Àkórí: Má ṣe gbàgbé Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá rẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀wàrà 27, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 26
Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu ti o so oṣu Ọ̀wàrà ati oṣu Belu 2024 pọ mọ ara wọn. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun tu ọ ninu nibikbi ti ara ti le ma ni ọ, bi o ti ṣe n lọ lọsẹ yi ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi, ki O si tun kun ọkan rẹ pẹlu ayọ akunwọsilẹ. Amin.
Ọrọ iyanju mi si ọ, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ yi, ni a mu lati ara awọn nkan diẹ ti Ọlọrun tipasẹ Wolii Aisaya ba wa sọ, eyi ti o si ka bayi:
“Emi ni, ani emi ni ẹni ti n tu yin ninu: ta ni iwọ ti iwọ o fi bẹru eniyan ti yoo ku, ati ọmọ eniyan ti a ṣe bi koriko. Ti iwọ si gbagbe Oluwa Ẹlẹdaa rẹ ti o ti na awọn ọrun, ti o si ti fi ipilẹ aye sọlẹ; ti iwọ si ti n bẹru nigba gbogbo lojoojumọ nitori irunu aninilara ni, bi ẹni pe o ti mura lati panirun? Nibo ni irunu aninilara ha gbe wa? Onde ti a ti ṣi nipo yara ki a baa le tu u silẹ, ati ki o ma baa ku sinu iho, tabi ki ounjẹ rẹ ma baa tan.” (Àìsáyà 51:12-14)
Ki ni nkan akọkọ ti Ọlọrun kede si wa nibiyi? Oun naa ni pe Oun ni olutunu wa. Eyi jasi pe ti ko ba ṣe pe O ba tu wa ninu, ẹnikẹni ko le tu wa ninu. Eyi si ni alaye fun bi ọpọ ni orilẹ-ede wa loni, pẹlu awọn Kiristiẹni naa, ṣe n sorikọ, ti ọkan wọn si n poruru. Eyi ti wọn yoo fi ma a wo Ọlọrun fun itunu, nṣe ni wọn n wo awọn eniyan kan tabi ijọba fun itunu. Niwọn igba ti wọn ba si n ṣe eyi, wọn ko ni lailai ni iriri itunu otitọ lori gbogbo awọn nkan ti o n lepa lati dojuti wọn tabi lati pa wọn run.
Nkan ẹkeji ti Ọlọrun sọ fun wa nipasẹ Aisaya, bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹsẹ yẹn, ni pe aṣiṣe ni lati fi ààyè gba ibẹru eniyan lati jẹ ki a gbagbe pe Oun ni Ọlọrun ati Ẹlẹdaa wa. Lotitọ, a le ni oniruuru awọn eniyan ni ayika wa ti wọn ti mura tan lati pọn wa loju tabi pa wa run. Ijọba ilẹ wa gan le ma ni nkan miran ti o n ṣe ju ki o ma pa wa lara ati ki o ma mu aye le fun wa lọ.
Sibẹsibẹ, a ko gbọdọ gbagbe pe ijọba wa ko ki i ṣe ẹlẹdaa wa, bẹẹ si ni awọn ọdaran ti o wa ni ilẹ wa naa ko ki i ṣe ẹlẹdaa wa. Ọlọrun ni Ẹlẹdaa wa. Nitorina, a ko gbọdọ fi aye gba ohunkohun ti ijọba wa tabi ti awọn ọdaran ti o wa ni awujọ wa le e ma a ṣe lati jẹ ki a ma fi igba gbogbo gbe ninu ibẹru ati ifoya. Idi si ni pe Ọlọrun Ẹlẹdaa wa yoo tu wa lara lotitọ, yoo si tun yi ohun gbogbo ti a n ṣe lodi si wa pada si rere fun wa.
Iwọ naa tun wo nkan ti Ọlọrun sọ fun wa lati ipasẹ Aisaya lẹẹkan si. O sọ wipe bi o tilẹ jẹ wipe awọn aninilara ti mura tan lati pa wa run, Oun yoo sọ ete-ibi wọn si wa di asan. Nitorina, bi a tilẹ n duro lati ri nkan ti ete wọn lati pọn wa loju yoo ja mọ, a ko ni ri nkankan.
Lafikun, Ọlọrun sọ wipe Oun ti n ran irawọ si awọn ti ọrọ orilẹ-ede yi ti fi sinu atimọle, ti wọn ko si le tọju ara wọn ati ẹbi wọn bi o ti ṣe yẹ. O sọ wipe wọn ko ni ku sinu ipo ti wọn wa yi. Idi si nipe Oun yoo gba wọn, O yoo si tun tẹ ebi ti o n pa wọn lọrun.
Njẹ o wa gba awọn nkan wọnyi gbọ bi? Ṣe o gbagbọ pe Ọlọrun yoo tu gbogbo wa ni orilẹ-ede yi ti ara n ni, ti a si n woju rẹ fun iranlọwọ ninu lotitọ? Ṣe o gbagbọ pe, gẹgẹ bi Ẹlẹdaa wa, O ni agbara lati fooro gbogbo awọn ti o n pọ wọn loju ati ti o n ṣiṣẹ lati fi wa sinu tubu iṣẹ ati idojuti titi lailai?
Ti o ba gba awọn nkan wọnyi gbọ, nṣe ni ki o ya fi opin si gbogbo ibẹru rẹ. Bẹẹni, fi opin si ibẹru pe iwọ ati ile rẹ yoo ku sinu ebi tabi pe o ko ni i le fun awọn ọmọ rẹ ni ẹkọ ti o ye kooro tabi pe nṣe ni iwọ yoo ku gẹgẹ bi ayalegbe tabi pe o ko ni lailai tẹgbẹ laye. Idi si ni pe Ọlọrun Ẹlẹdaa rẹ yoo tu ọ ninu lọna ti o peye. Eyi yoo si jẹ ki o gbagbe gbogbo awọn ọjọ inira ati ibanujẹ rẹ. Bẹẹ si ni yoo ri, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)



