni iṣoro. Ṣugbọn ko si bi yoo ṣe tẹsiwaju pẹlu rẹ ninu ibaṣepọ kan naa, ti o ko ba ni fun ni irufẹ ọwọ ati ifẹ ti awọn obi rẹ fun un.

Nibakanaa, Johanu fẹ ki awọn Juu yi mọ pe ti wọn ko ba ni mu Ọlọrun ni pataki bi baba-nla wọn, Aburahamu, ti ṣe ṣe, wọn ko ni jẹgbadun Ọlọrun bi o ti ṣe jẹ igbadun rẹ. Dipo eyi, nṣe ni Ọlọrun yoo wa awọn ọmọ miran fun ara rẹ ti yoo ba lo pọ bi Aburahamu ti ṣe ṣe, bi O tilẹ wa nilo lati gbe awọn ọmọ naa dide lati ara awọn okuta kan. Nkan ti eyi si n sọ fun wa ni pe ti a ko ba ni ṣe ifẹ Ọlọrun lati ọkan wa, ti o ba to asiko kan, yoo wa awọn miran ti yoo ṣe Oun ti O fẹ lati rọpo wa, bi o tilẹ jẹ wipe idile awọn ti wọn ti sin in, ti wọn si fẹran rẹ ni a ti jade wa.

A si wa ri apẹrẹ ninu Iwe mimọ lori bi O ti ṣe rọpo awọn kan ti wọn ko ni ṣe ifẹ rẹ pẹlu awọn ti o ṣetan lati ṣe ohun ti O fẹ. Fun apẹrẹ, O fi Samuẹli rọpo awọn ọmọkunrin Eli, O si fi ṣe onidajọ fun Isiraẹli dipo wọn. O tun rọpo Ọba Sọọlu pẹlu Dafidi, bi o tilẹ jẹ wipe Dafidi ko ki i ṣe ọmọ-ọba. Adura mi si pe o ko ni ba ọrọ rẹ de ibi ti yoo ti rọpọ iwọ naa pẹlu ẹlomiran ninu ijọba rẹ, ninu idile rẹ, ni adugbo rẹ tabi ni ibi iṣẹ tabi ile-iwe rẹ.

Ṣugbọn iwọ naa nilo lati bẹrẹ si ni mu ibaṣepọ rẹ pẹlu rẹ ni ọkunkundun. O nilo lati bẹrẹ si ni mu ṣiṣe ifẹ rẹ ni pataki. Ki ni awọn nkan ti O fẹ ki o ṣe? Awọn ibo wo ni O fẹ ki O lọ? Awọn eniyan wo ni O fẹ ki o ran lọwọ pẹlu nkan ini rẹ? O nilo lati fi ara balẹ lati gbadura ati lati kẹkọ ninu ọrọ rẹ lati mọ awọn nkan wọnyi ati lati fi ara rẹ jin fun wọn. Aijẹbẹ, ojọkan yo jọkan ti yoo jasi dandan fun un lati wa ẹlomiran lati ṣe ohun ti o kọ lati ṣe, nitoripe iṣẹ rẹ ko jẹ alaimaṣe.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *