Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lai-lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀wàrà 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ya aye rẹ ya ohunkohun ti o ba n di ọ lọwọ lati so eso lọpọlọpọ pẹlu ọrọ Ọlọrun, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ti ṣe ri ninu Iwe mimọ, ko to lati kan gbọ ọrọ Ọlọrun; o tun ṣe pataki ki a tun so eso nkan ti ọrọ ti a gbo n sọrọ nipa. Aijẹbẹ, gbogbo nkan ti a n gbọ yoo kan ṣofo danu lasan ni. Ọna kan pataki lati so eso nkan ti ọrọ ti a n gbọ n sọrọ nipa ni ki a gbe igbesẹ lori nkan ti ọrọ naa sọ. Sibẹsibẹ, ọpọ awọn ẹni ti o n gbọ ọrọ Ọlọrun ni ko ki i ṣiṣẹ le lori. Bibeli tilẹ sọrọ nipa awọn kan ti wọn ma n fi igba gbogbo kẹkọ ṣugbọn ti wọn ko si pàpà ni imọ otitọ. Ki ni idi ti eyi ṣe ri bẹ? Ki ni idi ti ẹnikan yoo fi ma fi igba gbogbo wa fun ipade ijọ, ti ko si tun ni ni imọ otitọ nkan ti Ọlọrun n ba a sọ, ka ma tilẹ ti sọ wipe ki o ṣiṣe le nkan ti a n ba a sọ? (2Tímótì 3:7)
Ki a ma deena pa ẹnu, gẹgẹ bi Oluwa ti fi han nipasẹ ọkan lara awọn owe rẹ, ọkan lara idi ti eyi fi ri bẹẹ ni pe awọn eniyan ma n jẹ ki ẹ̀gún fun nkan ti wọn n gbọ pa. Ki wa si ni awọn ẹgun ti Oluwa n sọrọ nipa? Nkan ti O sọ nipa wọn ni eyi: “Awọn wọnyi ni awọn ti a fun saarin ẹ̀gún: awọn ti o gbọ ọrọ naa. Aniyan aye, ati itanjẹ ọrọ, ati ifẹkufẹẹ ohun miiran si bọ sinu wọn, wọn fun ọrọ naa pa, bẹẹ ni o si jẹ alai-leso.” (Máàkù 4:18-19)
Njẹ o ri bayẹn? Lara awọn ẹgun ti o ma n fun ọrọ Ọlọrun pa ninu aye awọn eniyan aniyan. Eyi jasi pe, nigba ti awọn eniyan ba fi ara wọn jin lati ma ṣaniyan lori awọn iṣoro wọn, dipo ti wọn yoo fi maa ṣe aṣaro lori nkan ti Ọlọrun n ba wọn sọ, o di dandan ki awọn aniyan wọn wọnyi fun ọrọ ti wọn ti gba pa ti o ba to asiko kan. Nitorina, ọrọ naa ko ni ṣiṣẹ ninu aye wọn. O si wa ṣeni laanu pe, a ri ọpọ eniyan ti o n wa fun ipade ijọ, ti wọn si n fi gbogbo asiko wọn ṣe aniyan lori awọn iṣoro wọn dipo ti wọn yoo fi ma tẹtẹ si ọrọ Ọlọrun ti a n kọ wọn. Bawo wa ni irufẹ awọn wọnyi ṣe fẹ so eso rere pẹlu ọrọ Ọlọrun?
Ni afikun, Oluwa sọ fun wa pe itanjẹ ọrọ ati ilepa awọn eniyan naa tun wa lara awọn nkan ti o ma n fun ọrọ Ọlọrun pa ninu aye awọn eniyan. Eyi jasi pe nigba ti awọn eniyan ba ti fẹ fi tipa-tipa ni owo, ipo, iyi tabi igbadun, bi wọn tilẹ n gbọ ọrọ Ọlọrun, ọwọ wọn yoo ti kun debi pe wọn ko ni ri aye lati ṣe aṣaro lori ọrọ rẹ ati lati lo ninu aye wọn. Nitorina, ọrọ naa ko ni i le ṣiṣẹ ninu aye wọn, ki o si yi ati awọn ati igba wọn pada.
Idi niyi, bi mo ti ṣe sọ siwaju, ti a fi ri ọpọ eniyan ti o n wa si ipade ijọ lọsọọsẹ, ti aye wọn ko si yipada. Bẹẹni, idi niyi ti ọpọ fi n gbọ ọrọ Ọlọrun lọsọọsẹ ninu awọn ipade ijọ wọn, ti wọn si tun n gbe igbesẹ omugọ lori aye wọn, igbeyawo wọn, okowo wọn ati bẹẹ-bẹẹ lọ. Wọn ko jẹ ki ọrọ Ọlọrun ko ṣiṣẹ ninu aye wọn, ki o si sọ wọn da ẹni ti Ọlọrun fẹ ki wọn da. Dipo eyi, nṣe ni wọn n fun ọrọ naa pa nipasẹ awọn ibaṣepọ aimọ, ilepa ọrọ, ipo ati iyi ati itara fun aye-jijẹ.
Ṣe ki a wa pa gbogbo awọn ibaṣepọ wa ti sẹgbẹ kan nitoripe a fẹ wa pẹlu Jesu bi? Rara o! Ọrọ Ọlọrun ko pa a lasẹ fun wa pe ki a ṣe bẹ ẹ. Amọ ṣa o, o pa a laṣẹ fun wa lati ya gbogbo awọn ibaṣepọ wa si mimọ. Eyi jasi pe, o fẹ ki a ṣe amojuto awọn ibaṣepọ wa lọna ti o fi ogo fun Ọlọrun. Ibaṣepọ pẹlu ẹnikẹni, wayi, ti ko ba ti fi ogo fun Ọlọrun gbọdọ jẹ kikọ-silẹ fun wa. Aijẹbẹ, ibaṣepọ naa ko ni dẹkun lati ma fun ọrọ Ọlọrun pa ninu aye wa.
Lafikun, ṣe ko wa tọna fun wa ni lati ni ọrọ, lati wa ni ipo giga tabi lati jẹ gbajumọ? Rara o, eyi ko buru o. Amọ ti a ba fi aye gba ọkankan ninu awọn nkan wọnyi lati jẹ akọkọ ninu aye wa, ko si bi ọrọ Ọlọrun yoo ti le so eso ninu aye wa bi o ti tọ. Bawo wa ni ti faaji? Ṣe Ọlọrun ko fẹ ki jẹgbadun ara wa ni? O kuku fẹ ki a jẹgbadun ara wa. Amọ ti a ba wa sọ ohun gbogbo nipa aye yi di ọrọ faaji, ki a si bẹrẹ si ni ro wipe nkan yoo ṣe wa, ti a ko ba lọ si awọn ode kan, wo awọn sinima kan tabi jẹ awọn nkan adidun kan, ko si bi ọrọ Ọlọrun yoo ti ṣe so eso ninu aye wa bi o ti ọ — yoo ti di fifun pa.
Nitorina, ti isesorere rẹ pẹlu ọrọ Ọlọrun ti o n gbọ ba jẹ ọ logun rara, nṣe ni ki o ṣe idamọ ohunkohun ti o le ma fun ọrọ yi pa ninu ayẹ rẹ, ki o si mojuto lẹsẹkẹsẹ. Aijẹbẹ, bi o tilẹ n tẹti si ọrọ Ọlọrun titi Jesu yoo fi de, aye rẹ ko ni yipada lati da ohun ti Ọlọrun fẹ ki o da. Ṣe nkan ti o wa fẹ niyẹn bi? Mo gbadura pe ki o gba okun lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun lati bẹrẹ si ni ṣe ohun ti o tọ lati iṣẹju yi lọ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ ti o ga.
Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
