Kò lọ pẹ̀lú ọwọ́-òfo | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 26, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 4
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu yi, iyẹn oṣu Èbìbí 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ fun ọkan rẹ ni okun lati ni itara ti o to lati ri awọn ipese rẹ fun ọ lati tayọ ati lati gbe igbe ninu isinmi ni gbogbo eyi ti o ku ni ọjọ aye rẹ gba ati lati jẹgbadun awọn ipese naa, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ti ṣe ri ninu Iwe Mimọ, ẹnikẹni ti yoo ba ri ohunkohun gba lọwọ Ọlọrun gbọdọ mura, ki o si tun ni itara lati ri gba. Eyi jasi pe, ko to fun wa lati sọ wipe a ni igbagbọ lati rigba lọwọ Ọlọrun; a tun gbọdọ fi imura ati itara kun igbagbọ wa ninu rẹ. Aijẹbẹ, a le ma ri nkan ti ọkan wa fẹ gba lọwọ rẹ.
Otitọ ni pe Ọlọrun ma n ṣe ọpọlọpọ nkan fun wa lalai duro de imura tabi itara wa lati rigba lọwọ rẹ. Ṣugbọn awọn nkankan wa ti a ko le rigba lọwọ rẹ, ti ọkan wa ko ba mura, ki o si tara lati ri wọn gba. Ki wa ni awọn nkan naa? Emi ko le sọ ni pato nkan ti wọn jẹ. Idi si ni pe, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, ọpọ ni o n fi ojoojumọ gba oniruuru nkan daradara lati ọwọ Ọlọrun ti wọn ko si mu un ni pataki. Amọ ṣa o, irufẹ awọn wọnyi naa yoo si tun pada ri wipe awọn nkankan wa ti wọn ko le rigba lọwọ Ọlọrun lalai ba jẹ wipe wọn mura, ti wọn si tun tara lati ri wọn gba lọwọ rẹ.
Ni kukuru, niwọn igba ti a ko le sọ ni pato awọn nkan ti Ọlọrun yoo ṣe fun wa lọfẹ, lalai reti imura tabi itara lati ọdọ wa, yoo jẹ nkan ti o mọgbọn wa fun wa lati mura ati lati ni itara nigbakigba ti a ba nilo ohunkohun lati ọwọ rẹ. Bi bibeli si ṣe wa sọ, awọn ti o ba fi imura ati itara ṣafẹri rẹ ko ni lọ kuro lọdọ rẹ pẹlu ọwọ́-òfo. (Wo: Hébérù 11:6)
Fun apẹrẹ, a sọ fun wa ninu bibeli bi arabinrin Kenani kan ṣe gba itusilẹ ọmọdebinrin rẹ lọwọ Oluwa nipa igbagbọ, imura ati itara rẹ. Bi akọsilẹ naa ti ṣe lọ, nigba ti obinrin yi gbọ pe Jesu wa ni agbegbe rẹ, o kọkọ lọ ṣe iwadi ibi ti O wa. O si wa ibi ti O wa kan, bi o tilẹ jẹ wipe ko fẹ ki ẹnikẹni mọ wipe O n wa nibẹ. A wa ni lati jẹ wipe itara ati imura arabinrin yi ga gan niyẹn. (Wo: Máàkù 7:24-26)
Siwaju si, lẹyin gba ti o ti wa ibi ti Jesu wa kan, arabinrin yi tọ ọ wa, o si bẹrẹ si ni bẹ ẹ lati wo ọmọdebinrin rẹ ti ẹmi aimọ n gbe inu rẹ san. Ṣugbọn Jesu ko gbọ tirẹ tabi da a lohun. O kan ṣe bi igba ti ko gbọ nkan ti o n sọ ni. Ki ni idi? Idi ni pe iṣẹ iranṣẹ rẹ laye ni asiko yii ko kọja ki O pe awọn iru ọmọ Aburahamu pada si ọdọ Ọlọrun, ko si ni i ṣe pẹlu ki O kan si awọn keferi. Awọn keferi ni a o pada pe lẹyin iku, isinku, ajinde ati igbasoke rẹ. (Wo: Mátíù 15:24)
Bi nkan tilẹ wa ri bayi, arabinrin yi ko ma sọ ireti nu. Ko pòṣé, ki o yi pada, ki o si ma fi oju agberaga ọkunrin wo Jesu. Dipo eyi, nṣe ni o tẹsiwaju lati ma a tẹle ati lati ma a bẹ ẹ pe ki O wo ọdọmọdebinrin oun san. Nigba ti Jesu si wa pada fun ni aye lati sọrọ, awọn ọrọ wọnyi ni O sọ fun un: “Ko tọ ki a gbe ounjẹ awọn ọmọ fun awọn aja.” (Mátíù 15:26) Njẹ o ri bayẹn? Oluwa pe arabinrin yi ati ọmọ rẹ ni aja, aja awọn ọmọ Isiraẹli. O tun sọ siwaju pe wọn ko yẹ lati jẹ igbadun ohun ti Ọlọrun n fun ọrilẹ-ede Isiraẹli.
Sibẹsibẹ, obinrin yi ko ma binu. Dipo ti yoo fi binu, nṣe ni o da Oluwa wa lohun wipe, “Bẹẹ ni, sibẹsibẹ awọn aja a maa jẹ eerun ti o ti ori tabili olowo wọn bọ silẹ.” (Mátíù 15:27) Eyi jasi pe, bi o tilẹ jẹ wipe aja wọn ọmọ Isiraẹli ni wọn jẹ, wọn si le kopa ninu awọn nkan ti awọn ọmọ Isiraẹli n jẹgbadun, pẹlupẹlu iwosan. Nitoripe o si sọrọ bi eyi, Oluwa da a lohun, O si sọ ọrọ naa ti o tu ọmọ rẹ silẹ. (Wo: Mátíù 15:28)
Njẹ ki wa ni idi ti arabinrin yi fi rigba lọwọ Oluwa, pẹlupẹlu awọn iyọnu ati èébú ti o gba? Idi ni pe o mura, o si tun tara nipa itusilẹ ọdọmọdebinrin rẹ. Ti o ba si wa jẹ wipe ki o farada awọn eebu diẹ ni yoo jẹ ki eyi waye, o ṣetan lati farada wọn. Nitorina, ko kuro pẹlu ọwọ́-òfo.
Nibakan naa, ti awa naa ba mura, ti a si tun tara lati ri ohun yowu ti a ba fẹ gba lọwọ Ọlọrun gba, a ko ni kọbiara si idenakidena loju ọna wa; a ko ni kọbiara si eebu tabi ọrọ odi awọn eniyan. Lafikun, a ko ni wo iye asiko tabi ọjọ ti a o lo lati gbadura si Ọlọrun lati ri nkan ti a fẹ gba lọwọ rẹ gba. Dipo eyi, nṣe ni a o tẹ oju wa mọ, ti a ko si ni gbe e kuro titi a o fi ri ohun ti a fẹ gba lọwọ rẹ gba. Amọ ṣe a wa ṣetan lati ṣe eyi? Ṣe a ṣetan lati mura ati lati tara nigbakigba ti a ba fẹ gba nkan lọwọ Ọlọrun? Mo wa gbadura pe a o ṣe ọkan wa yẹ lati ṣe eyi, ki ayọ wa ba a le kun ni gbogbo abala aye wa, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)



