July 2023

Lọ ọpọlọ rẹ pẹ̀lú | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 30, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 13

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun yi, ọsẹ ti so oṣu Agẹmọ ati oṣu Ògún 2023 papọ mọra wọn. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma fi igba gbogbo kun ọkan rẹ pẹlu ọgbọn ti o peye lati lo gbogbo awọn idojukọ yowu ti o ba n ba pade laye gẹgẹ bi atẹgun si awọn ipo ti o ga ju eyi ti o wa yi lọ. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu iwe mimọ, Ọlọrun ko fi igba kankan sọ wipe a ko ni ba idojukọ pade laye yi. Dipo eyi, nkan ti O sọ fun wa ni pe a o dojuko oniruuru ipọnju ninu aye yi. Amọ ṣa o, O tun wa sọ fun wa pe ki a tujuka, bi o tilẹ jẹ wipe a ko le ṣalai ma ba iṣoro pada ninu aye yi. Ki si ni idi? Idi ni pe gbogbo igba ni yoo ma wa pẹlu wa lati ri pe a rin ni iṣẹgun. (Wo: Jòhánù 16:33; Hébérù 13:5-6)

Wayi o, ọkan lara awọn ọna ti Ọlọrun ma n gba jẹ ki a rin ni iṣẹgun lori awọn idojukọ ti o ba tọ wa wa ni nipa kikun wa pẹlu ọgbọn Ẹmi rẹ lati mojuto wọn. Bawo si ni a ṣe n gba ọgbọn rẹ fun idojukọ kọọkan ti a ba ni? Nkan akọkọ ti a nilo lati mọ ni pe Ọlọrun ti fun wa ni ọgbọn rẹ ninu ẹni naa ti a n pe ni Kirisiti. Idi si ni pe bibeli sọ fun wa Ọlọrun ti ṣe Kirisiti Jesu ni ọgbọn fun wa. Nitorina, gbogbo awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ni a ti ni ọgbọn rẹ ninu wa. O si yẹ ki a kọ lati ma fi igba gbogbo sọ fun ara wa pe, “Mo ni ọgbọn Ọlọrun ninu mi.” (Wo: 1Kọ́rínntì 1:30)

Amọ ṣa o, ki a ni ọgbọn Ọlọrun ninu wa ko ki i ṣe nkankanna pẹlu ki a ma lo o tabi ki a ma ṣe afihan rẹ. Erongba Ọlọrun, gẹgẹ bi a ti ri ninu Iwe mimọ, si wa ni lati fi ọgbọn rẹ han nipasẹ wa fun gbogbo awọn ẹda rẹ (Éfésù 3:10). Nitorina, gbogbo idojokọ ti a ba ba pade jẹ anfaani fun ọgbọn Ọlọrun lati Farahan nipasẹ wa.

Bawo wa ni a ṣe le jẹ ki ọgbọn Ọlọrun ti o wa ninu wa jẹ jijẹyọ tabi fifarahan niwaju idojukọ aye yi? Akọkọ, a le ṣe eyi nipa ki a ma kẹkọ ninu ọrọ Ọlọrun ati ki a tun ma ṣe aṣaro ninu rẹ. Pọọlu sọ fun Timoti pe ọrọ Ọlọrun ni agbara lati jẹ ki a ni ọgbọn lati ni iriri igbala nipasẹ Kirisiti Jesu (2Tímótì 3:15). Nitorina, ti o ba fẹ ki ọgbọn Ọlọrun ma ṣiṣẹ lẹsẹkẹsẹ ninu aye rẹ lati mojutọ idojukọ yowu ti o le ni, fi ojoojumọ fi ara rẹ jin lati ma kẹkọ ati lati ma ṣe aṣaro ninu Iwe mimọ.

Ọna keji ti a le gba jẹ ki ọgbọn Ọlọrun jẹyọ ninu wa ni nipasẹ adura gbigba. Jemisi sọ fun wa pe ki ẹnikẹni ti o ba ṣe alaini ọgbọn bere lọwọ Ọlọrun fun un, lalai ṣe iyemeji; Ọlọrun yoo si fi fun un. Ṣe eyi ko wa tako ọrọ Pọọlu ti o sọ fun wa pe a ti ni ọgbọn Ọlọrun? O ti o, ko tako o rara. Nṣe ni o tilẹ kin lẹyin. Nkan ti Jemisi n tọka si gan ni ifarahan ọgbọn Ọlọrun ninu aye wa. O n sọ pe ti a ba ba ara wa ni ipo ti nkan ti daru mọn wa loju, ti a ko si mọ ipinnu ti o tọ lati ṣe, ki a gbadura si Ọlọrun pe ki O jẹ ki ọgbọn ti a nilo ni asiko naa jẹyọ ninu wa. Ti a ba si ṣe eyi, dandan ni ki Ọlọrun da wa lohun. Nitorina, ma tun jẹ sọ wipe nkan daru mọ o loju mọ. Dipo eyi, nṣe ni ki o ma fi gbogbo igba bere lọwọ Ọlọrun pe ki O jẹ ki ọgbọn rẹ jẹyọ ninu rẹ lati mojuto ohun yowu ti o ba fẹ daru mọ o loju. (Wo: Jemisi 1:5-8)

Ọna kẹta lati jẹ ki ọgbọn Ọlọrun jẹyọ ninu wa ni ki a farabalẹ ronu nipa awọn idojukọ ti a n ba pade ati awọn ọna lati mojuto wọn. Wo o, Ọlọrun funrarẹ ni O fun wa ni amuyẹ lati le ronu ati lati le ṣe agbeyẹwo awọn nkan aye yi. Bi a ba si wa ṣe n lo amuyẹ yi si naa ni ọgbọn rẹ yoo ṣe ma farahan ninu wa si, bi a ko tilẹ ki i ṣe Kirisitiẹni.

O wa ṣeni laanu pe ọpọ ninu awọn ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ni a ko ki i fẹ ronu tabi lo ori wa rara ni didojukọ awọn iṣoro wa. Bẹẹni, a le ma gbadura, ki a tun ma ṣe aṣaro ninu Iwe Mimọ. Ṣugbọn ti o ba di pe ki a dojukọ iṣoro wa, ki a si farabalẹ wo awọn igbesẹ ododo ti a le gbe funra wa lati mojuto wọn, a ko ni ri wa rara. Nkan ti a n fẹ ni ki Ọlọrun ṣe ohun gbogbo fun wa. Ṣugbọn Ọlọrun ko ni ṣe awọn nkan ti O ti fun wa ni okun lati ṣe fun ara wa fun wa. Ti a ko ba si ṣe awọn nkan wọnyi funra wa, nṣe ni a o wa ni ojukanna, ti a o si tun di ẹni ikunna laye, nibiti a ba ti n sọ pe a n duro de Ọlọrun.

Kaakiri wa ni awọn eniyan wa ti wọn ko ni ẹsin rara, ti wọn ko ka Ọlọrun si pataki lọnakọna. Sibẹsibẹ, a n ri diẹ lara wọn ti wọn n ni itẹsiwaju laye. Ki ni idi? Idi ni pe wọn ti kọ bi a ti ṣe n ṣe amulo amuyẹ ti Ọlọrun fun wọn lati ṣe eto aye wọn ati lati ṣe agbeyẹwo awọn ọna ti wọn le gba yanju awọn iṣoro ti o n dojukọ wọn. Nitorina, ọgbọn Ọlọrun tabi ọgbọn Satani ma n ṣaba wa ni arọwọto wọn lati lo. Jesu Oluwa wa tilẹ sọrọ ninu owe rẹ kan nipa irufẹ awọn wọnyi kan ati bi o ti ṣe lo ọgbọn satani ti o wa ninu rẹ lati gba ara rẹ la lọwọ ainiṣẹ. Jesu wa pari owe yi nipa sisọ pe awọn ọmọ ti aye yi gbọn ju awọn ọmọ Ọlọrun lọ ni mimojuto nkan aye yi. Ki si ni idi? Idi ni pe awọn ma n ṣaba lo ọpọlọ ti Ọlọrun fun wọn ju wa lọ. (Wo: Lúùkù 16:1-8)

Nitorina, ti o ba fẹ ki ọgbọn Ọlọrun ma fi igba gbogbo ṣiṣẹ ninu rẹ lati yanju awọn idojukọ aye rẹ, ti o ba fẹ ki ọgbọn rẹ gbe ọ lati ipo iṣẹ ati itiju ti o wa lọ si ipo ọrọ ati iyi ti o ga, kọ bi a ti ṣe n lo ori rẹ naa pẹlu. Bẹẹ ni, ma fi igba gbogbo gbadura ati kẹkọ ọrọ Ọlọrun pẹlu itara. Ṣugbọn ma gbagbe pe Ọlọrun ti bukun fun ọ pẹlu ọpọlọ ti o le yanju oniruuru iṣoro pẹlu. Nitorina, lo o. Bi o si ti ṣe n lo, nṣe ni ọgbọn Ọlọrun yoo bẹrẹ si ni ṣan lati ipasẹ rẹ lainidiwọ ni ọna ti kọja ironu eniyan.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Lọ ọpọlọ rẹ pẹ̀lú | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 30, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 13 Read More »

Fẹ́, kí o sì tún gbọ́ràn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 23, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 12

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, alaafia ati aanu jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Agẹmọ 2023. Mo si gbadura pe ọkankan ninu awọn nkan ti Ọlọrun fẹ ki o ni ninu oṣu naa ko ni fo ọ ru, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti a fi han wa ninu Iwe mimọ ni pe ko to ki Ọlọrun fẹ ki a ni nkan tabi ki a da nkan. Awọn naa gbọdọ nifẹ, ki a si tun ma lakaka, lati jẹ ohun ti O fẹ ki a jẹ. Eyi si tun gbọdọ wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Aijẹbẹ, a ko ni da ohun ti O fẹ ki a da.

Fun apẹrẹ, ninu iwe Aisaya, Ọlọrun sọ eyi fun wa: “Bi ẹyin ba fẹ, ti ẹ si gbọran, ẹyin oo jẹ ire ile naa.” (Aisaya 1:19) Kini ọrọ yi n fi han wa? Akọkọ, o n fi han wa pe Ọlọrun fẹ ki a ni, ki a si tun jẹ igbadun awọn nkan ti o dara julọ nibikibi ti a ba wa. Irọ o, a le ma ma jẹ igbadun igbe aye ti o dara julọ nibi ti a wa lọwọlọwọ yi, yala nitori ìbí wa, ìpele ẹ̀kọ́ wa, ailoye bi a ti ṣe n ni owo ati lo o ati bẹẹbẹẹ lọ. Ṣugbọn eyi ko le yi otitọ ti o wa ninu pe ifẹ Ọlọrun ni pe ki ni, ki a si tun jẹgbadun awọn nkan ti o dara julọ nibi ti a ba wa pada.

Ekeji, ẹsẹ Iwe mimọ yi n fi han wa pe bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun fẹ awọn nkan ti o dara julọ fun wa, awa naa ni ipa ti a gbọdọ ko ki a ba le ni awọn nkan wọnyi, ki a si tun ba le jẹ igbadun wọn. Ki si ni awọn ipa yi? Akọkọ, a gbọdọ fẹ lati ni ati lati jẹgbadun nkan ti Ọlọrun fẹ fun wa. Ọlọrun ko ni fi tipatipa mu wa lati ni ohunkohun tabi lati tẹwọgba ohukohun lọwọ rẹ. Awa ni a gbọdọ nifẹ lati ni ohun ti O n naa si wa. Aijẹbẹ, a ko ni ni.

Ọlọrun, fun apẹrẹ, fẹ ki gbogbo awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose ko jade lati Ijibiti tẹwọgba ilẹ Kenani, ilẹ ti o n ṣan fun wara ati fun oyin. Ṣugbọn ọpọ ninu wọn ni ko mori de ilẹ naa. Ki lo fa? Wọn ko ni ifẹ lati nawọ gan ilẹ yi. Ki si ni idi ti wọn ko fi ṣetan lati nawọ gan an? Ibẹru! Ibẹru awọn omiran ti o wa ni ilẹ naa ni ko jẹ ki wọn fẹ lati gba a. Ṣugbọn Ọlọrun mọ wipe awọn omiran wa nibẹ ki O to nawọ ilẹ naa si wọn. Nkan ẹyokan ṣoṣo ti O si fẹ lati ọdọ wọn ni ki wọn ṣetan lati tẹwọ gba. Ilẹ naa ko ba si di ti wọn. Ṣugbọn nitoripe wọn ko nifẹ lati tẹwọ gba, wọn padanu rẹ, wọn si ṣegbe sinu aginju. Kiki awọn ti o nifẹ lati tẹwọ gba ilẹ naa laarin wọn ni o wọ ibẹ.

Ti awa naa ba fẹ lati ni ohun ti Ọlọrun fẹ fun wa, yoo fa a le wa lọwọ, bi o ti wu ki riri nkan naa gba dabi ẹni ti o le to. Bawo si ni a ṣe le fi han pe a nifẹ lati ni ohun ti o dara julọ ti Ọlọrun fẹ ki a ni laye yi, ki a si tun jẹ ẹni ti o fẹ ki a jẹ lọna ti o dara julọ? Nipa fifi itara ṣe aṣaro ninu ọrọ rẹ lati mọ awọn nkan ti O ti pese fun igbadun wa. Nipa gbigba adura si laisimi lati mu gbogbo ete ra daradara fun wa ṣẹ. Ati nipa gbigbe gbogbo igbesẹ ododo ti a ni agbara lati gbe lati jẹ ẹni ti O fẹ ki a jẹ ati lati ni ohun ti O fẹ ki a ni.

Nkan ekeji ti a nilo lati ni ati lati jẹgbadun awọn nkan ti o dara julọ ti Ọlọrun fẹ ki a ni laye yi ni igbọran. Ọlọrun ni awọn ọna tirẹ lati jẹ ki a ni ati ki a jẹ igbadun ipese rẹ fun wa. Nipa titẹle awọn ọna yi nikan si ni a ṣe le gba jẹgbadun wọn. Nitorina, bi a tilẹ nifẹ lati ni awọn nkan ti Ọlọrun fẹ ki a ni ati lati da ohun ti O fẹ ki a da, ti a ko ba tẹlẹ awọn ọna ati ete rẹ fun wa pẹlu ọkan igbọran, a o ṣina. Ti ba tilẹ wa ni awọn nkan ti O fẹ ki a nipa titẹle awọn ọna ti ara wa, o di dandan ki ijiya tẹle, ijiya yi si le gba awọn nkan ti o san ju awọn ti a ti ri danu kuro lọwọ wa.

Fun apẹrẹ, igba kan wa ti Ọlọrun fẹ fun awọn ọmọ Isiraẹli ni omi mu lati inu apata kan. O si sọ fun Mose pe ki o sọrọ si apata naa ni oju ẹnikọọkan wọn ati wipe apata naa yoo sun omi jade fun wọn ti o ba ti ṣe bẹ ẹ. Ṣugbọn nitoripe inu n bi Mose gidigidi ni asiko naa si awọn eniyan naa, o ṣe aigbọran si Ọlọrun nipa lilu apata naa ni igba meji pẹlu ọpa rẹ. Si iyalẹnu awọn ti o wa ni ibẹ, omi tu jade lati inu apata yi fun gbogbo wọn lati mu. Ṣugbọn Ọlọrun wa sọ fun pe ko ni wọ ilẹ ileri naa nitori aigbọran rẹ. (Wo: Numeri 20:1-13)

Ṣe o wa ri bayi pe o ṣeeṣe ki a ma ṣe aigbọran si Ọlọrun, ki a si tun ma ni iriri didara ati ojurere rẹ ninu aye wa lọna kan tabi omiran. Ṣugbọn gẹgẹ bi o ti ri fun Mose, aigbọran awa naa le gba awọn nkan ti o dara julọ ti Ọlọrun fẹ ki a ni danu kuro lọwọ wa. Nitorina, a gbọdọ ṣọ ara wa, ki a si ri daju pe bi a ti ṣe n fi ifẹ wa han lati ni awọn nkan ti Ọlọrun fẹ ki a ni naa ni a tun ṣe n gbọran si aṣẹ rẹ. Adura mi ni pe ki okun lati ṣe eyi ma fi igba gbogbo ṣiṣẹ ninu wa. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Fẹ́, kí o sì tún gbọ́ràn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 23, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 12 Read More »

Wọn kò le ṣàìmá pàdánù ẹ̀mí wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 16, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ Nọ́múbà: Vol. 12, No. 11

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun miran ninu oṣu Agẹmọ 2023. Mo gbadura pe ki Ọlọrun ma fi igba gbogbo pa ọ mọ kuro ninu idibajẹ awọn ọjọ ikẹyin yi, ki O si tun mu ọ duro ni mimọ ati ailabawọn niwaju Jesu Oluwa wa nigba ti O ba de. Amin.

Ni aipẹ yi, mo ri lori ẹrọ ayelujara awọn fọnran awọn ọdọkunrin ati ọdọbinrin wa kan ni orilẹ-ede yi ninu eyi ti wọn ti n bọ ara wọn si ihoho pẹlu aibikita nitori pe wọn fẹ ṣe ere idaraya. Wọn pe ere idaraya naa ni ipenija ayò ife-yíyípadà. Ọpọlọpọ ni o si n kopa ninu ìsínwín yi pẹlu igboya. Ki si ni idi? Wọn ṣa fẹ mu inu ara wọn dun, ki wọn si gbagbe irora ati ibanujẹ wọn. Wọn ko si wa kọ ohunkohun ti wọn ni lati ṣe ki eyi ba le waye. Awọn miran tilẹ tun ri gẹgẹ bi ọna lati pa owo pẹlu irọrun lori ẹrọ ayelujara.

Wayi o, awọn nkan wọnyi jẹ ki ara awọn ọrọ ti Jesu Oluwa wa sọ nipa awọn ọjọ ikẹyin wa si ọkan mi. O sọ wipe, “Ẹṣẹ yoo wa nibi gbogbo, yoo si sọ ifẹ ọpọ di tutu, ṣugbọn ẹni ti o ba foriti i dopin ni a o gba la.” (Matiu 24:12-13) Ki ni yoo wọpọ ni ibi gbogbo ni awọn ọjọ ikẹyin? Ẹṣẹ! Iṣekuṣe! Ẹtan! Bawo wa ni wiwọpọ awọn nkan wọnyi yoo ṣe pa awọn ọmọ Ọlọrun lara? Yoo jẹ ki ifẹ ọpọ ninu wọn fun Ọlọrun di tutu. Eyi jasi pe wọn ko ni ni itara lati gbe aye wọn fun Oluwa tabi lati sin in. Idi fun eyi si ni pe awọn naa fẹ ba awọn ọrẹ wọn, ololufẹ wọn, ẹbi wọn, aladugbo wọn ati bẹẹbẹẹ lọ ti ko mọ Oluwa rẹ́.

Ṣugbọn Oluwa tun wa jẹ ki o ye wa pe kiki awọn ti o ba duro ṣinṣin ninu ifẹ wọn si i ati ninu ifarajin wọn fun un titi de opin ni yoo ṣe igbala wọn ni aṣepe. Awọn ti o ba kọ ọ silẹ tabi ti wọn kọ igbe aye ododo silẹ nitori iwa ika, iṣekuṣe, ẹtan, ẹtanu tabi ilara ti o n waye ni ayika wọn ko le ṣe alaima sọ ẹmi wọn nu. Nitorina, ma ṣe jẹ ki ọkankan ninu awọn nkan buruku ti awọn ti o wa ni ayika rẹ n ṣe lati tọju ara wọn, daabo bo ara wọn tabi mu inu ara wọn dun jẹ ki ina ifẹ rẹ fun Ọlọrun ku. Dipo eyi, nṣe ni ki o bu ẹnu atẹ lu awọn iṣẹ ọwọ wọn, ki o kẹyin si wọn, ki o si dirọ mọ Oluwa. Eyi yoo si jasi ọgbọn fun ọ.

Ranti pe Jesu Oluwa wa sọ wipe, “Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gba ẹmi rẹ la, yoo sọ ẹmi rẹ nu ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmi rẹ nu nitori mi, yoo ri i.” (Matiu 16:25) Nkan ti eyi tunmọ si ni pe gbogbo awọn ọrẹ rẹ, ẹbi rẹ, akẹgbẹ rẹ ni ibi iṣẹ tabi ni ile-iwe, aladugbo rẹ tabi awọn ọmọ ijọ rẹ gan paapaa ti wọn ro wipe awọn yoo gba ara awọn la tabi pe awọn yoo mu inu ara wọn dun nipa ole jija, imutipara tabi ikopa ninu iṣẹ aṣewo tabi iṣeṣo owo yoo ri lọjọ kan pe awọn ko gba ara awọn la tabi mu inu ara wọn dun rara ati pe nṣe ni awọn pa ara awọn run. Ti iwọ naa ba si wa gba fun wọn lati tan ọ lati kopa ninu ẹṣẹ wọn, iwọ naa yoo ri lọjọ kan pe nṣe ni iwọ naa ti pa ara rẹ ati boya awọn ti o fẹran pẹlu run ninu ilakaka rẹ lati gba ẹmi rẹ la.

Ewo ni yoo wa jẹ ninu rẹ? Ṣe nṣe ni o o duro gẹgẹ bi olotitọ si Oluwa, bi o ti wu ki idojukọ ti aye yi n ju si ọ to, ki o si gbẹkẹle fun iṣẹgun, alaafia ati ayọ ni asiko gbogbo? Abi nṣe ni o o darapọ mọ gbogbo awọn eniyan ti o wa ni ayika rẹ ti wọn n fi ojoojumọ pa ara wọn run nigba ti wọn n gbiyanju lati gba ara wọn la? Ọwọ rẹ naa ni o ku si. Njẹ adura mi fun ọ wa ni pe ki Ẹmi Ọlọun fun ọkan rẹ ni okun lati ma fi iwa omugọ darapọ mọ aye yi ni sisa ere ije ti o di dandan ki o pari sinu iparun. Amin.

Ki o ni ọsẹ ologo.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Wọn kò le ṣàìmá pàdánù ẹ̀mí wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 16, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ Nọ́múbà: Vol. 12, No. 11 Read More »

Ṣe bí Rúùtù | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 09, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 10

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Agẹmọ 2023. Adura mi si ni pe a ko ni fi ohukohun ti o nilo fun iṣoriire ati alaafia rẹ pamọ fun ọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ara awọn nkan ti a fi han wa ninu Iwe mimọ ni pe a ko gbọdọ lalai lo awọn idojukọ wa gẹgẹ bi awawi fun gbigbe igbe aye ti ko ni itumọ ati ti ko lere. Dipo eyi, irufẹ idojukọ yowu ti a le ni, nṣe ni o yẹ ki a ṣi oju wa si awọn nkan ti o tọna ti a le ṣe pẹlu ọwọ wa lati jẹ ki aye dara si fun wa ati fun awọn ti o wa ni ayika wa. Awọn ti o ba si n ṣe eyi ni yoo ni iriri ogo ati igbega Ọlọrun ninu aye wọn, bi o ti wu ki ipo ti wọn wa laye kere to.

Fun apẹrẹ, nigba ti Ruutu de si ilẹ Isiraẹli pẹlu Naomi, iya ọkọ rẹ, ko de pẹlu nkankan, bẹẹni ko si tun ba nkankan nilẹ. O de si ibi ti ko ti ni ọrẹ tabi ẹbi ti o le tọ lọ fun iranwọ. Ṣibẹsibẹ, o nilo lati bori asiko yi lati le tọju ara rẹ ati iya ọkọ rẹ ti o ti darugbo. Ṣe o wa bẹrẹ si ni sọkun bi, ki o si ma sọ wipe aṣiṣe ni oun ṣe nipa fifi awọn eniyan oun silẹ lati tẹle Naomi? Rara o! Tabi ṣe o bẹrẹ si ni jade lọ lati ṣe iṣẹ aṣewo bi? Rara o! (Wo: Ruutu 1:19-22)

Ṣe o ri, Ruutu ni awọn idi ti o nitunmọ lati fi awọn eniyan rẹ ati ibalẹ-ọkan ti ko ba ma jẹgbadun pẹlu wọn silẹ. Ifẹ rẹ ni lati sa patapata fun ibọriṣa, iṣekuṣe ati iwa ika ti wọpọ laarin wọn. Ipinnu rẹ la si ti ṣe eyi ni o jẹ ki o tẹlẹ iya ọkọ rẹ, iya ọkọ ti ko ni nkankan ti o le ṣe fun, lọ si ilẹ Isiraẹli. Nitorina, o mọ pe o ṣeeṣe ki oun bẹrẹ igbe aye tuntun yi bi ọkan lara awọn akuṣẹ-julọ ti o wa nilu nigba ti o ba de ibẹ. Sibẹsibẹ, o wa nitoripe o woye pe o san fun oun lati jẹ akuṣẹ laarin awọn eniyan Ọlọrun ju lati jẹ ọlọrọ-julọ laarin awọn ika eniyan (84:10).

Nibakanna, ipinnu wa lati gbe aye wa fun Jesu Kirisiti le fi wa si ipo iṣẹ tabi idojuti ni awujọ wa. Ṣugbọn eyi ko jasi pe Ọlọrun fẹ ki a wa ni ipo naa titi lailai. Nkan ti O fẹ ni ki awọn eniyan rẹ ma wa ni ipo oke dipo ipo isalẹ. Nitorina, irufẹ ibi ipo kekere yowu ti a le wa laye lọwọlọwọ yi, Ọlọrun le gbe wa soke lati ibẹ lọ si ibi ti o yẹ ki a wa.

Amọ ṣa o, awa naa gbọdọ ṣetan lati ṣẹ bi Ruutu ni ipo ilẹlẹ yowu ti a le ti ba ara wa, ki a ba le ni iriri ojurere ati igbega Ọlọrun. Bawo si ni obinrin yi ṣe ṣe ti a fi gbe soke kuro ninu iṣẹ sinu ọrọ ati itura? Akọkọ, dipo ti yoo fi ma ṣe aroye nipa ipo ti o ti ba ara rẹ tabi ti yoo fi ma ṣe iranu kiri pẹlu agọ ara rẹ, nṣe ni o wa iṣẹ ṣe. Obinrin yi ko joko sile pẹlu iya-ọkọ rẹ, ki o ma gbadura ati ki o si tun ma reti pe ki Ọlọrun fi owo ranṣẹ si wọn. Dipo bẹẹ, nṣe ni o jade wa iṣẹ lọ. Ọlọrun si dari rẹ sẹnu iṣẹ kan, bi o tilẹ jẹ wipe iṣẹ naa ko le ṣe ju ki o fun wọn ni ounjẹ oojọ lọ ni akoko naa. (Wo o: Ruutu 2:1-3)

Wayi o, nkan ti mo n sọ kọ ni pe Ọlọrun ko le ma fi owo ranṣẹ si Ruutu ati Naomi nile. O le ṣe bẹ ẹ. Ṣugbọn ṣe wọn le sọ igba ti yoo fi owo ọhun ranṣẹ si wọn tabi iye ti yoo fi ranṣẹ si wọn nigbakukgba ti O ba fi ranṣẹ? Rara! Niwọn igba ti ko si ti wa sọ pe wọn ko le jade lọ lati ṣiṣẹ ati lati pawo, nkan ti o mọgbọn wa fun Ruutu ni lati jade lọ lati ṣiṣẹ. Ki o si wa ma reti Ọlọrun lati tipasẹ ṣiṣe eyi mu owo jade fun un.

Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe o suwọn fun ọ lati gbadura ati lati reti Ọlọrun lati pese fun aini rẹ lọna iyanu, o tun gbọdọ wa iṣẹ se, nitori pe Ọlọrun ti pa eyi ni aṣẹ (Efesu 4:28; 1Tẹsalonika 4:11-12). Fun idi eyi, nṣe ni ko wa iṣẹ fun ara rẹ lati ṣe, niwọn igba ti o ba ti jẹ iṣẹ ti o tọna labẹ ofin ni, dipo ti o o fi ma ṣe aroye, jale tabi ba agọ ara rẹ jẹ lati pa owo. Nipa bayi, Ọlọrun le pese fun aini rẹ lati ara iṣẹ yi ati nipa irufẹ ọna iyanu miran ti O ba tun yan.

Nkan keji ti Ruutu ṣe ni pe o ṣe iṣẹ ti o ri pẹlu ijafafa. Lotitọ, iṣẹ ti o ri yi jẹ iṣẹ olowo kekere ni asiko naa. Sibẹsibẹ o ṣe ni ọna ti adari oko ti o n ti n ṣiṣẹ fi kiyesi, ti o si sọrọ rẹ ni daradara fun oluwa rẹ, iyẹn Boasi, ẹni ti o wa lọ jẹ ibatan ọkọ Ruutu ti o ṣe alaisi. Eyi si ṣi ilẹkun ojurere ti o ga fun. Ti iwọ naa ba wa ṣe iṣẹ yowu ti o wa lọwọ rẹ bayi pẹlu gbogbo ọkan ati okun rẹ, o ṣeeṣe ki o jẹ pe ohun ni Ọlọrun yoo lo lati gbe ọ pade awọn ti yoo fi ojurere wo ọ, ti wọn yoo si tun gbe ọ soke. (Wo: Ruutu 2; Oniwaasu 9:10)
Nkan ẹkẹta ti a le ṣe awokọṣe rẹ lati ara Ruutu ni ifarabalẹ rẹ lati gba imọran ti o wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun (Ruutu 3-4). Lotitọ, o ni iya ọkọ ti o jẹ ẹni-bi-Ọlọrun, ti o si fi gbogbo igba wa ni arọwọto lati fun ni imọran lori irufẹ igbesẹ ti o tọ fun lati ma gbe. Ṣugbọn ti ko ba mu imọran iya yi ni ọkunkundun, ko ba ma ti bọ ninu iṣẹ, ki o si di gbajumọ bi a ti ṣe mọ ọn loni. Iwọ naa gbọdọ ṣe idamọ awọn ti Ọlọrun ti gbin sinu aye rẹ lati fun ọ ni imọran ti o peye. Bi wọn ba si ṣe n gba nimọran, ri daju pe o mu ni pataki ati pe o ṣe amulo rẹ. Nitoripe o le jẹ wipe imọran wọn gan, dipo owo, ni ohun naa ti o nilo lati dide bori gbogbo awọn idojukọ aye rẹ. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun fun ọ ni okun lati tẹwọgba awọn nkan wọnyi ati lati ṣe amulo wọn ninu aye rẹ lalai fi asiko ṣofo. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ṣe bí Rúùtù | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 09, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 10 Read More »

Jìnà réré sí ìbọ̀rìṣà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 02, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 9

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu miran ninu ọdun yi, iyẹn oṣu Agẹmọ 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ya aye ra ye ohunkohun ti o ni i ṣe pẹlu aiwa-bi-Ọlọrun ti o n di ẹkunrẹrẹ ifarahan ibukun rẹ lọwọ ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Gẹgẹ bi a ti ṣe sọ fun wa ninu bibeli, gbogbo awa ti a ti di atunbi lati ọwọ Ọlọrun ati nipasẹ igbagbọ wa ninu Kirisiti Jesu ni a ti bukun fun pẹlu gbogbo awọn ibukun ti o wa ninu awọn ọrun ninu rẹ (Efesu 1:3). O wa yẹ ki awọn ibukun wọnyi ma fi ara han ninu aye wa, ninu agọ ara wa, ninu ile wa, ninu iṣẹ wa, ninu okowo wa, ninu iṣẹ iranṣẹ wa ati bẹẹbẹẹ lọ. Ti wọn ko ba si ma fi ara ha ninu wọn, o yẹ ki a mọ idi rẹ. Nkan ti mo n sọ ni pe ti ko ba han kedere ninu aye wa pe ajogun ibukun Ọlọrun ni a jẹ, o yẹ ki a mọ nkan ti o fa.

Bi a sa ti ṣe mọ lati inu bibeli, bi o tilẹ jẹ wipe ẹru ni Josẹfu jẹ ni ile Potifa, ọkunrin yi si le sọ pe ara-ọtọ ni ọdọmọkunrin yi jẹ, pe alabakunfun lati ọwọ Ọlọrun ni o n ṣe (Jẹnẹsisi 39:1-6). Lafikun, bi o tilẹ jẹ wipe Daniẹli, Ṣediraki, Meṣaki ati Abẹdinigo wọ ilu Babiloni bi ẹru, gbogbo awọn ọba ti wọn ba ṣiṣẹ ni wọn le sọ pe alabakun fun lati ọwọ Ọlọrun ni wọn jẹ (Daniẹli 1-6). Siwaju si, bi o tilẹ jẹ wipe Labani ṣe ohun gbogbo ti o le ṣe lati yan Jakọbu jẹ ati lati ri daju pe ko ṣe rere labẹ rẹ, ko wa le jiyan pe Jakọbu gan ni idi ti Ọlọrun ṣe n bukun fun ile rẹ (Jẹnẹsisi 30:27-28).

Nitorina, awọn iṣẹlẹ aye wa, bi o ti wu ki wọn ma suwọn to, ko le di ifarahan ibukun Ọlọrun lọwọ ninu aye wa. Idi si ni pe ibukun Ọlọrun ni agbara ju nkan ti asiko kan tabi egun kan le di lọwọ lọ. Amọ ṣa o, nipasẹ iha ti a kọ si Ọlọrun ati si ọrọ rẹ, awa funrawa le di ifarahan agbara rẹ lọwọ ninu aye wa.

Fun apẹrẹ, nigba ti Mose pari pipe ibukun Ọlọrun sori awọn ọmọ Isiraẹli, o tẹsiwaju lati sọ nkan kan ti o le di ifarahan awọn ibukun yi lọwọ laarin wọn fun wọn. O so wipe, “Ri i daju pe ko si ọkunrin tabi obinrin, idile tabi ẹya laarin yin lonii ti ọkan an rẹ yoo yi kuro lọdọ Oluwa Ọlọrun wa lati lọ ati lati sin awọn ọlọrun awọn orilẹ ede naa; ri i daju pe ko si gbongbo ti o n mu iru eso kikan bẹẹ jade laarin yin. Nigba ti iru ẹni bẹẹ ba gbọ ibura yii, ki o gbadura ibukun sori ara rẹ nigba naa ni ki o ronu, “Emi yoo wa lalaafia, bi o tilẹ jẹ pe mo ti fi aake kọri nipa lilọ ninu ọna ti ara a mi.” Eyi yoo mu ijalu wa sori ilẹ tutu ati sori ilẹ gbigbẹ bakan naa.” (Deutaronomi 29:18-19)

Njẹ o ri bayẹn? Ibọriṣa ma n di ifarahan awọn ibukun Ọlọrun lọwọ. Ibọriṣa yoo mu ajalu ba ohun gbogbo ti o wa ninu aye rẹ, boya o dara ni tabi o buru. Nitorina, ti o ba n kopa ninu ibọriṣa, ko si bi o ti mura to lati gbadura ati lati gbawẹ, awọn ibukun Ọlọrun ko ni farahan ninu aye rẹ. Bẹẹni, niwọn igba ti o ba n kopa ninu ibọriṣa lọna kan tabi omiran, ti o n tẹriba fun awọn ọlọrun miran tabi ti o n bẹ wọn lọwẹ fun isoriire, ilera tabi aabo rẹ, awọn ibukun ti a ti fi fun ọ ninu Kirisiti Jesu ko ni ṣiṣẹ bi o ti yẹ ki wọn ṣiṣẹ.

Awọn idi niwọnyi ti ati Pọọlu ati Johanu ṣe sọ fun wa ninu awọn lẹta wọn lati sa fun ibọriṣa ati lati ya ara wa ya ohun gbogbo ti o n jẹ oriṣa (1Kọrinti 10:14; 1Johanu 5:21). Nitorina, jina si ohunkohun ti o n jẹ oriṣa ati ohunkohun ti o ba sorọ mọ ibọriṣa. Aijẹbẹ, o di dandan ki o ru owu Ọlọrun soke. Ti o ba si ru owu rẹ soke nipasẹ ipa ti o n ko ninu ibọriṣa, o gbọdọ reti pe ki O gbegidina ifarahan awọn ibukun rẹ ninu aye rẹ. Nitorina, bi o tilẹ n jẹwọ ọrọ ibukun rẹ, ti o n gbadura tabi ti awọn iranṣẹ Ọlọrun n bukun fun ọ, ko ni ṣiṣẹ. Gbogbo rẹ yoo kan ṣofo lasan ni. Ti ko ba si ki i ṣe nkan ti o fẹ ni eyi, ti o ko fẹ ki awọn adura rẹ ati awọn adura ti awọn miran n gba fun ọ ja si asan, nṣe ni ki o jina rere si ibọriṣa.

Siwaju si, ti o ko ba fẹ jẹ idi ti idena yoo ṣe ba ilọsiwaju awọn ti o wa ninu aye rẹ, jina si ibọriṣa. Idi si ni pe, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ko ki iṣe gbogbo igba naa ni o jẹ kiki awọn ti o n kopa ninu ibọriṣa nikan ti o ma n jiya rẹ; awọn igba miran ma n wa ti awọn ti o wa ninu aye wa naa ma n kopa ninu ijiya wọn. Idi niyi ti Mose ṣe sọ fun awọn ọmọ Isiraẹli ninu ẹsẹ bibeli ti o wa loke yẹn lati ma sọ ara wọn ati lati ri daju pe ko si ọkankan ninu wọn ti o n kopa ninu ibọriṣa. Aijẹbẹ, ko ki i ṣe ori aye rẹ ti o gbẹ nikan ni irufẹ ẹni bẹ yoo mu ajalu wa, yoo tun mu wa sori aye ti awọn naa ti a bomirin, ti o n gberu pẹlu.

Nibakan naa, iwọn naa ko gbọdọ fi aye gba awọn ti o pe ara wọn ni Kirisitiẹni ti o wa ninu aye rẹ lati ma kopa ninu ohunkohun ti o n jẹ ibọriṣa. Nṣe ni o yẹ ki o kilọ fun wọn gidigidi. Ti wọn ko ba si gbọ, o gbọdọ jina si wọn. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki iwọ naa kopa ninu ijiya wọn. Wayi o, awọn ti o sọ pe awọn mọ Ọlọrun ti o tun n kopa ninu ibọriṣa nikan ni eyi n tọka si (1Kọrinti 5:9-11). Nitorina, ma ṣe lo ilana yi lati ba awọn alaigbagbọ ti o wa ni ayika rẹ lo pọ. Ki a si ma fi gbogbo igba kun ọ pẹlu okun ati ọgbọn ti o peye lati yago fun ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ibọriṣa, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Jìnà réré sí ìbọ̀rìṣà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 02, 2023 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 9 Read More »