Àwọn tó lọ́ra láti kẹ́kọ̀ọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òkúdù 01, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 5
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Krisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu kẹfa ọdun yi, iyẹn oṣu Òkúdù 2025. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun ma a fi ojuoojumọ oṣu naa fun ọ ni okun lati ṣe amulo ti o peye oore-ọfẹ rẹ lati dagbasoke lati jẹ ohun gbogbo ti O fẹ ki o jẹ. Amin.
Ninu iwe awọn Heberu, onkowe yi sọ fun wa pe o ṣeeṣe ki idagbasoke wa ninu ẹmi ba idena pade. Ọkan lara awọn nkan ti o si le jẹ ki eyi waye ni aiṣetan wa lati ṣe akitiyan lati kọ otitọ Ọlọrun, lati ni oye rẹ ati lati ṣe amulo rẹ ninu aye wa. Wo bi o ti ṣe gbe ọrọ naa kalẹ:
“Nipa eyi awa ni ohun pupọ lati sọ, ti o si ṣoro lati tumọ, nitori pe ẹ yigbi ni gbogbọ. Nitori pe bayii o ti yẹ ki ẹ jẹ olukọni, ẹ tun wa ni ẹni ti ẹnikan yoo maa kọ ni ibẹrẹ ipilẹ ẹkọ awọn ọrọ Ọlọrun, ẹ si tun di iru awọn ti o n mu wara, ti wọn ko si fẹ ounjẹ lile.” (Hébérù 5:11-12)
Njẹ o ri bayẹn? Eniyan Ọlọrun yi ni ọpọlọpọ nkan ti o fẹ ba awọn ara ninu Oluwa ti o kọkọ gba lẹta rẹ yi sọ lori igbe aye igbagbọ ninu Kirisiti Jesu. Ṣugbọn o nira fun lati ṣe bẹẹ. Ki ni idi? Idi, gẹgẹ bi o ti ṣe sọ, ni pe wọn lọra lati kẹkọọ. Eyi ko si wa jasi pe wọn ko ni amuyẹ lati kẹkọọ ati lati ni oye nkan ti a n kọ wọn. Dipo bẹẹ, o jasi pe wọn ya ọlẹ ninu ki a kẹkọọ. A tun le sọ wipe eyi tunmọ si pe wọn ko ma ṣe akitiyan ti o nitunmọ kankan lati ni oye nkan ti a n kọ wọn ati lati fi wọn ṣiṣẹ ṣe.
Nitorina, bi eniyan Ọlọrun yi ti ṣe tẹsiwaju lati sọ ninu ẹsẹ bibeli naa, nigba ti o yẹ ki awọn eniyan wọnyi ti di olukọ, nigba ti o yẹ ki wọn ti di ẹni ti o n mojuto awọn ti o ṣẹṣẹ di onigbagbọ, nṣe ni awọn funralara wọn ṣi tun nilo ẹnikan ti yoo ṣẹṣẹ ma tun kọ wọn lẹẹkansi ni awọn nkan ipilẹ ọrọ Ọlọrun. Nigba ti o yẹ ki wọn ti di agbalala ninu ẹmi ti a le fa awọn ọmọ-ọwọ ninu ẹmi le lọwọ fun itọju, awọn funralara wọn si tun n fẹ ki a ma mojuto wọn bi ọmọ-ọwọ. Wa wo irufẹ iforo ti eyi ni lati jẹ fun eniyan Ọlọrun yi ati awọn adari awọn ara ninu Oluwa wọnyi. Bẹẹni, gbiyanju lati ro irufẹ irẹwẹsi ti eyi mu wa sinu ọkan wọn.
O si wa ṣeni laanu pe, loni gan, ẹwẹ, a si tun ri ọpọ awọn eniyan Ọlọrun ti awọn naa ya ọlẹ ninu ki a kọ awọn otitọ ẹmi ati ki a ṣe amulo awọn otitọ naa. Awọn wọnyi n jẹ ki awọn adari ijọ wọn ma kọ wọn ni nkankan naa ṣaaṣaa. Wọn n jẹ ki wọn ma ba wọn wi ṣaaṣaa lori bi wọn ṣe n gbe ile aye wọn ninu ẹtanu, ninu ikorira, ninu imọtara-ẹni-nikan, ninu ifẹkufẹ, ninu igberaga, ninu owu jijẹ ati ninu ainitara fun Ọlọrun. Nitorina, wọn n fa ifasẹyin fun iṣẹ iranṣẹ awọn adari wọn ati ti ijọ wọn – wọn n jẹ ki o nira fun wọn lati le kan si ati bukun fun ọpọ eniyan miran fun Oluwa.
Ki wa ni ki awọn adari ijọ ṣe si irufẹ awọn eniyan wọnyi? Ọna wo ni ki awọn adari gba lati mojuto awọn ti o n fooro ilakaka wọn lati tọ wọn ninu ifẹ Ọlọrun? Ni kukuru, bi onkọwe iwe Heberu ṣe sọ fun wa, nigba ti o ba to asiko kan, wọn yoo dẹkun lati ma tọju awọn ọlẹ-ẹmi onigbagbọ wọnyi bi ìkókó. Bẹẹni, wọn yoo nilo lati bẹrẹ si ni kọ wọn ni awọn nkan ti wọn ko fẹ kọ ati lati dẹkun lati ma mojuto wọn bi ọmọ-ọwọ ninu ẹmi nipa mimu wọn ṣe awọn nkan ti wọn ko fẹ ṣe funra wọn. (Wo: Hébérù 6:1-3)
Ṣe eyi yoo wa mu inu irufẹ awọn onigbagbọ wọnyi dun bi? Rara! Ki a tilẹ sọ otitọ, o le jẹ ki awọn miran lara wọn dẹkun patapata lati ma wa sinu ipade awọn ọmọ Ọlọrun. Amọ, yala o mu inu wọn dun tabi ko mu inu wọn dun, nkan ti o gbọdọ jẹ ṣiṣẹ gbọdọ jẹ ṣiṣe, ki awọn wọnyi ma ba a le di idagbasoke awọn ijọ wọn lọwọ mọ. Nitorina, ti o ba ti jẹ ọmọ Ọlọrun fun ọdun meji tabi ju bẹẹ lọ, ti o si tun wa kọ lati dagbasoke ninu igbagbọ rẹ ki o ba a le di ẹni ti adari ijọ rẹ le fi ọkan tan pẹlu oniruuru ojuṣe, o lọra lati kẹkọọ niyẹn, o si tun ya ọlẹ ninu ẹmi. Ti o ba si tẹsiwaju lati ri bi eleyi, ti o n fa ifasẹyin fun awọn adari ijọ rẹ, o le ma pẹ ti awọn naa yoo fi bẹrẹ si ni yẹra fun ọ, ki o ba a le dẹkun lati ma jẹ ìkókó ninu ẹmi. Eyi ko si le jẹ nkan ti yoo ba ọ lara mu.
Nitorina, sọji ki o to pẹ ju, ki o si bẹrẹ si ni gbadura si Ọlọrun pe ki O fun ọ ni itara ati okun ti o peye lati bẹrẹ si ni ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ lati dadasoke ninu ẹmi lọna ti o peye. Aijẹbẹ, ko ni pẹ rara ti awọn ti wọn di atunbi lẹyin rẹ yoo fi di olukọ rẹ ninu Oluwa.
Kí o ní oṣù Òkúdù 2025 alárinrin.
Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)


