Àkórí: Ǹjẹ́ o ti ń rànmù kiri bí? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 19, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 3

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia di ilọ̀po, ilọpo fun ọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ṣe ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ebibi 2024. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun, ti O ti gba wa kuro lọwọ ijọba okunkun, ti O si mu wa wa sinu ijọ ọmọ rẹ, fi opin si ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu iriri ìraǹmù ninu aye rẹ, ki o ba le farabalẹ jẹgbadun aye rẹ bi O ti fẹ ki o jẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, mo gbadura yẹn fun ọ nitoripe ko ki i ṣe ifẹ Ọlọrun ni fun wa lati ranmu laye. Idi si ni pe igbe aye iranmu ko ki i ṣe igbe aye isimi otitọ. Ko ki i ṣe igbe aye igbadun otitọ. Fun apẹrẹ, Ọlọrun sọ fun Kaini, lẹyin igba ti o pa arakunrin rẹ, pe isansa ati alarinkiri ni yoo jẹ. Ki ni eyi tunmọ si? Ki a ma fọrọgun, o tunmọ si pe bi o ti wu ki ibi yowu ti o ba ara rẹ ti dara to, ko ni ni itẹlọrun tabi idunnu nibẹ. Ki ni idi? O le jẹ wipe iṣẹ ọwọ rẹ ko ni lọ deede nibẹ. Tabi ki o jẹ wipe awọn eniyan ti o wa nibẹ yoo korira rẹ. Nkankan yoo ṣaa wa nibikibi ti o ba wa ti yoo ja a lole itẹlọrun. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 4)

Nitorina, Kaini yoo nilo lati ma parọ ibi ti yoo ma gbe lore-koore. Niwọn igba ti o ba si ni parọ ilegbe rẹ lati igba-de-igba, ko ni i le fi ara lelẹ jẹgbadun awọn eso laala rẹ. Yatọ si iyẹn, ti awọn iyawo ati ọmọ rẹ ko ba ṣetan lati ma ba a ranmu kaakiri, ko tun ni le jẹ igbadun ibaṣepọ rẹ pẹlu awọn naa. O yẹ ki o wa ri bayẹn pe igbe aye iranmu kiri ko ki i ṣe eyi ti o dara rara. Ọpọ igba ni o si ma n jẹ igbe aye adanikanṣe.

O wa ṣeni laanu pe igbe aye iranmu yi gan an ni ọpọ n gbe. Fun ọpọ ọdun, nṣe ni wọn n ranmu lati ibikan de ibikan, lati ibi iṣẹ de ibi iṣẹ, lati inu ijọ de inu ijọ ati pẹlupẹlu lati inu igbeyawo de inu igbeyawo. Sibẹsibẹ, wọn ko i ti ri itẹlọrun, alaafia ati isinmi ti wọn n wa laye. Ki ni idi? O ma a fẹrẹ ni lati jẹ wipe wọn ko mu Ọlọrun ni pataki ni tabi pe wọn ko kọbiara si ohun ti O n sọ fun wọn.

Ranti wipe bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ni O mu awọn ọmọ Isiraẹli jade kuro ninu Ijibiti, ki O ba a le mu wọn wọ ilẹ isinmi ti O ti pese silẹ fun wọn, ọpọ ninu wọn ni o jẹ wipe nṣe ni wọn ranmu titi ninu aginju fun ogoji ọdun. Ṣibẹsibẹ wọn ko si tun papa de ibi isinmi ti a ti pese silẹ fun wọn. Ki ni idi? Idi ni wipe wọn ko mu Ọlọrun ni ọkunkundun. Wọn ko gbagbọ pe O le dari awọn sinu ibi isinmi ti O ti pese silẹ fun wọn. Nitorina, wọn fi ogoji ọdun aye wọn ṣofo lori riranmu kiri ninu aginju, ti wọn ko si le jẹgbadun aye bi wọn ko ba ti jẹgbadun rẹ. (Wo: Númérì 13&14; Hébérù 3:15-19)

Wayi o, o wa ṣeeṣe ki o jẹ wipe iwọ naa ti n ranmu kiri laye yi, ti o ko si le sọ wipe o ti figbakanri ni iriri isinmi ati itẹlọrun ni awọn ibi ti o ti gbe tabi lori awọn iṣẹ tabi okowo ti o ti ṣe. O nilo lati kọkọ gba wipe o ti n ranmu laye ati wipe opin gbọdọ de ba iranmu rẹ. Ekeji, o nilo lati gbadura si Ọlọrun pe ki O ṣaanu fun ọ, ki O si fi opin si ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu iriri iranmu ninu aye rẹ, nkan yowu ti o le fa a wa sori aye rẹ. Yoo si da ọ lohun, yoo dari rẹ si ibi isinmi, yoo si tun fi ẹṣẹ rẹ mulẹ nibẹ.

Iwọ naa wo nkan ti a sọ ninu bibeli nipa ohun ti Ọlọrun ṣe fun awọn kan ti awọn naa ti fi igbakanri n ranmu kiri laye ri:

“Wọn n rin kaakiri ni aṣalẹ nibi ti ọna ko si: wọn ko ri ilu lati maa gbe. Ebi pa wọn, oungbẹ si gbẹ wọn, o rẹ ọkan wọn ninu wọn. Nigba naa, ni wọn kigbe pe Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ wọn. O si mu wọn jade nipa ọna titọ, ki wọn ki o le lọ si ilu ti wọn o maa gbe.” (Sáàmù 107:4-7)

Njẹ o ri bayẹn? Nigba ti awọn eniyan wọnyi ke pe Oluwa ninu iṣoro wọn, O da wọn lohun, O si tun tu wọn silẹ. Lọna wo? Nipa didari wọn si ibi isinmi ni. Yoo si ṣe ohun kanna fun ọ tabi fun ẹni naa ti o sunmọ ọ ti si n gbe igbe aye iranmu kiri, ti iwọ naa yoo ba kigbe si fun iranlọwọ. Ki wa ni o n duro de? Kigbe si fun iranlọwọ nibayi-bayi, o si dandan ki o ni ẹri ti o ga lati jẹ, lati ọsẹ yi lọ.

Ki ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

2 thoughts on “Àkórí: Ǹjẹ́ o ti ń rànmù kiri bí? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 19, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 3”

  1. Babarinde Oluwadunsin

    Omo Olorun ni lo lati mu Olorun ni Pataki,,nitori oun nikan lo Le fun wa ni isinmi. Nigbati abs ranmu kiri gba adura si Olorun yoo si gbawa.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *