Wákàtí kan péré! | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 30, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 13, No. 48
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so awọn oṣu Ẹrẹna ati Igbe ọdun 2025 papọ. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma fi ojoojumọ fun ọkan rẹ ni okun lati ṣe ohun gbogbo ti o tọ fun ọ lati ṣe lati le wa ni mimọ ati ailẹbi ni igba ti Jesu Oluwa wa ba de. Amin.
Ki Jesu Oluwa wa, nigba ti asiko rẹ to, ma ba a fa sẹyin kuro ninu kiku lori igi agbelebu fun irapada ọmọniyan, O nilo lati ṣe nkankan. Ki si nkan naa? O nilo lati gbadura. O wa nilo to iwọn asiko melo lati gbadura? Ko nilo odidi ọsẹ kan tabi odidi ọjọ kan lati gbadura. Wakati kan pere ni O nilo lati gbadura.
Bawo ni a ṣe wa mọ wipe wakati kan pere ni Jesu nilo ni asiko yi lati gbadura? A mọ nipasẹ Iwe mimọ. Bi akọsilẹ naa ṣe lọ, bi O ti ri wipe asiko Oun ti de tan, O mu mẹta lara awọn ọmọ-ẹyin rẹ, Peteru, Jemisi ati Johanu, lọwọ pẹlu rẹ lati lọ gbadura ni ibi kan ti a n pe ni Gẹtisimani. Ṣugbọn dipo ti wọn yoo fi ma gbaudra pẹlu rẹ, nṣe ni wọn n sun. Idi si ni pe o ti rẹ wọn gidigidi. Iwọ naa wo nkan ti bibeli sọ nipa awọn nkan wọnyi:
“O si wa, o ba wọn, wọn n sun, o si wi fun Peteru pe, Simoni, iwọ n sun? Iwọ ko le sọna ni wakati kan? Ẹ maa ṣọna, ki ẹ si maa gbadura, ki ẹ ma baa bọ sinu idanwo. Loootọ, ni ẹmi n fẹ, ṣugbọn o ṣe ailera fun ara.” (Máàkù 14:37-38)
Njẹ o ri bayẹn? Iwọn asiko melo ni Jesu woye pe ki awọn ọmọ-ẹyin yi lo lati gbadura pẹlu rẹ? Wakati kan pere! Lotitọ, Jesu le gbadura si Ọlọrun ju wakati kan lọ. Ṣaaju asiko yi, O ti gbadura ni ọpọ igba fun ọpọlọpọ wakati, nigba miran gan fun gbogbo aṣalẹ. Nitorina, ko yan lati gbadura fun wakati kan ni asiko yi nitoripe ko le gbadura fun ọpọlọpọ wakati. Dipo eyi, O yan lati ṣe bẹẹ nitoripe O mọ wipe ọpọlọpọ nkan ni a le yipada tabi ṣe pẹlu adura wa, bi ko tilẹ ju wakati kan lọ.
Wayi o, nitori adura wakati kan ti O gba si Ọlọrun fun ọkan rẹ ni akoko okunkun yi, O gba okun ati igboya ti o peye lati ku lori igi agbelebu ati lati gba irapada ayeraye fun wa. Bawo wa ni ti awọn ọmọ-ẹyin rẹ ti ko le darapọ mọ lati gbadura fun ara wọn fun wakati kan pere? Gbogbo wọn patapata ni wọn ṣẹ ẹ, ti wọn si tun kọ ọ silẹ. Ti ko ba wa jẹ wipe O ti gbadura fun wọn tẹlẹ pe ki igbagbọ wọn ma ṣe yẹ ni, ibi ti opin ko ba ti ba ibaṣepọ wọn pẹlu rẹ niyẹn.
Ki wa ni eyi n kọ wa gan? Oun naa ni pe a ko le sọ bi adura ti a ba gba tọkantọkan ṣe le ṣiṣẹ fun wa tabi fun awọn ọmọ eniyan si, bi o tilẹ jẹ wipe fun wakati kan pere ni. Ki a tilẹ sọ otitọ, adura ìṣẹ́jú kan gan an le jẹ iyatọ laarin iye ati iku, aṣeyọri ati ikuna, iṣẹgun ati ijakulẹ. Odiwọn asiko wo ni o gba Dafidi lati gbadura pe ki Ọlọrun sọ imọ Ahitofeli di asan? Boya ni o gba to iṣẹju kan lọ. Ṣibẹṣibẹ, adura naa yi ohun gbogbo nipa ọtẹ ti o fẹ fi opin si pada. Adura naa yọri si iṣẹgun rẹ lori Abusalomu. (Wo: 2Sámúẹ́lì 15:31)
Ṣe mo wa n sọ wipe iṣẹju kan tabi wakati kan pere ni ki o fi ma gbadura bi? Rara o! Ki a sọ otitọ, awọn iṣoro kan wa ti o jẹ wipe o le gba wa ni adura wakati pupọ tabi ọjọ pupọ ki wọn to niyanju. Ṣugbọn ti a ba kẹkọ lati ma fiyesi pe adura wa le yi itan pada, nṣe ni a o bẹrẹ si ni ṣe amulo ti o peye gbogbo asiko ti a ba ni lati gbadura, bi o tilẹ jẹ pe wakati kan pere ni. Adura mi si ni pe ki a kun ọkan wa pẹlu okun ti o peye lati ọdọ Ọlọrun lati ma fi ojoojumọ rin ninu imọlẹ otitọ yi, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)



